ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 12/15 ojú ìwé 8-10
  • Wọ́n “Ra Òtítọ́”!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n “Ra Òtítọ́”!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Bíbélì Fà Á Mọ́ra
  • Fífẹ̀rí Òtítọ́ Han Ara Ẹni
  • Ìsìn Èké Tojú Sú U
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 12/15 ojú ìwé 8-10

Wọ́n “Ra Òtítọ́”!

“RA ÒTÍTỌ́, kí o má sì ṣe tà á.” (Òwe 23:23) Ìyànjú tí ọlọgbọ́n ọkùnrin náà, Sólómọ́nì, gbani nìyẹn. Bí a tilẹ̀ lè sọ èyí nípa òtítọ́ ní gbogbogbòò, ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì nípa òtítọ́ tí a rí nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀ lè sinni lọ sí ìyè ayérayé! (Jòhánù 17:3, 17) Ṣùgbọ́n, kíyè sí i pé jíjèrè irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀ kì í wá lọ́fẹ̀ẹ́. Ẹnì kan ní láti ṣe tán láti “rà” á, ìyẹn ni pé, kí ó fi ohun kan du ara rẹ̀ tàbí kí ó pàdánù ohun kan kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ̀ ẹ́. (Fi wé Mátíù 13:45, 46.) Ní gbogbogbòò, àwọn ènìyàn kò ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn ènìyàn onígboyà tí iye wọn ń pọ̀ sí i ń ra òtítọ́ Bíbélì—lọ́pọ̀ ìgbà, ó ń ná wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan ti ara wọn.

Fún àpẹẹrẹ, gbé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà náà, Gánà, yẹ̀ wò. Ní June 1989, iye tí ó lé ní 34,000 ènìyàn ní ilẹ̀ yẹn ni ó ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń fi aápọn ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Lẹ́yìn náà, a fòfin de iṣẹ́ ìwàásù ní gbangba. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn aláìlábòsí ọkàn ń bá a lọ láti “ra òtítọ́”—láìka ìkálọ́wọ́kò òfin sí. Ìfòfindè náà wá sí òpin ní October 31, 1991, nígbà tí ó sì máa fi di àárín 1995, ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ péré lẹ́yìn tí a mú ìkálọ́wọ́kò náà kúrò, iye Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà aláápọn ní Gánà ti ròkè sí 46,104! Ní ọdún yìí, iye náà sì ti lọ sókè sí iye tí ó lé ní 52,800.

Kí ní ń mú kí àwọn ènìyàn fà mọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ìrúbọ wo ni àwọn kan ti ní láti ṣe láti “ra òtítọ́”? Láti dáhùn, ẹ jẹ́ kí a gbé ìrírí àwọn Kristẹni ará Gánà mẹ́ta kan yẹ̀ wò.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Bíbélì Fà Á Mọ́ra

Ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ gbé ìrírí obìnrin kan tí ó fi díẹ̀ lé ní 20 ọdún yẹ̀ wò. Bàbá rẹ̀ jẹ́ àlùfáà, síbẹ̀, ó yàn láti fi ẹ̀sìn bàbá rẹ̀ sílẹ̀. Kí ni ìdí rẹ̀? Ìfẹ́ rẹ̀ fún òtítọ́ ni.

Ó ṣàlàyé nígbà kan pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń wá sí ilé wa, bí wọ́n ti ń lọ láti ilé dé ilé. Lẹ́yìn ìjíròrò ráńpẹ́ pẹ̀lú wọn, mo wá mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń fi kọ́ni fìdí rinlẹ̀ gbọn-ingbọn-in nínú Bíbélì. Mo béèrè ìbéèrè lórí àwọn kókó ẹ̀kọ́ bíi Mẹ́talọ́kan, ọ̀run àpáàdì, àìleèkú ọkàn, àti ní pàtàkì, ìgbàgbọ́ wò-ó-sàn. Ó dá mi lójú gidigidi pé àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ wọ̀nyí wá láti inú Bíbélì. Ṣùgbọ́n Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé nǹkan kò rí bẹ́ẹ̀.”—Láti mọ ojú ìwòye Bíbélì lórí àwọn kókó ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ wo Máàkù 13:32; Róòmù 6:23; Ìṣe 10:40; àti Kọ́ríńtì Kíní 13:8-10.

Ọ̀dọ́bìnrin náà fi kún un pé: “Síbẹ̀, àtakò líle koko wá láti ọ̀dọ̀ ìdílé mi, pàápàá jù lọ láti ọ̀dọ̀ bàbá mi. Ó rò pé a ń ṣì mí lọ́nà. Ṣùgbọ́n, mo mọ̀ pé ohun tí mò ń kọ́ láti ọ̀dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ òtítọ́. Mo gbìyànjú láti fi àwọn nǹkan wọ̀nyí hàn bàbá mi láti inú Bíbélì, ṣùgbọ́n, ó kọ̀ láti tẹ́tí sílẹ̀. Àní, àtakò náà túbọ̀ le koko sí i.

“Ṣùgbọ́n, n kò fòyà. Mo mọ̀ pé kìkì ìmọ̀ tòótọ́ ní ń sinni lọ sí ìyè ayérayé nínú Párádìsé, mo sì ti pinnu láti dì í mú ṣinṣin. Nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó wà ládùúgbò gbọ́ nípa ìṣòro tí mo dojú kọ, wọ́n fi ìfẹ́ ṣèrànwọ́ fún mi, wọ́n fún mi níṣìírí, wọ́n sì pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí kan fún mi. Èyí ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ Jésù tí ó wà nínú Jòhánù 13:35 pé: ‘Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.’ Ìdánilójú tí mo ní pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ń ṣe ìsìn tòótọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn òbí mi kíyè sí i pé mo ti yí ìgbésí ayé mi pa dà sí rere, inú wọ́n dùn sí ohun tí wọ́n rí, ìṣarasíhùwà wọn sí mi sì yí pa dà—débi pé bàbá mi sọ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí pé kí wọ́n máa bá ẹ̀gbọ́n mi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!”

Fífẹ̀rí Òtítọ́ Han Ara Ẹni

‘Ríra òtítọ́’ tún jẹ́ ìpèníjà fún àwọn ọ̀dọ́ kan tí àwọn òbí Ẹlẹ́rìí tọ́ dàgbà. Àwọn èwe kan nítẹ̀sí láti fojú tín-ínrín òtítọ́ inú Bíbélì. Bí wọ́n bá kọ̀ láti sọ irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀ di ti ara wọn, ìgbàgbọ́ wọn yóò ṣákìí, kò sì ní fìdí rinlẹ̀. (Fi wé Mátíù 13:20, 21.) Nathaniel, ọkùnrin ará Gánà kan, tí ó ti lé ní 30 ọdún, sọ nípa bí ó ṣe “ra òtítọ́” nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́.

Ó rántí pé: “Láti ìgbà tí mo ti wà ní ìkókó ni àwọn òbí mi ti fi Bíbélì kọ́ mi. Bí mo ti ń dàgbà, mò ń bá wọn lọ sí òde ìwàásù, ṣùgbọ́n n kò tí ì pinnu láti di Ẹlẹ́rìí. Bí àkókò ti ń lọ, mo wá mọ̀ pé mo ní láti ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan fúnra mi.

“Lákọ̀ọ́kọ́, mo ní láti fi dá ara mi lójú pé Bíbélì ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe ìwé ọlọ́wọ̀ èyíkéyìí mìíràn. Nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́, mo kọ́ pé òun nìkan ṣoṣo ni ìwé ọlọ́wọ̀ tí ó ní ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ṣíṣe kedere, tí ó nímùúṣẹ lọ́nà pípéye. Mo tún kọ́ pé Bíbélì ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òtítọ́ tí ó bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ mu nínú—fún àpẹẹrẹ, pé ilẹ̀ ayé ‘rọ̀ lójú òfo.’ (Jóòbù 26:7) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, kí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó mọ̀ nípa oòrùn wa àti àwọn ọ̀wọ́ rẹ̀, ni a ti kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ó lè mí sí àwọn ènìyàn láti kọ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ sílẹ̀!a

“Lẹ́yìn ìyẹn, mo fẹ́ mọ ètò ìsìn tí ń kọ́ni ní òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni, tí ó sì ń ṣe é. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìsìn ń fi ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì, Mẹ́talọ́kan, àti àìleèkú ọkàn tí ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú kọ́ni. Ṣùgbọ́n, àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí kò bọ́gbọ́n mu lójú mi. Mo ronú pé: “Kì í ha ń ṣe bàbá oníkà ni yóò ki ọwọ́ ọmọ rẹ̀ sínú ìkòkò omi tí ń hó láti fìyà jẹ ẹ́? Báwo, nígbà náà, ni Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ yóò ṣe fi àwọn ọmọ rẹ̀ sínú hẹ́ẹ̀lì oníná, tí yóò sì jẹ́ kí wọ́n jìyà? Ṣùgbọ́n, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ni ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Bíbélì bíi Róòmù 6:23, tí ó sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú”—kì í ṣe hẹ́ẹ̀lì oníná kan. Ìyẹn bọ́gbọ́n mu lójú mi.

“Mo tún kíyè sí i pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń béèrè pé kí gbogbo mẹ́ńbà wọ́n gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì, wọ́n sì ń yọ gbogbo àwọn tí wọ́n bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà láìronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Lójú ìwòye gbogbo èyí, mo parí èrò sí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó ní òtítọ́, mo sì ṣe ìpinnu ara ẹni láti di ọ̀kan nínú wọn. Mo ṣiṣẹ́ kára láti tóótun láti ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí kan.”—Kọ́ríńtì Kíní 5:11-13.

Ìrírí Nathaniel ṣàkàwé dáradára pé àwọn èwe tí àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí tọ́ dàgbà pàápàá gbọ́dọ̀ “ra òtítọ́.” Kì í ṣe pé kí wọ́n kàn máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ lásán bíi pé a ń fipá mú wọn. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Bèróà ìgbàanì, wọ́n ní láti ‘fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá nǹkan wọ̀nyí rí bẹ́ẹ̀.’ (Ìṣe 17:11) Èyí ń gba àkókò àti ìsapá, ṣùgbọ́n ó lè yọrí sí ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin àti ìdánilójú.—Fi wé Éfésù 3:17-19.

Ìsìn Èké Tojú Sú U

Ọkùnrin ará Gánà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Godwin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni 70 ọdún nígbà tí ó fi Ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian àti Ẹgbẹ́ Lọ́ọ̀jì sílẹ̀. Godwin sọ pé: “Àwọn nǹkan ń ṣẹlẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì tí mo rí i pé kò tọ̀nà. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èdè àìyedè ọlọ́jọ́ pípẹ́ wáyé, ó ṣì ń bá a lọ síbẹ̀. Nígbà míràn, àwọn ọlọ́pàá ní láti wá láti mú kí àlàáfíà àti ìwà létòlétò wà! Èmi kò rò pé èyí bójú mu fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Lẹ́yìn náà, ìṣòro kan ṣẹlẹ̀ láàárín èmi àti ẹlẹ́sìn Presbyterian bíi tèmi kan. Kóòtù àdúgbò gbọ́ ẹjọ́ wa, wọ́n sì dá ọkùnrin kejì lẹ́bi. Ṣùgbọ́n, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì náà gbè sẹ́yìn ọkùnrin yìí, ó sì gbìdánwò láti bá mi wí níwájú gbogbo ìjọ! Mo sọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn mi fún un, mo sì fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀—ẹsẹ̀ mi kò sì tẹ ibẹ̀ mọ́ láé.

“Àkókò díẹ̀ kọjá, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì kàn sí mi nílé. Lákọ̀ọ́kọ́, mo tẹ́tí sílẹ̀ kìkì nítorí tí n kò fẹ́ lé àwọn ènìyàn tí ń sọ nípa Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, mo bẹ̀rẹ̀ sí i kíyè sí i pé, bí mo tilẹ̀ ti jẹ́ ẹlẹ́sìn Presbyterian fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, ohun púpọ̀ wà tí n kò mọ̀ nípa Bíbélì. Fún àpẹẹrẹ, n kò mọ̀ rárá pé Bíbélì nawọ́ ìrètí gbígbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé síni.b Nígbà tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí i lọ sí àwọn ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìṣesí wọn, pàápàá ìwọṣọ àti ìmúra àwọn èwe àárín wọn, wú mi lórí púpọ̀púpọ̀. Àwọn wọ̀nyí gan-an ni àwọn tí ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì!”

Síbẹ̀, ‘ríra òtítọ́’ ń béèrè pé kí ó ṣe ìyípadà tí ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Godwin rántí pé: “Mo jẹ́ ọmọ Ẹgbẹ́ Lọ́ọ̀jì. Bí a tilẹ̀ mọ̀ ọ́n sí ẹgbẹ́ ọmọ ìyá, tí ń pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn mẹ́ńbà rẹ̀, mo máa ń ṣe àwọn ètùtù tí ó ní lílo agbárí àti egungun àti pípe àwọn ẹ̀mí nínú. A gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí wọ̀nyí ń ran àwọn tí ó ní àjọṣe pẹ̀lú wọn lọ́wọ́ láti mú ipò tẹ̀mí dàgbà.

“Ìkẹ́kọ̀ọ́ mi ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé Jèhófà Ọlọ́run kórìíra lílọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò nítorí ó lè mú ẹnì kan wá sábẹ́ agbára Sátánì àti àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú rẹ̀.c N óò ha máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Lọ́ọ̀jì pẹ̀lú gbogbo awo rẹ̀, àbí kí n jáwọ́, kí n sì mú inú Jèhófà dùn? Mo yan èyí tí ó gbẹ̀yìn. Mo run gbogbo ohun tí mo ní tí ó jẹ mọ́ ti Ẹgbẹ́ Lọ́ọ̀jì, títí kan ẹ̀wù tí mo máa ń wọ̀ lọ sí àwọn ìpàdé Ẹgbẹ́ Lọ́ọ̀jì. Mo nírìírí ìjótìítọ́ ìlérí Jésù nígbà tí ó sọ pé, ‘Òtítọ́ yóò dá yín sílẹ̀ lómìnira’! (Jòhánù 8:32) Nísinsìnyí, mò ń láyọ̀ láti ṣàjọpín àwọn ohun tí mo ti kọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. N kò kábàámọ̀ kankan rárá.”

Bákan náà, ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún aláìlábòsí ọkàn ti fi àwọn ohun ńlá du ara wọn láti lè “ra òtítọ́.” Bíi àwọn Kristẹni mẹ́ta tí a sọ̀rọ̀ nípa wọn níhìn-ín, wọn kò kábàámọ̀ kankan nípa ìyípadà tí wọ́n ṣe. Òtítọ́ Bíbélì ti fún wọn ní ‘ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ gidi mú gírígírí.’ (Tímótì Kíní 6:19) “Ìyè tòótọ́ gidi” yẹn àti gbogbo àwọn ìbùkún tí ń bá a rìn lè jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú títí ayérayé, bí ìwọ yóò bá “ra òtítọ́.”

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

b Fún àpẹẹrẹ, wo Orin Dáfídì 37:9-11, 29.

c Wo Diutarónómì 18:10-12 àti Gálátíà 5:19-21.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Nathaniel

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Godwin

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́