ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/97 ojú ìwé 3-5
  • A Ń Fẹ́—30,000 Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ń Fẹ́—30,000 Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Pàtàkì Tó Yẹ Ká Fojú Sùn Lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀ Yìí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ṣé A Óò Ṣe É Lẹ́ẹ̀kan Sí I?—Ìpè Mìíràn fún Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ẹ Polongo Àwọn Ìtayọlọ́lá Jèhófà Kárí Ayé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Wàásù Kí O sì Tún Jẹ́rìí Kúnnákúnná
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 2/97 ojú ìwé 3-5

A Ń Fẹ́—30,000 Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́

Ìwọ Ha Lè Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ ní March? April? May Bí?

1 “A Ń Fẹ́ 1,000 Oníwàásù” ni àkọlé àpilẹ̀kọ kan tí a tẹ̀ jáde nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) April 1881. Ó ní ìkésíni kan nínú, sí gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́, “àwọn ẹni tí Olúwa ti fi ìmọ̀ òtítọ́ Rẹ̀ jíǹkí,” láti lo gbogbo àkókò tí wọ́n bá lè lò láti nípìn-ín nínú títan òtítọ́ Bíbélì kálẹ̀. A fún àwọn tí wọ́n bá lè yọ̀ǹda ìlàjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àkókò wọn pátápátá fún iṣẹ́ Olúwa níṣìírí láti yọ̀ǹda ara wọn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere olùpínwèé ìsìn kiri—àwọn aṣáájú fún àwọn aṣáájú ọ̀nà lónìí.

2 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà ti yí pa dà láti àwọn ọdún 1800 wá, ohun kan ṣì jẹ́ òtítọ́ síbẹ̀—àwọn olùṣèyà-símímọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run fẹ́ láti máa bá a nìṣó ní lílo àkókò púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú títan ìhìn rere náà kálẹ̀. Ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ń ran àwọn akéde ìjọ lọ́wọ́ láti mú kí ìjáfáfá wọn túbọ̀ sunwọ̀n sí i bí wọ́n ṣe ń lo àfikún àkókò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Ìjọba náà.—Kól. 4:17; 2 Tím. 4:5.

3 Láti ìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arákùnrin àti arábìnrin ti ń gbádùn ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ìtara ọkàn fún ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà yí lọ sókè débi pé a dé góńgó tí ó ju 22,000 aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ ní ìpínlẹ̀ ẹ̀ka Nàìjíríà ní April 1990! Dájúdájú, ṣíṣeéṣe náà wà láti dé góńgó tuntun 30,000 ní 1997.

4 A fún ọ níṣìírí láti fi ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣe góńgó rẹ ní ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú oṣù March, April, àti May. Èé ṣe tí a fi fi oṣù March kún un? Nítorí pé, ní ọdún yìí, Ìṣe Ìrántí ikú Jésù bọ́ sí Sunday, March 23. Kò sí ọ̀nà míràn tí ó sàn jù tí a lè gbà lo àwọn ọ̀sẹ̀ tí ó ṣáájú Ìṣe Ìrántí náà ju láti fi ìtara nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba tí Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Kristi, dá sílẹ̀ lọ. Bí a óò ti máa fúnni ní òkìtì ẹ̀rí ní March, a lè ké sí ọ̀pọ̀ olùfìfẹ́hàn láti dara pọ̀ mọ́ wa ní ṣíṣèrántí ikú Kristi. March yóò tún jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ní ti pé, fún ìgbà àkọ́kọ́, a óò gbé ìwé tuntun náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, jáde lákànṣe. Ní àfikún sí i, oṣù March ní Saturday márùn-ún àti Sunday márùn-ún nínú, ní fífàyègba ìgbòkègbodò kíkún rẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ní òpin ọ̀sẹ̀. Dájúdájú, nínú oṣù April àti May, ìsapá onítara tí ń bá a nìṣó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yóò mú kí a lè pa dà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́ tí a rí, kí a sì bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun nínú ilé, ní lílo ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? A óò tún kárí ìpínlẹ̀ wa dáradára, ní pàtàkì ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀, ní lílo àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí ó bágbà mu.

5 Ta Ni Ó Tóótun Láti Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́?: Ìwé náà, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 114 ṣàlàyé pé: “Ipo ara-ẹni yowu tí tirẹ lè jẹ́, bi iwọ bá ti ṣe iribọmi tí o sì wà ní iduro deedee nipa iwarere, iwọ lè ṣeto lati dé oju-ila 60 wakati tí a beere fun ní oṣu kan ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá-oko ki o sì gbagbọ pe o lè sìn fun oṣu kan tabi jù bẹẹ lọ gẹgẹ bi aṣaaju-ọna oluranlọwọ, awọn alagba ijọ yoo ní inudidun lati ṣiṣẹ lori iwe-ìwọṣẹ́ rẹ fun anfaani iṣẹ-isin yii.” Ìwọ ha lè wá àyè fún àǹfààní yìí ní March? April? May bí?

6 Ìṣarasíhùwà rere ti àwọn alàgbà, pa pọ̀ pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn tọkàntọkàn láti ọ̀dọ̀ àwọn akéde yòó kù, yẹ kí ó mú kí ìdáhùnpadà sí ìkésíni fún 30,000 aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ yìí ní àṣeyọrí tí ó ga. (Héb. 13:7) A fún gbogbo olórí ìdílé níṣìírí láti wádìí iye àwọn tí ó lè dára pọ̀ mọ́ òtú àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn oṣù tí ń bọ̀ nínú agbo ilé wọn.—Orin Dá. 148:12, 13; fi wé Ìṣe 21:8, 9.

7 Má ṣe yára parí èrò sí pé o kò lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nítorí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ tí ń gba gbogbo àkókò, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́, ẹrù iṣẹ́ ìdílé, tàbí àwọn àìgbọdọ̀máṣe mìíràn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu. Fún àwọn kan, ó lè má ṣeé ṣe láti nípìn-ín; síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú ìṣètò rere àti ìbùkún Jèhófà, wọ́n lè kẹ́sẹ járí. (Orin Da. 37:5; Òwe 16:3) Jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà lo agbára ìdarí lórí àwọn àyíká ipò rẹ; má ṣe jẹ́ kí àwọn àyíká ipò rẹ̀ lo agbára ìdarí lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. (Òwe 13:19a) Nítorí náà, pẹ̀lú ìfẹ́ lílágbára fún Jèhófà àti fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, ó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ láti ṣàtúntò bí wọ́n ṣe ń lo ìgbésí ayé wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kí wọ́n lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i ní oṣù kan lẹ́ẹ̀kan. (Lúùk. 10:27, 28) Ọ̀pọ̀ ìbùkún wà ní ìpamọ́ fún àwọn tí wọ́n bá lo ara wọn tokunratokunra nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà.—1 Tím. 4:10.

8 Ohun Tí Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Ń Ṣàṣeparí Rẹ̀: Ìsapá tọkàntọkàn tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń ṣe láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ń yọrí sí igbe ìyìn ńlá sí Jèhófà. Bí àwọn olùpòkìkí Ìjọba wọ̀nyí ṣe ń tiraka láti tan ìhìn rere náà kálẹ̀ dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn sí i, a túbọ̀ ń fa àwọn pẹ̀lú sún mọ́ Jèhófà sí i nítorí pé wọ́n ń kọ́ láti túbọ̀ gbára lé e fún ẹ̀mí àti ìbùkún rẹ̀.

9 Níní àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, aṣáájú ọ̀nà déédéé, àti aṣáájú ọ̀nà àkànṣe tí ń ṣiṣẹ́ láàárín wa ń pèsè àkọ̀tun ẹ̀mí alágbára nínú ìjọ. Ìtara ọkàn wọn máa ń ranni bí wọ́n ti ń sọ nípa àwọn ìrírí tí wọ́n ń ní nínú pápá. Èyí ń sún àwọn ẹlòmíràn láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ohun àkọ́múṣe wọn àti ṣíṣeéṣe tí wọ́n ní fún nínípìn-ín tí ó pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, tí í ṣe iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ. Arábìnrin kan tí ó ṣe batisí ni ẹni 70 ọdún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́gán láìdáwọ́dúró. Nígbà tí a bi í léèrè ní àwọn ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà nípa ìdí tí ó fi ń tiraka tó bẹ́ẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ní ọjọ́ orí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣooṣù, ó sọ pé òun nímọ̀lára bí ẹni pé òun ti fi 70 ọdún àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé òun ṣòfò, òun kò sì fẹ́ fi èyíkéyìí nínú àwọn ọdún ìwàláàyè òun yòó kù ṣòfò mọ́!

10 Ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń kópa nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ń mú òye iṣẹ́ tí a mú sunwọ̀n sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ dàgbà. Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan wí pé: ‘Nígbà tí mo wà ní kékeré, mo máa ń bá àwọn òbí mi lọ sínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù wọn. Iṣẹ́ ìsìn pápá gbádùn mọ́ni gan-an. Ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń lọ, mo wá rí i pé mo yàtọ̀ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòó kù ní ilé ẹ̀kọ́. Ó wá ṣòro fún mi nígbà náà láti bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́. Nígbà tí mo bá ń wàásù láti ilé dé ilé, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù pípàdé ẹnì kan tí mo mọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́. Nínú ọ̀ràn tèmi, mo rò pé ìbẹ̀rù ènìyàn ni ìṣòro náà. [Òwe 29:25] Lẹ́yìn tí mo jáde ní ilé ẹ̀kọ́, mo pinnu láti gbìyànjú ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà fún ìgbà díẹ̀. Nítorí èyí, wíwàásù wá wù mí ju bí ó ti rí tẹ́lẹ̀ lọ. N kò tún wò ó gẹ́gẹ́ bí ìgbòkègbodò tí a fi ń dánú dùn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì wò ó gẹ́gẹ́ bí ẹrù ìnira. Bí mo ṣe ń rí i tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi ń tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́, mo gbádùn ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn jíjinlẹ̀ ti rírí ẹ̀rí náà pé Jèhófà Ọlọ́run ń ti ìsapá mi lẹ́yìn.’ Ọ̀dọ́ yìí tẹ̀ síwájú láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé.

11 Bí a bá wò ó láti ojú ìwòye gbígbéṣẹ́, nígbà tí ọ̀pọ̀ bá ṣiṣẹ́ sìn nínú ìjọ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, a máa ń kárí ìpínlẹ́ dáradára. Arákùnrin tí ń bójú tó yíyan àwọn ìpínlẹ̀ fúnni lè béèrè fún ìrànwọ́ àwọn olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà ní kíkárí àwọn apá ibi tí a kì í sábà ṣe. Gbígbé oúnjẹ dání àti lílo odindi ọjọ́ kan nínú iṣẹ́ ìsìn yóò mú kí ó ṣeé ṣe láti ṣe àwọn ibi tí ó jìnnà nínú ìpínlẹ̀ náà pàápàá.

12 Àwọn Alàgbà Ní Láti Ṣe Ìmúrasílẹ̀ Ṣáájú: Jálẹ̀ oṣù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ń bọ̀, a gbọ́dọ̀ ṣètò láti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ onírúurú ìgbòkègbodò ìjẹ́rìí ní àwọn àkókò tí ó yàtọ̀ nínú ọ̀sẹ̀, títí kan ọ̀sán àti ìrọ̀lẹ́, kí ọ̀pọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó lè kópa nínú rẹ̀. Ní àfikún sí ṣíṣe iṣẹ́ ilé dé ilé, fi àkókò fún ìjẹ́rìí òpópónà, ṣíṣe ìpínlẹ̀ okòwò, àti kíkàn sí àwọn tí kò sí nílé tẹ́lẹ̀ kún un. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ń ṣe aṣáájú ọ̀nà láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn pẹ̀lú ìjọ ní àkókò tí yóò gbéṣẹ́, tí yóò sì rọrùn jù lọ fún àwọn aṣáájú ọ̀nà. A gbọ́dọ̀ fi gbogbo ìṣètò fún iṣẹ́ ìsìn pápá tó ìjọ létí dáradára. A gbọ́dọ̀ ṣètò bíbójútó àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn dáradára. Ní àfikún sí i, a gbọ́dọ̀ mú kí ìpínlẹ́ tí ó tó wà, kí a sì béèrè fún ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn ní kánmọ́.

13 Wéwèé Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Iṣẹ́ Ìsìn Tìrẹ Fúnra Rẹ: Arákùnrin kan, tí ó kọ́kọ́ fòyà ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, wí pé: “Ní ti gidi, ó rọrùn gidigidi ju bí mo ṣe ronú pé yóò rí lọ. Ó wulẹ̀ ń fẹ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ dídára ni.” Ní ojú ewé ẹ̀yìn àkìbọnú yìí, ó ha rí àpẹẹrẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kan tí ó lè wúlò fún ọ bí? Wákàtí 15 lọ́sẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni gbogbo àkókò tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

14 Láti lè ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, àwọn ìyàwó ilé àti àwọn oníṣẹ́ ọ̀sán lọ́pọ̀ ìgbà lè ṣètò láti lo òwúrọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ àti àwọn oníṣẹ́ alẹ́ ní gbogbogbòò lè ya ọ̀sán sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn tí ń lo àkókò kíkún lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ti rí i pé ó ṣeé ṣe láti gbàyè ọjọ́ kan lọ́sẹ̀ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tàbí láti ya gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, ní àfikún sí ṣíṣe ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́. Ọ̀pọ̀ tí iṣẹ́ ìsìn pápá wọn kì í sábà kọjá ìgbòkègbodò òpin ọ̀sẹ̀ ń yan àwọn oṣù tí ó ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́. Ní ọdún yìí, ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ ní ti March, títí kan August àti November. Ní lílo ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó ní àlàfo tí a lè kọ nǹkan sí ní ojú ìwé 6, tí a pèsè gẹ́gẹ́ bí amọ̀nà, ronú jinlẹ̀ tàdúràtàdúrà nípa ohun tí yóò jẹ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ ìsìn tìrẹ tí yóò gbéṣẹ́ fún ipò tìrẹ.

15 Àǹfààní kan tí ìpèsè jíjẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní ni pé ó ṣeé tẹ̀ síhìn-ín tẹ̀ sọ́hùn-ún. O lè yan àwọn oṣù tí ìwọ yóò ṣe aṣáájú ọ̀nà, o sì lè ṣiṣẹ́ sìn léraléra bí o bá ṣe fẹ́. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láìdáwọ́dúró, ṣùgbọ́n tí o kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, o ha ti ronú nípa fíforúkọsílẹ̀ ní oṣù kẹ́ta-kẹ́ta síra jálẹ̀ ọdún bí? Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó ṣeé ṣe fún àwọn kan láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láìdáwọ́dúró fún àkókò gígùn.

16 Gbígbáradì fún Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà Alákòókò Kíkún: Ọ̀pọ̀ tí ó ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà yóò fẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé, ṣùgbọ́n, wọ́n ń ṣiyè méjì bóyá àwọn ní àkókò, àyíká ipò, tàbí agbára fún un. Dájúdájú, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí ń ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé nísinsìnyí kọ́kọ́ lo iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láti gbára dì fún iṣẹ́ alákòókò kíkún. Nípa mímú ìṣètò aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ẹni pọ̀ sí i fún kìkì wákàtí kan lóòjọ́, tàbí fún odindi ọjọ́ kan lọ́sẹ̀, ó ṣeé ṣe láti kúnjú ìṣètò aṣáájú ọ̀nà déédéé. Láti mọ̀ bí ìyẹn yóò bá ṣeé ṣe fún ọ, èé ṣe tí o kò fi gbìyànjú láti ya 90 wákàtí sọ́tọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tí ó bá ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Ní ìgbà kan náà, ìwọ yóò máa ní ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ sí i, tí yóò mú kí o gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí ó gún régé.

17 Arábìnrin kan gbádùn ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ọdún mẹ́fà láìdáwọ́dúró. Ní gbogbo àkókò yẹn, góńgó rẹ̀ ni láti wọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Láti lè ṣe ìyẹn, ó dán iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò pẹ̀lú ìrètí pípèsè ipò kan tí yóò jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ 90 wákàtí tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Lóṣooṣù, ó ń ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tàbí méjì láti lè pinnu bóyá ó lè ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣàyẹ̀wò wọn, ó rò pé ọwọ́ òun kò lè tó iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Síbẹ̀, ó ń bá a nìṣó láti máa béèrè lọ́wọ́ Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó ń múra fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, ó ka àpilẹ̀kọ kan nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1991 tí ó wí pé: “Dipo gbígbé itẹnumọ tí kò yẹ kari wakati ti a beere fun, eeṣe ti o ko fi pa afiyesi pọ̀ sórí anfaani ti a mu pọ sii lati ṣajọpin ninu iṣẹ ikojọpọ naa? (Johanu 4:35, 36)” Ó wí pé: “Mo tún gbólóhùn yí kà fún ìgbà márùn-ún tàbí ìgbà mẹ́fà, mo sì ní ìdánilójú pé èyí jẹ́ ìdáhùn Jèhófà. Ní àkókò yẹn, mo pinnu láti wọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ aláàbọ̀ àkókò kò dára tó, ó fi ìwé ìwọṣẹ́ rẹ̀ lélẹ̀ fún dídi aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, a yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ pa dà, a sì fún un ní àwọn wákàtí ìṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí ó bọ́ sí i gẹ́ẹ́ fún un. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Ọwọ́ Jèhófà rè é, àbí òun kọ́?,” ó sì fi kún un pé: “Nígbà tí o bá béèrè fún ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ Jèhófà, tí o sì rí i gbà, má ṣe kọ̀ ọ́—tẹ́wọ́ gbà á.” Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ gidigidi láti ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé, bóyá ní òpin oṣù mẹ́ta ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní March, April, àti May yí, ìwọ yóò ní ìdánilójú pé ìwọ pẹ̀lú lè kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

18 A ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò bù kún ìtara àwọn ènìyàn rẹ̀, yóò sì ti ìsapá wọn lẹ́yìn bí wọ́n ti ń kéde ìhìn rere ìgbàlà nígbà àkànṣe àkókò ìgbòkègbodò yí. (Aísá. 52:7; Róòm. 10:15) Ìwọ yóò ha dáhùn sí ìpè fún 30,000 aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nípa kíkópa ní March? April? May bí?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

Bí A Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Gẹ́gẹ́ Bí Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́

■ Ní ìgbọ́kànlé nínú àṣeyọrí ìfojúsọ́nà rẹ

■ Gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó bù kún ìsapá rẹ

■ Ké sí akéde mìíràn láti ṣe aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú rẹ

■ Wéwèé ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ ìsìn tí ó gbéṣẹ́

■ Béèrè fún ìwé ìròyìn púpọ̀

■ Ṣètìlẹ́yìn fún ìṣètò ìjọ fún iṣẹ́ ìsìn

■ Wá àǹfààní láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́