“Jẹ́rìí Kúnnákúnná sí Ìhìn Rere”
1. Ìhìn rere wo la ní láti wàásù fáráyé?
1 Nínú ayé tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìhìn rere yìí, àǹfààní ló jẹ́ fún wa “láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:24) Apá kan lára ìhìn rere tá a fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ ni pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tá a wà yìí máa tó kásẹ̀ nílẹ̀ tí ayé tuntun òdodo Jèhófà sì máa rọ́pò rẹ̀, níbi tí “àwọn ohun àtijọ́ ti [máa] kọjá lọ.” (2 Tím. 3:1-5; Ìṣí. 21:4) Lákòókò yẹn, àìsàn ò ní sí mọ́. (Aísá. 33:24) Àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú máa jáde wá látinú sàréè, wọ́n á sì tún dara pọ̀ mọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. (Jòh. 5:28, 29) Ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé máa di Párádísè ẹlẹ́wà. (Aísá. 65:21-23) Ìtọ́wò lèyí jẹ́ lára àwọn ìhìn rere tá a ní láti wàásù fáráyé!
2. Kí nìdí tí àkókò tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi fi máa fún wa láǹfààní àrà-ọ̀tọ̀ láti wàásù ìhìn rere?
2 A máa láǹfààní àrà-ọ̀tọ̀ láti wàásù ìhìn rere yìí láwọn oṣù March, April àti May. Ojú ọjọ́ máa ń mọ́lẹ̀ rekete fún ọ̀pọ̀ wákàtí níbi púpọ̀ lágbàáyé láwọn oṣù wọ̀nyẹn, èyí sì máa fún wa láǹfààní láti lo àkókò tó pọ̀ sí i lóde ẹ̀rí. Yàtọ̀ síyẹn, tí oòrùn bá ti wọ̀ lọ́jọ́ Sátidé March 22 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, ìyẹn ètò tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
3. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe púpọ̀ sí i lóde ẹ̀rí gẹ́gẹ́ bí ìdílé?
3 Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́: Ṣé wàá lè ṣètò àkókò rẹ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan, oṣù méjì tàbí oṣù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a mẹ́nu bà lókè yìí? Ẹ ò ṣe kúkú jíròrò rẹ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín? Tí ìdílé lápapọ̀ bá fọwọ́ so wọ́pọ̀, ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ìdílé yín lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. (Òwe 15:22) Ẹ fi ọ̀rọ̀ yìí sádùúrà, kẹ́ ẹ wá rí bí Jèhófà ṣe máa bù kún ìsapá yín. (Òwe 16:3) Ká tiẹ̀ wá ní kò sẹ́nì kankan nínú ìdílé yín tó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, gbogbo yín lè fi ṣe àfojúsùn yín láti ṣe púpọ̀ sí i lóde ẹ̀rí, bẹ́ ẹ ti ń bá àwọn tó láǹfààní láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣiṣẹ́.
4. Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ bóojí-o-jími lò ń ṣe, báwo lo ṣe lè ṣètò àkókò rẹ tí wàá fi lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
4 Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ bóojí-o-jími lò ń ṣe, o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó o bá ní ìṣètò tó mọ́yán lórí. Tó bá ṣeé ṣe, o lè wàásù lákòókò ìsinmi ọ̀sán. O sì lè béèrè fún ìpínlẹ̀ ara ẹni tó sún mọ́ ilé ẹ tàbí ibi tó o ti ń ṣiṣẹ́, kó o lè máa wàásù níbẹ̀ fún nǹkan bíi wákàtí kan kó o tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tàbí lẹ́yìn iṣẹ́. O tún lè ní àkókò tó pọ̀ sí i tó o lè lò lóde ẹ̀rí, tó o bá ṣètò láti ṣe àwọn nǹkan tí kò ṣe pàtàkì láwọn oṣù míì, tó o sì tún ń ṣiṣẹ́ dìrọ̀lẹ́ lóde ẹ̀rí láwọn òpin ọ̀sẹ̀. Àwọn kan máa ń gba ọjọ́ kan tàbí méjì láti sinmi lẹ́nu iṣẹ́ kí wọ́n lè fi jáde òde ẹ̀rí.
5. Báwo lo ṣe lè ran àwọn tó ti lọ́jọ́ lórí tàbí àwọn aláìlera lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
5 Tó o bá ti lọ́jọ́ lórí tàbí tó o bá jẹ́ aláìlera, bó bá sì jẹ́ pé ńṣe lo ò lókun tó, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó o bá ń lo wákàtí mélòó kan lóde ẹ̀rí lójoojúmọ́. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ ní “agbára tó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7) Ǹjẹ́ o mọ̀ pé arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún lé mẹ́fà [106] ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́! Àwọn ìbátan ẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí àtàwọn míì nínú ìjọ ràn án lọ́wọ́ kó lè wàásù láti ilé dé ilé, ó ṣe ìpadàbẹ̀wò, ó darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì kópa nínú àwọn apá iṣẹ́ ìsìn mìíràn. Ó ran àwọn mẹ́wàá kan lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arábìnrin àgbàlagbà yẹn sọ pé: “Tí mo bá ronú lórí àǹfààní àrà-ọ̀tọ̀ tí mo ní láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, mo túbọ̀ máa ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn wá, ìmọrírì tí mo ní sí Jèhófà, Ọmọ rẹ̀, àti ètò rẹ̀ sì ti wá kọjá kèrémí. Tọkàntọkàn ló fi máa ń wù mí láti sọ pé ‘o ṣé o, Jèhófà!’”
6. Báwo làwọn ọ̀dọ́ tó ti ṣèrìbọmi àmọ́ tó ṣì ń lọ síléèwé ṣe lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
6 Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́ tó ti ṣèrìbọmi ni ẹ́, àmọ́ tó o ṣì ń lọ síléèwé, ìwọ náà lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bíi tàwọn tó ń ṣiṣẹ́ bóojí-o-jími, ìwọ náà lè máa lo òpin ọ̀sẹ̀ lóde ẹ̀rí. Tó bá ṣeé ṣe láwọn ọjọ́ kan, o lè máa lo nǹkan bíi wákàtí kan lóde ẹ̀rí lẹ́yìn tẹ ẹ bá ti jáde níléèwé. O sì lè lo àsìkò ọlidé láti jáde òde ẹ̀rí. Bó o bá fẹ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ.
7. Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti fi kún ìtara àwọn ará lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá lásìkò Ìrántí Ikú kristi?
7 Ẹ Fi Kún Ìtara Wọn: Àwọn alàgbà lè ṣe púpọ̀ sí i láti túbọ̀ fi kún ìtara ìjọ nípasẹ̀ àpẹẹrẹ wọn. (1 Pét. 5:2, 3) Wọ́n lè ṣètò láti fi kún iye ìgbà tí ìjọ máa ń pàdé pọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá torí àwọn tó bá fẹ́ máa jáde òde ẹ̀rí láàárọ̀ kùtù hàì àtàwọn tó fẹ́ máa jáde lẹ́yìn iṣẹ́ tàbí lẹ́yìn tí wọ́n bá jáde níléèwé. Kí alábòójútó iṣẹ́-ìsìn rí i dájú pé ètò wà nílẹ̀ fún àwọn arákùnrin tó tóótun láti kó àwọn ará lọ sóde, kó ṣètò ìpínlẹ̀ ìwàásù tó máa tó wọn ṣe, kó sì rí i pé ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láwọn oṣù tí ìgbòkègbodò àrà-ọ̀tọ̀ yìí máa wáyé.
8. Kí la rí kọ́ látinú ìrírí ìjọ kan?
8 Oṣù mélòó kan ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi làwọn alàgbà ìjọ kan ti bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń ṣèfilọ̀ iye àwọn akéde tí wọ́n ti fọwọ́ sí pé kí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Èyí jẹ́ kó dá àwọn tó fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù lójú pé àwọn á rẹ́ni bá jáde. Yàtọ̀ sígbà tí wọ́n máa ń pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tẹ́lẹ̀, àwọn alàgbà ìjọ yẹn tún ṣètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá láàárọ̀ kùtù àti láwọn ìrọ̀lẹ́. Ohun tí gbogbo ìsapá wọn yọrí sí ni pé lóṣù April ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì àwọn akéde ìjọ yẹn tó ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, akéde mẹ́tà lé láàádọ́ta [53] tán-n-tán!
9. Kí nìdí tí àsìkò tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi fi jẹ́ àkókò tó dáa jù fáwọn tó bá tóótun láti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù?
9 Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Wàásù: Táwọn ẹni tuntun àtàwọn ọ̀dọ́ bá ti tóótun láti máa ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá, ẹ lè jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn akéde tó nírìírí ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ lè wáyé lásìkò tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn akéde máa fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lóde ẹ̀rí. Ṣó o ní ẹnì kan tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ti ń hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo Jèhófà? Ṣó o láwọn ọmọ tó níwà rere tí wọ́n sì ń ṣe dáadáa tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn àmọ́ tí wọn ò tíì di akéde? Tí irú àwọn wọ̀nyí bá fẹ́ di akéde tí kò tí ì ṣèrìbọmi, tó o sì rò pé wọ́n tóótun, o lè sọ fún ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ yín. Alága àwọn alábòójútó máa ṣètò pé kí alàgbà méjì bá ìwọ àti ọmọ rẹ tàbí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jíròrò ọ̀rọ̀ náà.
10. Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́?
10 Àwọn oṣù tá a fẹ́ mú yìí tún jẹ́ àkókò àrà-ọ̀tọ̀ táwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ lè padà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn nínú ìjọ. Káwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àtàwọn alàgbà tó kù sapá gidigidi láti bẹ irú àwọn wọ̀nyí wò, kí wọ́n sì pè wọ́n láti bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Tó bá jẹ́ pé ọjọ́ ti pẹ́ tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́mọ́, kí alàgbà méjì kọ́kọ́ fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn kí wọ́n lè mọ̀ bóyá wọ́n tóótun.—km-YR 11/00 ojú ìwé 7.
11. Ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lọ wo ni Ọlọ́run gbà fi “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [rẹ̀]” hàn sáráyé?
11 Múra Sílẹ̀ De Ìrántí Ikú Kristi: Ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lọ tí Ọlọ́run gbà fi “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [rẹ̀]” hàn sí wa ni fífi tó fi ọmọ rẹ̀ rà wá padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. (Ìṣe 20:24) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó moore Ọlọ́run ló máa kóra jọ kárí ayé lọ́jọ́ Sátidé March 22, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀, láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ẹ jẹ́ ká pe gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá síbi ètò pàtàkì tó ń jẹ́rìí sí inú rere tá ò lẹ́tọ̀ọ́ sí àmọ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa yìí.
12. Àwọn wo ló yẹ ká pè síbi Ìrántí Ikú Kristi?
12 Kọ orúkọ àwọn tó o fẹ́ pè. Ó dájú pé wàá kọ orúkọ àwọn mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́, aládùúgbò, ojúlùmọ̀ níbi iṣẹ́ tàbí níléèwé, àwọn tó o ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà kan rí, àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní lọ́ọ́lọ́ọ́ àtàwọn tó o máa ń padà bẹ̀ wò lóòrèkóòrè. Táwọn tó o pè síbi Ìrántí Ikú Kristi bá láwọn ìbéèrè, o lè lo àfikún àpilẹ̀kọ tó dá lé Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tó wà lójú ìwé 206 sí 208 nínú ìwé Bíbélì fi kọ́ni láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Èyí tún lè jẹ́ ọ̀nà kan tó o lè gbà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn, nítorí wàá láǹfààní láti sọ fún wọn pé ìwé yìí gan-an la fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
13. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún ìsapá àwọn akéde méjì tí wọ́n fi ṣe àfojúsùn wọn láti pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi?
13 Arábìnrin kan kọ orúkọ ìdílé méjì dín láàádọ́ta [48] tó fẹ́ pè sórí ìwé kan. Tó bá ti ń sọ fún wọn ló ti máa sàmì sórúkọ wọn, tó sì máa kọ ọjọ́ tó sọ fún wọn sílẹ̀. Ẹ ò rí i bí inú ẹ̀ ti dùn tó nígbà táwọn mẹ́rìn dín lọ́gbọ̀n [26] lára àwọn tó pè, wá síbi Ìrántí Ikú Kristi! Arákùnrin tó ni ilé ìtajà kan pe ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olórí ìsìn síbi Ìrántí Ikú Kristi. Ọkùnrin náà lọ síbẹ̀, lẹ́yìn náà ló wá sọ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n pé, “Ohun tí mo kọ́ nípa Bíbélì láàárín wákàtí kan ju èyí tí mo ti fi ọgbọ̀n ọdún kọ́ ní Sọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì lọ.” Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn tá a ṣe Ìrántí Ikú Kristi ló ti gbà pé kí wọ́n máa fi ìwé Bíbélì fi kọ́ni bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
14. Ìkéde tó máa kárí ayé wo la máa bẹ̀rẹ̀ sí ṣe láti March 1?
14 Ìkéde: Kárí ayé la máa pín àkànṣe ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi bẹ̀rẹ̀ láti Sátidé March 1 títí di March 22. Gbogbo wa ló yẹ ká ṣe ohun tá a bá lè ṣe láti kọ́wọ́ ti ìkéde pàtàkì yìí. Ohun tó máa dáa jù ni pé ká fi ìwé ìkésíni náà lé àwọn onílé lọ́wọ́ dípò ká fi há ẹnu ọ̀nà wọn. Àmọ́ ṣá o, tí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín bá tóbi, àwọn alàgbà lè pinnu pé kẹ́ ẹ máa dọ́gbọ́n fi ìwé ìkésíni há ẹnu ọ̀nà àwọn tẹ́ ò bá bá nílé. Òpin ọ̀sẹ̀ la ó máa wá fún àwọn èèyàn láwọn ìwé ìròyìn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde.
15. Báwo la ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi?
15 Bó ṣe jẹ́ pé àkókò tá a ní láti pín ìwé ìkésíni náà ò pọ̀ tó, ó máa dáa tá ò bá jẹ́ kí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa gùn jàǹràn janran. Sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́ tọyàyàtọyàyà. O lè sọ pé: “A fẹ́ rí i dájú pé a fìwé pe ìwọ, ìdílé rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ síbi ètò pàtàkì kan tó máa wáyé ní March 22. Ìwé ìkésíni rẹ rèé. Àlàyé síwájú sí i wà nínú ìwé ìkésíni yìí.” Ó ṣeé ṣe kí onílé láwọn ìbéèrè, ó sì lè gba ìwé ìkésíni náà kó sì ṣèlérí pé òun máa wá. Kọ orúkọ àwọn tó sọ pé àwọn máa wá, kó o sì padà bẹ̀ wọ́n wò.
16. Ìrírí wo ló fi hàn pé fífi ìwé pe àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wá síbi Ìrántí Ikú Kristi ṣe pàtàkì gan-an?
16 Lọ́dún tó kọjá, ṣójà kan rí ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n fi há ẹnu ilẹ̀kùn rẹ̀. Ó pinnu láti lọ, àmọ́ ó ní láti tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá ẹ̀. Nígbà tó fìwé ìkésíni náà han ọ̀gá ẹ̀, ńṣe lọ̀gá dákẹ́ lọ sii, lẹ́yìn náà ló wá sọ pé Ẹlẹ́rìí làwọn òbí òun àti pé òun náà máa ń tẹ̀ lé wọn lọ sáwọn ìpàdé. Ọ̀gá ẹ̀ ò wulẹ̀ fún un láyè pé kó lọ, àmọ́ òun alára tẹ̀ lé e débẹ̀!
17. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ò tíì tàsé ète tó mú kí Ọlọ́run fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa?
17 Fi Ìmọrírì Hàn: Bí Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2008 ṣe ń sún mọ́lé, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ronú lórí inú rere tá ò lẹ́tọ̀ọ́ sí tí Jèhófà fi hàn sí wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwá ń pàrọwà fún yín pé kí ẹ má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀.” (2 Kọ́r. 6:1) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ò tíì tàsé ète tó mú kí Ọlọ́run fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ṣùgbọ́n lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 6:4) Nítorí náà, à ń fi hàn pé a mọrírì ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa yìí, tá a bá ń hùwà ọmọlúwàbí tá a sì ń fìtara wàásù ìhìn rere. A máa láǹfààní àrà-ọ̀tọ̀ láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ jíjẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere lásìkò Ìrántí Ikú Kristi.
[Àpótí tó wà lójú ewé 3]
Àwọn Wo Ló Lè Ṣe Aṣààjú Ọ̀nà Olùránlọ́wọ́?
◼ Àwọn ìdílé
◼ Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ bóojí-o-jími
◼ Àwọn tó lọ́jọ́ lórí àtàwọn aláìlera
◼ Àwọn ọmọ iléèwé
[Àpótí tó wà lójú ewé 4]
Tó O Bá Ń Fún Àwọn Èèyàn Ní Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi:
◼ Má ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ gùn jù, kó o sì fìtara sọ̀rọ̀
◼ Kọ orúkọ àwọn tó sọ pé àwọn máa wá, kó o sì padà bẹ̀ wọ́n wò
◼ Fún àwọn èèyàn láwọn ìwé ìròyìn láwọn òpin ọ̀sẹ̀