ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/11 ojú ìwé 3
  • A Ṣe Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Kó Lè Fa Ọ̀pọ̀ Èèyàn Mọ́ra

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ṣe Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Kó Lè Fa Ọ̀pọ̀ Èèyàn Mọ́ra
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àyípadà Kíkọyọyọ Ti Bá Ilé Ìṣọ́!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ilé Ìṣọ́ Ẹ̀dà Tuntun Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!—Àwọn Àkànṣe Ìwé-Ìròyìn Òtítọ́ Bíbọ́sákòókò
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 7/11 ojú ìwé 3

A Ṣe Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Kó Lè Fa Ọ̀pọ̀ Èèyàn Mọ́ra

1. Báwo ni ẹ̀rú olóòótọ́ àti olóye ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?

1 Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ń lo onírúurú ọ̀nà láti wàásù ìhìn rere kó lè jèrè “ènìyàn gbogbo,” bẹ́ẹ̀ náà ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye ṣe ń lo àwọn ìwé ìròyìn wa láti wàásù fún àwọn èèyàn tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sì yàtọ̀ síra. (1 Kọ́r. 9:22, 23) Ká lè máa lo àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ́nà tó dáa, ó dára ká máa ronú nípa àwọn èèyàn tá a torí wọn ṣe àwọn ìwé ìròyìn náà.

2. Àwọn wo la torí wọn ṣe ìwé ìròyìn Jí!?

2 Jí!: Àwọn tá a torí wọn ṣe ìwé ìròyìn Jí! ni irú àwọn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé “ẹ̀yin ènìyàn Áténì.” (Ìṣe 17:22) Kì í ṣe inú ẹ̀sìn Kristẹni ni wọ́n bí àwọn èèyàn yẹn sí, òye díẹ̀ sì ni wọ́n ní nípa Ìwé Mímọ́. Bákan náà, àwọn tí ìmọ̀ Bíbélì tí wọ́n ní kò tó nǹkan tàbí tí wọn ò tiẹ̀ ní ìmọ̀ Bíbélì rárá la torí wọn ṣe ìwé ìròyìn Jí! Wọ́n lè má mọ ohunkóhun nípa ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni, wọ́n lè má fi bẹ́ẹ̀ fọkàn tán ẹ̀sìn, tàbí kí wọ́n má mọ̀ pé Bíbélì ní àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò gan-an. Ìdí pàtàkì tá a fi ń ṣe ìwé ìròyìn Jí! ni láti jẹ́ kí àwọn tó ń kà á mọ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ wà. Ìdí míì tá a tún fi ń ṣe é ni pé kí àwọn tó ń kà á lè ní ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì, kí wọ́n sì lè mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn yòókù.

3. Àwọn wo la dìídì torí wọn ṣe ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́?

3 Ilé Ìṣọ́: Àwọn tá a torí wọn ṣe ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tá à ń lò lóde ẹ̀rí ní ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run àti Ìwé Mímọ́ dé ìwọ̀n àyè kan. Wọ́n ní ìmọ̀ díẹ̀ nípa Bíbélì, àmọ́ wọn kò lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́nà tó péye. Ńṣe ni wọ́n dà bí àwọn tí Pọ́ọ̀lù sọ pé wọ́n “bẹ̀rù Ọlọ́run.” (Ìṣe 13:14-16) Torí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe dìídì ṣe ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Pọ́ọ̀lù gbà pé àwọn tó ń ka lẹ́tà òun mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, wọ́n sì ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́. (1 Kọ́r. 1:1, 2) Bákan náà, a kọ àwọn àpilẹ̀kọ tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ ní ìpàdé fún àwọn tó máa ń wá sí ìpàdé wa déédéé, tí wọ́n sì mọ èdè tí àwa Ẹlẹ́rìí sábà máa ń lò àti ohun tá a gbà gbọ́.

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ohun tó wà nínú ẹ̀dà ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan tá à ń lò lóde ẹ̀rí?

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe la máa ń fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé ìròyìn wa pa pọ̀, ẹyọ kan la sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tá a bá ń bá onílé sọ̀rọ̀. Torí náà, fi ṣe àfojúsùn rẹ láti mọ ohun tó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà. Èyí á lè jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti mọ èyí tó máa fa ẹni tó o bá pàdé mọ́ra.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́