Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
Njẹ Sekaraya, baba Johanu Arinibọmi, ni a sọ di adití ati alaileesọrọ pẹlu, bi ó ti dabi ẹni pe Luuku 1:62 fihan bi?
Awọn kan ti pari èrò pe Sekaraya tun di adití. A kà ninu akọsilẹ Bibeli pe: “Wọn sì sọ orukọ [ọmọ naa] ni Sekaraya, gẹgẹ bi orukọ baba rẹ̀. Iya rẹ̀ si dahun, ó ni, Bẹẹkọ; bikoṣe Johanu ni a o pè é. Wọn sì wí fun un pe, kò sí ọ̀kan ninu awọn ará rẹ̀ ti a ń pe ni orukọ yii. Wọn sì ṣe apẹẹrẹ si baba rẹ̀, bi o ti ń fẹ́ ki a pè é. Ó sì beere wàláà, ó kọ, wi pe, Johanu ni orukọ rẹ̀.”—Luuku 1:59-63.
Bi o ti wu ki o ri, kò sí ohunkohun ninu akọsilẹ yii ti ó sọ ní pàtó pe Sekaraya kò lè gbọran fun sáà akoko kan.
Ni iṣaaju angẹli Geburẹli ti kede bíbọ̀ ìbí ọmọkunrin kan ti yoo pe ni Johanu fun Sekaraya. Ó ṣoro fun Sekaraya arugbo lati gba iyẹn gbọ́. Angẹli naa dahun pada pe: “Sì kiyesi i, iwọ yoo yadi, iwọ ki yoo sì lè fọhun, titi ọjọ naa ti nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹ, nitori iwọ kò gba ọrọ mi gbọ́ ti yoo ṣẹ ni akoko wọn.” (Luuku 1:13, 18-20) Angeli naa sọ pe ọrọ sisọ Sekaraya, ki i ṣe ọrọ gbígbọ́ rẹ̀, ni a o nipa le lori.
Akọsilẹ naa sọ siwaju sii pe: “Nigba ti o sì jade [lati inu ibi mimọ], kò lè fọhun si [awọn eniyan ti wọn ń duro]: wọn sì woye pe o ri ìran ninu tẹmpili: nitori ti ó ń ṣe apẹẹrẹ si wọn, ó sì ya odi.” (Luuku 1:22) Ọrọ Giriiki naa ti a tumọ nihin-in si “yadi” gbé ero jíjẹ́ ẹni ti kò mú hánhán, ni sisọrọ, ni gbígbọ́ràn, tabi mejeeji jade. (Luuku 7:22) Ki ni nipa Sekaraya? Ó dara, gbé ohun ti ó ṣẹlẹ nigba ti a mú un larada yẹwo. “Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọgan, okùn ahọn rẹ̀ sì tú, ó sì sọrọ, ó sì ń yin Ọlọrun.” (Luuku 1:64) Iyẹn lọna ti ó bá ọgbọn mu ṣamọna si oju-iwoye naa pe agbara ati sọrọ Sekaraya nikan ni ailera bá.
Eeṣe, nigba naa ti awọn miiran fi beere ọrọ lọwọ Sekaraya ‘nipa àmì ohun ti ó fẹ́ ki a pe [ọmọ naa]?’ Awọn olutumọ kan tilẹ tú eyi si “ni èdè àmì” tabi “ni lilo èdè alámì.”
Sekaraya, ẹni ti ó ti jẹ́ alaileesọrọ lati akoko ikede angẹli naa, ni a maa ń fagbara mu niye igba lati lo ifaraṣapejuwe, iru èdè alámì kan, lati ṣalaye araarẹ̀. Fun apẹẹrẹ, ó “ń ṣe apẹẹrẹ si” awọn wọnni ti wọn wà ninu tẹmpili. (Luuku 1:21, 22) Nigba ti ó beere fun wàláà nikẹhin, ó gbọdọ ti lo awọn àmì tabi ifaraṣapejuwe. (Luuku 1:63) Ó ṣeeṣe, nigba naa, pe awọn wọnni ti wọn yí i ka laaarin akoko aileesọrọ rẹ̀ ni wọn tún ni ìtẹ̀sí lati lo ifaraṣapejuwe.
Bi o ti wu ki o ri, alaye ti ó ṣeeṣe ju fun awọn àmì ti a mẹnukan ni Luuku 1:62 wà. Elisabẹti ṣẹṣẹ sọ èrò rẹ̀ nipa orukọ ọmọkunrin rẹ̀ ni. Nitori naa, laini ta kò ó, wọn wulẹ lè ti gbé igbesẹ bibojumu ti ó kan ti gbigba ipinnu ọkọ rẹ̀. Wọn lè ṣe iyẹn pẹlu mími ori lasan tabi àmì ifaraṣapejuwe. Otitọ naa pe wọn kò kọ ibeere wọn silẹ fun Sekaraya lati kà tilẹ lè jẹ́ ẹ̀rí pe ó ti gbọ́ awọn ọrọ iyawo rẹ̀. Nipa bayii, mími ori lasan tabi àmì jijọra kan ti a ṣe lè ni ipa naa pe, ‘Ó dara, gbogbo wa (ati iwọ naa, Sekaraya) gbọ́ idamọran rẹ̀, ṣugbọn ki ni ipinnu rẹ ikẹhin nipa orukọ ọmọ naa?’
Ati lọgan lẹhin naa iṣẹ iyanu miiran ṣẹlẹ, tí ó yi ipo naa pada. “Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọn rẹ̀ sì tú, ó sì sọrọ.” (Luuku 1:64) Kò si idi fun mimẹnukan ìgbọ́ràn rẹ̀ bi a kò bá ti nipa lori iyẹn.