Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 24
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 24
Orin 38
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR orí 9 ìpínrọ̀ 1 sí 12, àpótí tó wà lójú ìwé 101
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 14-16
No. 1: Númérì 14:26-43
No. 2: Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Òfin Ọlọ́run? (Sm. 119:97)
No. 3: Ibi Tí A Ti Lè Rí Ìtùnú Gbà (lr orí 31)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 218
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ September 1 àti Jí! July—September. Sọ̀rọ̀ ṣókí lórí ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Ní káwọn ará sọ ìbéèrè tí wọ́n fẹ́ fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n máa fẹ́ kà. Ṣàṣefihàn kan tàbí méjì.
20 min: “Ẹ Sapá Gidigidi Láti Wàásù Fáwọn Ọkùnrin.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 9, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu alàgbà kan. Kí ló mú kó sapá kọ́wọ́ ẹ̀ lè tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ? Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wo ló ti rí gbà, ta ló sì dá a lẹ́kọ̀ọ́?
Orin 204