ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 12/15 ojú ìwé 4-7
  • Orísun Kérésìmesì Òde Òní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Orísun Kérésìmesì Òde Òní
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpìlẹ̀ Tí Ó Wọ́
  • Ìwà Ìbàjẹ́ Wọlé
  • Ọdún Àṣekáyé
  • Àtúnṣe Kérésìmesì
  • “Ẹ Fẹ́ Òtítọ́ Àti Àlàáfíà”
  • Keresimesi—Eeṣe Ti Ó Fi Gbajúmọ̀ Tobẹẹ ni Japan?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Kérésìmesì—Èé Ṣe Táwọn Ará Ìlà Oòrùn Ayé Pàápàá Fi Ń Ṣe É?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Kí Ni Keresimesi Túmọ̀ Sí fún Ọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kí Ló Máa Ń Jẹ Àwọn Èèyàn Lógún Nígbà Ọdún Kérésì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 12/15 ojú ìwé 4-7

Orísun Kérésìmesì Òde Òní

FÚN àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn yíká ayé, àkókò Kérésìmesì jẹ́ àkókò ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ nínú ọdún. Ó jẹ́ àkókò oúnjẹ dídọ́ṣọ̀, àkókò bíbọlá fún àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, àti àkókò wíwàpapọ̀ ìdílé. Ọdún Kérésìmesì tún jẹ́ àkókò tí àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí ń gbádùn fífi káàdì ránṣẹ́ sí ara wọn àti fífún ara wọn lẹ́bùn.

Ṣùgbọ́n, ní 150 ọdún péré sẹ́yìn, Kérésìmesì jẹ́ ọdún tí ó yàtọ̀ pátápátá. Nínú ìwé rẹ̀, The Battle for Christmas, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn, Stephen Nissenbaum, kọ̀wé pé: “Kérésìmesì . . . jẹ́ àkókò ọtí àmuyíràá, nígbà tí a ń pa òfin tí ń darí ìwà àwọn ènìyàn ní gbangba tì fún ìgbà díẹ̀ láti lè fàyè gba ‘pọ̀pọ̀ṣìnṣìn’ tí a kò lè ṣàkóso, bíi pé a ń ṣayẹyẹ Mardi Gras ní December.”

Lójú àwọn tí ó ka Kérésìmesì sí ohun ọlọ́wọ̀, àpèjúwe yìí lè bà wọ́n lọ́kàn jẹ́. Èé ṣe tí ẹnikẹ́ni yóò fi fẹ́ kó àbàwọ́n bá ọdún kan tí a sọ pé a fi ń rántí ọjọ́ ìbí Ọmọ Ọlọ́run? Ìdáhùn náà lè yà ọ́ lẹ́nu.

Ìpìlẹ̀ Tí Ó Wọ́

Láti ìgbà tí a ti bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹrin ni awuyewuye ti wọnú ọ̀ràn Kérésìmesì. Fún àpẹẹrẹ, ìbéèrè wà lórí ọjọ́ ìbí Jésù. Níwọ̀n bí Bíbélì kò ti sọ ọjọ́ tàbí oṣù pàtó tí a bí Kristi, onírúurú ọjọ́ ni a ti dá lábàá. Ní ọ̀rúndún kẹta, àwùjọ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tí wọ́n jẹ́ ará Íjíbítì fi sí May 20, nígbà tí àwọn mìíràn fọwọ́ sí àwọn ọjọ́ tí ó ṣáájú ìyẹn, irú bíi March 28, April 2, tàbí April 19. Nígbà tí yóò fi di ọ̀rúndún kejìdínlógún, a ti so ìbí Jésù mọ́ oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún! Nígbà náà, báwo wá ni a ṣe yan December 25 nígbẹ̀yìngbẹ́yín?

Ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ gbà pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ni ó yan December 25 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìbí Jésù. Èé ṣe? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó fà á jù lọ ni pé àwọn Kristẹni ìjímìjí fẹ́ kí ọjọ́ náà bọ́ sí ọjọ́ ayẹyẹ àwọn ará Róòmù abọ̀rìṣà tí wọ́n fi ń sàmì sí ‘ọjọ́ ìbí oòrùn tí a kò lè ṣẹ́gun.’” Ṣùgbọ́n èé ṣe tí àwọn Kristẹni tí àwọn abọ̀rìṣà ti ṣenúnibíni rírorò sí fún ohun tí ó lé ní ọ̀rúndún méjì àti ààbọ̀ yóò fi ṣàdédé juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn tí ó ṣenúnibíni sí wọn?

Ìwà Ìbàjẹ́ Wọlé

Ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún Tímótì pé “àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà” yóò yọ́ wọnú ìjọ Kristẹni, wọn yóò sì ṣi ọ̀pọ̀ lọ́nà. (Tímótì Kejì 3:13) Ìpẹ̀yìndà ńláǹlà yí bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì. (Ìṣe 20:29, 30) Lẹ́yìn ohun tí a pè ní ìyílọ́kànpadà Constantine ní ọ̀rúndún kẹrin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn abọ̀rìṣà rọ́ sínú oríṣi ẹ̀sìn Kristẹni tí ó gbilẹ̀ nígbà náà. Kí ni ó yọrí sí? Ìwé Early Christianity and Paganism sọ pé: “Ní ìfiwéra, àwùjọ kéréje àwọn onígbàgbọ́ aláápọn parẹ́ mọ́ ògìdìgbó àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ lára.”

Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ti jẹ́ òtítọ́ tó! Ṣe ni ó dà bíi pé ìwà ìbàjẹ́ abọ̀rìṣà ti gbé ojúlówó ẹ̀sìn Kristẹni mì káló. Kò sì sí ibòmíràn tí ìbàjẹ́ yìí ti hàn gbangba ju nínú ọdún ṣíṣe lọ.

Ní ti gidi, ayẹyẹ kan ṣoṣo tí a pàṣẹ pé kí àwọn Kristẹni máa ṣe ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. (Kọ́ríńtì Kíní 11:23-26) Nítorí àṣà ìbọ̀rìṣà tí ó so mọ́ ayẹyẹ àwọn ará Róòmù, àwọn Kristẹni ìjímìjí kò lọ́wọ́ nínú wọn. Nítorí èyí, àwọn abọ̀rìṣà ọ̀rúndún kẹta pẹ̀gàn àwọn Kristẹni, ní sísọ pé: “Ẹ kì í ṣèbẹ̀wò sí ibi ìpàtẹ; ẹ kò nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ṣekárími; ẹ kọ àpèjẹ ìta gbangba, ẹ sì kórìíra ìfagagbága ọlọ́wọ̀.” Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn abọ̀rìṣà ń fọ́nnu pé: “Àwa ń fi ọ̀yàyà, àsè, orin àti eré ìdárayá jọ́sìn àwọn ọlọ́run.”

Nígbà tí yóò fi di àárín gbùngbùn ọ̀rúndún kẹrin, àròyé náà ti rọlẹ̀. Lọ́nà wo? Bí àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà ṣe túbọ̀ ń wọnú agbo, bẹ́ẹ̀ ni èrò ìpẹ̀yìndà ń pọ̀ sí i. Èyí yọrí sí jíjuwọ́sílẹ̀ fún ayé àwọn Róòmù. Ní sísọ̀rọ̀ lórí èyí, ìwé The Paganism in Our Christianity sọ pé: “Ó jẹ́ ìlànà Kristẹni gan-an láti tẹ́wọ́ gba àwọn ayẹyẹ abọ̀rìṣà tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti jẹ́ kí ó fa àwọn ènìyàn mọ́ra, àti láti kà wọ́n sí ohun pàtàkì nínú ẹ̀sìn Kristẹni.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìpẹ̀yìndà ńlá náà ti ń ṣàkóbá gidigidi. Ìmúratán àwọn tí a fẹnu lásán pè ní Kristẹni láti gba àwọn ayẹyẹ abọ̀rìṣà wọlé mú kí a tẹ́wọ́ gbà wọ́n dé ìwọ̀n kan láwùjọ. Láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn Kristẹni pẹ̀lú wá ní ọ̀pọ̀ ayẹyẹ ọdọọdún bíi ti àwọn abọ̀rìṣà. Kò yani lẹ́nu pé, Kérésìmesì mú ipò iwájú láàárín wọn.

Ọdún Àṣekáyé

Bí oríṣi ẹ̀sìn Kristẹni tí ó gbilẹ̀ ṣe ń tàn kálẹ̀ ní Yúróòpù, Kérésìmesì ń bá a tàn kálẹ̀ lọ. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye náà pé ó yẹ láti máa ṣàjọyọ̀ kan ní bíbọlá fún ọjọ́ ìbí Jésù. Nítorí bẹ́ẹ̀, ní ọdún 567 Sànmánì Tiwa, Ìgbìmọ̀ Ìlú Tours “kéde ọjọ́ 12 láti ọjọ́ Kérésìmesì títí dé ọjọ́ Epiphany gẹ́gẹ́ bí àkókò ọlọ́wọ̀ àti aláyẹyẹ.”—The Catholic Encyclopedia for School and Home.

Kò pẹ́ tí Kérésìmesì fi ṣàmúlò ọ̀pọ̀ apá fífanimọ́ra nínú ayẹyẹ ìkórè tí a ti sọ dìbàjẹ́ ti àríwá Yúróòpù. Bí àwọn alárìíyá aláriwo ti ń lọ́wọ́ nínú jíjẹ àjẹkì àti mímu àmuyíràá, àríyá di ohun tí ó wọ́pọ̀ ju ìtara ìsìn lọ. Kàkà tí wọn yóò fi kìlọ̀ fúnni nípa ìwà àìníjàánu náà, ṣọ́ọ̀ṣì fọwọ́ sí i. (Fi wé Róòmù 13:13; Pétérù Kíní 4:3.) Ní ọdún 601 Sànmánì Tiwa, Póòpù Gregory Kìíní kọ̀wé sí Mellitus, míṣọ́nnárì rẹ̀ ní England, ó sọ fún un pé kí ó “má ṣe dáni lẹ́kun irú àwọn ayẹyẹ abọ̀rìṣà ìgbàanì bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó mú wọn wọnú àwọn ààtò ìsìn Ṣọ́ọ̀ṣì, kìkì pé kí ó yí ìdí tí wọ́n fi ń ṣe é pa dà láti orí ète ti ìbọgibọ̀pẹ̀ sí ti Kristẹni.” Ohun tí Arthur Weigall, tí ó fìgbà kan jẹ́ olùbẹ̀wò àgbà fún ohun ìṣẹ̀ǹbáyé fún ìjọba Íjíbítì, sọ nìyẹn.

Nígbà Sànmánì Agbedeméjì, àwọn ọlọ́kàn ìyípìlẹ̀dà rí i pé ó pọn dandan kí àwọn sọ̀rọ̀ jáde nípa irú àwọn àṣerégèé bẹ́ẹ̀. Wọ́n gbé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àṣẹ kalẹ̀ ní ìlòdìsí “ṣíṣe àríyá Kérésìmesì lọ́nà òdì.” Ọ̀mọ̀wé Penne Restad, nínú ìwé rẹ̀ Christmas in America—A History, sọ pé: “Àwọn àlùfáà kan tẹnu mọ́ ọn pé ìran ènìyàn aláìpé nílò àkókò gbẹ̀fẹ́ àti àṣerégèé, níwọ̀n bí a bá ti ṣe é lábẹ́ ìbòjú náà pé ẹ̀sìn Kristẹni ni ń ṣe kòkárí rẹ̀.” Èyí wulẹ̀ dá kún ìdàrúdàpọ̀ náà ni. Ṣùgbọ́n, kò fi bẹ́ẹ̀ mú ìyàtọ̀ kankan wá, nítorí àwọn àṣà abọ̀rìṣà ti dà pọ̀ mọ́ ti Kérésìmesì gidigidi, tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò fi fẹ́ fi wọ́n sílẹ̀ mọ́. Òǹkọ̀wé Tristram Coffin, sọ ọ́ lọ́nà yí pé: “Àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò [ń] ṣe ohun tí wọ́n [ti] ń ṣe tẹ́lẹ̀, wọn kò sì fiyè sí ìjiyàn àwọn atẹ̀lélànà ìwà rere.”

Nígbà tí àwọn ará Yúróòpù fi bẹ̀rẹ̀ títẹ Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé dó, Kérésìmesì ti di ọdún tí a mọ̀ bí ẹni mowó. Síbẹ̀, a kò tẹ́wọ́ gba Kérésìmesì ní àgbègbè Àríwá Amẹ́ríkà tí Britain ṣàkóso. Àwọn Aláfọ̀mọ́ ayípìlẹ̀dà ka ayẹyẹ náà sí ti abọ̀rìṣà, wọ́n sì fòfin dè é ní Massachusetts láàárín ọdún 1659 sí 1681.

Lẹ́yìn tí a gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí ìfòfindè náà, ṣíṣayẹyẹ Kérésìmesì lọ sókè jákèjádò àgbègbè Àríwá Amẹ́ríkà tí Britain ṣàkóso, ní pàtàkì ní gúúsù New England. Ṣùgbọ́n, lójú ìwòye ìtàn ọdún náà, kò yani lẹ́nu pé àwọn kan ka gbígbádùn ara wọn sí ohun tí ó ṣe pàtàkì ju bíbọlá fún Ọmọ Ọlọ́run lọ. Àṣà Kérésìmesì kan tí ó ń dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ ní pàtàkì ni ti ọtí àmuyíràá. Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ń pariwo gèè yóò rọ́ wọlé àwọn ọlọ́rọ̀ àdúgbò, wọn yóò sì béèrè fún oúnjẹ àti ohun mímu bí ẹní ń fọgbọ́n tọrọ nǹkan. Bí onílé náà bá kọ̀, wọn yóò sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i, lọ́pọ̀ ìgbà, wọn yóò sì ba ilé náà jẹ́.

Ipò nǹkan burú sí i ní àwọn ọdún 1820 tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Nissenbaum fi sọ pé “yánpọnyánrin ìgbà Kérésìmesì” di “ewu láwùjọ níwọ̀n tí ó lékenkà.” Ní àwọn ìlú bíi New York àti Philadelphia, àwọn onílẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gba àwọn ṣọ́léṣọ́lé láti máa ṣọ́ ilé wọn. A tilẹ̀ sọ pé New York City ṣètò àjọ ọlọ́pàá akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àkọ́kọ́ láti lè kápá rúkèrúdò ìwà ipá nígbà Kérésìmesì ti ọdún 1827 sí 1828!

Àtúnṣe Kérésìmesì

Ọ̀rúndún kọkàndínlógún mú ìyípadà ńláǹlà wá fún aráyé. Bí àwọn ọ̀nà ilẹ̀ àti ọ̀nà ojú irin alásokọ́ra ṣe ń dé, àwọn ènìyàn, ẹrù, àti ìròyìn bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri lọ́nà yíyára kánkán sí i. Ìyípadà sí sànmánì iṣẹ́ ẹ̀rọ pèsè àràádọ́ta iṣẹ́, àwọn ilé iṣẹ́ sì ń yára mú ọjà jáde láìsọsẹ̀. Ìyípadà sí iṣẹ́ ẹ̀rọ tún mú àwọn ìṣòro tuntun àti èyí tí ó díjú tí ó jẹ́ ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà wá, tí ó wá nípa lórí ọ̀nà tí a gbà ń ṣayẹyẹ Kérésìmesì.

Tipẹ́tipẹ́ ni àwọn ènìyàn ti ń lo àkókó ọdún gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan láti fún ìdè ìdílé lókun, wọ́n sì lo Kérésìmesì pẹ̀lú lọ́nà bẹ́ẹ̀. Nípa fífarabalẹ̀ ṣàtúnṣe díẹ̀ lára àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ Kérésìmesì àtijọ́, lọ́nà tí ó gbéṣẹ́, àwọn tí ń gbé e lárugẹ yí Kérésìmesì pa dà kúrò ní ayẹyẹ ẹhànnà onípọ̀pọ̀ṣìnṣìn sí ọdún tí a gbé karí ọ̀ràn ìdílé.

Ní tòótọ́, nígbà tí yóò fi di ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún, a bẹ̀rẹ̀ sí í wo Kérésìmesì gẹ́gẹ́ bí ojútùú sí ìwà abèṣe ti ìgbésí ayé Amẹ́ríkà òde òní. Ọ̀mọ̀wé Restad sọ pé: “Nínú gbogbo ọdún, Kérésìmesì jẹ́ ohun èlò pípé fún títàtaré ìsìn àti ẹ̀mí ìsìn sínú ilé àti fún ṣísàtúnṣe àṣerégèé àti ìkùnà àwọn ènìyàn.” Ó fi kún un pé: “Fífúnnilẹ́bùn, ṣíṣètọrẹ àánú, àní ìkíni ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ nígbà ọdún pàápàá àti ṣíṣe igi títutù yọ̀yọ̀ tí a gbé sínú pálọ̀ tàbí, lẹ́yìn náà, tí a gbé sí gbọ̀ngàn ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ Ìsinmi lọ́ṣọ̀ọ́, àti gbígbádùn rẹ̀, ń so àwọn mẹ́ńbà ìdílé kọ̀ọ̀kan mọ́ra, ó ń so wọ́n mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì ń so wọ́n mọ́ àwùjọ.”

Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ lónìí ń ṣe Kérésìmesì gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti fi ìfẹ́ wọn hàn fún ẹnì kíní kejì àti láti pa ìṣọ̀kan ìdílé mọ́. Dájúdájú, ohun tí a kò ní láti gbójú fò dá ni àwọn apá tẹ̀mí. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń ṣe Kérésìmesì láti bọlá fún ọjọ́ ìbí Jésù. Wọ́n lè lọ sí ibi àwọn ààtò ìsìn àkànṣe ní ṣọ́ọ̀ṣì, kí wọ́n ṣayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí Jésù nínú ilé, tàbí kí wọ́n gbàdúrà ọpẹ́ sí Jésù fúnra rẹ̀. Ṣùgbọ́n ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wò ọ̀ràn náà? Ó ha tẹ́wọ́ gba àwọn nǹkan wọ̀nyí bí? Gbé ohun tí Bíbélì ní í sọ yẹ̀ wò.

“Ẹ Fẹ́ Òtítọ́ Àti Àlàáfíà”

Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn wọnnì tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Jésù gbé ìgbésí ayé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Ìgbà gbogbo ni ó máa ń sọ òtítọ́. Ó fara wé Bàbá rẹ̀, “Olúwa Ọlọ́run òtítọ́,” lọ́nà pípé pérépéré.—Orin Dáfídì 31:5; Jòhánù 14:9.

Nípasẹ̀ àwọn ojú ewé Bíbélì, Jèhófà ti mú un ṣe kedere pé òun kórìíra gbogbo onírúurú ẹ̀tàn. (Orin Dáfídì 5:6) Lójú ìwòye èyí, kò ha jẹ́ ohun tí ó takora pé ọ̀pọ̀ apá tí a so mọ́ Kérésìmesì ni ó ní èké nínú bí? Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa ìtàn àgbọ́sọ nípa Bàbá Kérésìmesì. O ha ti gbìyànjú láti ṣàlàyé fún ọmọ kan nípa ìdí tí Bàbá Kérésì fi fẹ́ láti máa gba inú ihò èéfín wọlé dípò gbígba ẹnu ọ̀nà wọlé, gẹ́gẹ́ bí a ti gbà gbọ́ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀? Báwo sì ni ó ṣe ṣeé ṣe fún Bàbá Kérésì láti ṣèbẹ̀wò sí ọ̀pọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ilé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan ṣoṣo? Àgbàlàǹgbó tí ń fò ńkọ́? Nígbà tí ọmọ kan bá wá mọ̀ pé ńṣe ni àwọn òbí òun tan òun jẹ láti mú òun gbàgbọ́ pé Bàbá Kérésì jẹ́ ẹni gidi, kò ha ní dín ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó ní nínú wọn kù bí?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia sọ ní kedere pé: “Àwọn àṣà abọ̀rìṣà . . . wọnú Kérésìmesì.” Nígbà náà, èé ṣe tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì míràn ti Kirisẹ́ńdọ̀mù fi ń bá a nìṣó láti máa ṣe ọdún kan tí àwọn àṣà rẹ̀ kò pilẹ̀ láti inú ẹ̀sìn Kristẹni? Ìyẹn kò ha fi hàn pé wọ́n fàyè gba àwọn ẹ̀kọ́ ìbọ̀rìṣà bí?

Nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Jésù kò fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti jọ́sìn òun. Jésù alára wí pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn [ọlọ́wọ̀] fún.” (Mátíù 4:10) Bákan náà, lẹ́yìn ìṣelógo Jésù lókè ọ̀run, áńgẹ́lì kan wí fún àpọ́sítélì Jòhánù pé kí ó “jọ́sìn Ọlọ́run,” ní fífihàn pé ohunkóhun kò yí pa dà nípa ọ̀ràn yí. (Ìṣípayá 19:10) Èyí mú ìbéèrè náà wá pé, Jésù yóò ha fọwọ́ sí gbogbo ìjọsìn àfọkànṣe tí a darí sí i, dípò Bàbá rẹ̀, nígbà Kérésìmesì bí?

Ó ṣe kedere pé, àwọn òtítọ́ nípa Kérésìmesì òde òní kì í ṣe àsọdùn. Ní pàtàkì, ó jẹ́ ọdún kan tí a hùmọ̀ tí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí sì ń tọ́ka sí ìtàn rírẹninípòwálẹ̀ tí ó ní. Nígbà náà, pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn rere, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Kristẹni ti pinnu láti má ṣe Kérésìmesì. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ryan sọ nípa Kérésìmesì pé: “Inú àwọn ènìyàn máa ń dùn yàtọ̀ nínú àwọn ọ̀jọ́ díẹ̀ kan láàárín ọdún nígbà tí ìdílé yóò wà pa pọ̀, tí gbogbo wọn yóò sì máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́, kí ni ó jẹ́ bàbàrà nípa ìyẹn? Àwọn òbí mi máa ń fún mi lẹ́bùn jálẹ̀ ọdún!” Ọ̀dọ́ ọlọ́dún 12 mìíràn sọ pé: “N kò nímọ̀lára pé a fi nǹkan dù mí. Mo máa ń gba ẹ̀bùn jálẹ̀ ọdún, kì í wulẹ̀ ṣe ní ọjọ́ àkànṣe kan nígbà tí àwọn ènìyàn ń nímọ̀lára pé ó di dandan láti ra ẹ̀bùn.”

Wòlíì Sekaráyà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti “fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.” (Sekaráyà 8:19) Bí àwa, bíi Sekaráyà àti àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ ìgbàanì míràn, bá “fẹ́ òtítọ́,” a kò ha ní yẹra fún ayẹyẹ ìsìn èké èyíkéyìí tí ń mú ẹ̀gàn bá Jèhófà, “Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè” bí?—Tẹsalóníkà Kíní 1:9.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“N kò nímọ̀lára pé a fi nǹkan dù mí. Mo máa ń gba ẹ̀bùn jálẹ̀ ọdún”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́