Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 1
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 1
Orin 31 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 7 ìpínrọ̀ 9 sí 13, àti àpótí tó wà lójú ìwé 56 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 87-91 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 89:26-52 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Àwọn Olóòótọ́ Ìránṣẹ́ Jèhófà Fi Máa Ń Láyọ̀ (5 min.)
No. 3: Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Jọ́sìn Àgbélébùú?—td 2B (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Lo àbá tó sọ nípa bá a ṣe lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀, tó wà lójú ìwé yìí, láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù August. Fún gbogbo àwọn ará ní ìṣírí láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
10 min: Máa Fi Àpèjúwe Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 240 sí 243. Ní kí àwọn ará sọ àpèjúwe kúkúrú tí wọ́n ti lò láti fèrò wérò pẹ̀lú onílé kan tàbí ẹni tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì yọrí sí rere.
15 min: Àwọn Ọ̀ràn Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ. Alàgbà tó tóótun ni kó sọ àsọyé yìí. A gbé e ka ìwé àsọyé náà “Ohun Táwọn Òbí Lè Ṣe Kí Wọ́n Lè Dáàbò Bo Ọmọ Wọn Kí Wọ́n Má Bàa Fa Ẹ̀jẹ̀ Sí Wọn Lára.”
Orin 129 àti Àdúrà