ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/07 ojú ìwé 1
  • Àyípadà Kíkọyọyọ Ti Bá Ilé Ìṣọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àyípadà Kíkọyọyọ Ti Bá Ilé Ìṣọ́!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Ẹ̀dà Tuntun Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Sí Ẹ̀yin Òǹkàwé Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Òun Náà Ni!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ilé Ìṣọ́ Tá A Fi Èdè Gẹ̀ẹ́sì Tó Rọrùn Kọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 7/07 ojú ìwé 1

Àyípadà Kíkọyọyọ Ti Bá Ilé Ìṣọ́!

1 Níbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, a gbọ́ ìfilọ̀ kan nínú ìjọ tó múnú gbogbo wa dùn. A sọ nínú ìfilọ̀ náà pé láti January ọdún 2008, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ á di oríṣi méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀kan fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti èkejì fún ẹgbẹ́ ará kárí ayé! Bóyá ó tiẹ̀ ti ń ṣe ẹ́ bíi kó o béèrè pé: ‘Ìyàtọ̀ wo ló máa wà nínú méjèèjì? Àǹfààní wo ló wà nínú kí ìwé ìròyìn náà wà fún àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀? Ṣé àwọn nǹkan tuntun kan á wà nínú rẹ̀ tá a lè máa wọ̀nà fún ni?’

2 Ìyàtọ̀ Tó Wà Nínú Méjèèjì: Èyí tá a ó máa kọ déètì ọjọ́ kìíní oṣù sí lára la ó máa fi sóde. Àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ó máa dìídì darí àwọn àpilẹ̀kọ inú rẹ̀ sí. Èyí tá a ó máa kọ déètì ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù sí lára lá o máa lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, a ò sì ní í máa lò ó lóde ẹ̀rí. Inú rẹ̀ ni gbogbo àpilẹ̀kọ tá a ó máa jíròrò ní ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ jálẹ̀ oṣù kan á máa wà àtàwọn àpilẹ̀kọ míì tó bójú mu fáwa ìránṣẹ́ Jèhófà tá a ti ṣèyàsímímọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe la máa dìídì ṣe èyí tá a ó máa lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ́nà tó máa fa àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ tó ṣeé ṣe kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì mọ́ra, síbẹ̀ àkàgbádùn ló máa jẹ́ fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n ní ti ìwé ìròyìn Jí!, yóò ṣì máa wà fún tonílé tàlejò, títí kan àwọn oníyèméjì àtàwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristi.

3 Ibi Tí Ọ̀kọ̀ọ̀kan Wọn Dáa Sí: Nínú èyí tá a ó máa lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́, kò ní pọn dandan mọ́ láti ṣàlàyé àwọn gbólóhùn bí “aṣáájú-ọ̀nà” nítorí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kìkì pé a ó máa rí i pé àlàyé inú rẹ̀ bójú mu fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn. Èyí tá a ó máa fi sóde wá ń kọ́ o? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe la ó máa ṣe àṣàyàn àwọn ẹ̀kọ́ tá ó máa gbé jáde, a máa rí i dájú pé a kọ ọ́ lọ́nà tí ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà á fi lè máa kà á tán tinú tẹ̀yìn, táá sì máa gbádùn rẹ̀. Ó dájú pé kò sí èyí tí Kristẹni kan mú tí ò ní gbádùn kíkà rẹ̀. Ó tún máa ṣeé ṣe fún wa láti múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó gbéṣẹ́ tá a ó lè máa lò jálẹ̀ oṣù sílẹ̀ torí pé ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kan ṣoṣo àti Jí! kan ṣoṣo la ó máa lò lóde ẹ̀rí.

4 Àwọn Nǹkan Tuntun: Àwọn nǹkan tuntun mélòó kan rèé tá a ní lọ́kàn pé yóò máa wà nínú èyí tá a ó máa fi sóde. Apá kan lára rẹ̀ á jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ pọ́ńbélé lọ́nà tó rọrùn láti lóye. Apá mìíràn á jíròrò bí Bíbélì ṣe lè ran ìdílé lọ́wọ́. Apá kan á wà táá tún máa ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti ṣètò fún Bíbélì kíkà. Ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan á máa ní àpilẹ̀kọ kan táá máa ṣàlàyé apá kan pàtó nínú Bíbélì tó kọ́ wa nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́.

5 À ń gbà á ládùúrà pé ká lè máa rí ìtìlẹ́yìn Jèhófà nínú ọ̀nà tuntun tá a fẹ́ máa gbà tẹ Ilé Ìṣọ́. Ká sì lè túbọ̀ máa tipasẹ̀ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! mú ìhìn rere détígbọ̀ọ́ àwọn ẹni yíyẹ.—Mát. 10:11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́