Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 21
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 21
Orin 97 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 18 ìpínrọ̀ 1 sí 9 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Nehemáyà 12-13 (10 min.)
No. 1: Nehemáyà 13:15-22 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Fún Jèhófà Ọlọ́run Ní Ìjọsìn Tá A Yà Sọ́tọ̀ Gédégbé—Ẹ́kís. 20:5 (5 min.)
No. 3: Ìdè Ìgbéyàwó Gbọ́dọ̀ Ní Ọlá—td 19A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Jèhófà Kò Ní Fi Àwọn Ẹni Ìdúróṣinṣin Rẹ̀ Sílẹ̀. (Sm. 37:28) Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 15, 2010, ojú ìwé 12 sí 15. Sọ ìrírí tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò ìrírí kọ̀ọ̀kan, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: Bá A Ṣe Lè Parí Ọ̀rọ̀ Lọ́nà Tó Múná Dóko Lóde Ẹ̀rí. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 221, ìpínrọ̀ 5, sí ìparí ojú ìwé 222. Ní ṣókí ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì látinú àpilẹ̀kọ náà.
10 min: “‘Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná’ Nípa Ìjọba Ọlọ́run.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 31 àti Àdúrà