Àkókò Ìrántí Ikú Kristi Máa Ń Jẹ́ Ká Lè Fi Kún Ìgbòkègbodò Wa!
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú nípa fífi kún ìgbòkègbodò wa ní oṣù March, April àti May?
1 Ǹjẹ́ o lè fi kún ipa tó ò ń kó lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ láàárín àkókò Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀ lọ́nà yìí? Láwọn ibi púpọ̀, ojú ọjọ́ máa dáa, ilẹ̀ kò sì ní máa tètè ṣú. Àwọn akéde kan máa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tàbí ní iléèwé, wọ́n sì lè lo àkókò ìsinmi náà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bẹ̀rẹ̀ láti April 2, a máa ṣe ìpolongo àkànṣe láti fi pe àwọn èèyàn síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe ní April 17. Lẹ́yìn náà, a óò ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti mú kí ìfẹ́ àwọn tó wá túbọ̀ pọ̀ sí i, a óò sì tún pè wọ́n láti wá gbọ́ àkànṣe àsọyé tá a máa sọ ní ọ̀sẹ̀ April 25. Ká sòótọ́, a ní ìdí tó pọ̀ láti ronú lórí bá a ṣe máa fi kún ìgbòkègbodò wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní oṣù March, April, àti May.
2. Ọ̀nà tó dára wo la lè gbà mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wà gbòòrò sí i?
2 Ṣíṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́: Ọ̀nà kan tó dáa láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i ni pé ká ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọwọ́ gbogbo wa ló máa ń dí, èyí gba pé ká tètè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò sílẹ̀, ká sì ṣe àyípadà tó bá yẹ nínú àwọn ìgbòkègbodò wa. (Òwe 21:5) Kódà a lè sún àwọn ohun kan tá a máa ń ṣe déédéé àmọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan síwájú. (Fílí. 1:9-11) O tún lè bá àwọn ẹlòmíì nínú ìjọ sọ̀rọ̀ pé o fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà, kó o lè mọ̀ bóyá àwọn náà á fẹ́ lọ́wọ́ nínú ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ pẹ̀lú rẹ.
3. Báwo ni àwọn ìdílé ṣe lè ṣètò láti fi kún ìgbòkègbodò wọn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?
3 Ó máa dára kẹ́ ẹ jíròrò àfojúsùn yín gẹ́gẹ́ bí ìdílé nígbà tẹ́ ẹ bá tún fẹ́ ṣe Ìjọsìn Ìdílé. (Òwe 15:22) Tẹ́ ẹ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ìdílé yín ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Tẹ́ ẹ bá wá rí i pé èyí kò ṣeé ṣe ńkọ́? Nínú ìdílé yín ẹ ṣì lè ṣètò láti fi kún ìgbòkègbodò yín lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ nípa jíjáde òde ẹ̀rí ní ìrọ̀lẹ́ tàbí kẹ́ ẹ máa pẹ́ díẹ̀ sí i lóde ẹ̀rí láwọn òpin ọ̀sẹ̀.
4. Àwọn ìbùkún wo la máa rí gbà tá a bá fi kún ìgbòkègbodò wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi yìí?
4 Jèhófà ń kíyè sí gbogbo ohun tá à ń ṣe láti jọ́sìn rẹ̀, ó sì mọrírì àwọn ohun tá à ń yááfì. (Héb. 6:10) A máa ń láyọ̀ tá a bá fún Jèhófà àtàwọn èèyàn ní nǹkan. (1 Kíró. 29:9; Ìṣe 20:35) Ṣé wàá fi kún ìgbòkègbodò rẹ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi yìí, kó o sì rí ayọ̀ àti ìbùkún jìgbìnnì tó máa tìdí ẹ̀ yọ?