Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Lóṣù December ọdún 2010, a kọ́ àwọn èèyàn tí iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé àádọ́ta lé nírínwó àti mẹ́fà [600,456], lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé wọn. Ó dájú pé ńṣe ni ọ̀rọ̀ ọ̀pọ̀ lára wọn máa dà bíi ti ẹnì kan tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní abúlé kan, tó sọ pé: “A ti ń gbàdúrà pé kí àwọn èèyàn wá máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Bẹ́ ẹ ṣe wá síbí yìí fi hàn pé Ọlọ́run ti dáhùn àdúrà wa. Ẹ fara balẹ̀ dáhùn àwọn ìbéèrè wa, ẹ sì ṣàlàyé Bíbélì lọ́nà tó tọ́.” Ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti ṣèrànwọ́ fún irú àwọn èèyàn wọ̀nyí tó ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́.—Mát. 7:13, 14.