Ohun Pàtàkì Tó Yẹ Ká Fojú Sùn Lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀ Yìí
1. Kí ló yẹ ká fojú sùn lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀ lọ́nà yìí?
1 Bá a bá fẹ́ tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run, dandan ni ká ní ohun tá a ó máa fojú sùn. Àwọn nǹkan wo lo ní lọ́kàn láti fojú sùn lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀ yìí? Ọ̀kan lára ohun tó dáa jù téèyàn lè fojú sùn ni ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àkókò yìí gan-an ló yẹ láti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ níwọ̀n bí ìgbòkègbodò aláyọ̀ yìí ti gba pé kéèyàn múra sílẹ̀ dáadáa. Kí nìdí tó fi yẹ kó o fojú sun iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
2. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ronú nípa fífi ojú sun iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
2 Ìdí Tó Fi Yẹ Kéèyàn Ṣiṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́: Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ máa ń jẹ́ ká lè sin Baba wa ọ̀run “lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́” nípa fífi kún àkókò tá a fi ń wàásù. (1 Tẹs. 4:1) Bá a bá ń ronú nípa ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, á wù wá láti máa sọ fáwọn ẹlòmíì nípa rẹ̀. (Sm. 34:1, 2) Jèhófà mọ ohun tí kálukú wa ń yááfì lámọ̀dunjú, ó sì mọrírì bá a ṣe ń sapá ká lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Héb. 6:10) Inú wa máa ń dùn gan-an torí a mọ̀ pé bá a ṣe ń sapá takuntakun ń tẹ́ Jèhófà lọ́rùn.—1 Kíró. 29:9.
3, 4. Ọ̀nà wo ni iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lè gbà ṣe wá láǹfààní?
3 Bó bá ṣe pẹ́ tó téèyàn ti ń ṣe nǹkan, ni nǹkan ọ̀hún á máa rọrùn sí i táá sì máa dùn mọ́ onítọ̀hún sí i. Bí àkókò tó ò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bá ṣe ń pọ̀ sí i tó ni wàá túbọ̀ máa mọwọ́ rẹ̀ tó. Wàá túbọ̀ mọ béèyàn ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, wàá sì lè lo Bíbélì dáadáa. Bó o bá ṣe ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn tó, ni ìgbàgbọ́ ọ̀hún á ṣe máa jinlẹ̀ sí i tó. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n ti ní in láàárín àkókò tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
4 Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tún lè mú kẹ́ni tó ti ń rẹ̀wẹ̀sì pa kítí mọ́ra. Ẹnì kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé rí i pé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ti ń gba òun lọ́kàn jù, ó sì pinnu láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan. Ó ní: “Ó jọ èmi alára lójú pé ìgbàgbọ́ mi tún lè lágbára tó bẹ́ẹ̀ láàárín oṣù kan ṣoṣo! Ni mo bá kúkú ní kí n máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nìṣó, èyí ló sì mú kí n tún padà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé.”
5. Bó bá ń ṣe wá bíi pé a ò kúnjú òṣùwọ̀n, kí la lè ṣe?
5 Bá A Ṣe Lè Borí Ohun Tó Lè Dí Wa Lọ́wọ́: Kì í yá àwọn kan lára láti gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ torí wọ́n rò pé àwọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọwọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Bó bá jẹ́ ohun tó ń fa ìwọ náà sẹ́yìn nìyẹn, rántí pé Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó ṣe ran Jeremáyà náà lọ́wọ́. (Jer. 1:6-10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘ẹnu Mósè wúwo, ahọ́n rẹ̀ sì wúwo,’ síbẹ̀ Jèhófà lò ó láti mú ìfẹ́ Rẹ̀ ṣẹ. (Ẹ́kís. 4:10-12) Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà, bó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò tóótun.
6. Béèyàn bá ní ìṣòro àìlera tàbí tí ọwọ́ rẹ̀ bá sábà máa ń dí, ọgbọ́n wo ló lè dá sí i kó bàa lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
6 Ṣé kì í ṣe àìlera tàbí ọwọ́ ẹ tó sábà máa ń dí jù lo ṣe ń lọ́ra láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Bí ara ẹ ò bá le, ṣíṣe é wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ bí agbára ẹ bá ṣe mọ á mú kó túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bí ọwọ́ ẹ bá sábà máa ń dí, bóyá á ṣeé ṣe fún ẹ láti sún àwọn ìgbòkègbodò tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan sí oṣù míì. Àwọn kan tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ tó ń gbà wọ́n lákòókò ti ra ìgbà padà láti fi ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nípa gbígba àyè ìsinmi ọjọ́ kan tàbí méjì.—Kól. 4:5.
7. Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn gbàdúrà kó bàa lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
7 Bó O Ṣe Lè Ṣe É: Sọ fún Jèhófà nínú àdúrà pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ń wù ẹ́. Ní kí Jèhófà tì ẹ́ lẹ́yìn bó o ṣe ń sapá láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. (Róòmù 12:11, 12) Ó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání nípa bó o ṣe lè tún ìgbòkègbodò rẹ tò. (Ják. 1:5) Bí iṣẹ́ ọ̀hún ò bá wù ẹ́ látọkàn wá, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù máa dá ẹ lọ́rùn.—Lúùkù 10:1, 17.
8. Báwo ni títẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 15:22 ṣe lè mú kó ṣeé ṣe fún ẹ láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
8 Gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ẹ lè jíròrò bẹ́ ẹ ṣe lè fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣe àfojúsùn. (Òwe 15:22) Ó lè ṣeé ṣe kí ẹnì kan nínú ìdílé yín ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, kẹ́yin tó kù sì máa kọ́wọ́ tì í. Ó dáa téèyàn bá lè jíròrò bó ṣe ń wù ú láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn míì nínú ìjọ, pàápàá, àwọn tí ọ̀ràn wọn jọ tẹni. Èyí lè fi kún ìtara àwọn ará láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
9. Àwọn oṣù wo lo lè yàn láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
9 Ó máa dáa kó o wo bí ìgbòkègbodò rẹ ṣe máa rí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀ yìí, kó o sì pinnu ìgbà tó o rò pé wàá lè ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bó bá jẹ́ pé àkókò tó pọ̀ lo fi ń ṣiṣẹ́ tàbí pé o ṣì ń lọ sílé ẹ̀kọ́, o lè múra sílẹ̀ de oṣù tí ọlidé máa bọ́ sí tàbí àwọn oṣù tó ní Sátidé tàbí Sunday márùn-ún. Bí àpẹẹrẹ, Sátidé àti Sunday márùn-ún ló wà nínú oṣù September, December, March àti August. Sátidé márùn-ún ló wà nínú oṣù May, Sunday márùn-ún ló sì wà nínú oṣù June. Bí ara rẹ ò bá le, o lè fẹ́ yan àwọn oṣù tí ojú ọjọ́ ti sábà máa ń dáa. Ó sì lè jẹ́ pé oṣù tí alábòójútó àyíká bá bẹ ìjọ yín wò lo máa fẹ́ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, wàá láǹfààní láti wà ní apá àkọ́kọ́ ìpàdé tó máa bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ṣe. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé March 22 ni Ìrántí Ikú Kristi tọdún 2008 máa wáyé, ó máa dáa láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March, April àti May. Gbàrà tó o bá ti yan oṣù tó o fẹ́ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ohun tó kàn ni pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò tó máa mú kó o lè máa bá wákàtí rẹ.
10. Kí lo lè ṣe bó ò bá lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
10 Ká wá sọ pé o ṣì rí i pé o ò ní lè ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀ yìí, o ṣì lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ náà. Má ṣe dẹwọ́ ṣíṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù, kó o sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé inú Jèhófà dùn sí gbogbo ohun tó o bá lè ṣe. (Gál. 6:4) Ní báyìí, o ṣì lè máa ti àwọn tó ń gbádùn àǹfààní yìí lẹ́yìn kó o sì máa fún wọn níṣìírí. Kódà o lè ṣètò ìgbòkègbodò rẹ débi tí wàá fi lè máa bá wọn jáde láwọn ọjọ́ míì láàárín ọ̀sẹ̀.
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ̀ pé àkókò kánjúkánjú la wà yìí?
11 Àwa èèyàn Jèhófà mọ̀ pé àkókò kánjúkánjú la wà yìí. Iṣẹ́ kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe, wíwàásù ìhìn rere sì niṣẹ́ ọ̀hún. Iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà ni, àkókò tó kù sì kéré. (1 Kọ́r. 7:29-31) Ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àti sáwọn aládùúgbò wa máa sún wa láti ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀ yìí, bó o bá sapá tó o sì múra sílẹ̀ dáadáa, wàá lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, iṣẹ́ pàtàkì tó yẹ ká fojú sùn!