Kí Ni Keresimesi Túmọ̀ Sí fún Ọ?
Báwo ni ìwọ yóò ṣe dáhùn? Keresimesi jẹ́ (1) àkókò kan láti wà papọ̀ pẹ̀lú ìdílé rẹ; (2) àkókò fún àwọn àpèjẹ; (3) àkókò ìsìn; (4) àkókò pákáǹleke; (5) àkókò tí àárò ń sọni; (6) àkókò ìṣòwò gbáà.
BÍ Ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè yanilẹ́nu, nínú 1,000 ènìyàn tí a fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ní Britain, kìkì ìpín 6 nínú ọgọ́rùn-ún ni ó ka Keresimesi sí ayẹyẹ ìsìn níti gidi. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, ìpín 48 nínú ọgọ́rùn-ún ronú nípa Keresimesi ní pàtàkì gẹ́gẹ́ bí àkókò tí ó yẹ láti wà pẹ̀lú ìdílé wọn. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ gbà pé ó jẹ́ àkànṣe àkókò fún àwọn ọmọdé. Láti mú àpẹẹrẹ kan wá, nígbà tí a bi ọmọbìnrin ẹni ọdún 11 kan pé kí ni ó fẹ́ràn jùlọ nípa Keresimesi, ó fèsì pé: “Ìrusókè ìmọ̀lára, ìmọ̀lára ayọ̀, [àti] fífúnni ní ẹ̀bùn.” Ìwé náà The Making of the Modern Christmas gbà pé “àwọn ìtẹnumọ́ tí ó lágbára jùlọ nínú . . . Keresimesi ‘aláṣà àtọwọ́dọ́wọ́’ láìsí iyèméjì dá lórí ilé, ìdílé àti ní pàtàkì àwọn ọmọ.”
Ṣùgbọ́n ní pàtàkì jùlọ nínú Kristẹndọm ti ìwọ̀ oòrùn ni Keresimesi ti jẹ́ àlámọ̀rí ìdílé, nígbà tí àwọn ìbátan bá péjọpọ̀ láti ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ẹ̀bùn. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí Ṣọ́ọ̀ṣì Eastern Orthodox ti ń lo agbára ìdarí tí ó pọ̀ jùlọ, àwọn ènìyàn ti gbé ìtẹnumọ́ púpọ̀ karí Easter; síbẹ̀, àkókò Keresimesi máa ń sábà jẹ́ sáà ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́.
“Ìgbòkègbodò Ìṣòwò”
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé Keresimesi ti “wá di ètò-ìṣòwò . . . tí ń pe àfiyèsí.” Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí ibi tí èyí ti jẹ́ òtítọ́ ju Japan lọ.
Ìwé ìròyìn Washington Daily Record ròyìn pé: “Àwọn ara Japan ti jáwọ́ nínú gbogbo bojúbojú ti ìsìn, wọ́n sì ti yí Keresimesi padà sí ìgbòkègbodò ìṣòwò níti gidi.” Ó fikún un pé ní Japan, Keresimesi jẹ́ “ayẹyẹ pàtàkì kan nínú èyí tí a ti gbé ìtẹnumọ́ tí ó pọ̀ jùlọ karí ètò-ìṣòwò tí a sì gbé ìtẹnumọ́ tí kò tó nǹkan karí apá tí ó jẹ́ ti ìsìn.”
Kódà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fi ẹnu lásán sọ pé wọ́n jẹ́ ti Kristian, “apá tí ó jẹ́ ti ìsìn” yìí sábà máa ń ṣòro láti dámọ̀. Ní nǹkan bí i 40 ọdún sẹ́yìn, ìwé-ìléwọ́ kan tí ń sọ̀rọ̀ lòdì sí Keresimesi kédàárò pé: “Ètò ìṣòwò ni ó ń gbé Keresimesi ga. Ó jẹ́ sáà tí a lè rí ti owó ṣe jùlọ nínú ọdún. Àwọn ọkùnrin oníṣòwò aláfẹnujẹ́ Kristian a máa fi ojú sọ́nà fún sáà Keresimesi, kì í ṣe nítorí Kristi, bíkòṣe nítorí èrè owó.” Ẹ sì wo bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣe jẹ́ òtítọ́ tó lónìí! Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀, agbára káká ni ó fi tó ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta tí ó gbẹ̀yìn ọdún kí a tó máa gbọ́ àwọn ìránnilétí nípa iye ọjọ́ tí ó kù láti bẹ̀rẹ̀ sí í ra àwọn ẹ̀bùn fún Keresimesi tí ń bọ̀. Ọjà túbọ̀ máa ń yá sí i bí ọdún bá ti ń parí lọ, tí nǹkan bí i ìdámẹ́rin nínú àwọn ọjà tí a ń tà ní àwọn ilé-ìtajà lọ́dọọdún sì máa ń jẹ́ ní àkókò Keresimesi.
Ohun yòówù kí Keresimesi túmọ̀ sì fún ọ nísinsìnyí, bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ lè máa ṣe ọ́ ní kàyéfì gidigidi. Bibeli níti tòótọ́ ha ti fífúnni ní ẹ̀bùn nígbà Keresimesi lẹ́yìn bí? Àwọn ayẹyẹ Keresimesi òde-ìwòyí ha bá ìsìn Kristian mu nítòótọ́ bí? Jẹ́ kí a wò ó ná.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Èpo ẹ̀yìn ìwé: Thomas Nast/Dover Publications, Inc., 1978