Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 25
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 25
Orin 97 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 7 ìpínrọ̀ 1 sí 8, àti àpótí tó wà lójú ìwé 53 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 79-86 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 84:1–85:7 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú Sí?—td 2A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Fi Gbà Pé Ọlọ́run Wà—Ják. 2:19 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀. Sọ ìwé tá a máa lò lóde ẹ̀rí lóṣù August, kó o sì ṣe àṣefihàn kan nípa bá a ṣe lè lò ó.
10 min: Wọ́n Ń Wàásù Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Aláìlera Ni Wọ́n. Ìjíròrò tó dá lórí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2003, àpótí tó wà lójú ìwé 6. Fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2008, ojú ìwé 19 sí 21. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìrírí kọ̀ọ̀kan, ní kí àwọn ará sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
20 min: “A Ṣe Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Kó Lè Fa Ọ̀pọ̀ Èèyàn Mọ́ra.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 2, fi ìṣẹ́jú kan sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà nínú Jí! July–September. Lẹ́yìn náà, kó o ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀, kó o sì ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Jí! náà lóde ẹ̀rí. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 3, kó o ṣe ohun kan náà nípa Ilé Ìṣọ́ August 1.
Orin 134 àti Àdúrà