Ẹ Polongo Àwọn Ìtayọlọ́lá Jèhófà Kárí Ayé
1. Kí ló ń mú wa polongo ìtayọlọ́lá Jèhófà káàkiri ayé?
1 “Tìrẹ, Jèhófà, ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ìtayọlọ́lá àti iyì; nítorí ohun gbogbo tí ó wà ní ọ̀run àti ní ilẹ̀ ayé jẹ́ tìrẹ.” (1 Kíró. 29:11) Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti bá a ṣe mọrírì Ọlọ́run wa ṣe máa ń nípa lórí wa? Ó ń jẹ́ ká lè máa ‘polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni tó pè wá jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.’ (1 Pét. 2:9) A ò gbọ́dọ̀ dákẹ́ sísọ fáwọn ẹlòmíì nípa Ọlọ́run wa gíga jù lọ! A máa ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti polongo ìtayọlọ́lá Jèhófà lóṣù March, April àti May.
2. Àkànṣe ètò wo ló wà nílẹ̀ láti fi polongo Ìrántí Ikú Kristi, àwọn wo ló sì lè kópa nínú ẹ̀?
2 Àkànṣe Ètò Láti Fi Pe Àwọn Èèyàn Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi: Ní ọjọ́ Monday, April 2, a óò jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ nípa ìtayọlọ́lá Jèhófà nígbà tá a bá ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi. A óò bẹ̀rẹ̀ sí í pín àkànṣe ìwé ìkésíni tá a máa fi pe àwọn èèyàn wá síbẹ̀ láti March 17 títí di April 2. A rọ gbogbo ẹ̀yin ará láti kọ́wọ́ tì í ní kíkún. Àkókò yìí ló máa dára gan-an fáwọn ẹni tuntun láti bẹ̀rẹ̀ sí í kéde ìhìn rere bí wọ́n bá tóótun. Bó o bá ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí àwọn ọmọ tí wọ́n lè tóótun, o ò ṣe kúkú fi tó àwọn alàgbà létí.
3. Kí la lè sọ bá a bá fẹ́ pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi?
3 Ètò yìí á fara jọ èyí tá a ṣe nígbà tí Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” ń bọ̀ lọ́nà. A máa kó ìwé ìkésíni tó pọ̀ tó ránṣẹ́ kí akéde kọ̀ọ̀kan bàa lè rí àádọ́ta [50] gbà kí aṣáájú-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan sì lè rí àádọ́jọ [150] gbà. Máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀ ní ṣókí, bóyá kó o sọ pé: “Ìwé ìkésíni tiyín rèé o, a fi ń pè yín síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan tó máa ń wáyé lọ́dọọdún. A ó máa retí yín o. Àwọn ohun tẹ́ ẹ máa fẹ́ mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà wà nínú ìwé ìkésíni yẹn.” Àmọ́ ṣá o, bí onílé bá ní ìbéèrè, wá àyè láti dáhùn ìbéèrè rẹ̀. Àpilẹ̀kọ lórí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 206 nínú àfikún tó wà lẹ́yìn ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, á wúlò gidigidi fún dídáhùn irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Láwọn òpin ọ̀sẹ̀, ìwé ìròyìn tó ní déètì oṣù tá a wà àtàwọn àkànṣe ìwé ìkésíni náà la ó máa lò. Kọ orúkọ àti àdírẹ́sì ẹni tó bá fìfẹ́ hàn, kó o sì ṣètò láti lọ padà bẹ̀ wọ́n wò.
4. Báwo la ṣe máa pín àwọn ìwé tá a máa fi pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi?
4 Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ẹ rí i pé ẹnì kọ̀ọ̀kan tẹ́ ẹ bá bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lẹ fún ní àkànṣe ìwé ìkésíni yìí. Fún ìdí èyí, ẹ ṣàkọsílẹ̀ nípa àwọn tí ẹ kò bá bá nílé, kẹ́ ẹ sì ṣètò àtipadà lọ nígbà mìíràn. Kí àwọn ìjọ tí ìwé ìkésíni púpọ̀ bá ṣẹ́ kù sí lọ́wọ́ fi wọ́n há ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò sí nílé ní ọ̀sẹ̀ tó kángun sí ìgbà Ìrántí Ikú Kristi, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ṣáájú ìgbà náà. Rí i dájú pé àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ, àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìbátan, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn aládùúgbò àtàwọn ojúlùmọ̀ mìíràn rí ìwé ìkésíni náà gbà.
5. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìsinsìnyí ló yẹ ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò tó bá yẹ láti lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
5 Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́: Ṣé wàá kúkú gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kó o bàa lè túbọ̀ fi àkókò tó pọ̀ polongo ìtayọlọ́lá Jèhófà lóṣù March, April àti May? Bó o bá máa ṣe é, ó máa gba pé kó o ṣe àwọn àyípadà díẹ̀ kan nínú ìṣètò rẹ̀ o. (Éfé. 5:15-17) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé wàá láyọ̀, Jèhófà ò sì ní ṣaláì bù kún ẹ torí ìsapá yòówù tó o bá ṣe láti fi kún àkókò tó ò ń lò nínú iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀. (Òwe 10:22) Níwọ̀n bí àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti sún mọ́lé, ìsinsìnyí ló dáa láti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀.—Òwe 21:5.
6. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìrírí arábìnrin ẹni àádọ́rùn-ún ọdún tó ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún tó kọjá?
6 Arábìnrin ẹni àádọ́rùn-ún ọdún kan láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún tó kọjá. Ó ní: “Mo fẹ́ràn láti máa roko nínú ọgbà mi, nígbà tí àkókò sì tó láti bẹ̀rẹ̀ sí í gbin ọ̀gbìn, mo kíyè sí i pé kò yẹ kí n fi ohun tó yẹ kó gbẹ̀yìn ṣáájú. Torí pé ó wù mí láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, mo pinnu láti wọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March.” Ǹjẹ́ arábìnrin yìí rí ìbùkún èyíkéyìí gbà? Ohun tóun fúnra ẹ̀ sọ ni pé “mo túbọ̀ dojúlùmọ̀ àwọn ara tá a jọ wà nínú ìjọ, èyí sì mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.” Ṣé àwa náà lè fojú ṣùnnùkùn wo àwọn nǹkan tá à ń fi àkókò wa ṣe, ká sì wò ó bóyá a lè ṣe àwọn àyípadà kan tó máa jẹ́ ká gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
7. Ǹjẹ́ ó ṣòro láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
7 Bó o ṣe máa rí àádọ́ta wákàtí táwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ń ròyìn lè má nira tó bó o ṣe rò. Kọ́kọ́ gbàdúrà nípa àwọn ìgbòkègbodò rẹ ná, ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wàá máa tẹ̀ lé, kó o sì kọ ọ́ sínú kàlẹ́ńdà rẹ. O mọ ipò tó yí ẹ ká ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Bó o bá ní àìlera tàbí tó jẹ́ pé ńṣe ni o ò fi bẹ́ẹ̀ lókun, o ṣì lè máa fi wákàtí mélòó kan wàásù lójúmọ́. Bákan náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn tó wà níléèwé lè ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, bí wọ́n bá lè máa jáde lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ tàbí ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀.
8. Kí ló jẹ́ kí tọkọtaya kan lè ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
8 Àwọn ìdílé kan wà tó jẹ́ pé gbogbo wọn ló jọ gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sígbà kan náà. Ó tó ọdún mélòó kan táwọn tọkọtaya kan fi ń gbé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ yẹ̀ wò torí wọ́n rò pé bí ipò nǹkan ṣe rí fáwọn ò ní jẹ́ káwọn lè ṣe é. Kí ni wọ́n ṣe sí i? Ohun táwọn fúnra wọn sọ ni pé: “A gbàdúrà sí Jèhófà kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohun tó ti ń wù wá látọjọ́ tó pẹ́ láṣeyọrí.” Ìgbà tí wọ́n sì ṣètò àwọn nǹkan wọn bó ṣe yẹ, ó ṣeé ṣe fún wọn láti gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Wọ́n sọ síwájú sí i pé: “Ẹnu ò gbàròyìn. Àǹfààní tá a rí nínú ẹ̀ pọ̀. Ìwọ náà tiẹ̀ gbìyànjú rẹ̀ wò ná. Òótọ́ kan ni pé ohun tó mú káwa méjì yìí lè ṣe é, ìwọ̀ náà lè ṣe é.”
9. Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín tó máa tẹ̀ lé e, kí lẹ lè ṣe láti múra sílẹ̀ de àwọn oṣù àkànṣe ìgbòkègbodò tó ń bọ̀ lọ́nà yìí?
9 Kí ló dé tẹ́ ò kúkú fi àkókò díẹ̀ sílẹ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín láti jíròrò bí gbogbo yín ṣe lè fi kún àkókò tẹ́ ẹ̀ ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láwọn oṣù tó ń bọ̀? Ká tiẹ̀ wá ní gbogbo ìdílé yín ò lè ṣe é, ẹ lè kọ́wọ́ ti ẹnì kan lára yín láti ṣe é. Bí kò bá ṣeé ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ lè jọ pinnu láti lo àkókò tó pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ láwọn oṣù àkànṣe ìgbòkègbodò tó ń bọ̀ lọ́nà yìí.
10. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ sọ fáwọn ẹlòmíì nípa bó ṣe ń wù wá láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi?
10 Ẹ Gbárùkù Tira Yín: Báwọn èèyàn bá rẹni tó nítara, wọ́n máa ń fẹ́ fara wé e. Máa sọ̀rọ̀ nípa bó o ṣe fẹ́ràn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó. Èyí lè fáwọn ẹlòmíràn níṣìírí láti ṣe iṣẹ́ náà. Láfikún sí i, àwọn tó ti ṣe iṣẹ́ náà rí lè fún ẹ láwọn àbá tó máa jẹ́ kó o lè mọ ètò tó yẹ kó o ṣe àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó yẹ kó o máa tẹ̀ lé kí wákàtí rẹ lè máa pé. (Òwe 15:22) Bó bá ṣeé ṣe fún ẹ láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, o ò ṣe ké sí akéde mìíràn tí ipò yín jọra kẹ́ ẹ lè jọ ṣe iṣẹ́ aláyọ̀ yìí?
11. Ọ̀nà wo làwọn alàgbà lè gbà mú kí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ yá àwọn ará lára láti gbà láwọn oṣù tó ń bọ̀?
11 Ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà ló ti ṣe àyípadà tó yẹ nínú ìṣètò wọn kí wọ́n bàa lè lọ́wọ́ sí ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn pàtàkì yìí. (Héb. 13:7) Ó dájú pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń fáwọn ará níṣìírí! Bákan náà, báwọn alàgbà bá ń fi ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣe ọ̀rọ̀ sọ pẹ̀lú àwọn ará, ó lè jẹ́ kí iṣẹ́ náà yá àwọn ará lára láti ṣe. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìṣírí díẹ̀ tàbí ọ̀rọ̀ ìyànjú tó lè ranni lọ́wọ́ làwọn kan nílò tí wọ́n á fi pinnu láti gbaṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Bóyá ó sì ṣeé ṣe kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣètò fún àfikún ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá kó bàa lè ṣeé ṣe fún gbogbo gbòò láti rẹ́ni bá ṣiṣẹ́, kódà lẹ́yìn àkókò iṣẹ́ tàbí lẹ́yìn àkókò ilé ìwé. Kẹ́ ẹ máa ṣe ìfilọ̀ ìṣètò yìí déédéé. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sì tún rí i pé ìpínlẹ̀ ìwàásù tó pọ̀ tó wà, níbi táwọn ará ti lè ṣiṣẹ́, àti pé wọ́n ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ tó lọ́wọ́.
12. Kí lo tún lè ṣe bó ò bá lè gbaṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
12 Bó bá tiẹ̀ wá ṣẹlẹ̀ pé ipò nǹkan ò jẹ́ kó o lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, o lè fáwọn tó máa ṣe é níṣìírí, o sì lè gbàdúrà fún wọn. (Òwe 25:11; Kól. 4:12) O lè ṣètò láti bá wọn ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀ tàbí kó o lò ju àkókò tó o máa ń lò tẹ́lẹ̀ lóde ẹ̀rí lọ́jọ́ tó o bá bá wọn ṣiṣẹ́.
13. Kí là ń fojú sọ́nà fún láti rí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, kí ni ìjọ yín sì ní láti ṣe ká bàa lè kẹ́sẹ járí?
13 À Ń Fẹ́ Kí Èèyàn Ẹgbẹ̀rún Lọ́nà Ọgbọ̀n [30,000] Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ ní April: Iye aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó pọ̀ jù tó tíì ṣiṣẹ́ náà rí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lóṣù kan ṣoṣo jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàlélógún àti méjì [23,002], ìyẹn lóṣù April ọdún 2003. Ìdí nìyí tá a fi pinnu pé ó yẹ ká lè rí tó èèyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] tó máa yọ̀ọ̀da ara wọn láti gba iṣẹ́ náà. Ká sọ pé a pín àwọn akéde tó wà nínú ìjọ kan ní mẹ́sàn-án mẹ́sàn-án, bí ẹyọ ẹnì kan lára àwọn mẹ́sàn-án mẹ́sàn-án náà bá gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, nígbà tí gbogbo ìjọ tá a ní ní Nàìjíríà bá fi máa ṣe bẹ́ẹ̀, a ó ti ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] tó máa ṣe iṣẹ́ náà. Ó ṣe tán, àwọn ìjọ kan lè ní iye akéde tó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ tó máa yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe é. Ó máa rọrùn fún gbogbo ìjọ láti rí akéde kan láàárín akéde mẹ́sàn-án tó máa gbaṣẹ́ náà. Kékeré kọ́ ni kóríyá tó máa ṣe fún ìjọ, ó sì máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù yín kúnnákúnná!
14. Kí ló mú kí oṣù April jẹ́ oṣù tó dáa jù láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
14 Kí ló mú kí oṣù April jẹ́ oṣù tó dára gan-an láti fi ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Ìbẹ̀rẹ̀ oṣù April ni Ìrántí Ikú Kristi máa bọ́ sí, èyí sì máa fún wa láǹfààní tó pọ̀ láti padà bẹ àwọn tó wá wò. Ẹ fún wọn ní ìwé ìròyìn, kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ bó bá yá. Nítorí náà, bá a bá lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April, á máa ní àǹfààní tó pọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láfikún sí i, òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún ni oṣù April ní, àti pé àkókò yẹn ni ọlidé wọn máa bọ́ sí, èyí tó máa jẹ́ kó rọrùn fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ àtàwọn tó ṣì wà nílé ìwé láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù wa bí àkókò Ìrántí Ikú Kristi ṣe ń sún mọ́lé?
15 Bá a ṣe ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún la túbọ̀ ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Àkókò tó ṣẹ́ kù láti fi sọ fáwọn ẹlòmíì nípa Ọlọ́run wa gíga jù lọ ò pọ̀ mọ́. (1 Kọ́r. 7:29) Gbàrà tí àkókò Ìrántí Ikú Kristi ọdún yìí bá ti kọjá, àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tá a máa ní láti yin Bàbá wa ọ̀run lọ́dún náà ti lọ títí láé nìyẹn. Ǹjẹ́ ká múra sílẹ̀ nísinsìnyí láti ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láàárín oṣù March, April àti May ká lè polongo ìtayọlọ́lá Jèhófà!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Ṣé A Lè Rí Tó Ẹgbẹ̀rún Lọ́nà Ọgbọ̀n [30,000] Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣù April?
◼ Ẹ fojú ṣùnnùkùn wo bẹ́ ẹ ṣe ń lo àkókò yín
◼ Ẹ jíròrò bẹ́ ẹ ṣe lè ṣe é gẹ́gẹ́ bí ìdílé
◼ Ẹ sọ fáwọn ẹlòmíì bó ṣe ń wù yín tó láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́