ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Ó gbẹ́ wàláà òkúta méjì míì (1-11)

      • Ohun tí Jèhófà fẹ́ (12-22)

        • Bẹ̀rù Jèhófà, kí o sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ (12)

Diutarónómì 10:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “áàkì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:1

Diutarónómì 10:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:4

Diutarónómì 10:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá.”

  • *

    Tàbí “kóra jọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:15
  • +Ẹk 20:1; 34:28; Di 4:13
  • +Di 4:36; 5:4
  • +Ẹk 19:17; Di 5:22

Diutarónómì 10:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2006, ojú ìwé 31

Diutarónómì 10:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 20:23, 24; 33:31, 38
  • +Nọ 20:28

Diutarónómì 10:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ilẹ̀ olómi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:33

Diutarónómì 10:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:50; 3:6; 8:14
  • +Nọ 3:30, 31
  • +Nọ 6:23-27; Di 21:5; 2Kr 30:27

Diutarónómì 10:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:20, 24; Di 18:1

Diutarónómì 10:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 24:18; 34:28
  • +Ẹk 32:14

Diutarónómì 10:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:18

Diutarónómì 10:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 6:8
  • +Di 5:29
  • +Di 5:33; Joṣ 22:5
  • +Di 6:5; Lk 10:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 25

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2009, ojú ìwé 10

Diutarónómì 10:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 6:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2009, ojú ìwé 10

Diutarónómì 10:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ọ̀run tó ga jù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:11; Sm 24:1; 115:16

Diutarónómì 10:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:37

Diutarónómì 10:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “dá ọkàn yín bí ẹni dá adọ̀dọ́.”

  • *

    Ní Héb., “ẹ má sì mú ọrùn yín le.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:6
  • +Ẹk 34:9; Di 9:6; 31:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2007, ojú ìwé 13

Diutarónómì 10:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 18:11; 2Kr 2:5; Sm 97:9
  • +Iṣe 10:34; Ro 2:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 114

Diutarónómì 10:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aláìlóbìí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 68:5; Jem 1:27
  • +Le 19:10; Di 24:14; Sm 146:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 113-114

Diutarónómì 10:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:21; Le 19:34

Diutarónómì 10:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 4:8

Diutarónómì 10:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:2; Ifi 19:6
  • +2Sa 7:23

Diutarónómì 10:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:27; Ẹk 1:5; Iṣe 7:14
  • +Jẹ 15:1, 5

Àwọn míì

Diu. 10:1Ẹk 34:1
Diu. 10:3Ẹk 34:4
Diu. 10:4Ẹk 32:15
Diu. 10:4Ẹk 20:1; 34:28; Di 4:13
Diu. 10:4Di 4:36; 5:4
Diu. 10:4Ẹk 19:17; Di 5:22
Diu. 10:5Ẹk 34:29
Diu. 10:6Nọ 20:23, 24; 33:31, 38
Diu. 10:6Nọ 20:28
Diu. 10:7Nọ 33:33
Diu. 10:8Nọ 1:50; 3:6; 8:14
Diu. 10:8Nọ 3:30, 31
Diu. 10:8Nọ 6:23-27; Di 21:5; 2Kr 30:27
Diu. 10:9Nọ 18:20, 24; Di 18:1
Diu. 10:10Ẹk 24:18; 34:28
Diu. 10:10Ẹk 32:14
Diu. 10:11Jẹ 15:18
Diu. 10:12Mik 6:8
Diu. 10:12Di 5:29
Diu. 10:12Di 5:33; Joṣ 22:5
Diu. 10:12Di 6:5; Lk 10:27
Diu. 10:13Di 6:24
Diu. 10:141Kr 29:11; Sm 24:1; 115:16
Diu. 10:15Di 4:37
Diu. 10:16Di 30:6
Diu. 10:16Ẹk 34:9; Di 9:6; 31:27
Diu. 10:17Ẹk 18:11; 2Kr 2:5; Sm 97:9
Diu. 10:17Iṣe 10:34; Ro 2:11
Diu. 10:18Sm 68:5; Jem 1:27
Diu. 10:18Le 19:10; Di 24:14; Sm 146:9
Diu. 10:19Ẹk 22:21; Le 19:34
Diu. 10:20Lk 4:8
Diu. 10:21Ẹk 15:2; Ifi 19:6
Diu. 10:212Sa 7:23
Diu. 10:22Jẹ 46:27; Ẹk 1:5; Iṣe 7:14
Diu. 10:22Jẹ 15:1, 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 10:1-22

Diutarónómì

10 “Ìgbà yẹn ni Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Kí ìwọ fúnra rẹ gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́,+ kí o sì wá bá mi lórí òkè náà; kí ìwọ fúnra rẹ tún fi pákó ṣe àpótí.* 2 Màá kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lórí àwọn wàláà àkọ́kọ́ tí o fọ́ túútúú sára wàláà tí o bá gbẹ́, kí o sì gbé e sínú àpótí náà.’ 3 Torí náà, mo fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àpótí kan, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́, mo gun òkè náà lọ pẹ̀lú wàláà méjèèjì ní ọwọ́ mi.+ 4 Ó wá kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ti kọ tẹ́lẹ̀ sára àwọn wàláà náà,+ ìyẹn Òfin Mẹ́wàá,*+ tí Jèhófà bá yín sọ lórí òkè náà látinú iná,+ ní ọjọ́ tí ẹ pé jọ;*+ Jèhófà sì kó o fún mi. 5 Mo pa dà, mo sì sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè náà,+ mo gbé àwọn wàláà náà sínú àpótí tí mo ṣe, wọ́n sì wà níbẹ̀, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún mi gẹ́lẹ́.

6 “Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbéra ní Béérótì Bene-jáákánì lọ sí Mósírà. Ibẹ̀ ni Áárónì kú sí, ibẹ̀ sì ni wọ́n sin ín sí,+ Élíásárì ọmọ rẹ̀ wá di àlùfáà dípò rẹ̀.+ 7 Wọ́n gbéra láti ibẹ̀ lọ sí Gúdígódà, láti Gúdígódà lọ sí Jótíbátà,+ ilẹ̀ tó ní àwọn odò tó ń ṣàn.*

8 “Ìgbà yẹn ni Jèhófà ya ẹ̀yà Léfì sọ́tọ̀+ kí wọ́n lè máa gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà,+ kí wọ́n sì máa dúró níwájú Jèhófà, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ fún un, kí wọ́n sì máa fi orúkọ rẹ̀ súre,+ bí wọ́n ṣe ń ṣe títí dòní. 9 Ìdí nìyẹn tí wọn ò fi fún Léfì ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀. Jèhófà ni ogún rẹ̀, bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe sọ fún un.+ 10 Èmi fúnra mi dúró sórí òkè náà bí mo ṣe ṣe nígbà àkọ́kọ́ fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru,+ Jèhófà sì tún gbọ́ mi ní àkókò yẹn.+ Jèhófà ò fẹ́ pa yín run. 11 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Máa lọ níwájú àwọn èèyàn náà, kí ẹ múra láti gbéra, kí wọ́n lè lọ gba ilẹ̀ tí mo búra fún àwọn baba ńlá wọn pé màá fún wọn.’+

12 “Ní báyìí, ìwọ Ísírẹ́lì, kí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ kí o ṣe?+ Kò ju pé: kí o máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí o máa fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ 13 kí o sì máa pa àwọn òfin àti àṣẹ Jèhófà tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́ fún àǹfààní ara rẹ.+ 14 Wò ó, Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló ni ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run,* pẹ̀lú ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀.+ 15 Àwọn baba ńlá yín nìkan ni Jèhófà sún mọ́ tó sì fi ìfẹ́ hàn sí, ó sì ti yan ẹ̀yin ọmọ wọn+ nínú gbogbo èèyàn, bí ẹ ṣe jẹ́ lónìí yìí. 16 Ní báyìí, kí ẹ wẹ ọkàn yín mọ́,*+ kí ẹ má sì ṣe agídí* mọ́.+ 17 Torí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run+ àti Olúwa àwọn olúwa, Ọlọ́run tó tóbi, tó lágbára, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tí kì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni,+ tí kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 18 Ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba* àti opó,+ ó sì nífẹ̀ẹ́ àjèjì,+ ó ń fún un ní oúnjẹ àti aṣọ. 19 Kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ àjèjì, torí ẹ di àjèjì ní ilẹ̀ Íjíbítì.+

20 “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o máa bẹ̀rù, òun ni kí o máa sìn,+ òun ni kí o rọ̀ mọ́, orúkọ rẹ̀ sì ni kí o máa fi búra. 21 Òun ni Ẹni tí wàá máa yìn.+ Òun ni Ọlọ́run rẹ, tó ṣe gbogbo ohun àgbàyanu àtàwọn ohun tó ń dẹ́rù bani yìí fún ọ, tí o sì fi ojú ara rẹ rí i.+ 22 Àwọn baba ńlá rẹ àti ìdílé wọn jẹ́ àádọ́rin (70) èèyàn* nígbà tí wọ́n lọ sí Íjíbítì,+ àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti mú kí o pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́