ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/02 ojú ìwé 3-4
  • “Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Kíkún”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Jẹ́ Onítara fún Ohun Rere!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • “Jẹ́rìí Kúnnákúnná sí Ìhìn Rere”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • “Ẹ . . . Máa Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 3/02 ojú ìwé 3-4

“Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà”

1 Ní àwọn ọdún tó kẹ́yìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ onítara tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe, ó ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Tímótì àti Títù. Irú ọ̀rọ̀ ìṣírí kan náà ló kọ ránṣẹ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ó sọ fún Títù pé ó yẹ kí “àwọn tí ó ti gba Ọlọ́run gbọ́” máa “gbé èrò inú wọn ka orí dídi àwọn iṣẹ́ àtàtà mú.” (Títù 3:8) Ó sọ fún Tímótì pé àwọn tí wọ́n gbé ìrètí wọn lé Ọlọ́run ní láti “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (1 Tím. 6:17, 18) Ìmọ̀ràn àtàtà mà lèyí o fún gbogbo wa! Àmọ́, kí ló máa sún wa láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ àtàtà nínú ìgbésí ayé wa? Kí sì làwọn iṣẹ́ àtàtà tá a lè ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bẹ níwájú?

2 Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà àti ìfẹ́ tá a ní sí i, àti àgbàyanu ìrètí tó fún wa ló máa sún wa láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ àtàtà. (1 Tím. 6:19; Títù 2:11) Àkókò tá a wà yìí nínú ọdún, ní pàtàkì, ni à ń rán wa létí pé Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé kí ó lè dá Baba rẹ̀ láre, kí ó sì ṣí ọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tí ó bá tọ́ sí. (Mát. 20:28; Jòh. 3:16) A óò mú èyí ṣe kedere nígbà ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ní March 28. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìrètí jíjèrè ìyè àìnípẹ̀kun tá a ní sún wa láti ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe kí a lè “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà”? Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, ó yẹ bẹ́ẹ̀! Kí làwọn iṣẹ́ tá a lè ṣe lákòókò yìí?

3 Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Tá A Lè Ṣe Lóṣù March àti Láwọn Oṣù Tó Máa Tẹ̀ Lé E: Dájúdájú, a óò lọ síbi Ìṣe Ìrántí, èyí tó jẹ́ ayẹyẹ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé. (Lúùkù 22:19) Àmọ́, a fẹ́ láti ṣàjọpín ayọ̀ tá a máa ń ní lákòókò ayẹyẹ yẹn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Bó o bá wo ìròyìn iṣẹ́ ìsìn nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2002, wà á rí i pé lọ́dún tó kọjá, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kárí ayé, iye àwọn tó bá wa ṣe Ìṣe Ìrántí fi ìlọ́po mẹ́ta, mẹ́rin, márùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lé sí iye àwọn akéde tó wá. Dájúdájú, gbogbo àwọn ará nínú ìjọ ló sapá gidigidi láti pín ìwé ìkésíni fún Ìṣe Ìrántí jákèjádò ìpínlẹ̀ wọn. Nítorí náà, a fẹ́ láti lo àkókò púpọ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó láti ìsinsìnyí lọ títí di March 28 láti pe àwọn èèyàn wá síbi Ìṣe Ìrántí, kí a lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrètí tí a ní fún ìgbàlà.

4 Ní oṣù April, báwo la ṣe lè máa bá iṣẹ́ àtàtà tá a bẹ̀rẹ̀ lóṣù March nìṣó, ká bàa lè jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà”? Nípa bíbá a nìṣó láti máa nípìn-ín tìtaratìtara nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ni, kí a lè jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Títù 2:14; Mát. 24:14) Bí kò bá ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March, ǹjẹ́ o lè ṣe é lóṣù April àti May, tàbí ọ̀kan nínú oṣù méjèèjì? Bó o bá ṣe aṣáájú ọ̀nà lóṣù March, ǹjẹ́ o lè máa bá a lọ?

5 Àwọn kan tó ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rí i pé àwọn lè lo wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá nígbà tí wọ́n bá ń lọ síbi iṣẹ́, bóyá nípa jíjẹ́rìí ní òpópónà tàbí nípa wíwàásù fún àwọn tó máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù. Àwọn mìíràn ṣètò láti máa lò lára àkókò oúnjẹ ọ̀sán wọn láti jẹ́rìí. Àwọn kan rí i pé ó ṣeé ṣe fún àwọn láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láàárín àkókò yẹn pẹ̀lú òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kan. Ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tó jẹ́ ìyàwó ilé ti ya àkókò sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá ṣì wà ní ilé ẹ̀kọ́. Nípa títètè jí láwọn ọjọ́ kan pàtó láti bójú tó àwọn iṣẹ́ ilé wọn, wọ́n ní àkókò sí i lọ́wọ́ ọ̀sán fún iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.—Éfé. 5:15, 16.

6 Kódà, bí kò bá tiẹ̀ ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ o lè ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ara ẹni tìrẹ kí o lè túbọ̀ kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe “láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí [o sì] múra tán láti ṣe àjọpín” òtítọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.—1 Tím. 6:18.

7 Máa Rántí Pé Iṣẹ́ Àtàtà ni Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn: Lọ́dọọdún, àwọn olùfìfẹ́hàn máa ń pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí. Ǹjẹ́ yóò lè ṣeé ṣe fún díẹ̀ lára àwọn ará nínú ìjọ láti darí àfiyèsí sí àwọn tí wọ́n ń pésẹ̀ àmọ́ tí wọn kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́? Ǹjẹ́ a lè padà lọ bẹ̀ wọ́n wò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? Àwọn kan lára àwọn tó bá wa ṣe Ìṣe Ìrántí lè jẹ́ ẹbí àwọn Ẹlẹ́rìí. Àwọn mìíràn lè ti kẹ́kọ̀ọ́ nígbà kan sẹ́yìn, kí ó kàn jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìṣírí díẹ̀ ni wọ́n nílò láti tún bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì máa wá sí ìpàdé déédéé. Ẹ sì wo bí inú wa ṣe máa dùn tó tá a bá rí i tí wọ́n wá di onítara ìránṣẹ́ Jèhófà bí i tiwa!

8 Ó ṣeé ṣe kí a rí àwọn olùfìfẹ́hàn púpọ̀ sí i tá a lè padà lọ bẹ̀ wò bá a bá túbọ̀ kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣù March àtàwọn oṣù tó máa tẹ̀ lé e. Gbìyànjú láti fi ìbéèrè kan sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn náà, sọ pé wàá padà wá láti wá dáhùn ìbéèrè náà. Èyí ni yóò ṣí ọ̀nà ìpadàbẹ̀wò sílẹ̀. Ohun tó dáa jù ni pé ká tètè padà lọ bẹ̀ wọ́n wò. Bí kò bá ṣeé ṣe fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn nígbà àkọ́kọ́ tá a padà lọ bẹ̀ wọ́n wò, ká gbìyànjú bó bá ti lè ṣeé ṣe tó láti bẹ̀rẹ̀ tá a bá tún lọ.

9 Nígbà tá a bá ń lọ́wọ́ nínú ìjẹ́rìí òpópónà, ó yẹ ká ní i lọ́kàn pé a fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn tá a bá pàdé. Àwọn olùfìfẹ́hàn ti fún ọ̀pọ̀ àwọn akéde ní orúkọ wọn, àdírẹ́sì wọn àti nọ́ńbà tẹlifóònù wọn nígbà tí wọ́n jẹ́rìí fún wọn ní òpópónà. Bí ẹni tó o bá pàdé kì í bá gbé ní ìpínlẹ̀ rẹ, gba fọ́ọ̀mù Please Follow Up (S-43) ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kọ ọ̀rọ̀ kún un, kí o sì mú un fún akọ̀wé ìjọ, ẹni tí yóò fi ránṣẹ́ sí ìjọ tó wà ní ìpínlẹ̀ tí onítọ̀hún ń gbé. Bí èyí kò bá ṣeé ṣe fún akọ̀wé láti ṣe, kí ó fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka kí a lè bójú tó o. Lọ́nà yìí, a ó lè túbọ̀ ran olùfìfẹ́hàn náà lọ́wọ́.

10 Bí onítọ̀hún bá ní tẹlifóònù tó sì fún ọ ní nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ̀ àmọ́ tí kò fi àdírẹ́sì rẹ̀ pẹ̀lú, lo tẹlifóònù láti fi ṣe ìpadàbẹ̀wò onítọ̀hún. Múra ohun tó o máa sọ sílẹ̀ ṣáájú. Jẹ́ kí ìwé Reasoning rẹ wà lárọ̀ọ́wọ́tó kó o lè tètè lò ó. Àwọn kan ti ṣàṣeyọrí nídìí bíbá àwọn èèyàn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lórí tẹlifóònù, títí kan àwọn tí wọ́n ti pààrà ọ̀dọ̀ wọn àmọ́ tí wọn kì í bá nílé. Arábìnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè nọ́ńbà tẹlifóònù lọ́wọ́ àwọn obìnrin olùfìfẹ́hàn tí ó bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé, àbájáde èyí sì ni pé ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

11 Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Alàgbà Láti Lè Ran Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Lọ́wọ́: Inú àwọn alàgbà máa ń dùn gan-an láti fún àwọn wọ̀nyí ní àfiyèsí onífẹ̀ẹ́. Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pinnu fúnra wọn láti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Wọ́n wá rí i pé ó ṣe pàtàkì láti sún mọ́ ètò àjọ Jèhófà ká tó lè ní ààbò tẹ̀mí tí Bíbélì sọ ní Sáàmù 91. Díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí ti múra tán báyìí láti máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i. Bí àwọn mìíràn tí ó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ bá pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí lóṣù yìí, inú wọn lè dùn sí i tí a bá ní a máa bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà á ṣètò fún ẹnì kan láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn tó bá fẹ́ ìrànlọ́wọ́ lọ́nà yìí. Bá a bá ké sí ọ láti wá ran ẹnì kan lọ́wọ́, a óò mọrírì ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ gan-an ni.—Róòmù 15:1, 2.

12 Máa Bá A Nìṣó Ní “Dídi Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Mú”: Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ti rí i pé ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá wọn gbé pẹ́ẹ́lí sí i láwọn oṣù tó tẹ̀ lé e. Wọ́n ṣalábàápàdé àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n rí i pé ó yẹ káwọn padà lọ bẹ̀ wò. Èyí ló mú kí wọ́n túbọ̀ sapá láti máa lọ sóde ẹ̀rí lemọ́lemọ́ láti bàa lè padà lọ bẹ àwọn olùfìfẹ́hàn náà wò. Àwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.

13 Síbẹ̀, àwọn mìíràn ní ayọ̀ tó pọ̀ gan-an nínú iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni débi pé èyí sún wọn láti tún àwọn ìwéwèé wọn gbé yẹ̀ wò kí wọ́n lè mọ ohun àkọ́múṣe. Látàrí èyí, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan láti dín iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí wọ́n ń ṣe kù kí wọ́n sì máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Àwọn mìíràn kúkú yáa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ó wá ṣeé ṣe fún wọn láti túbọ̀ gbé ìrètí wọn ka Ọlọ́run, láì gbé e ka orí àwọn nǹkan tí ayé lè fúnni. Wọ́n rí i pé jíjẹ́ “aláìṣahun, [àti ẹni tó] múra tán láti ṣe àjọpín,” mú ìbùkún jìngbìnnì látọ̀dọ̀ Jèhófà wá fún àwọn, ó sì fún ìrètí tí àwọn ní láti gbádùn “ìyè tòótọ́” lókun. (1 Tím. 6:18, 19) Dájúdájú, bí ọ̀pọ̀ bá ṣe ń tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà sí ni gbogbo ìjọ yóò ṣe máa jàǹfààní sí. Àwọn aṣáájú ọ̀nà sábà máa ń sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní, wọ́n sì máa ń ké sí àwọn mìíràn láti bá wọn kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Èyí sì máa ń jẹ́ kí ipò tẹ̀mí ìjọ sunwọ̀n sí i.

14 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà” ní sáà Ìṣe Ìrántí yìí àti láwọn oṣù tó ń bọ̀ nípa títúbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ẹ jẹ́ ká fi ìmoore wa hàn fún ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ìyẹn ni fífún tó fún wa ní ìrètí gbígbé títí láé nínú ayé tuntun òdodo.—2 Pét. 3:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́