ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/03 ojú ìwé 3-4
  • Wàásù Kí O sì Tún Jẹ́rìí Kúnnákúnná

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wàásù Kí O sì Tún Jẹ́rìí Kúnnákúnná
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ń Fẹ́—30,000 Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ṣé A Óò Ṣe É Lẹ́ẹ̀kan Sí I?—Ìpè Mìíràn fún Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ẹ Polongo Àwọn Ìtayọlọ́lá Jèhófà Kárí Ayé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ohun Pàtàkì Tó Yẹ Ká Fojú Sùn Lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀ Yìí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 2/03 ojú ìwé 3-4

Wàásù Kí O sì Tún Jẹ́rìí Kúnnákúnná

1 Gẹ́gẹ́ bí “aṣáájú àti aláṣẹ,” Jésù dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nítorí iṣẹ́ ìwàásù kíkàmàmà tó wà níwájú wọn. (Áísá. 55:4; Lúùkù 10:1-12; Ìṣe 1:8) Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ nínú ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Ó pa àṣẹ ìtọ́ni fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná pé Ẹni tí Ọlọ́run ti fàṣẹ gbé kalẹ̀ nìyí pé kí ó jẹ́ onídàájọ́ alààyè àti òkú.” (Ìṣe 10:42) Báwo la ṣe lè jẹ́rìí kúnnákúnná?

2 Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí kọ́ nípa gbígbé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Nígbà tó ń pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin láti ìjọ Éfésù, ó rán wọn létí pé: “Èmi kò . . . fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tí ó lérè nínú fún yín tàbí kúrò nínú kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé. Ṣùgbọ́n mo jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì nípa ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ní àwọn àdánwò tó ń fara dà, ó ṣiṣẹ́ kára láti rí i pé òun sọ ìhìn rere náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Kò wò ó pé bí òun bá sáà ti sọ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì fún àwọn olùgbọ́ òun, ìyẹn náà ti tó, àmọ́ ó gbìyànjú láti jẹ́ kí wọ́n mọ “gbogbo ìpinnu Ọlọ́run.” Kó lè ṣàṣeparí èyí, ó múra tán láti ṣe àfikún ìsapá àti láti fi àwọn nǹkan kan du ara rẹ̀. Ó sọ síwájú sí i pé: “Èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan kan tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, bí mo bá sáà ti lè parí ipa ọ̀nà mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”—Ìṣe 20:20, 21, 24, 27.

3 Ọ̀nà wo la lè gbà fara wé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lónìí? (1 Kọ́r. 11:1) Ó jẹ́ nípa wíwá àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àtàwọn ìdílé lódindi tí wọ́n jẹ́ ẹni yíyẹ rí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa fúnra wa ní àwọn ìṣòro tiwa tó ń bá wa fínra. Ó tún jẹ́ nípa sísapá láti wàásù ìhìn rere náà fún gbogbo ẹ̀yà àti èdè, àti nípa ṣíṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti ran àwọn tó bá fìfẹ́ hàn lọ́wọ́. (Mát. 10:12, 13) Èyí ń béèrè àkókò, ìsapá, àti ìfẹ́ fún àwọn èèyàn.

4 Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́? Oṣù March àti April lè jẹ́ àkókò tó dára gan-an fún ọ láti jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn èèyàn nípa ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé ohun ìwúrí gbáà ló jẹ́ láti rí i tí ọ̀pọ̀ àwọn akéde sapá gidigidi láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún tó kọjá!

5 Àwọn ìṣírí tí ètò àjọ Jèhófà ń pèsè ru arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin ọdún sókè, ẹni tí àwọn àìsàn kan tún ń ṣe. Ó kọ̀wé pé: “Ìṣírí náà tanná ran ìfẹ́ tó ti wà lọ́kàn mi látọjọ́ pípẹ́, ó sì jẹ́ kí n pinnu pé màá rí i pé mo ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ bí kò tiẹ̀ ju lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo sí i lọ.” Ó pinnu láti ṣe é ní oṣù March. Ó sọ pé: “Mo kọ́kọ́ jókòó, mo sì ṣírò ohun tó máa ná mi. Mo bá ọmọbìnrin mi jíròrò ohun tí mò ń wéwèé láti ṣe nítorí màá nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́ ó ṣe ohun tó jọ mí lójú nítorí pé, ńṣe lòun náà lọ gbàwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.” Láàárín oṣù náà, arábìnrin àgbàlagbà náà lo wákàtí méjìléláàádọ́ta nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó sọ pé: “Àìmọye ìgbà ni mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi lágbára nígbà tí mo bá rí i pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ lókun nínú mọ́. Nígbà tí oṣù yẹn parí, inú mi dùn lọ́pọ̀lọpọ̀, àìmọye ìgbà ni mo sì ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe ràn mí lọ́wọ́. Màá fẹ́ láti gbìyànjú rẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan sí i.” Ìrírí tó fún arábìnrin wa láyọ̀ yìí lè jẹ́ ìṣírí fún àwọn mìíràn tó ń wù lójú méjèèjì láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láìka àwọn àìsàn líle koko tí wọ́n lè ní sí.

6 Arákùnrin kan tí wọ́n dá dúró lẹ́nu iṣẹ́ láìròtẹ́lẹ̀ lo àǹfààní náà láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bó ti ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ nínú oṣù náà, ó rí i pé ìtara òun fún iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ sí i, nígbà tó sì máa fi di òpin oṣù náà, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun kan. Nígbà tó ń ronú lórí ìrírí rẹ̀, ó sọ pé: “Oṣù oníbùkún gbáà ló jẹ́!” Ó láyọ̀ gan-an fún bí Jèhófà ṣe tọ́ ọ sọ́nà tó sì ràn án lọ́wọ́! Dájúdájú, Jèhófà tú ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún rẹ̀ sórí arákùnrin náà fún àfikún ìsapá tó ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, yóò sì bù kún ìwọ náà pẹ̀lú.—Mál. 3:10.

7 Ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ akéde. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin láti ṣiṣẹ́ náà láìka ẹrù iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ti ìdílé sí, títí kan àwọn ìṣòro ara ẹni. Ṣíṣe ìjẹ́rìí kúnnákúnná sábà máa ń béèrè pé ká fi àkókò wa tó ṣeyebíye àti okun wa rúbọ, àmọ́ àwọn ìbùkún jìngbìnnì tá a máa rí gbà kò láfiwé.—Òwe 10:22.

8 Oṣù March àti April jẹ́ àkókò tó dára gan-an láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún ló wà nínú oṣù March. Wíwàásù láwọn òpin ọ̀sẹ̀ wọ̀nyí àti láwọn ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn tó máa ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ di ìrọ̀lẹ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Láfikún sí i, o tún lè wàásù láwọn ọjọ́ họlidé nínú oṣù April. Àwọn kan lè ní àkókò ìsinmi níléèwé tàbí lẹ́nu iṣẹ́, èyí tí wọ́n lè lò láti dójú ìlà àádọ́ta wákàtí tí à ń béèrè. Láti lè rí àádọ́ta wákàtí yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú oṣù March tàbí April, ǹjẹ́ o lè lo ọ̀kan lára àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tá a dámọ̀ràn fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí? Jíròrò ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn; ó dájú pé ìyẹn yóò fún àwọn kan níṣìírí láti dára pọ̀ mọ́ ọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bí o kò bá ní lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, gbé góńgó kan pàtó kalẹ̀ fún àwọn oṣù wọ̀nyí, kó o sì máa bá àwọn tó bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà ṣiṣẹ́. Wéwèé nísinsìnyí kó o bàa lè túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ní oṣù March àti April.

9 Fi Ìmọrírì Hàn fún Ìṣe Ìrántí: Lọ́dọọdún, ní sáà Ìṣe Ìrántí, ìmọrírì fún ẹbọ ìràpadà Jésù máa ń sún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ‘ra àkókò padà’ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. (Éfé. 5:15, 16) Lọ́dún tó kọjá, ní Nàìjíríà, àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún ó lé mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún [16,101] ló ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà ní oṣù March nígbà tí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá ó lé irínwó àti mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [13,487] ṣe é ní oṣù April. Èyí túmọ̀ sí pé, ní ìpíndọ́gba, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá àti ẹgbẹ̀rin dín mẹ́fà [14,794] ló ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn oṣù yìí. Iye yẹn ju ìpíndọ́gba àwọn akéde tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́tàdínlógójì [4,837], tí wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nínú oṣù kọ̀ọ̀kan tó ṣáájú nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn yẹn. Sáà Ìṣe Ìrántí yìí tún fún wa ní àǹfààní láti fi ìmọrírì àtọkànwá wa hàn fún ẹbọ ìràpadà Kristi nípa títúbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.

10 Bí April 16 ti ń sún mọ́lé, máa ronú lórí ohun tí Ìṣe Ìrántí túmọ̀ sí fún ọ. Ronú lórí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ikú Kristi, tó sì wá yọrí sí ikú rẹ̀ àtàwọn ohun tó kó àníyàn bá a gidigidi. Tún ṣàṣàrò lórí ayọ̀ tá a gbé ka iwájú Jésù àti bí èyí ṣe ràn án lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́. Tún ronú lórí ipò tó wà báyìí gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ, tó ń bójú tó iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (1 Kọ́r. 11:3; Héb. 12:2; Ìṣí. 14:14-16) Lẹ́yìn náà, wá fi ìmọrírì rẹ hàn fún gbogbo ohun tí Kristi ti ṣe nípa kíkópa ní kíkún dé àyè tí ipò rẹ bá yọ̀ọ̀da fún ọ.

11 Fún Àwọn Ẹlòmíràn Níṣìírí Láti Jẹ́rìí Kúnnákúnná: Bí àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá kópa nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, wọ́n á lè fún àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ níṣìírí. Nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn akéde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá àti nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, wọn yóò láǹfààní láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kópa nínú àkànṣe ìgbòkègbodò yìí. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa fi ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nínú oṣù March àti April ṣe ọ̀rọ̀ àdúrà, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìsapá gbogbo wa lápapọ̀ láti jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn èèyàn yọrí sí rere.

12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yóò fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣètò ìjọ fún ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i lóṣù March àti April, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ní pàtàkì gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣe àwọn ètò yíyẹ fún iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà. Kí ó ṣètò àwọn ibi tí a óò ti ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ọjọ́, àti àkókò tí yóò rọrùn fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn akéde, kí ó sì rí i pé à ń ṣèfilọ̀ èyí déédéé. Ó lè ṣètò fún pípàdé láwọn ìgbà bíi mélòó kan lóòjọ́, kí gbogbo àwọn ará nínú ìjọ lè tipa bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti kópa nínú onírúurú ọ̀nà ìjẹ́rìí. Èyí lè jẹ́ ṣíṣe àwọn ìpínlẹ̀ tó jẹ́ ibi ìtajà, ìjẹ́rìí òpópó ọ̀nà, lílọ láti ilé dé ilé, ṣíṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò, tàbí jíjẹ́rìí nípasẹ̀ tẹlifóònù. Láfikún sí i, kó tún ṣètò kí ìjọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn ìwé ìròyìn lọ́wọ́, kí àwọn ìpínlẹ̀ sì wà láti ṣe láàárín àwọn oṣù náà.

13 Ìwé Ìmọ̀ la óò fi lọni ní oṣù March, kí a sì ní i lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó dára tí a lè lò láti fi ìwé Ìmọ̀ lọni wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002. Ìwé tí a óò fi lọni ní oṣù April yóò jẹ́ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Gbìyànjú láti máa lo àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dámọ̀ràn, tó ń fara hàn nínú apá tí a pè ní “Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn.” Kí gbogbo wa múra sílẹ̀ dáadáa ká bàa lè jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn èèyàn.

14 Ẹ wo bí a ti jẹ́ aláyọ̀ tó láti máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Kristi Jésù, tí í ṣe Orí ìjọ, àti fún àǹfààní tá a ní láti máa wàásù ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn! Bí oṣù March àti April ti ń wọlé bọ̀, ẹ jẹ́ ká tún sapá lẹ́ẹ̀kan sí i láti mú kí àwọn oṣù yìí jẹ́ oṣù tí a tíì ṣe dáadáa jù lọ, bá a ti ń ṣègbọràn sí àṣẹ Kristi pé ká wàásù ká sì jẹ́rìí kúnnákúnná.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

Oríṣiríṣi Ọ̀nà Tá A Lè Fi Ṣe Iṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ ní Oṣù March àti April 2003

Ọjọ́ Wákàtí

Monday 1 2 — — 2 —

Tuesday 1 — 3 — — —

Wednesday 1 2 — 5 — —

Thursday 1 — 3 — — —

Friday 1 2 — — — —

Saturday 5 4 3 5 6 7

Sunday 2 2 3 2 2 3

March 56 56 54 55 50 50

April 50 50 51 53 — —

Ǹjẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọ̀nyí lè ṣiṣẹ́ fún ọ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́