Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Alábòójútó Olùṣalága
1 Láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ jẹ́ ẹrù iṣẹ́ tí ó wúwo gidigidi. (Ìṣe 20:28; 1 Tím. 3:1) Èyí ni àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tí yóò ṣàlàyé onírúurú ẹrù iṣẹ́ àwọn alàgbà Kristẹni kí gbogbo wa lè mọrírì iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n ń ṣe nítorí wa.
2 Society ni ó máa ń yan alábòójútó olùṣalága láti sìn títí lọ. Bí alábòójútó olùṣalága ṣe ń ṣe kòkárí àwọn nǹkan, èyí ń mú kí àwọn alàgbà fún àwọn ẹrù iṣẹ́ wọn ní àfiyèsí tí ó yẹ. (Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 41 àti 42) Kí ni èyí ní nínú?
3 Alábòójútó olùṣalága ni ó máa ń gba lẹ́tà ìjọ, yóò sì fi í fún akọ̀wé lọ́gán láti bójú tó o. Láti múra sílẹ̀ fún ìpàdé àwọn alàgbà, alábòójútó olùṣalága yóò gba àbá láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà lórí ọ̀ràn tí ó yẹ kí wọ́n jíròrò, yóò sì kó àjẹ́ńdà jọ. Òun ni yóò tún jẹ́ alága ní ìpàdé àwọn alàgbà. Nígbà tí a bá ṣe àwọn ìpinnu, yóò rí sí i pé a ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìpinnu náà lọ́nà tí ó yẹ. Òun ni ó máa ń bójú tó mímúrasílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti ṣíṣètò àwọn ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Òun ni ó máa ń fọwọ́ sí gbogbo ìfilọ̀ tí a ń ṣe fún ìjọ, yóò fàṣẹ sí gbogbo owó tí a bá fẹ́ san fún ìnáwó lórí àwọn nǹkan ìlò, yóò sì rí i dájú pé a ń ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ lẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún.
4 Gẹ́gẹ́ bí alága, alábòójútó olùṣalága ni ó máa ń ṣe kòkárí iṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ. Nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá fẹ́ di akéde tí kò tíì ṣe batisí tàbí nígbà tí akéde tí kò tíì ṣe batisí bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, alábòójútó olùṣalága yóò ṣètò pé kí àwọn alàgbà jíròrò pẹ̀lú rẹ̀. Alábòójútó olùṣalága ni ó tún máa ń mú ipò iwájú ní mímúrasílẹ̀ fún ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká kí ìjọ lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ láti inú ìgbòkègbodò ọ̀sẹ̀ àkànṣe yìí.
5 Ẹrù iṣẹ́ alábòójútó olùṣalága pọ̀, ó sì jẹ́ onírúurú. Bí ó ṣe ń fi ìrẹ̀lẹ̀ bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú “ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan,” gbogbo wa ní láti ṣe ipa tiwa nípa fífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà. (Róòmù 12:8) Bí a bá jẹ́ “onígbọràn” tí a sì “jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba” fún àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín wa, wọn yóò lè ṣe iṣẹ́ wọn pẹ̀lú ìdùnnú tí ó kọyọyọ.—Héb. 13:17.