ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/07 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 30
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 7/07 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 9

Orin 4

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ July 15 àti Jí! July–September. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 4 fún Jí! July–September.)

15 min: Kí Ló Ń Jẹ́ Kéèyàn Ní Ojúlówó Ayọ̀? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ May 15, 2006, ojú ìwé 28 àti 29, ìpínrọ̀ 11 àti 12. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó jẹ́ pé iṣẹ́ ìsìn ló gbájú mọ́ dípò kó máa lé fàájì tàbí iṣẹ́ olówó ńlá. Kí ló mú kẹ́ni náà gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn? Ọ̀nà wo nìyẹn sì ti gbà fún un láyọ̀?

20 min: Àpótí Ìbéèrè. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Ka gbogbo àpilẹ̀kọ náà níkọ̀ọ̀kan, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Fi àlàyé kún un látinú ìwé ìròyìn Jí! ti June 8, 2005, ojú ìwé 13 àti 14, lábẹ́ àkòrí náà “Ẹ̀tàn Pọ̀ Ńbẹ̀, O Kò sì Lè Mọ Àṣírí Wọn” àti “Yan Ọ̀rẹ́ Tó O Lè Fojú Rí Dípò Ọ̀rẹ́ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”

Orin 91 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 16

Orin 16

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù July sílẹ̀.

20 min: Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Àlàáfíà Máa Jọba Nínú Ìjọ Kí Ìjọ sì Wà Ní Mímọ́. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 144 sí 150.

15 min: “Àyípadà Kíkọyọyọ Ti Bá Ilé Ìṣọ́!”a

Orin 189 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 23

Orin 133

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ August 1 àti Jí! July–September. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 4 fún Jí! July–September.)

20 min: Ẹ Jẹ́ Ọ̀làwọ́. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ January 15, 2005, ojú ìwé 21 sí 23 lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Ẹ Ní Ẹ̀mí Aájò Àlejò fún Ará Yín.” Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́. Ọ̀nà wo ni wọ́n ti gbà hùwà ọ̀làwọ́? Ìbùkún wo làwọn àti ìdílé wọn ti rí?

15 min: Bó O Ṣe Lè Máa Múra Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tó Gbéṣẹ́. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 2, ìpínrọ̀ 1 àti 2. Ṣe àṣefihàn méjì tó máa jẹ́ kí àwùjọ rí bí wọ́n ṣe lè lo àwọn ìwé tá a dábàá fún lílò nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù August.

Orin 61 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 30

Orin 200

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù July sílẹ̀.

15 min: Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Lẹ́mìí Ìfara-Ẹni-Rúbọ. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2005, ojú ìwé 8 àti 9.

20 min: “Aláyọ̀ Ni Ẹni Tí Ń Bá A Nìṣó ní Fífarada Àdánwò.”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ní kí àwùjọ sọ bí ìgbàgbọ́ wọn tó lágbára ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n kàn ṣàdédé bá ara wọn nínú àdánwò. O lè ti sọ fẹ́nì kan tàbí ẹni méjì ṣáájú pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti dáhùn.

Orin 13 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 6

Orin 106

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Ìdí Tá A Fi Ń Padà Lọ Léraléra.”c Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, ní kí àwùjọ sọ ohun tó mú kí wọ́n tún máa nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fìgbà kan rí kórìíra àti máa tẹ́tí sí wa, tàbí kí wọ́n ti máa ta kò wá.

Orin 211 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́