ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
    Ilé Ìṣọ́—2009 | October 1
    • Kí Ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?

      Diutarónómì 10:12, 13

      KÌ Í fi gbogbo ìgbà rọrùn tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣègbọràn tàbí ká má ṣègbọràn. Bí ọ̀gá kan bá jẹ́ ẹni líle tàbí ẹni tó máa ń rin kinkin, ìgbọ́ràn tí àwọn tó wà lábẹ́ rẹ̀ á máa fún un kò ní tọkàn wọn wá. Àmọ́, tọkàntọkàn làwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run fi ń ṣègbọràn sí i. Kí nìdí? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ nínú Diutarónómì 10:12, 13.a

      Nígbà tí Mósè ń ṣàkópọ̀ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń fẹ́, ó béèrè ìbéèrè pàtàkì yìí pé: “Kí sì ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń béèrè lọ́wọ́ rẹ”? (Ẹsẹ 12) Ọlọ́run lẹ́tọ̀ọ́ láti béèrè ohunkóhun tó fẹ́ lọ́wọ́ wa. Ó ṣe tán, òun ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, òun náà ni Orísun ìwàláàyè wa àti Ẹni tó ń gbé e ró. (Sáàmù 36:9; Aísáyà 33:22) Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti béèrè pé ká jẹ́ onígbọràn. Síbẹ̀, kì í fipá mú wa. Kí ló ń béèrè lọ́wọ́ wa? Ohun tó ń béèrè ni pé ká jẹ́ “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà.”—Róòmù 6:17.

      Kí ló lè mú ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run látọkàn wá? Mósè sọ ohun pàtàkì kan tó lè ràn wá lọ́wọ́, ó ní: “Bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”b (Ẹsẹ 12) Ìbẹ̀rù yìí kì í ṣe ìbẹ̀rù oníjìnnìjìnnì bíi tẹni tó ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, àmọ́ ó jẹ́ ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀. Tá a bá ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ohun tó lè mú un bínú.

      Kí ni olórí ohun tó yẹ kó mú ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run? Mósè sọ pé: ‘Máa fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kó o sì máa sìn ín.’ (Ẹsẹ 12) Ìfẹ́ fún Ọlọ́run ju ohun tí èèyàn kàn ń rò lọ́kàn lọ. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Nígbà míì, wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù tó wà fún ohun tí ẹnì kan ń rò lọ́kàn fún ohun tí èrò náà mú kó ṣe.” Ìwé yẹn tún sọ pé ohun tó túmọ̀ sí láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni pé, kéèyàn máa fìfẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Lẹ́nu kan ṣá, tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́, a óò máa ṣe ohun tá a mọ̀ pé ó máa múnú rẹ̀ dùn.—Òwe 27:11.

      Báwo ló ṣe yẹ kí ìgbọràn wa sí Ọlọ́run jinlẹ̀ tó? Mósè sọ pé: “Máa rìn ní gbogbo ọ̀nà [Ọlọ́run].” (Ẹsẹ 12) Jèhófà fẹ́ ká ṣe gbogbo nǹkan tó ń béèrè lọ́wọ́ wa? Ṣé irú ìgbọràn àtọkànwá bẹ́ẹ̀ máa ṣèpalára fún wa? Rárá o.

  • Kí Ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
    Ilé Ìṣọ́—2009 | October 1
    • a Lóòótọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ ni Mósè ń bá sọ̀rọ̀, síbẹ̀ ìlànà tó wà níbẹ̀ kan gbogbo ẹni tó bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn.—Róòmù 15:4.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́