Diutarónómì
27 Mósè pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà pé: “Kí ẹ pa gbogbo àṣẹ tí mò ń pa fún yín lónìí mọ́. 2 Ní ọjọ́ tí ẹ bá sọdá Jọ́dánì sí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, kí ẹ to àwọn òkúta ńláńlá jọ, kí ẹ sì rẹ́ ẹ.*+ 3 Kí ẹ wá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí sára wọn tí ẹ bá ti sọdá, kí ẹ lè wọ ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ṣe ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́.+ 4 Tí ẹ bá ti sọdá Jọ́dánì, kí ẹ to àwọn òkúta yìí sórí Òkè Ébálì,+ kí ẹ sì rẹ́ ẹ,* bí mo ṣe ń pa á láṣẹ fún yín lónìí. 5 Kí ẹ tún mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, òkúta ni kí ẹ fi mọ ọ́n. Ẹ má fi irin gbẹ́ ẹ.+ 6 Odindi òkúta ni kí ẹ fi mọ pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà Ọlọ́run yín lórí rẹ̀. 7 Kí ẹ rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ kí ẹ jẹ ẹ́ níbẹ̀,+ kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 8 Kí ẹ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ inú Òfin yìí sára àwọn òkúta náà, kó sì hàn kedere.”+
9 Mósè àtàwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì wá sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ ti di èèyàn Jèhófà Ọlọ́run yín lónìí.+ 10 Kí ẹ máa fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ+ àti ìlànà rẹ̀ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún yín lónìí.”
11 Mósè pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà lọ́jọ́ yẹn pé: 12 “Àwọn ẹ̀yà yìí ló máa dúró lórí Òkè Gérísímù+ láti súre fún àwọn èèyàn náà tí ẹ bá ti sọdá Jọ́dánì: Síméónì, Léfì, Júdà, Ísákà, Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. 13 Àwọn ẹ̀yà yìí ló sì máa dúró lórí Òkè Ébálì+ láti kéde ègún: Rúbẹ́nì, Gádì, Áṣérì, Sébúlúnì, Dánì àti Náfútálì. 14 Kí àwọn ọmọ Léfì gbóhùn sókè dáadáa, kí wọ́n sì sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì pé:+
15 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá gbẹ́ ère+ tàbí tó ṣe ère onírin,*+ tó jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣẹ́ ọnà,* tó sì gbé e pa mọ́.’ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’*)
16 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá fojú kéré bàbá àti ìyá rẹ̀.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
17 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá sún ààlà ọmọnìkejì rẹ̀.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
18 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá mú kí afọ́jú ṣìnà.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
19 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá ṣe èrú nínú ẹjọ́+ àjèjì, ọmọ aláìníbaba* tàbí opó.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
20 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá bá ìyàwó bàbá rẹ̀ sùn, torí ó ti dójú ti bàbá rẹ̀.’*+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
21 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá bá ẹranko èyíkéyìí lò pọ̀.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
22 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá bá arábìnrin rẹ̀ sùn, ì báà jẹ́ ọmọ bàbá rẹ̀ tàbí ọmọ ìyá rẹ̀.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
23 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá bá ìyá ìyàwó rẹ̀ sùn.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
24 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá lúgọ de ọmọnìkejì rẹ̀, tó sì pa á.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
25 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀.’*+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
26 “‘Ègún ni fún ẹni tí kò bá pa àwọn ọ̀rọ̀ inú Òfin yìí mọ́ láti fi hàn pé ó fara mọ́ wọn.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)