ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 1 ojú ìwé 10-ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 8
  • Ìkéde Méjì Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkéde Méjì Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ihin-iṣẹ Lati Ọrun Wá
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • A San Èrè-Ẹ̀san fún Wọn fún Rírìn Láìlẹ́bi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Wọ́n Bí Ẹni Tó Máa Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 1 ojú ìwé 10-ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 8
Gébúrẹ́lì fara han Sekaráyà; Èlísábẹ́tì lóyún

ORÍ 1

Ìkéde Méjì Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

LÚÙKÙ 1:5-33

  • ÁŃGẸ́LÌ GÉBÚRẸ́LÌ SỌ TẸ́LẸ̀ PÉ WỌ́N MÁA BÍ JÒHÁNÙ ARINIBỌMI

  • GÉBÚRẸ́LÌ SỌ FÚN MÀRÍÀ PÉ Ó MÁA BÍ JÉSÙ

Ọlọ́run ló fi Bíbélì jíǹkí wa, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló sì wà nínú ẹ̀. Ìdí tó fi fún wa ni pé ó fẹ́ kó máa tọ́ wa sọ́nà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká wo ìkéde méjì pàtàkì tí áńgẹ́lì kan ṣe ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn. Gébúrẹ́lì lorúkọ áńgẹ́lì náà, òun ni ẹni “tó ń dúró nítòsí, níwájú Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:19) Báwo ni nǹkan ṣe rí lára àwọn tí áńgẹ́lì náà jíṣẹ́ pàtàkì yẹn fún?

Nǹkan bí ọdún 3 Ṣ.S.K. ni Gébúrẹ́lì jíṣẹ́ àkọ́kọ́. Ibo ló ti jíṣẹ́ náà? Agbègbè Jùdíà ni, ó ṣeé ṣe kó má jìnnà sí Jerúsálẹ́mù. Ibẹ̀ ni àlùfáà Jèhófà kan tó ń jẹ́ Sekaráyà ń gbé. Òun àti Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ̀ ti dàgbà, wọn ò sì rọ́mọ bí. Nígbà tó kan Sekaráyà láti lọ ṣiṣẹ́ àlùfáà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, Gébúrẹ́lì fara hàn án lójijì lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ tùràrí.

Ẹ̀rù ba Sekaráyà, ó sì yẹ kẹ́rù bà á lóòótọ́. Àmọ́ áńgẹ́lì náà fi í lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Má bẹ̀rù, Sekaráyà, torí a ti ṣojúure sí ọ, a sì ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan fún ọ, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jòhánù.” Gébúrẹ́lì fi kún un pé “ẹni ńlá ló máa jẹ́ lójú Jèhófà,” ó sì máa “ṣètò àwọn èèyàn tí a ti múra sílẹ̀ fún Jèhófà.”—Lúùkù 1:13-17.

Sekaráyà ń fọwọ́ ṣàpèjúwe

Ó ṣòro fún Sekaráyà láti gba ọ̀rọ̀ yẹn gbọ́. Kí ló fà á? Ohun tó fà á ni pé òun àti Èlísábẹ́tì ti dàgbà. Torí náà, Gébúrẹ́lì sọ fún un pé: “O ò ní lè sọ̀rọ̀, wàá sì ya odi títí di ọjọ́ tí àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, torí pé o ò gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́.”—Lúùkù 1:20.

Ní gbogbo àkókò yẹn, àwọn tó wà ní ìta tẹ́ńpìlì ń wò ó pé kí ló dé tí Sekaráyà fi pẹ́ tóyẹn. Nígbà tó yá, ó jáde, àmọ́ kò lè sọ̀rọ̀. Ó kàn ń fọwọ́ ṣàpèjúwe ni. Ó ṣe kedere pé ó ti rí nǹkan tó yà á lẹ́nu nínú tẹ́ńpìlì.

Nígbà tí Sekaráyà parí iṣẹ́ rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì, ó pa dà sílé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Èlísábẹ́tì lóyún. Oṣù márùn-ún ni Èlísábẹ́tì fi wà nínú ilé, tí ò jẹ́ káwọn èèyàn rí òun, bó ṣe ń retí ìgbà tóun máa bímọ.

Gébúrẹ́lì fara han Màríà

Gébúrẹ́lì wá lọ jíṣẹ́ kejì. Ta ló jẹ́ ẹ fún? Ọ̀dọ́bìnrin kan tí kò tíì lọ́kọ ni, Màríà lorúkọ ẹ̀, ìlú Násárẹ́tì lágbègbè Gálílì ló sì ń gbé. Kí ni áńgẹ́lì náà sọ fún un? Ó sọ pé: “O ti rí ojúure Ọlọ́run. Wò ó! o máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.” Ó wá fi kún un pé: “Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá, wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, . . . ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”—Lúùkù 1:30-33.

Wo bí Gébúrẹ́lì ṣe máa mọyì àǹfààní tó ní láti lọ jíṣẹ́ méjèèjì yìí. Bá a ṣe ń ka ìtàn Jòhánù àti Jésù, a máa rí ìdí tí àwọn ìkéde méjì yìí fi ṣe pàtàkì gan-an.

  • Ta ni Ọlọ́run rán láti lọ jíṣẹ́ pàtàkì méjì fáwọn èèyàn?

  • Àwọn wo ló jíṣẹ́ méjèèjì náà fún?

  • Kí lo rò pé ó fà á tí ìkéde méjì tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fi ṣòro láti gbà gbọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́