Keresimesi—Eeṣe Ti Ó Fi Gbajúmọ̀ Tobẹẹ ni Japan?
IGBAGBỌ ninu Baba Keresimesi jinlẹ laaarin awọn ọmọde ni orilẹ-ede Japan onisin Buddha ati Shinto. Ni 1989, awọn ọmọde ni Japan kọ 160,000 lẹta si Santa World ni Sweden. Kò sí orilẹ-ede miiran ti ó fi eyi ti ó pọju bẹẹ lọ ranṣẹ. Wọn kọ awọn lẹta naa ni ireti títẹ́ ifẹ ọkàn wọn lọrun, ìbáàjẹ́ “Computer Ayaworan” ti ọmọde fi nṣere tí iye rẹ̀ jẹ́ 18,000-yen ($136, owo U.S.) tabi fídíò eré idaraya ti o ṣee gbé kiri ti iye rẹ̀ jẹ́ 12,500-yen ($95, owo U.S.).
Fun awọn ọdọmọbinrin ara Japan, ìbẹ́yà keji rode ni Aisun ọjọ Keresimesi ni itumọ akanṣe. Iwe irohin Mainichi Daily News sọ pe, “Gẹgẹ bi ìwádìíwò kan nipa awọn ọdọbinrin ti fihan, 38 ipin ninu ọgọrun-un sọ pe awọn ti wewee fun Aisun ọjọ Keresimesi ni oṣu kan ṣaaju.” Awọn ọdọkunrin ni awọn ète ìdákọ́ńkọ́ ni fifẹ lati wà pẹlu ọrẹbinrin wọn ni Aisun ọjọ Keresimesi. “Èrò rere kan ni lati gbadura ni iparọrọ pẹlu ọrẹbinrin rẹ,” ni iwe irohin kan fun awọn ọdọkunrin damọran. “Ẹ ṣe e ni ibikan ti ó gbayì. Àjọṣepọ̀ yin yoo tete tubọ di timọtimọ sii.”
Awọn baálé ilé ní Japan tun reti lati kàn sí awọn agbara idán kan nipa awọn aṣa-atọwọdọwọ Keresimesi wọn ti ríra “kéèkì kan ti a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́” nigba ti wọn ba npada lọ si ile lati ibi iṣẹ. Kiko ipa Santa Claus ni wọn lero pe ó jẹ́ ìsanpadà fun ṣíṣàìnáání idile ni iyoku ọdun.
Nitootọ, Keresimesi ti fi gbòǹgbò mulẹ laaarin awọn ara ilẹ Japan ti kii ṣe Kristẹni. Niti tootọ, ipin 78 ninu ọgọrun-un awọn ti ile itaja mú un-fúnraàrẹ kan wadiiwo wi pe awọn ṣe ohun akanṣe kan fun Keresimesi. Iṣiro ifiwera naa pọ̀ yamùrá ni orilẹ-ede kan nibi ti kiki ipin 1 ninu ọgọrun-un iye eniyan ilu ti sọ pe awọn gbagbọ ninu isin Kristẹni. Bi wọn ti nfẹnu lasan sọ pe awọn jẹ́ onisin Buddha tabi Shinto, ara dẹ̀ wọn gan-an ni gbigbadun họlide “Kristẹni.” Ninu iwe ọjọ ati oṣu kíka rẹ̀, papọ pẹlu awọn ajọdun ilẹ Japan, Ojubọ Shinto Ise olokiki naa fi December 25 si itolẹsẹẹsẹ gẹgẹ bii “ọjọ ìbí Kristi.” Awọn iran ibi ti awọn ti kii ṣe Kristẹni ti kun fun ariya lakooko Keresimesi, bi o ti wu ki o ri, gbé ibeere naa dide pe:
Ayẹyẹ Ti Taa ni Keresimesi?
Iwe atumọ ede naa Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary tumọ Keresimesi bii “ọjọ iranti isin Kristẹni kan ní December 25 . . . ti ó nṣayajọ ọjọ ìbí Kristi.” A ti foju wo o gẹgẹ bi akoko fun “awọn Kristẹni” lati “ṣọkan ninu imọlara ayọ wọn lori ọjọ́ ìbí Kristi.”
Awọn ti wọn nṣayẹyẹ Keresimesi gẹgẹ bi ajọdun isin kan patapata lè ri awọn ti wọn yi ìlò ọjọ naa pada si ti ayé pẹlu ṣiṣariya ati fifunni lẹbun gẹgẹ bi amunibinu ati alaibọwọ fun ohun mimọ paapaa. “Ni Japan a ti wá ní eyi ti o buru julọ ninu iṣowo alaimọra: kò si Kristi,” ni ọmọ ilẹ America kan ti ngbe ni Japan kọ. Omiran kọwe nipa Keresimesi ilẹ Japan pe, “Ni oju awọn ará Iwọ-oorun, kii ṣe tolotolo [eyi ti a kii saba ri ni awọn ọja ilẹ Japan] ni o di eyi ti a fẹ́kù, ṣugbọn eyi ti o ṣe pataki julọ ninu awọn eroja, ẹmi rẹ̀.”
Nigba naa, ki ni ẹmi Keresimesi? O ha jẹ́ ayika isin ṣọọṣi kan pẹlu awọn orin Keresimesi, igi Keresimesi, ati awọn abẹla rẹ̀, eyi ti ọpọlọpọ nlo wọn fun irin ajo kanṣoṣo wọn lọdọọdun si ṣọọṣi bi? Tabi o ha jẹ́ ifẹ, imoriya rere naa, ati ẹbun fifunni naa ni ó nsun ọpọlọpọ lati jẹ́ ọlawọ bi? O ha jẹ ipo iparọrọ ti o gbode ni oju ogun bi awọn jagunjagun ti kiyesi awọn ọjọ melookan ti “alaafia lori ilẹ-aye” bi?
Lọna yiyanilẹnu, ẹmi Keresimesi naa saba maa nkuna lati mu alaafia wá ani si inu ile. Ni ibamu pẹlu iwadiiwo 1987 kan ni England, a fojubu u pe ‘ogun abẹle’ yoo bẹ́ silẹ ninu ipin 70 ninu ọgọrun-un ile awọn ara Gẹẹsi lakooko Keresimesi ni ọdun yẹn. Ìjà jíjà lori owo yoo jẹ́ lajori okunfa naa. Ọti amuju ati ṣiṣai ṣe ojuṣe ẹni ninu idile pẹlu nṣamọna si ìjà.
“Mo nṣe kayeefi bi a kò ba ti npadanu ohun kan nipa itumọ tootọ ti Keresimesi,” ni ara Iwọ-oorun kan ti ngbe ni Japan ẹni ti o bẹ ile wò ni akoko Keresimesi lẹnu aipẹ yii wí. “Ni gbogbo Dec. 25, mo nimọlara iru ifojusọna kan naa lati pada si iru Keresimesi alaṣa ìgbà atijọ ọlọ́jọ́ pipẹ yẹn—ayẹyẹ oloriṣa ti o nṣaṣeyẹ opin ìgbà otutu nipa jijọsin awọn igi ati ṣiṣe awọn ariya alariwo. A sì ni gbogbo awọn idẹkun oloriṣa naa—awọn igi àfòmọ́, igi Keresimesi, igi fir ati bẹẹ bẹẹ lọ—ṣugbọn lọna kan ṣaa Keresimesi kò rí bakan naa mọ́ lati ìgbà ti awọn Kristẹni ti fipa gba a ti wọn sì yi i pada si ajọdun isin kan.”
Lọna ti kò ṣee sẹ́, Keresimesi jẹ́ họlide oloriṣa kan. Awọn Kristẹni ijimiji kò ṣe ayẹyẹ rẹ̀ “nitori pe wọn ka ayẹyẹ ìbí ẹnikẹni si aṣa oloriṣa kan,” ni The World Book Encyclopedia sọ. Awọn ajọdun oloriṣa Saturnalia ati Ọdun Titun ni ó jẹ́ orisun ariya ṣiṣe ati iṣepaṣipaarọ awọn ẹbun.
Bi Keresimesi ni pataki ba jẹ́ oloriṣa, awọn ojulowo Kristẹni gbọdọ beere ibeere naa, Keresimesi ha wà fun awọn Kristẹni bi? Ẹ jẹ ki a wo ohun ti Bibeli sọ nipa ayẹyẹ ọjọ ìbí Kristi.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Ipilẹṣẹ Ayẹyẹ Keresimesi
Bi o tilẹ jẹ pe awọn kulẹkulẹ bi o ṣe ri gan-an ni o ti sọnu saaarin awọn ohun ìgbà laelae, awọn itọkasi wà pe ni 336 C.E., iru Keresimesi kan ni awọn ṣọọṣi Roomu nṣayẹyẹ rẹ̀. “Ọjọ Keresimesi ni a fi si December 25 pẹlu ète kan,” ni The New Encyclopædia Britannica ṣalaye, “lati taari ajọdun nla ọlọrun oorun si ipo afiyesi.” Iyẹn jẹ nigba ti awọn oloriṣa kowọnu awọn ariya alariwo lakooko awọn ajọdun mejeeji naa Roman Saturnalia ati ọjọ iranti opin ìgbà otutu ti Celtic ati Germany. The New Caxton Encyclopedia sọ pe “awọn Ṣọọṣi lo anfaani naa lati sọ ajọdun naa di ti isin Kristẹni.”