ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/98 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún August

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún August
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 3
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 31
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 8/98 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún August

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 3

Orin 216

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti oṣù May ti orílẹ̀-èdè yìí àti ti ìjọ àdúgbò.

20 min: “August Yóò Ha Jẹ́ Oṣù Aláìlẹ́gbẹ́ Bí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàyẹ̀wò àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “215,000!” pẹ̀lú. Fún gbogbo ará níṣìírí láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní oṣù August àti lóṣooṣù nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tuntun.

15 min: “Nasẹ̀ Ìwé Walaaye Titilae Lọ́nà Gbígbéṣẹ́.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ àti àṣefihàn kan tàbí méjì lórí àwọn ìyọsíni tí a dábàá.

Orin 191 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 10

Orin 127

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ké sí àwọn ará láti ṣàlàyé ṣókí nípa bí a ṣe lè gba orúkọ àti àdírẹ́sì ẹnì kan tí a jẹ́rìí fún ní òpópónà, ní ibi ìgbọ́kọ̀sí, tàbí níbòmíràn, kí a lè padà ṣiṣẹ́ lórí ìfẹ́ tí ó fi hàn.

15 min: Àwọn àìní àdúgbò. Rán gbogbo ará létí pé kí wọ́n nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní oṣù August.

20 min: “Ẹ̀yin Èwe—Ẹ Lo Àǹfààní Ẹ̀kọ́ Yín Lọ́nà Rere.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àwọn àlàyé tí ó bá bá a mu kún un láti inú Jí! (Gẹ̀ẹ́sì) ti April 8, 1992, ojú ìwé 17 sí 19, àti Ilé-Ìṣọ́nà ti July 15, 1991, ojú ìwé 23 sí 26.

Orin 37 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 17

Orin 163

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Rán gbogbo ará létí pé kí wọ́n nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí.

35 min: “Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Nàìjíríà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún gbogbo ará níṣìírí láti ti iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn.

Orin 108 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 24

Orin 213

5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé òpin ọ̀sẹ̀ kan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù ní August, fún gbogbo ará níṣìírí pé kí wọ́n kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ kí oṣù yìí tó parí.

20 min: Bí A Ṣe Lè Máa Bá A Lọ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà. Ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà ti September 15, 1993, ojú ìwé 28 sí 31. Fọ̀rọ̀ wá aṣáájú ọ̀nà kan lẹ́nu wò tí ó ti kọ́ bí a ṣe ń kojú àwọn ìṣòro lílekoko, tí ó sì ń bá a lọ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà.

20 min: Má A Lo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa Lọ́nà Rere. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Nípa lílo àwọn àpẹẹrẹ ẹnu àìpẹ́ yìí, ṣàkàwé àwọn ìsọfúnni tí ó bá àkókò mu tí a rí ní ojú ewé Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa àti àwọn àǹfààní tí a ń jẹ láti inú rẹ̀: (1) àwọn àpilẹ̀kọ tí ń sún wa láti nípìn-ín déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́; (2) àwọn ìrírí tí ń fún wa níṣìírí nínú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa; (3) àwọn àbá tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìhìn rere náà kalẹ̀ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́; (4) ìfilọ̀ nípa àwọn ìtẹ̀jáde tuntun tí ó wà tí wọ́n ṣàǹfààní ní ìpínlẹ̀ àdúgbò; (5) ìròyìn nípa iṣẹ́ ìsìn, tí ó ń fi bí ìgbòkègbodò iṣẹ́ Ìjọba náà ṣe ń lọ sí hàn; (6) Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run, èyí tí ń ròyìn ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ náà kárí ayé; (7) àwọn ìfilọ̀ àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń fi àwọn ohun tí a óò ṣe lọ́jọ́ iwájú tó wa létí ṣáájú; (8) àwọn Àpótí Ìbéèrè tí ń dáhùn àwọn ìbéèrè lórí ọ̀ràn tí a ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ gidigidi; àti (9) àwọn àkìbọnú tí ń sọ fún wa nípa àwọn àpéjọpọ̀, ìgbétáásì àkànṣe, àti àwọn ọ̀ràn mìíràn tí ń mú kí a fún àwọn àìní wa nípa tẹ̀mí ní àfiyèsí. Fún gbogbo ará níṣìírí láti máa ka ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n máa fi àwọn àbá rẹ̀ sílò, kí wọ́n máa mú un wá sí Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí wọ́n sì máa tọ́jú rẹ̀ sínú fáìlì wọn fún ìtọ́kasí lọ́jọ́ iwájú.

Orin 210 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 31

Orin 65

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti oṣù August sílẹ̀. Kí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rí i pé gbogbo àwọn tí ó wà ní àwùjọ wọn fi ìròyìn wọn sílẹ̀ kí a lè ṣírò gbogbo rẹ̀ pa pọ̀ ní September 6.

15 min: “Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Alábòójútó Olùṣalága.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó olùṣalága. Lẹ́yìn ṣíṣàtúnyẹ̀wò àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀, kí ó yin ìjọ fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn alàgbà bí wọ́n ti ń ṣolùṣọ́ àgùntàn agbo.

18 min: Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòro ní Ilé Ẹ̀kọ́. Alàgbà kan jíròrò pẹ̀lú àwọn òbí méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n ní ọmọ ní ilé ẹ̀kọ́. Ní ṣókí, ṣàlàyé mélòó kan nínú àwọn ìṣòro tí ó wọ́pọ̀ tí àwọn ọmọ máa ń bá pàdé, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé rẹ̀ nínú Jí! ti August 8, 1994, ojú ìwé 5 sí 7. Lẹ́yìn náà, ní títọ́kasí ojú ìwé 8 sí 10, jíròrò bí àwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì máa bá a lọ láti ní àjọṣe tí ó gbámúṣé láàárín òbí àti olùkọ́.

Orin 24 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́