ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 12/1 ojú ìwé 32
  • Àwọn Ohùn tí Ó Kín Ìgbàgbọ́ Lẹ́yìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ohùn tí Ó Kín Ìgbàgbọ́ Lẹ́yìn
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 12/1 ojú ìwé 32

Àwọn Ohùn tí Ó Kín Ìgbàgbọ́ Lẹ́yìn

BÍ Ọ̀RÚNDÚN tí ó kẹ́yìn tí ń lọ sópin, àwọn ohùn tí ó kín ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, ọgbọ́n-èrò-orí, àti ọgbọ́n ayé lẹ́yìn ń nípa ìdarí búburú lórí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun àti ìmísí Bibeli.

Ṣùgbọ́n kì í ṣe àwọn ohùn wọ̀nyí nìkan ni a ń gbọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèwádìí rí i pé ohun púpọ̀ wà tí a lè sọ láti kín ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun lẹ́yìn dípò àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun. Àwọn ẹ̀kọ́ wọn tún fi àwọn ẹ̀rí jaburata hàn pé Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a mísí.

Ohùn kan tí ó tayọlọ́lá ni ti C. T. Russell jẹ́. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ka ìdìpọ̀-ìwé rẹ̀ ti 1886 The Divine Plan of the Ages. Àkòrí lílágbára kan nínú rẹ̀ ni “The Existence of a Supreme Intelligent Creator Established” (A Fìdí Wíwà Ẹlẹ́dàá Ọlọ́gbọ́nlóye Onípò-Àjùlọ Múlẹ̀).

Ní àwọn ẹ̀wádún tí ó tẹ̀lé e, Russell kọ àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́, ìwé àṣàrò kúkúrú, àti àwọn ìwé tí ó pèsè àwọn ìdí tí kò ṣeé jáníkoro fún gbígbàgbọ́ nínú Ọlọrun àti Bibeli. Àwọn wọ̀nyí ní Watch Tower Bible and Tract Society tẹ̀jáde. Ààrẹ rẹ̀ kejì, J. F. Rutherford, kọ ìwé Creation (1927) àti àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó túbọ̀ mú kí àwọn ohùn tí ó kín ìgbàgbọ́ lẹ́yìn rinlẹ̀dòdò.

Láìpẹ́ yìí àwùjọ ẹgbẹ́ yẹn ti pèsè àfikún ìsọfúnni lọ́ọ́lọ́ọ́ lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè pèsè irú rẹ̀ fún ọ láti lè gbé e yẹ̀wò pẹ̀lú ìrònújinlẹ̀.

Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni síwájú síi tàbí bí ìwọ yóò bá fẹ́ kí ẹnì kan kàn sí ọ láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ́lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú tí a tò sí ojú-ìwé 2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́