ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 12/15 ojú ìwé 28-29
  • Jèhófà Ń Fi Ìyọ́nú Ṣàkóso

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ń Fi Ìyọ́nú Ṣàkóso
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífarawé Ìyọ́nú Jèhófà
  • Ìyọ́nú Nínú Ayé Oníkà
  • Máa Ṣàánú Fáwọn Ẹlòmíì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Máa Fàánú Hàn Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Ẹ Ní Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 12/15 ojú ìwé 28-29

Jèhófà Ń Fi Ìyọ́nú Ṣàkóso

JÁLẸ̀ ìtàn, ọ̀pọ̀ alákòóso ẹ̀dá ènìyàn ti lo agbára wọn láìka ìjìyà àwọn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí sí. Ṣùgbọ́n, Jèhófà pèsè ìyàtọ̀ pátápátá nípa yíyan orílẹ̀-èdè kan—Ísírẹ́lì—tí ó sì fi ìyọ́nú ṣàkóso rẹ̀.

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì jẹ́ ẹrú ní Íjíbítì ìgbàanì, Jèhófà gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́. “Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un. . . . Nínú ìfẹ́ rẹ̀ àti nínú ìyọ́nú rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ tún wọn rà.” (Aísáyà 63:9, NW) Jèhófà gba Ísírẹ́lì sílẹ̀, ó pèsè oúnjẹ fún wọn lọ́nà ìyanu, ó sì mú wọn dé ilẹ̀ àwọn tìkára wọn.

Ìwà ìyọ́nú Jèhófà tún jẹ yọ síwájú sí i nínú àwọn òfin tí ó fún orílẹ̀-èdè yí. Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fi ìyọ́nú bá àwọn ọmọ aláìlóbìí, opó, àti àwọn àtìpó olùgbé lò. Wọn kò gbọ́dọ̀ kófà àwọn aláàbọ̀ ara.

Òfin béèrè pé kí a fi ìyọ́nú hàn sí àwọn aláìní. Àwọn òtòṣì lè pèéṣẹ́ lẹ́yìn ìkórè. A máa ń wọ́gi lé gbèsè nígbà ọdún Sábáàtì (ọdún keje). A gbọ́dọ̀ dá gbogbo ilẹ̀ tí a jogún, tí a ti tà pa dà ní ọdún Júbílì (ọdún àádọ́ta). Ìwé Ancient Israel—Its Life and Institutions ròyìn pé: “Ní Ísírẹ́lì, kò fìgbà kan sí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ irú èyí tí ó wà ní òde òní.” “Nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí i tẹ̀dó, gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ni ó gbádùn àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bára dọ́gba.”—Léfítíkù 25:10; Diutarónómì 15:12-14; 24:17-22; 27:18.

Fífarawé Ìyọ́nú Jèhófà

Ìyọ́nú Ọlọ́run ń sún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, jálẹ̀ ìtàn, àwọn ọba tuntun kan ti pa àwọn mẹ́ńbà ìlà ìdílé ọba àná tí ó kù láyé. Ṣùgbọ́n Dáfídì ìránṣẹ́ Jèhófà kò ṣe èyí. Lẹ́yìn ikú Ọba Sọ́ọ̀lù, Dáfídì dáàbò bo Mefibóṣẹ́tì, ọmọ ọmọ Sọ́ọ̀lù àti ajogún rẹ̀, tí ó kù láyé. “Ọba ní ìyọ́nú sí Mefibóṣẹ́tì ọmọkùnrin Jónátánì ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù.”—Sámúẹ́lì Kejì 21:7, NW.

Kò sí ẹ̀dá ènìyàn kankan tí ó fara wé ìyọ́nú Jèhófà tó Jésù. Ìyọ́nú Ọlọ́run ni ó sún un ṣe ọ̀pọ̀ nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Nígbà kan, adẹ́tẹ̀ kan pàrọwà fún un pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Àánú ṣe Jésù, ó sì fọwọ́ kàn án, ó wí pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” (Máàkù 1:40-42) Ní àkókò míràn, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn tẹ̀ lé Jésù. Láàárín ariwo gèè náà, Jésù kọbi ara sí àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tí wọ́n kígbe pé: “‘Olúwa, ṣàánú fún wa, Ọmọkùnrin Dáfídì!’ . . . Bí àánú ti ṣe é, Jésù fọwọ́ kan ojú wọn, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n sì ríran.”—Mátíù 20:29-34.

Pé èrò pọ̀ kò ní kí àánú àwọn ẹlòmíràn má ṣe Jésù. Nítorí tí ó ti pẹ́ tí wọ́n ti jẹun kẹ́yìn, ó sọ nígbà kan pé: “Àánú ogunlọ́gọ̀ náà ń ṣe mí.” Nítorí náà, ó bọ́ wọn lọ́nà ìyanu. (Máàkù 8:1-8) Nígbà tí Jésù ń rìnrìn àjò kiri, kì í ṣe pé ó ń kọ́ ogunlọ́gọ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n, ó tún wà lójúfò sí àìní wọn. (Mátíù 9:35, 36) Lẹ́yìn irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò ní àkókò kankan tí ọwọ́ dilẹ̀ àní láti jẹun pàápàá. Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ fún wa pé: “Nítorí náà wọ́n gbéra lọ nínú ọkọ̀ lọ sí ibi tí ó dá ní àwọn nìkan. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn rí wọn tí wọ́n ń lọ ọ̀pọ̀ sì mọ̀ nípa rẹ̀, àti láti gbogbo àwọn ìlú ńlá náà wọ́n fi ẹsẹ̀ sáré lọ sí ibẹ̀ pa pọ̀ wọ́n sì ṣáájú wọn. Tóò, ní jíjáde, ó rí ogunlọ́gọ̀ ńlá, ṣùgbọ́n àánú wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.”—Máàkù 6:31-34.

Kì í wulẹ̀ ṣe àìsàn àti ipò òṣì àwọn ènìyàn ni ó ru ìmọ̀lára Jésù sókè, bí kò ṣe ipò tẹ̀mí wọn. Àwọn aṣáájú wọn ti kó wọn nífà, nítorí náà, “àánú wọ́n ṣe” Jésù. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà fún “àánú wọ́n ṣe é” túmọ̀ sí “láti nímọ̀lára pé àwọn ìfun ẹni ń yán hànhàn.” Jésù mà jẹ́ oníyọ̀ọ́nú ní tòótọ́ o!

Ìyọ́nú Nínú Ayé Oníkà

Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba ọ̀run ti Jèhófà nísinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Ọlọ́run ń fi ìyọ́nú ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ̀ lónìí. “‘Dájúdájú, wọn yóò sì di tèmi,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘ní ọjọ́ náà nígbà tí èmi yóò mú àkànṣe dúkìá wá. Èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí wọn.’”—Málákì 3:17, NW.

Àwọn tí wọ́n fẹ́ láti jàǹfààní ìyọ́nú Jèhófà gbọ́dọ̀ fara wé ọ̀nà rẹ̀. Ní tòótọ́, a ń gbé nínú ayé tí àwọn ènìyàn ti nífẹ̀ẹ́ nínú bíbá ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn nìṣó ju nínú ríran àwọn aláìní lọ́wọ́. Àwọn ẹni ńlá sábà máa ń wá èrè ní fífi ààbò àwọn òṣìṣẹ́ àti oníbàárà wọn sínú ewu. Ní Tímótì Kejì 3:1-4, Bíbélì, lọ́nà pípéye, ṣàpèjúwe ipò ìwà rere àkókò wa, tí ó ti pa ìyọ́nú ọkàn ọ̀pọ̀ ènìyàn kú tán.

Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí a rí àǹfààní láti fi ìyọ́nú hàn. A ha lè pèsè ìrànwọ́ tí àwọn aládùúgbò wá nílò fún wọn bí? Ẹnì kan ha wà tí ń ṣàìsàn tí a lè bẹ̀ wò bí? A ha lè tu àwọn tí ó sorí kọ́ nínú bí, ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn náà: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún fún àwọn ọkàn tí ó sorí kọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera”?—Tẹsalóníkà Kíní 5:14.

Ìyọ́nú yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún híhùwà pa dà lọ́nà òǹrorò nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá ṣàṣìṣe. A sọ fún wa pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìkorò onínú-burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú. Ṣùgbọ́n kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nìkíní kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín lẹ́nìkíní kejì fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.”—Éfésù 4:31, 32.

Ìyọ́nú yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìtẹ̀sí láti ṣi agbára wa lò. Bíbélì sọ pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” (Kólósè 3:12) Ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti fi ara wa sí ipò àwọn tí ó wà lábẹ́ wa. Jíjẹ́ oníyọ̀ọ́nú ní í ṣe pẹ̀lú jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti olùfòyemọ̀, dípò kí a jẹ́ ẹni tí ó ṣòro láti tẹ́ lọ́rùn. Kò yẹ kí a fi ìjáfáfá kẹ́wọ́ fún bíbá àwọn ènìyàn lò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ara ẹ̀rọ kan lásán. Bákan náà, nínú ìdílé, àwọn ọkọ oníyọ̀ọ́nú ń rántí pé àwọn aya wọ́n jẹ́ ohun ìlò aláìlerató. (Pétérù Kíní 3:7) Ríronú lórí àpẹẹrẹ ìyọ́nú Jésù lè ràn wá lọ́wọ́ nínú gbogbo èyí.

Níwọ̀n bí àánú àwọn ènìyàn ti ṣe Jésù gidigidi nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, a lè ní ìdánilójú pé òun jẹ́ Alákòóso oníyọ̀ọ́nú nísinsìnyí, òun yóò sì máa bá a lọ láti jẹ́ bẹ́ẹ̀. Orin Dáfídì 72 sọ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “Òun yóò máa ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà ènìyàn, yóò máa gba àwọn ọmọ àwọn aláìní, yóò sì fa aninilára ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Òun yóò sì jọba láti òkun dé òkun, àti láti odò nì dé òpin ayé. Òun yóò dá tálákà àti aláìní sí, yóò sì gba ọkàn àwọn aláìní là.”—Orin Dáfídì 72:4, 8, 13.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ tálákà, yóò sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ fún àwọn ọlọ́kàn tútù ayé; . . . [yóò] lu àwọn ènìyàn búburú pa.” Lẹ́yìn ṣíṣàpèjúwe bí àwọn ènìyàn burúkú bí ẹranko ẹhànnà yóò ṣe yí ọ̀nà wọn pa dà, àsọtẹ́lẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Wọn kì yóò pani lára, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò pani run ní gbogbo òkè mímọ́ mi: nítorí ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:4-9) Ní ti gidi, àwùjọ ènìyàn kárí ayé, tí wọ́n mọ Jèhófà, tí wọ́n sí fara wé ọ̀nà oníyọ̀ọ́nú mà ni ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yí ń ṣèlérí rẹ̀ o!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́