Ìṣe Ìrántí—Ìṣẹ̀lẹ̀ Kan Tí Ó Ní Ìjẹ́pàtàkì Gíga Lọ́lá!
1 Ní ọjọ́ Sunday, March 23, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, a óò ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. (Lúùk. 22:19) Èyí ní tòótọ́ jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ní ìjẹ́pàtàkì gíga lọ́lá! Nípa pípa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́ títí dé ikú, Jésù fẹ̀rí hàn pé ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn láti pa ìfọkànsìn Oníwà-bí-Ọlọ́run tí ó pé pérépéré mọ́ kódà lábẹ́ másùnmáwo lílekoko, ní títipa báyìí gbé ẹ̀tọ́ ipò ọba aláṣẹ Jèhófà lárugẹ. (Héb. 5:8) Ní àfikún sí i, ikú Kristi pèsè ìrúbọ ẹ̀dá ènìyàn pípé tí a nílò láti ra aráyé pa dà, ní mímú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ láti wà láàyè láìnípẹ̀kun. (Jòh. 3:16) Nípa wíwà níbi Ìṣe Ìrántí náà, a lè fi ìmọrírì àtọkànwá wa hàn fún ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa àti fún ìrúbọ tí Jésù ṣe fún wa.
2 A fún gbogbo ènìyàn níṣìírí láti tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tí a ṣètò fún March 18 sí 23, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn lórí 1997 Calendar of Jehovah’s Witnesses. Pẹ̀lúpẹ̀lù, jíjíròrò tí ìdílé bá jíròrò orí 112 sí 116 ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí yóò ṣèrànwọ́ láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí ọ̀sẹ̀ náà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn.
3 Ìwọ ha lè mú kí àkókò tí o ń lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá pọ̀ sí i ní àkókò Ìṣe Ìrántí bí? Ọ̀pọ̀ akéde yóò lo àǹfààní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún tí ń bẹ nínú oṣù March ní kíkún láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Èé ṣe tí o kò fi jẹ́ ọ̀kan lára wọn? Gbogbo wa lè nípìn-ín ní kíkún ní títẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwá síbi Ìṣe Ìrántí náà. Níwọ̀n bí ó ti bọ́ sí ọjọ́ Sunday, yóò rọrùn fún ọ̀pọ̀ láti wá. Rí i dájú pé o ké sí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn olùfìfẹ́hàn míràn láti dara pọ̀ mọ́ wa. Ṣàjọpín ohun tí ó wà ní ojú ìwé 127, ìpínrọ̀ 18, nínú ìwé Ìmọ̀ pẹ̀lú wọn, nípa ọjọ́ kan nínú ọdún tí a ní láti pa mọ́ lákànṣe.
4 Fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún gbogbo ohun tí ikú Jésù túmọ̀ sí fún wa gbégbèésẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ gíga lọ́lá jù lọ ti 1997 yí. Wà níbẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ March 23, nígbà tí àwọn Kristẹni tòótọ́ níbi gbogbo yóò fi ìṣòtítọ́ pa Ìṣe Ìrántí náà mọ́.