ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 7/1 ojú ìwé 26-29
  • Ọwọ Rẹ Dí Ninu Awọn Òkú Iṣẹ́ Tabi Ninu Iṣẹ-isin Jehofa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọwọ Rẹ Dí Ninu Awọn Òkú Iṣẹ́ Tabi Ninu Iṣẹ-isin Jehofa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídá Awọn Òkú Iṣẹ Mọ̀
  • Ṣiṣọra Lodisi Awọn Òkú Iṣẹ
  • Jẹ Kí Ọwọ́ Rẹ Dí Ninu Iṣẹ-Isin Jehofa
  • Awọn Anfaani Jíjẹ́ Ẹni Ti Ọwọ́ Rẹ̀ Dí Ninu Iṣẹ-Isin Jehofa
  • Ìgbàgbọ́ àti Iṣẹ́ Máa Sọ Ẹ́ Di Olódodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí La Fi Gbà Wọ́n Là, Kì í Ṣe Iṣẹ́ Nìkan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • “Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Kí ni A Gbọ́dọ̀ Ṣe Láti Rí Ìgbàlà?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 7/1 ojú ìwé 26-29

Ọwọ Rẹ Dí Ninu Awọn Òkú Iṣẹ́ Tabi Ninu Iṣẹ-isin Jehofa

“MÁ BÌÍNÚ, ṣugbọn ọwọ́ mi dí.” Eyi ni ọ̀kan lara awọn gbolohun aifohunṣọkan ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń dojukọ bi wọn ti ń waasu ihinrere Ijọba naa ni gbangba. (Matteu 24:14) Ati nigba ti ijẹwọsọ naa “ọwọ́ mi dí” kò tumọsi ohunkohun nigba miiran ju itọrọ gafara ti o rọrun lati lo, otitọ naa ni pe ọpọlọpọ ni ọwọ wọn dí. Awọn ni “aniyan ayé yii”—awọn ikimọlẹ ti wíwá ounjẹ oojọ, sísan awọn iwe gbese, lilọ si ati pipada bọ̀ lati ibi iṣẹ, títọ́ awọn ọmọ, bibojuto ile, ọkọ̀ ayọkẹlẹ, ati awọn ohun ìní miiran ti fẹrẹẹ jẹrun.—Matteu 13:22.

Bi o ti wu ki o ri, nigba ti ọwọ́ awọn eniyan lè dí nitootọ, awọn diẹ ni wọn ń lọwọ ninu awọn iṣẹ ti ń sèso tabi ti ń mesojade nitootọ. Ó jẹ́ gẹgẹ bi ọkunrin ọlọgbọn naa Solomoni ti kọwe nigbakanri pe: “Nitori pe ki ni eniyan ni ninu gbogbo laalaa ati aapọn rẹ̀ ti o fi ń ṣe laalaa labẹ oorun? Nitori pe ọjọ rẹ̀ gbogbo, ikaanu ni, ati iṣẹ rẹ̀, ibinujẹ; nitootọ àyà rẹ̀ kò sinmi ni òru. Eyi pẹlu asán ni.”—Oniwasu 2:22, 23.

Bibeli tun pe iru igbokegbodo alaimesowa bẹẹ ni “awọn òkú iṣẹ.” (Heberu 9:14, NW) Iru awọn iṣẹ bẹẹ ha jẹgàba lori igbesi-aye rẹ bi? Eyi gbọdọ jẹ́ idaniyan ńlá fun ọ gẹgẹ bii Kristian kan, niwọn bi o ti jẹ pe Ọlọrun yoo “san án fun olukuluku eniyan gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.” (Orin Dafidi 62:12) Niwọn bi ó si ti jẹ pe “akoko ti o kù dínkù,” awa ni pataki nilati daniyan pe a kò fi akoko ṣòfò pẹlu awọn iṣẹ ti wọn jẹ́ òkú. (1 Korinti 7:29) Ṣugbọn ki ni awọn òkú iṣẹ? Oju wo ni o yẹ ki a fi wò wọn? Bawo si ni ó ṣe lè dá wa loju pe ọwọ́ wa dí fun awọn iṣẹ ti wọn niyelori niti gidi?

Dídá Awọn Òkú Iṣẹ Mọ̀

Ni Heberu 6:1, 2 (NW), Paulu kọwe pe: “Fun idi yii, nisinsinyi ti a ti fi awọn ẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ nipa Kristi silẹ, ẹ jẹ ki a tẹsiwaju si ipo gende, ki a maṣe tun fi ipilẹ lélẹ̀ mọ́, eyiini ni, ironupiwada kuro ninu awọn òkú iṣẹ, ati igbagbọ sọdọ Ọlọrun, ẹ̀kọ́ lori awọn baptism ati gbigbe awọn ọwọ́ leni, ajinde òkú ati idajọ ainipẹkun.” Ṣakiyesi pe “ẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ” ní “ironupiwada kuro ninu awọn òkú iṣẹ” ninu. Gẹgẹ bii Kristian, awọn onkawe Paulu ti ronupiwada kuro ninu iru awọn òkú iṣẹ bẹẹ ṣaaju. Bawo ni o ṣe ri bẹẹ?

Ṣaaju titẹwọgba Kristi, awọn kan ni ọrundun kìn-ín-ní ti lọwọ ninu ‘awọn òkú iṣẹ ti ara,’ tí í ṣe, “ìwà àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ibọriṣa, aṣa bíbá ẹmi lò,” ati awọn iṣe buburu miiran. (Galatia 5:19-21, NW) Bi wọn kò bá dá a duro, iru awọn iṣẹ bẹẹ ìbá ti yọrisi iku tẹmi wọn. Bi o ti wu ki o ri, pẹlu aanu, awọn Kristian wọnni ti yipada kuro ninu ipa-ọna apanirun wọn, wọn ti ronupiwada, a sì ti ‘wẹ wọn mọ́ tonitoni.’ Wọn tipa bayii gbadun iduro mimọ tonitoni pẹlu Jehofa.—1 Korinti 6:9-11.

Bi o ti wu ki o ri, kì í ṣe gbogbo Kristian ni wọn nilati ronupiwada kuro ninu awọn iṣẹ ti wọn jẹ buburu tabi oniwa palapala. Lẹta Paulu ni a kọ ni ipilẹ si awọn Ju onigbagbọ, ọpọlọpọ ninu awọn tí kò sí iyemeji pe wọn rọ̀ timọtimọ mọ́ Ofin Mose ṣaaju titẹwọgba Kristi. Ninu awọn òkú iṣẹ wo, nigba naa, ni wọn ti ronupiwada? Dajudaju kò sí ohun ti o ṣàìtọ́ pẹlu titẹle ti wọn tẹle awọn aato isin ati ti ounjẹ tí Ofin beere fun. Ofin kò ha jẹ́ “mímọ́ ati ododo ati daradara”? (Romu 7:12, NW) Bẹẹni, ṣugbọn ni Romu 10:2, 3, Paulu sọ nipa awọn Ju pe: “Mo gba ẹ̀rí wọn jẹ́ pe, wọn ni ìtara fun Ọlọrun, ṣugbọn kì í ṣe gẹgẹ bi ìmọ̀. Nitori bi wọn kò ti mọ ododo Ọlọrun, ti wọn sì ń wá ọ̀nà lati gbé ododo araawọn kalẹ, wọn kò tẹriba fun ododo Ọlọrun.”

Bẹẹni, awọn Ju fi aṣiṣe gbagbọ pe nipa fifi ìṣefínnífínní tẹle Ofin, wọn yoo ri igbala gbà. Bi o ti wu ki o ri, Paulu ṣalaye pe “a kò dá ẹnikẹni lare nipa iṣẹ ofin, bikoṣe nipa igbagbọ ninu Jesu Kristi.” (Galatia 2:16) Lẹhin ti a pese irapada Kristi tán, awọn iṣẹ Ofin—kò sí bi wọn ṣe lè jẹ ti ẹlẹmii isin tabi ti ọmọluwabi tó—jẹ́ awọn òkú iṣẹ wọn kò sì ni iniyelori eyikeyii yoowu ninu jijere igbala. Awọn Ju ọlọkan títọ́ tipa bayii wa ojurere Ọlọrun nipa rironupiwada kuro ninu iru awọn òkú iṣẹ bẹẹ ati gbigba iribọmi lati fàmì ṣapẹẹrẹ ironupiwada wọn.—Iṣe 2:38.

Ki ni ohun ti a ri kọ́ lati inu eyi? Pe awọn òkú iṣẹ lè ní ninu ju awọn iṣe buburu tabi oniwa palapala lọ; wọn kó iṣẹ eyikeyii ti ó jẹ́ òkú, asán, tabi alaileso nipa tẹmi mọra. Ṣugbọn ṣe gbogbo awọn Kristian kò ti ronupiwada kuro ninu iru awọn òkú iṣẹ bẹẹ ṣaaju baptism wọn ni bi? Otitọ ni, ṣugbọn awọn Kristian kan ní ọrundun kìn-ín-ní lẹhin naa ṣubu sinu iwa palapala. (1 Korinti 5:1) Ati laaarin awọn Kristian Ju, itẹsi wà lati pada si ṣiṣe awọn òkú iṣẹ ti Ofin Mose. Paulu nilati rán iru awọn bẹẹ leti lati maṣe pada si òkú iṣẹ.—Galatia 4:21; 5:1.

Ṣiṣọra Lodisi Awọn Òkú Iṣẹ

Nitori naa awọn eniyan Jehofa lonii gbọdọ ṣọra ki wọn maṣe ṣubu pada sinu ìdẹkùn awọn òkú iṣẹ. A ń kọlù wá ní ohun ti o fẹrẹẹ jẹ́ ní gbogbo ìhà nipasẹ awọn ikimọlẹ lati juwọsilẹ nipa ti iwarere, lati jẹ́ alabosi, ati lati lọwọ ninu awọn iwa palapala ti ibalopọ takọtabo. Ó bani ninujẹ lati sọ, pe ẹgbẹẹgbẹrun awọn Kristian lọdọọdun ń juwọsilẹ fun iru awọn ikimọlẹ bẹẹ, bi wọn bá sì jẹ́ alaironupiwada a ń lé wọn jade kuro ninu ijọ Kristian. Ju ti igbakigba rí lọ, nigba naa, Kristian kan gbọdọ kọbiara si amọran Paulu ni Efesu 4:22-24 pe: “Ẹ . . . bọ́ akopọ animọ ìwà ogbologboo naa silẹ, eyi ti o bá ipa-ọna ìwà yin ti iṣaaju ṣe deedee ati eyi ti a ń sọdibajẹ gẹgẹ bi awọn ifẹ-ọkan itannijẹ rẹ̀; ṣugbọn a nilati sọ yin di titun ninu ipá ti ń sún ero inu yin ṣiṣẹ, ẹ sì nilati gbé akopọ animọ ìwà titun wọ̀ eyi ti a dá gẹgẹ bi ifẹ-inu Ọlọrun ninu ododo tootọ ati iduroṣinṣin.”

Nitootọ, awọn ará Efesu tí Paulu kọwe si ti gbé akopọ animọ ìwà titun wọ̀ dé iwọn gbigbooro kan. Ṣugbọn Paulu ràn wọn lọwọ lati mọriri pe ṣiṣe bẹẹ jẹ́ ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ ti ń baa lọ kan! Laisi isapa ti ko dawọduro, awọn Kristian ni a lè sìn pada sinu awọn òkú iṣẹ nipasẹ awọn ifẹ-ọkan ti ń baa niṣo gẹgẹ bi agbara idari asọnidibajẹ. Ohun kan naa ni o jẹ otitọ nipa wa lonii. A gbọdọ maa làkàkà lemọlemọ lati gbé animọ ìwà titun naa wọ̀, ki a maṣe jẹ́ ki o di alabawọn nipasẹ awọn iwa animọ eyikeyii ti a ní ninu ọ̀nà igbesi-aye wa atijọ. A gbọdọ takete sí—koriira—irú awọn iṣẹ buburu ti ara ayikeyii. “Ẹyin ti o fẹ́ Oluwa [“Jehofa,” NW], ẹ koriira ibi,” ni olorin naa gbaniniyanju.—Orin Dafidi 97:10.

Lọna ti o yẹ fun igboriyin, ọpọ jaburata awọn eniyan Jehofa lonii ti kọbiara si imọran yii wọn sì wà ní mímọ́ tonitoni niti iwarere. Bi o ti wu ki o ri, awọn kan ni a ti fà kuro loju ọ̀nà nipasẹ awọn iṣẹ ti wọn kò fi dandan ṣaitọ ninu araawọn ṣugbọn ti wọn jásí asán ati alaileso nigbẹhin-gbẹhin. Fun apẹẹrẹ, awọn kan ti di ẹni ti o ti ara bọ ihumọ rírí-owó patapata tabi kíkó awọn ohun ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì jọ. Ṣugbọn Bibeli kilọ pe: “Awọn ti ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a maa bọ́ sinu idanwo ati idẹkun, ati sinu were ifẹkufẹẹ pipọ ti i panilara, iru eyi ti i maa ri eniyan sinu iparun ati ègbé.” (1 Timoteu 6:9) Fun awọn miiran, ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ayé ti jásí idẹkun kan. Loootọ, ìwọ̀n ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ayé kan lè pọndandan fun rírí iṣẹ. Ṣugbọn ninu ilepa ìmọ̀-ẹ̀kọ́ giga ti ayé ti ń jẹ akoko, awọn kan ti pa araawọn lara nipa tẹmi.

Bẹẹni, ọpọlọpọ iṣẹ lè má ṣaitọ niti iwarere ninu araawọn. Ṣugbọn sibẹ wọn jẹ́ òkú bi wọn kò bá fikun igbesi-aye wa niti gidi nisinsinyi tabi mu wa jere ojurere lọdọ Jehofa Ọlọrun. Iru awọn iṣẹ bẹẹ ń jẹ akoko ati okun ṣugbọn kò mú awọn anfaani tẹmi eyikeyii jade, kò ni itura ti ó wà pẹtiti.—Fiwe Oniwasu 2:11.

Kò sí iyemeji pe iwọ ń làkàkà kárakára lati jẹ́ ki ọwọ́ rẹ dí ninu awọn igbokegbodo tẹmi ti ó níláárí. Bi o ti wu ki o ri, ó dara lati ṣe ayẹwo araarẹ deedee. Lati ìgbà dé ìgbà, iwọ lè bi araarẹ leere awọn ibeere bii: ‘Ìkópa mi ninu iṣẹ-isin ati lilọ si ipade ha ń wọ́lẹ̀ nitori pe mo ti gba iṣẹ ounjẹ oojọ kan ti kò pọndandan bi?’ ‘Mo ha ni akoko fun eré itura ṣugbọn ti n kò ni akoko ti o tó fun ikẹkọọ idile ati ti ara-ẹni bi?’ ‘Mo ha ń lo akoko ati okunra pupọ lati bojuto awọn ohun-ìní ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ṣugbọn ti mo kùnà lati bojuto awọn alaini ninu ijọ, iru bii awọn alaisan ati awọn arugbo bi?’ Idahun si awọn ibeere wọnyi lè ṣipaya aini kan ni apá ọdọ rẹ lati mu ki awọn iṣẹ tẹmi jẹ́ agbapo kìn-ín-ní julọ.

Jẹ Kí Ọwọ́ Rẹ Dí Ninu Iṣẹ-Isin Jehofa

Gẹgẹ bi 1 Korinti 15:58 (NW) ti sọ, ‘pupọ rẹpẹtẹ wà lati ṣe ninu iṣẹ Oluwa.’ Eyi ti o gba iwaju julọ ni iṣẹ iwaasu Ijọba ati sisọni di ọmọ-ẹhin. Ni 2 Timoteu 4:5, Paulu rọni pe: “Fi wiwaasu Ihinrere naa ṣe iṣẹ igbesi-aye rẹ, ninu iṣẹ-isin onítara.” (Jerusalem Bible) Awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ tun ni pupọ lati ṣe ninu bibojuto awọn aini agbo. (1 Timoteu 3:1, 5, 13; 1 Peteru 5:2) Awọn olori idile—ti ọpọ ninu wọn jẹ́ obi anìkàntọ́mọ—tun ni awọn ẹrù-iṣẹ́ wiwuwo ninu bibojuto awọn idile wọn ati riran awọn ọmọ wọn lọwọ lati dagba ninu ipo ibatan wọn pẹlu Ọlọrun. Iru iṣẹ bẹẹ lè tánnilókun, kí ó tilẹ munilómi nigba miiran. Ṣugbọn bi kìí bá ṣe òkú iṣẹ, wọn a maa mú itẹlọrun gidi wá!

Iṣoro naa ni pe: Bawo ni ẹnikan ṣe lè rí akoko lati ṣaṣepari gbogbo awọn iṣẹ pipọndandan ti o níláárí wọnyi? Ibara-ẹni-wi ati iṣeto ara-ẹni ṣekókó. Ni 1 Korinti 9:26, 27, Paulu kọwe pe: “Emi ń sare, kì í ṣe bi ẹni ti kò dá loju; bẹẹ ni emi ń jà, kì í ṣe bi ẹnikan ti ń lu afẹfẹ: ṣugbọn emi ń pọ́n araami loju, mo sì ń mú un wá sabẹ itẹriba: pe lẹhin ti mo ti waasu fun awọn ẹlomiran, nitori ohunkohun, ki emi tikaraami maṣe di ẹni itanu.” Ọ̀nà kan lati fi ilana ẹsẹ iwe mimọ yii silo yoo jẹ́ lati ṣayẹwo ọ̀nà ti o ń gbà ṣe nǹkan ati ọ̀nà ti o ń gbà gbé igbesi-aye rẹ lati igba de igba. Iwọ tún lè ṣawari pe iwọ lè mú ọpọlọpọ ohun ti kò pọndandan ti ń fa akoko ati okunra rẹ gbẹ kuro.

Fun apẹẹrẹ, o ha ń lo ọpọ julọ ninu okunra ati akoko rẹ fun wiwo tẹlifiṣọn, eré itura, kíkà iwe kan ṣáá, tabi awọn igbokegbodo áfipawọ́ bi? Gẹgẹ bi ọrọ-ẹkọ kan ninu The New York Times ti wi, apẹẹrẹ wiwọpọ ninu awọn agbalagba ni United States ń farafun tẹlifiṣọn wíwò “ti o wulẹ ju 30 wakati lọ lọ́sẹ̀ kan.” Dajudaju iru akoko bẹẹ ni a lè lò lọna ti o sàn jù! Aya alaboojuto arinrin-ajo kan rohin pe: “Mo fẹrẹẹ yọ gbogbo ohun tí ń fi akoko ṣòfò kuro tán, bii wiwo tẹlifiṣọn.” Ki ni iyọrisi rẹ̀? Ó ṣeeṣe fun un lati ka idipọ iwe gbédègbẹ́yọ̀ Bibeli meji naa Insight on the Scriptures tán latokedelẹ!

Iwọ tun lè nilati gbé ìwọ̀n ti o lè gbà mú ọ̀nà ti o ń gbà gbé igbesi-aye rẹ rọrun sii dé yẹwo. Solomoni wi pe: “Dídùn ni oorun oniṣẹ, ìbáà jẹ ounjẹ diẹ tabi pupọ: ṣugbọn itẹlọrun ọlọ́rọ̀ ki i jẹ ki o sùn.” (Oniwasu 5:12) Ọpọ ninu akoko ati okunra rẹ ni o ha ń lò lati bojuto awọn ohun-ìní ọrọ̀ alumọọni ti kò pọndandan bi? Niti gidi, bi a bá ṣe ni ohun pupọ sii tó, bẹẹ ni a nilati tọju, mú ki awọn adíyelófò daabobo, tunṣe, ati pamọ pupọ sii tó. Yoo ha ṣanfaani fun ọ lati wulẹ mú awọn ohun-ìní kan kuro lọwọ araarẹ bi?

Níní itolẹsẹẹsẹ ti o bá ọgbọ́n mu jẹ́ ọ̀nà miiran lati gbà lo akoko rẹ lọna didara ju. Iru itolẹsẹẹsẹ bẹẹ gbọdọ gba ti aini tí ẹnikan ni fun isinmi tabi eré itura rò. Ṣugbọn awọn ire tẹmi ni a gbọdọ fi ṣe agbapò kìn-ín-ní. A gbọdọ ya akoko sọtọ fun lilọ si gbogbo awọn ipade ijọ deedee. Iwọ tun lè pinnu awọn ọjọ tabi irọlẹ ti o lè lò fun iṣẹ ajihinrere ṣaaju. Pẹlu iwewee ti o fi iṣọra ṣe, ó tilẹ lè ṣeeṣe fun ọ lati mu ipin rẹ ninu iṣẹ-isin naa pọ sii, boya ni ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna oluranlọwọ lati ìgbà de ìgbà. Bi o ti wu ki o ri, rí i daju pe, o ṣe itolẹsẹẹsẹ akoko fun ikẹkọọ àdáṣe ati ti idile, papọ pẹlu imurasilẹ kúnnákúnná fun awọn ipade. Nipa wíwà ni imurasilẹ, kì í ṣe kìkì pe iwọ funraarẹ yoo ri ohun pupọ jere ní awọn ipade nikan ni ṣugbọn iwọ yoo wà ni ipo didara ju lati “runisoke si ifẹ ati awọn iṣẹ rere” nipasẹ awọn ọrọ ilohunsi rẹ.—Heberu 10:24, NW.

Wíwá akoko fun ikẹkọọ lè beere fun ṣiṣe awọn irubọ diẹ. Fun apẹẹrẹ, idile Beteli kari ayé ń jí ni kutukutu loroowurọ lati ṣe ijiroro ẹsẹ iwe mimọ ojumọ. Yoo ha ṣeeṣe fun ọ lati ra akoko diẹ pada loroowurọ fun ikẹkọọ ara-ẹni bi? Olorin naa sọ pe: “Emi ṣaaju kutukutu owurọ, emi ké: emi ń ṣe ireti ninu ọrọ rẹ.” (Orin Dafidi 119:147) Dajudaju, jíjí ni kutukutu yoo beere fun ṣiṣe itolẹsẹẹsẹ wakati ti o bá ọgbọ́n mu fun lilọ sùn ní alẹ́ ki o baa lè bẹrẹ ọjọ keji pẹlu ara líle ti ó sì balẹ̀.

Awọn Anfaani Jíjẹ́ Ẹni Ti Ọwọ́ Rẹ̀ Dí Ninu Iṣẹ-Isin Jehofa

Níní “pupọ rẹpẹtẹ lati ṣe ninu iṣẹ Oluwa” beere fun iwewee, ibara-ẹni wi, ati ifara-ẹni-rubọ. Ṣugbọn iwọ yoo gbadun awọn anfaani alailonka gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀. Nitori naa jẹ́ ki ọwọ́ rẹ dí, kì í ṣe ninu awọn òkú iṣẹ tabi iṣẹ asán ti ń mú kìkì òfo ati irora wa, ṣugbọn ninu iṣẹ-isin. Nitori pe nipasẹ iru awọn iṣẹ bẹẹ ni iwọ ń fi igbagbọ rẹ hàn, jere itẹwọgba Ọlọrun, ati nigbẹhin-gbẹhin, èrè ìyè ainipẹkun!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ṣiṣe itolẹsẹẹsẹ ti o bá ọgbọ́n mu ń ran Kristian kan lọwọ lati tubọ fi ọgbọ́n lo akoko rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́