ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/98 ojú ìwé 1
  • A Lè Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Tí Ó Tóbi Jù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Lè Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Tí Ó Tóbi Jù
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn . . . Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
  • “Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ọwọ Rẹ Dí Ninu Awọn Òkú Iṣẹ́ Tabi Ninu Iṣẹ-isin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 9/98 ojú ìwé 1

A Lè Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Tí Ó Tóbi Jù

1 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi kún fún iṣẹ́ tí ó tayọ. Ó bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà iṣẹ́ ìyanu, ó mú ọ̀pọ̀ lára dá, ó sì jí àwọn kan dìde kúrò nínú ikú. (Mát. 8:1-17; 14:14-21; Jòh. 11:38-44) Ìgbòkègbodò rẹ̀ gba àfiyèsí odindi orílẹ̀-èdè. Síbẹ̀, ní alẹ́ tí ó ṣáájú ikú rẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olùṣòtítọ́ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, ẹni yẹn pẹ̀lú yóò ṣe àwọn iṣẹ́ tí èmi ń ṣe; yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí.” (Jòh. 14:12) Báwo ni a ṣe lè ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó “tóbi jù?”

2 Nípa Kíkárí Ìpínlẹ̀ Tí Ó Pọ̀ Ju Tirẹ̀: Ìgbòkègbodò Jésù kò kọjá Palẹ́sìnì, nígbà tí ó sì jẹ́ pé ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ láti jẹ́rìí “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” tí ó jìnnà ré kọjá ibi tí Jésù fúnra rẹ̀ ti wàásù. (Ìṣe 1:8) Iṣẹ́ ìwàásù tí ó bẹ̀rẹ̀ ti kárí ayé ní báyìí, ó ti dé 232 ilẹ̀. (Mát. 24:14) Ìwọ ha ń ní ìpín kíkún nínú ṣíṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tí a yàn fún ìjọ rẹ bí?

3 Nípa Dídé Ọ̀dọ̀ Àwọn Ènìyàn Púpọ̀ Ju Tirẹ̀: Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù fi sílẹ̀ láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó kò tó nǹkan. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí fífi tí wọ́n fi ìtara jẹ́rìí ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkàn tí ó tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí a sì batisí ní ọjọ́ yẹn. (Ìṣe 2:1-11, 37-41) Ṣíṣàkójọ àwọn tí ó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” ń bá a nìṣó títí di ọjọ́ wa, tí a ń batisí èyí tí ó ju 1,000 ènìyàn lójoojúmọ́ ní ìpíndọ́gba. (Ìṣe 13:48) Ìwọ ha ń ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ aláìlábòsí-ọkàn níbikíbi tí o bá ti lè rí wọn kí o sì padà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn bí ó bá ti ṣeé ṣe kí ó yá tó?

4 Nípa Fífi Àkókò Gígùn Ju Tirẹ̀ Wàásù: Ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ péré ni Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Àkókò tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa ti fi ń wàásù ti gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Láìka bí àkókò tí a óò gbà wá láyè láti máa bá iṣẹ́ yìí lọ yóò ṣe gùn tó, a kún fún ìmoore pé a ń ran ọmọ ẹ̀yìn tuntun kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí tọ ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè. (Mát. 7:14) Ìwọ ha ń ní púpọ̀ láti ṣe lóṣooṣù nínú iṣẹ́ Olúwa bí?—1 Kọ́r. 15:58.

5 A lè ní ìgbọ́kànlé pé bí Jésù ṣe ń tì wá lẹ́yìn, a óò túbọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi jù gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tòótọ́.—Mát. 28:19, 20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́