Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 11
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 11
Orin 34 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 6 ìpínrọ̀ 9 sí 16 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 69-73 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 72:1-20 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Tòótọ́ Bá Àkọsílẹ̀ Ìṣẹ̀dá Tó Wà Nínú Bíbélì Mu—td 29A (5 min.)
No. 3: Ẹ̀kọ́ Táwọn Ọ̀dọ́ Lè Rí Kọ́ Lára Hesekáyà àti Jòsáyà Ọba (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Lo Ìbéèrè Láti Kọ́ni Lọ́nà tó Múná Dóko—Apá 3. Ìjíròrò tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 238, ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 239. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn kókó kan tàbí méjì látinú àpilẹ̀kọ náà.
10 min: “Máa Fi ‘Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́’ Hàn.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
10 min: Ẹ Máa Wádìí Dájú Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù. (Fílí. 1:10) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn olórí ìdílé méjì tí wọ́n máa ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ déédéé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wọn máa ń dí lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti bójú tó nínú ìdílé. Báwo ni wọ́n ṣe máa ń wá àyè jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú bí ọwọ́ wọn ṣe máa ń dí? Báwo ni àwọn àti ìdílé wọn ṣe jàǹfààní látinú bí wọ́n ṣe ń kópa déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?
Orin 73 àti Àdúrà