ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 12/1 ojú ìwé 31
  • ‘Àwọn Ìṣe Rẹ̀ Ń Tọ̀ Ọ́ Lẹ́yìn’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Àwọn Ìṣe Rẹ̀ Ń Tọ̀ Ọ́ Lẹ́yìn’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 12/1 ojú ìwé 31

‘Àwọn Ìṣe Rẹ̀ Ń Tọ̀ Ọ́ Lẹ́yìn’

NÍ AGOGO 8:50 òwúrọ̀ ní ọjọ́ Thursday, July 28, 1994, George D. Gangas parí ipa ọ̀nà rẹ̀ ti orí ilẹ̀-ayé. Ẹni ọdún 98 ni. George Gangas tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹni-àmì-òróró, ti jẹ́ mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti October 15, 1971.

Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ ojúlùmọ̀ Arákùnrin Gangas mọ̀ nípa ìfẹ́ rẹ̀ fún òdodo àti ìkórìíra rẹ̀ fún ìwà búburú. Wọ́n rántí ọ̀nà tí ó gbà ṣàpèjúwe Satani gẹ́gẹ́ bí òpùrọ́ lílékenkà, paraku, búburú, alákọra, àti òkúùgbẹ́. Ní ìyàtọ̀ gédégbé, ó sọ̀rọ̀ nípa Jehofa gẹ́gẹ́ bí Bàbá onífẹ̀ẹ́, onínúure, oníyọ̀ọ́nú, oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, àti olùbìkítà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tún rántí ìfẹ́ rẹ̀ fún bíbéèrè àwọn ìbéèrè láti inú Bibeli. Nínú ìjíròrò èyíkéyìí, kò ní ṣaláì béèrè àwọn ìbéèrè​—⁠àwọn kan máa ń rọrùn, àwọn díẹ̀ lára wọn sì máa ń nira. Níti tòótọ́, ó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ Bibeli.

Arákùnrin Gangas ṣèrìbọmi ní July 15, 1921. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìgbésí-ayé rẹ̀ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún (ṣíṣe aṣáájú-ọnà) ní March 1928. Nípa bẹ́ẹ̀, ó wà nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún fún àròpọ̀ ọdún 66. Ó di mẹ́ḿbà òṣìṣẹ́ ní orílé-iṣẹ́ Watch Tower Bible and Tract Society ní Brooklyn ní October 31, 1928.

Ìtàn ìgbésí-ayé rẹ̀ jáde nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti December 1, 1967. Ní tòótọ́ ó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tẹ̀mí ti Ọlọrun. Nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yẹn, ó sọ àwọn gbólóhùn amúnilọ́kànyọ̀ wọ̀nyí jáde pé: “Mo fẹran iye mo si fẹ ki awọn arakunrin mi ni iye pẹlu. Mo nronu bakanna bi aposteli Paulu pe awọn ohun gbogbo miran jẹ ‘ofo nitori itayọ imọ; Kristi Jesu.’”​—⁠Filippi 3:8.

Arákùnrin Gangas fihàn nípa ìṣe rẹ̀ pé òun níti gidi nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè, ó sì fi pẹ̀lú ìháragàgà ṣàjọpín ‘ìmọ̀ rẹ̀ nípa Kristi Jesu’ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Àárò rẹ̀ yóò sọ wá, ṣùgbọ́n ẹ wo bí a ṣe láyọ̀ tó pé òun ti gba èrè rẹ̀ ti ọ̀run nísinsìnyí! Wàyí o, ‘òun yóò sinmi kúrò nínú làálàá rẹ̀, nítorí pé àwọn ìṣe rẹ̀ ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.’​—⁠Ìfihàn 14:13, New International Version.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́