Ẹ Ní Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́
“Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inúrere, . . . wọ ara yín láṣọ.” —KOLOSSE 3:12, NW.
1. Èéṣe tí àìní ńláǹlà fi wà fún ìyọ́nú lónìí?
KÒ TÍÌ sí ìgbà kan rí nínú ọ̀rọ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn tí àwọn ènìyàn púpọ̀ rẹpẹtẹ tíì ní àìní fún ìtìlẹ́yìn oníyọ̀ọ́nú tó báyìí. Lójú àìsàn, ebi, àìgbanisíṣẹ́, ìwà ọ̀daràn, ogun, rúgúdù, àti àwọn ìjábá ti ìṣẹ̀dá tí ń jà rànyìn, àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ènìyàn nílò ìrànlọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ìṣòro kan wà tí ó tilẹ̀ léwu jù, ìyẹn sì ni ipò ìṣòro tẹ̀mí aráyé tí ó ti rékọjá gèjíà. Satani, tí ó mọ̀ pé àkókò òun kúrú, “ń ṣi gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9, 12, NW) Fún ìdí èyí, ní pàtàkì àwọn wọnnì tí ń bẹ lẹ́yìn òde ìjọ Kristian tòótọ́ ń bẹ nínú ewu ti pípàdánù ìwàláàyè wọn, Bibeli sì fagilé ìrètí àjíǹde èyíkéyìí fún àwọn wọnnì tí a bá pa nígbà ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọrun tí ń bọ̀wá.—Matteu 25:31-33, 41, 46; 2 Tessalonika 1:6-9.
2. Èéṣe tí Jehofa kò fi tíì pa àwọn ènìyàn búburú run?
2 Síbẹ̀, títí di wákàtí ìkẹyìn yìí, Jehofa Ọlọrun ń bá a nìṣó láti máa fi sùúrù àti ìyọ́nú hàn fún àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ènìyàn burúkú. (Matteu 5:45; Luku 6:35, 36) Òun ti ṣe èyí nítorí ìdí kan náà tí ó mú kí ó fi ìjìyà orílẹ̀-èdè Israeli aláìṣòtítọ́ falẹ̀. “Bí èmi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wí, èmi kò ní inúdídùn ní ikú ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n kí ènìyàn búburú yípadà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀ kí ó sì yè: ẹ yípadà, ẹ yípadà kúrò nínú ọ̀nà búburú yín; nítorí kí ni ẹ̀yin ó ṣe kú, Ilé Israeli?”—Esekieli 33:11.
3. Àpẹẹrẹ wo ni a ní nípa ìyọ́nú Jehofa fún àwọn wọnnì tí wọn kìí ṣe ènìyàn rẹ̀, kí sì ni ohun tí a lè rí kọ́ nínú èyí?
3 Ìyọ́nú Jehofa ni a tún nasẹ̀ rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn burúkú ará Ninefe. Jehofa rán wòlíì rẹ̀ Jona láti kìlọ̀ fún wọn nípa ìparun tí ó rọ̀dẹ̀dẹ̀. Wọ́n dáhùnpadà lọ́nà gbígbéṣẹ́ sí ìwàásù Jona wọ́n sì yípadà. Èyí sún Ọlọrun oníyọ̀ọ́nú náà, Jehofa, láti fawọ́sẹ́yìn ní pípa ìlú-ńlá náà run ní àkókò yẹn. (Jona 3:10; 4:11) Bí àánú Ọlọrun bá ṣe àwọn ará Ninefe, tí ìbá ti ṣeéṣe fún láti ní àjíǹde, báwo ni òun yóò ti nímọ̀lára ìyọ́nú lọ́pọ̀lọpọ̀ tó fún àwọn ènìyàn tí wọ́n dojúkọ ìparun àìnípẹ̀kun lónìí!—Luku 11:32.
Iṣẹ́ Ìyọ́nú Tí Kò Ní Àfiwé
4. Báwo ni Jehofa ṣe ń fi ìyọ́nú hàn fún àwọn ènìyàn lónìí?
4 Ní ìbámu pẹ̀lú àkópọ̀ ìwà oníyọ̀ọ́nú rẹ̀, Jehofa ti fàṣẹ fún àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti máa báa nìṣó ní ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn pẹ̀lú “ìhìnrere ìjọba” náà. (Matteu 24:14, NW) Nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì fìmọrírì dáhùnpadà sí iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí, Jehofa ń ṣí ọkàn-àyà wọn payá láti gba ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà wọlé. (Matteu 11:25; Iṣe 16:14) Ní ṣíṣàfarawé Ọlọrun wọn, àwọn Kristian tòótọ́ ń fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn nípa pípadà ṣe ìkésíni sọ́dọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn, ní ríràn wọ́n lọ́wọ́, níbi tí ó bá ti ṣeéṣe, nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Nípa báyìí, ní 1993, iye àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó ju million mẹ́rin àti ààbọ̀, ní àwọn orílẹ̀-èdè 231, lo iye tí ó ju billion kan wákàtí fún wíwàásù láti ilé dé ilé àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn. Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fìfẹ́hàn wọ̀nyí, lẹ́yìn náà, ní àǹfààní yíya ìgbésí-ayé ara wọn sí mímọ́ fún Jehofa àti dídarapọ̀ mọ́ òtú àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ tí a ti batisí. Nípa báyìí, àwọn pẹ̀lú fi ara wọ́n fún iṣẹ́ ìyọ́nú tí kò ní àfiwé yìí tí a ń ṣe nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́la tí a ṣì dẹkùn mú sínú ayé Satani tí ń kú lọ yìí.—Matteu 28:19, 20; Johannu 14:12.
5. Nígbà tí ìyọ́nú àtọ̀runwá bá ti dé ìpẹ̀kun rẹ̀, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ìsìn tí ó bá fi Ọlọrun hàn lọ́nà òdì?
5 Láìpẹ́ Jehofa yóò gbégbèésẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “akin ọkùnrin ogun.” (Eksodu 15:3, NW) Nítorí ìyọ́nú tí ó ní fún orúkọ rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn rẹ̀, òun yóò palẹ̀ ìwà búburú mọ́ kúrò yóò sì fìdí ayé titun òdodo kan múlẹ̀. (2 Peteru 3:13) Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm ni wọn yóò kọ́kọ́ nírìírí ọjọ́ ìrunú Ọlọrun. Àní bí Ọlọrun kò ti dá tẹ́ḿpìlì rẹ̀ tí ó wà ní Jerusalemu sí kúrò lọ́wọ́ ọba Babiloni, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni òun kì yóò dá àwọn ètò-àjọ ìsìn tí wọ́n ti fi í hàn lọ́nà òdì sí. Ọlọrun yóò fi í sínú ọkàn-àyà àwọn mẹ́ḿbà Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti sọ Kristẹndọm àti gbogbo onírúurú ìsìn èké yòókù di ahoro. (Ìfihàn 17:16, 17) Jehofa polongo pé, “Bí ó ṣe ti èmi ni, ojú mi kì yóò dásí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, ṣùgbọ́n èmi óò san ọ̀nà wọn padà sí orí wọn.”—Esekieli 9:5, 10.
6. Ní àwọn ọ̀nà wo ni a gbà ń sún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti fi ìyọ́nú hàn?
6 Nígbà tí àkókò ṣì wà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń bá a nìṣó láti fi ìyọ́nú hàn fún àwọn aládùúgbò wọn nípa fífi ìtara wàásù ìhìn-iṣẹ́ Ọlọrun fún ìgbàlà. Lọ́nà tí ó sì tún bá ìwà ẹ̀dá mu, wọ́n ń ran àwọn ènìyàn tí wọ́n bá ni àìní àwọn ohun ti ara lọ́wọ́, níbi tí ó bá ti ṣeéṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, níti èyí, ẹrù-iṣẹ́ wọn àkọ́kọ́ jẹ́ láti bójútó àìní àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí ó súnmọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí àti àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ìbátan wọn nínú ìgbàgbọ́. (Galatia 6:10; 1 Timoteu 5:4, 8) Ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ ìpèsè ìrànlọ́wọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe nítorí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n ti jìyà lọ́wọ́ onírúurú ìjábá ti jásí àwọn àpẹẹrẹ ìyọ́nú kíkàmàmà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Kristian kò níláti dúró de yánpọnyánrin ṣáájú kí wọ́n tó fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn. Wọ́n tètè máa ń fi èyí hàn nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bójútó àwọn ságbà-súlà ìgbésí-ayé ojoojúmọ́.
Ó Jẹ́ Apákan Àkópọ̀ Ìwà Titun Náà
7. (a) Nínú Kolosse 3:8-13, báwo ni a ṣe so ìyọ́nú pọ̀ mọ́ àkópọ̀ ìwà titun? (b) Kí ni ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú kí ó rọrùn fún àwọn Kristian láti ṣe?
7 Òtítọ́ ni pé ipò ẹ̀ṣẹ̀ wa àti agbára ìdarí búburú ayé Satani jẹ́ ìdínà fún wa láti jẹ́ oníyọ̀ọ́nú lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Bibeli fi rọ̀ wá láti kọ “ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, ati ọ̀rọ̀ rírùn akóninírìíra” sílẹ̀. Dípò èyí a gbà wá nímọ̀ràn láti ‘fi àkópọ̀-ìwà titun wọ ara wa láṣọ’—àkópọ̀ ìwà kan tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ọlọrun. Ṣáájú ohun gbogbo, a pàṣẹ fún wa láti “fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inúrere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú, ìwàtútù, ati ìpamọ́ra” wọ ara wa láṣọ. Lẹ́yìn náà ni Bibeli wá fi ọ̀nà gbígbéṣẹ́ kan tí a lè gbà ṣàṣefihàn àwọn ànímọ́ wọ̀nyí hàn wá. “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nìkínní kejì kí ẹ sì máa dáríji ara yín fàlàlà lẹ́nìkínní kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní èrèdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti dáríjì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹlu máa ṣe.” Ó túbọ̀ máa ń rọrùn láti dáríjini bí a bá ti mú “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú” dàgbà fún àwọn arákùnrin wa.—Kolosse 3:8-13, NW.
8. Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti ní ẹ̀mí ìdáríjì?
8 Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ìkùnà náà láti fi ìdáríjì oníyọ̀ọ́nú hàn ń jẹ ipò ìbátan wa pẹ̀lú Jehofa lẹ́sẹ̀. Èyí ni Jesu fihàn lọ́nà lílágbára nínú àkàwé rẹ̀ nípa ẹrú náà tí kìí dáríjini, tí ọ̀gá rẹ̀ gbé jù sínú túbú “títí yoo fi san gbogbo gbèsè tí ó jẹ padà.” Irú ìbálò yìí tọ́ sí ẹrú náà nítorí pé, lọ́nà kan tí ń múni jígìrì, ó kùnà láti fi ìyọ́nú hàn fún ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí ó bẹ̀bẹ̀ fún àánú. Jesu parí àpèjúwe náà ní wíwí pé: “Ní irú-ọ̀nà kan naa ni Baba mi ọ̀run yoo gbà bá yín lò pẹlu bí olúkúlùkù yín kò bá dáríji arákùnrin rẹ̀ lati inú ọkàn-àyà yín wá.”—Matteu 18:34, 35, NW.
9. Báwo ni ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ṣe tanmọ́ apá ṣíṣe pàtàkì jùlọ nínú àkópọ̀ ìwà titun náà?
9 Jíjẹ́ oníyọ̀ọ́nú lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ jẹ́ apá pàtàkì mìíràn kan nínú ìfẹ́. Ìfẹ́ sì ni àmì tí a fi ń dá ìsìn Kristian tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀. (Johannu 13:35) Nípa báyìí, àpèjúwe Bibeli nípa àkópọ̀ ìwà titun parí lọ́nà yìí pé: “Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nitori ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kolosse 3:14, NW.
Ìlara—Ohun Ìdínà kan fún Ìyọ́nú
10. (a) Kí ni ó lè mú kí ìlara ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà wa? (b) Ìyọrísí búburú wo ni ó lè ti inú ìlara wá?
10 Nítorí ipò ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, àwọn ìmọ̀lára ìlara lè yára ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà wa. A lè bùkún arákùnrin tàbí arábìnrin kan pẹ̀lú àwọn agbára-ìṣe kan lọ́nà ti ẹ̀dá tàbí àwọn àǹfààní ohun ti ara tí àwa kò ní. Tàbí ó sì lè jẹ́ pé ẹnìkan ti rí àwọn àkànṣe ìbùkún àti àǹfààní tẹ̀mí gbà. Bí a bá ń ṣe ìlara irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, yóò ha ṣeéṣe fún wa láti fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ bá wọn lò bí? Bóyá ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọ̀lára owú lè farahàn ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àríwísí tàbí ìwà aláìnínúure, nítorí tí Jesu sọ nípa àwọn ẹ̀dá ènìyàn pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ ninu ọkàn-àyà ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.” (Luku 6:45, NW) Àwọn mìíràn lè darapọ̀ nínú irú ṣíṣe àríwísí bẹ́ẹ̀. A sì lè tipa bẹ́ẹ̀ ba àlàáfíà ìdílé tàbí ti ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọrun jẹ́.
11. Báwo ni àwọn arákùnrin Josefu mẹ́wàá ṣe kùnà láti fi àyè sílẹ̀ fún ìyọ́nú nínú ọkàn-àyà wọn, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?
11 Gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé ńlá kan yẹ̀wò. Àwọn ọmọkùnrin Jakọbu mẹ́wàá tí wọ́n dàgbà jùlọ kórìíra Josefu àbúrò wọn nítorí pé òun ni ààyò olùfẹ́ bàbá wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, “wọn kò sì lè sọ̀rọ̀ sí i ní àlàáfíà.” Lẹ́yìn náà a fi àwọn àlá àtọ̀runwá kẹ́ Josefu, tí ń fi ẹ̀rí hàn pé Jehofa ṣojúrere sí i. Èyí mú kí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ “tún kórìíra rẹ̀ sí i.” Nítorí pé wọn kò fa gbòǹgbò owú tu kúrò nínú ọkàn-àyà wọn, kò fi àyè sílẹ̀ fún ìyọ́nú ó sì yọrísí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo.—Genesisi 37:4, 5, 11.
12, 13. Kí ni a níláti ṣe nígbà tí ìmọ̀lára owú bá wọ inú ọkàn-àyà wa?
12 Lọ́nà ìkà, wọn ta Josefu sí oko ẹrú. Nínú ìgbìdánwò láti sin ìwà àìtọ́ wọn ní òkú òru, wọn fi ìtànjẹ mú kí bàbá wọn máa ronú pé ẹranko ẹhànnà kan ni ó ti pa Josefu jẹ. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ẹ̀ṣẹ̀ wọn wá sí ojútáyé nígbà tí ìyàn mú wọn lọ́ràn-anyàn láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Egipti láti ra oúnjẹ. Olùṣàbójútó oúnjẹ, tí wọn kò mọ̀ pé òun ni Josefu, fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n wá ṣe amí ni ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n máṣe wá ìrànlọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ òun mọ́ bíkòṣe pé wọ́n mú Benjamini, àbúrò wọn tí ó kéré jù wá. Ní àkókò yìí Benjamini ti di ààyò olùfẹ́ bàbá wọn, wọ́n sì mọ̀ pé Jakọbu kì yóò fẹ́ láti jẹ́ kí ó lọ.
13 Nítorí náà lórí ìdúró níbẹ̀ níwájú Josefu, ẹ̀rí-ọkàn wọn sún wọn láti gbà pé: “Àwa jẹ̀bi nítòótọ́ nípa ti arákùnrin wa [Josefu], níti pé, a rí àròkàn ọkàn rẹ̀, nígbà tí ó bẹ̀ wá, àwa kò sì fẹ́ ígbọ́; nítorí náà ni ìyọnu yìí ṣe bá wa.” (Genesisi 42:21) Nípasẹ̀ ìbálò oníyọ̀ọ́nú rẹ̀ tí ó fi ìdúróṣinṣin hàn, Josefu ran àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́ láti fi ẹ̀rí ìjójúlówó ìrònúpìwàdà wọn hàn. Lẹ́yìn náà ni ó sọ ẹni tí òun jẹ́ fún wọn ó sì fi ìwà ọ̀làwọ́ dáríjì wọ́n. Ìṣọ̀kan ìdílé ní a mú padàbọ̀sípò. (Genesisi 45:4-8) Gẹ́gẹ́ bíi Kristian, a níláti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú èyí. Ní mímọ àwọn àbájáde búburú ti ìlara, a níláti gbàdúrà sí Jehofa fún ìrànlọ́wọ́ láti lè fi “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú” rọ́pò àwọn ìmọ̀lára owú.
Àwọn Ohun Ìdínà Mìíràn fún Ìyọ́nú
14. Èéṣe tí a fi níláti yẹra fún mímú ara wa wá sábẹ́ agbára ìdarí ìwà-ipá tí kò yẹ?
14 Ohun ìdínà mìíràn fún jíjẹ́ oníyọ̀ọ́nú wa lè jẹyọ láti inú mímú araawa wá sábẹ́ agbára ìdarí ìwà-ipá. Àwọn eré-ìdárayá àti eré-ìnàjú tí ń ṣe ìgbéjáde ìwà-ipá ń gbé ìfẹ́-ọkàn lílágbára fún rírí ìgbádùn nínú ìwà-ipá lárugẹ. Ní àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bibeli, àwọn abọ̀rìṣà máa ń wo àwọn ìjà-ìdíje eléré ìjà ikú àti onírúurú ìdá ènìyàn lóró mìíràn déédéé ní àwọn pápá ìjà-ìdíje ti Ilẹ̀-Ọba Romu. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan ti sọ, irú àwọn eré ìnàjú bẹ́ẹ̀ “sọ ìmọ̀lára ìbánikẹ́dùn nítorí ìjìyà èyí tí ń fìyàtọ̀ sáàárín ẹ̀dá ènìyàn àti ẹranko dòkú.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn eré ìnàjú nínú ayé òde-òní ní ìyọrísí kan náà. Àwọn Kristian, tí wọ́n ń làkàkà láti jẹ́ oníyọ̀ọ́nú lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, gbọ́dọ̀ máa ṣe àṣàyàn lọ́nà gíga níti àwọn ohun tí wọ́n ń yàn fún kíkà, àwọn àwòrán sinimá, àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n. Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́nmu, wọ́n ń fi àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 11:5 sọ́kàn pé: “Ẹni tí ń fẹ́ ìwà agbára, [ni] ọkàn [Jehofa] kórìíra.”
15. (a) Báwo ni ẹnìkan ṣe lè kùnà lọ́nà wíwúwo láti fi ìyọ́nú hàn? (b) Báwo ni àwọn Kristian tòótọ́ ṣe ń dáhùnpadà sí àìní àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn aládùúgbò?
15 Ó tún ṣeéṣe kí ẹnìkan tí ó jẹ́ anìkànjọpọ́n jẹ́ aláìní ìyọ́nú. Èyí léwu gan-an, gẹ́gẹ́ bí aposteli Johannu ti ṣàlàyé pé: “Ẹni yòówù tí ó bá ní àlùmọ́ọ́nì ayé yii fún ìtìlẹyìn ìgbésí-ayé tí ó sì rí i tí arákùnrin rẹ̀ ṣe aláìní síbẹ̀ tí ó sì sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mọ́ ọn, ní ọ̀nà wo ni ìfẹ́ fún Ọlọrun fi dúró ninu rẹ̀?” (1 Johannu 3:17, NW) Àwọn àlùfáà olódodo lójú ara-ẹni àti ọmọ Lefi inú àpèjúwe Jesu nípa aládùúgbò rere ará Samaria fi àìní ìyọ́nú bí irú èyí hàn. Ní rírí ipò ìṣòro arákùnrin ẹlẹgbẹ́ wọn tí ó jẹ́ Ju tí kò tíì kú tán, àwọn wọ̀nyí bọ́ sí òdìkejì ojú-ọ̀nà wọ́n sì ń bá ọ̀nà wọn lọ. (Luku 10:31, 32) Ní ìyàtọ̀ sí èyí, àwọn Kristian oníyọ̀ọ́nú ń tètè dáhùnpadà sí àìní àwọn arákùnrin wọn nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Àti gẹ́gẹ́ bí ará Samaria inú àpèjúwe Jesu, wọ́n tún ń ṣàníyàn nípa àìní àwọn àlejò. Wọ́n ń tipa báyìí yọ̀ọ̀da àkókò, okun, àti àlùmọ́ọ́nì ìgbésí-ayé wọn fún mímú iṣẹ́ sísọni dí ọmọ-ẹ̀yìn gbòòrò síwájú. Ní ọ̀nà yìí wọ́n ń kó ipa pàtàkì nínú ìgbàlà àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn.—1 Timoteu 4:16.
Ìyọ́nú fún Àwọn Tí Ń Ṣàìsàn
16. Àwọn ààlà wo ni a máa ń bá pàdé nígbà tí a bá ń bójútó àwọn ọ̀ràn tí ó jẹmọ́ àìsàn?
16 Àìsàn jẹ́ ìpín aráyé aláìpé, tí ó jẹ́ ẹni kíkú. Èyí kò yọ àwọn Kristian sílẹ̀, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú wọn kìí sìí ṣe oníṣẹ́ ìṣègùn, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi ti àwọn kan lára àwọn Kristian ìgbàanì tí wọ́n gba irú àwọn agbára bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi àti àwọn aposteli rẹ̀. Lẹ́yìn ikú àwọn aposteli Kristi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ ní tààràtà pẹ̀lú wọn, irú àwọn agbára ìyanu bẹ́ẹ̀ ti kọjá lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, agbára-ìṣe wa láti ran àwọn tí ń jìyà àìsàn ti ara, títíkan ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ àti ọdẹ-orí lọ́wọ́, mọníwọ̀n.—Iṣe 8:13, 18; 1 Korinti 13:8.
17. Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ láti inú ọ̀nà tí a gbà bá Jobu ọkùnrin náà tí ń ṣàìsàn tí ó sì ń ṣọ̀fọ̀ lò?
17 Lọ́pọ̀ ìgbà ni ìsoríkọ́ máa ń bá àmódi rìn. Fún àpẹẹrẹ, Jobu olùbẹ̀rù Ọlọrun ní ìsoríkọ́ gidigidi nítorí àìsàn mímúná àti àwọn àjálù-ibi tí Satani mú wá sórí rẹ̀. (Jobu 1:18, 19; 2:7; 3:3, 11-13) Ó nílò àwọn ọ̀rẹ́ tí wọn yóò fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ bá a lò tí wọn yóò sì “sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún” fún un. (1 Tessalonika 5:14, NW) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn olùtùnú mẹ́ta tí a fẹnu lásán pè bẹ́ẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ wọn sì fi ìkùgbù wá sí ìparí èrò tí ó lòdì. Wọ́n mú kí ipò ìsoríkọ́ Jobu túbọ̀ lágbára síi nípa mímẹ́nukàn án pé àwọn àjálù rẹ̀ jẹ́ nítorí àwọn àṣìṣe rẹ̀ kan. Bí wọ́n ti jẹ́ oníyọ̀ọ́nú lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, àwọn Kristian yóò yẹra fún kíkó sínú irú pàkúté bẹ́ẹ̀ nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn bá ń ṣàìsàn tàbí soríkọ́. Ní àwọn ìgbà mìíràn, pàtàkì ohun tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nílò ni ìwọ̀nba ìbẹ̀wò onínúure láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àti àwọn Kristian mìíràn tí wọ́n dàgbàdénú tí wọn yóò fi pẹ̀lú ìbánikẹ́dùn tẹ́tísílẹ̀, fi ìmòye hàn, tí wọ́n yóò sì pèsè ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu.—Romu 12:15; Jakọbu 1:19.
Ìyọ́nú fún Àwọn Aláìlera
18, 19. (a) Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn alàgbà bá àwọn aláìlera tàbí àwọn tí wọ́n ṣe àṣìṣe lò? (b) Bí ó bá tilẹ̀ pọndandan láti ṣètò ìgbìmọ̀ onídàájọ́, èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì fún àwọn alàgbà láti fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ bá àwọn oníwà-àìtọ́ lò?
18 Àwọn alàgbà ní pàtàkì gbọ́dọ̀ jẹ́ oníyọ̀ọ́nú. (Iṣe 20:29, 35) Bibeli pàṣẹ pé, “Ó yẹ kí awa tí a ní okun máa ru àìlera awọn wọnnì tí kò lókun.” (Romu 15:1, NW) Níwọ̀n bí a ti jẹ́ aláìpé, gbogbo wa ni a ń ṣe àṣìṣe. (Jakọbu 3:2) Ìwà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ni a nílò nínú ìbálò wa pẹ̀lú ẹnìkan tí ó “ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nipa rẹ̀.” (Galatia 6:1, NW) Àwọn alàgbà kò jẹ́ fẹ́ láti dàbí àwọn Farisi tí wọ́n jẹ́ olódodo lójú araawọn tí wọ́n jẹ́ aláìfòyebánilò nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi Òfin Ọlọrun sílò.
19 Ní ìyàtọ̀, àwọn alàgbà ń tẹ̀lé àwọn àpẹẹrẹ oníyọ̀ọ́nú lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi. Pàtàkì iṣẹ́ wọn ni láti gbéró, fún ní ìṣírí, kí wọ́n sì tu àwọn àgùtàn Ọlọrun lára. (Isaiah 32:1, 2) Dípò gbígbìyànjú láti darí àwọn ọ̀ràn nípasẹ̀ àwọn ìlànà jáǹtìrẹrẹ, wọ́n ń fọ̀rànlọ àwọn ìlànà rere tí ń bẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Fún ìdí yìí, iṣẹ́ àwọn alàgbà níláti jẹ́ láti gbéniró, láti mú ìdùnnú àti ìmọrírì fún ìwàrere-ìṣeun Jehofa wá sínú ọkàn-àyà àwọn arákùnrin wọn. Bí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kan bá ṣe àṣìṣe tí kò tó nǹkan, alàgbà kan yóò yẹra fún títọ́ ọ sọ́nà ní etígbọ̀ọ́ àwọn ẹlòmíràn. Bí ó bá pọndandan rárá láti sọ̀rọ̀, ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ìyọ́nú yóò sún alàgbà náà láti mú onítọ̀hún bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kí ó sì jíròrò ìṣòro náà níbi tí àwọn ẹlòmíràn kò ti ní gbọ́ wọn. (Fiwé Matteu 18:15.) Bí ó ti wù kí ẹnìkan ṣòro láti bá lò tó, ọ̀nà ìgbàyọsíni alàgbà náà níláti jẹ́ ti onísùúrù, olóye àti èyí tí ń rannilọ́wọ́. Òun kì yóò fẹ́ láti wá àwọn àwáwí láti lè lé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò nínú ìjọ. Kódà nígbà tí ó bá pọndandan láti ṣètò ìgbìmọ̀ onídàájọ́, àwọn alàgbà yóò fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn nínú ìbálò wọn pẹ̀lú ẹni tí ó lọ́wọ́ nínú ìwà-àìtọ́ wíwúwo náà. Ìwà pẹ̀lẹ́ wọn lè ṣèrànwọ́ láti mú ẹni náà wá sí ìrònúpìwàdà.—2 Timoteu 2:24-26.
20. Nígbà wo ni fífi ìyọ́nú ti ìmí-ẹ̀dùn hàn kò ní jẹ́ ohun yíyẹ, èésìtiṣe?
20 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àkókò máa ń wà nígbà tí ìránṣẹ́ Jehofa kò lè fi ìyọ́nú hàn. (Fiwé Deuteronomi 13:6-9.) Fún Kristian kan láti “jáwọ́ dídarapọ̀ ninu ìbákẹ́gbẹ́pọ̀” pẹ̀lú ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan tímọ́tímọ́ kan tí a ti yọlẹ́gbẹ́ lè jẹ́ ìdánwò gidi kan nítòótọ́. Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹnìkan máṣe juwọ́sílẹ̀ fún ìmọ̀lára ìkáàánú. (1 Korinti 5:11-13, NW) Irú ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ lè fún ẹni tí ó ṣe àṣìṣe náà ní ìṣírí láti ronúpìwàdà. Síwájú síi, nínú ìbálò wọn pẹ̀lú ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà òdìkejì, àwọn Kristian gbọ́dọ̀ yẹra fún fífi ìyọ́nú hàn lọ́nà tí kò yẹ èyí tí ó lè jálẹ̀ sí ìwà pálapàla takọtabo.
21. Ní àwọn agbègbè mìíràn wo ni ó ti yẹ kí a fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí sì ni àwọn àǹfààní rẹ̀?
21 A kò ní àlàfo àyè tí ó pọ̀ tó láti jíròrò gbogbo àgbègbè púpọ̀ tí ó wà nínú èyí tí a ti nílò ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́—nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà, àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀, àwọn wọnnì tí ń jìyà inúnibíni láti ọ̀dọ̀ alábàáṣègbéyàwó tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Bákan náà pẹ̀lú ni ó yẹ kí a bá àwọn alàgbà tí ń ṣiṣẹ́ kára lò pẹ̀lú ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. (1 Timoteu 5:17) Bọ̀wọ̀ fún wọn kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn. (Heberu 13:7, 17) Aposteli Peteru kọ̀wé pé: “Gbogbo yín . . . ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.” (1 Peteru 3:8, NW) Nípa híhùwà ní ọ̀nà yìí lábẹ́ gbogbo ipò tí ó bá béèrè fún un, a ń gbé ìṣọ̀kan àti ayọ̀ lárugẹ nínú ìjọ a sì ń mú kí òtítọ́ fa àwọn ará ìta mọ́ra. Lékè gbogbo rẹ̀, a ń tipa báyìí bọlá fún Bàbá wa, Jehofa, oníyọ̀ọ́nú lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Báwo ni Jehofa ṣe fi ìyọ́nú hàn fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀?
◻ Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti ní ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí ó lè dí wa lọ́wọ́ láti máṣe ní ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́?
◻ Báwo ni ó ṣe yẹ kí a bá àwọn aláìsàn àti àwọn tí ó soríkọ́ lò?
◻ Àwọn wo ní pàtàkì ni wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, èésìtiṣe?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
ÀWỌN FARISI ALÁÌNÍYỌ̀Ọ́NÚ
ỌJỌ́ ìsinmi Sábáàtì ni a retí pé kí ó jẹ́ ìbùkún ti ara àti tẹ̀mí fún àwọn ènìyàn Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn aṣáájú ìsìn àwọn Ju ṣe ìgbékalẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ìlànà tí kò bọlá fún òfin Sábáàtì ti Ọlọrun wọ́n sì sọ ọ́ di ẹrù-ìnira fún àwọn ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, bí jàm̀bá bá ṣẹlẹ̀ sí ẹnìkan tàbí bí àìsàn bá ṣe é, kò lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà ní ọjọ́ Sábáàtì àyàfi bí ìwàláàyè rẹ̀ bá wà nínú ewu.
Ilé-ẹ̀kọ́ àwọn Farisi kan mógìírí tóbẹ́ẹ̀ lórí ọ̀nà tí ó gbà ṣètumọ̀ òfin Sábáàtì débi tí ó fi sọ pé: “Ẹnìkan kìí tu àwọn aṣọ̀fọ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbọdọ̀ bẹ àwọn tí ń ṣàìsàn wò ní ọjọ́ Sábáàtì.” Àwọn aṣáájú ìsìn mìíràn yọ̀ọ̀da fún irú àbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ Sábáàtì ṣùgbọ́n wọ́n sọ pàtó pé: “Omijé ni a kàléèwọ̀.”
Nípa báyìí, Jesu fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ dẹ́bi fún àwọn aṣáájú ìsìn Ju fún gbígbójúfo àwọn ohun ṣíṣe pàtàkì jù tí Òfin béèrè fún, irú bí ìdájọ́-òdodo, ìfẹ́, àti àánú. Abájọ nígbà náà tí ó fi sọ fún àwọn Farisi pé: “Ẹ . . . sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ nípasẹ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín”!—Marku 7:8, 13, NW; Matteu 23:23; Luku 11:42.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ní àwọn ilẹ̀ 231 àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe iṣẹ́ ìyọ́nú tí kò ní àfiwé nínú ilé àwọn ènìyàn, ní àwọn òpópónà, àní ní àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n pàápàá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Mímú ara ẹni wá sábẹ́ agbára ìdarí ìwà-ipá, bíi nípasẹ̀ ohun tí a ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n, ń jin ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ lẹ́sẹ̀