Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún February
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 3
Orin 27
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ṣàyẹ̀wò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ọjọ́ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun.”
15 min: “Nípìn-ín Nínú Iṣẹ́ Tí A Kì Yóò Tún Ṣe Mọ́ Láé.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Bí àkókò bá ti wà tó, fi àwọn kókó kún un láti inú “Keeping on the Watch—How?” (Bíbá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà—Báwo?), ní ojú ewé 714 àti 715 ìwé Proclaimers.
20 min: “Fífi Ìjẹ́kánjúkánjú Sọ ìhìn Rere Náà.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 5) Lẹ́yìn sísọ̀rọ̀ ṣókí lórí ìpínrọ̀ 1, alága jíròrò ìpínrọ̀ 2 sí 5 pẹ̀lú akéde méjì tàbí mẹ́ta. Wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dámọ̀ràn, wọ́n sì sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí ìwọ̀nyí tàbí àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ jíjọra fi lè gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ àdúgbò. Àwọn akéde, ní pípààrọ̀ ara wọn, ṣe ìfidánrawò ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan. Alága gbóríyìn fún wọn, ó sì dámọ̀ràn àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà mú kí àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ náà gbéṣẹ́ sí i. Lẹ́yìn náà, ó béèrè àwọn ọ̀nà tí ọwọ́ fi lè tẹ góńgó bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ àwùjọ. Ó fúnni ni èrò pàtó nípa bí a óò ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Orin 34 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 10
Orin 29
7 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Mẹ́nu kan àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ tí ń bẹ nínú àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tí a lè lò nínú iṣẹ́ ìsìn ní ọ̀sẹ̀ yí. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run.
10 min: “Fífi Ìjẹ́kánjúkánjú Sọ Ìhìn Rere Náà.” (Ìpínrọ̀ 6 sí 8) Ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ìpínrọ̀ 6 àti 7. Tẹnu mọ́ àìní náà láti ṣe ìpadàbẹ̀wò níbi tí a bá ti fi ọkàn ìfẹ́ hàn.
28 min: “A Ń Fẹ́—30,000 Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. Fa àwọn kókó tí ó wà nínú àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 3 yọ. Ṣàyẹ̀wò ìṣètò tí a fi ṣàpẹẹrẹ, tí ó wà ní ojú ìwé 6. Akéde kọ̀ọ̀kan tí ó ti ṣe ìrìbọmi yẹ kí ó ronú fúnra rẹ̀ tàdúràtàdúrà bóyá òun lè forúkọ sílẹ̀ fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn akéde tí kò tí ì ṣe batisí lè mú ìpín wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbòòrò sí i nípa gbígbé góńgó wákàtí tiwọn lóṣooṣù kalẹ̀.
Orin 43 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 17
Orin 30
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
13 min: “Ìṣe Ìrántí—Ìṣẹ̀lẹ̀ Kan Tí Ó Ní Ìjẹ́pàtàkì Gíga Lọ́lá!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fúnni níṣìírí láti mú kí oṣù March lódindi jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nípa ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Tẹnu mọ́ lílo ìwé ìkésíni sí Ìṣe Ìrántí.
22 min: Bíbẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Inú Ilé. Ní àwọn oṣù àìpẹ́ yìí, a ti fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìwé ẹlẹ́yìn líle síta. Èyí pèsè ìpìlẹ̀ fún bíbẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé sí i. Ṣàyẹ̀wò ohun tí a ṣàṣeparí rẹ̀ ládùúgbò ní fífi àwọn ìwé àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn sóde. Fún àwọn akéde níṣìírí láti pa dà ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ọkàn ìfẹ́ tí a fi hàn. Jẹ́ kí àwọn akéde díẹ̀ ṣàlàyé ní pàtó, ìsapá tí wọ́n ṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun nínú ilé. Tẹnu mọ́ ọn pé apá kan iṣẹ́ àṣẹ wa ni láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) A lè ṣe èyí lọ́nà gbígbéṣẹ́ bí a bá sakun láti fi àwọn ìmọ̀ràn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996 sílò.
Orin 47 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 24
Orin 32
18 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Kéde orúkọ gbogbo àwọn tí yóò ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní March. Ṣàlàyé pé kò tí ì pẹ́ jù láti fi ìwé ìwọṣẹ́ sílẹ̀. Fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ní Saturday, March 1. Sọ àwọn àfikún ètò tí ìjọ tí ṣe fún àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn nínú oṣù náà. Fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Àpótí Ìbéèrè.
12 min: “Àwọn Ìbátan Rẹ Ńkọ́?” Kí ọkọ àti aya jíròrò àpilẹ̀kọ náà pa pọ̀, kí wọ́n sì pinnu bí wọn yóò ṣe sọ ìhìn rere náà fún àwọn ìbátan tí kò gbà gbọ́.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, February 15, 1990, ojú ìwé 25 sí 27.
15 min: Ṣàyẹ̀wò Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Àfilọni fún March—Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Jíròrò àwọn ìdí tí ìdílé fi ń fọ́ sí wẹ́wẹ́ nínú àwùjọ òde òní ní ṣókí. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, October 15, 1992, ojú ìwé 4 sí 7.) Ṣàyẹ̀wò kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé náà, ní ojú ìwé 3. Ké sí àwùjọ láti tọ́ka sí àwọn orí tí ó lè pèsè ìpìlẹ̀ fún ìfilọni. Tọ́ka sí àpótí ẹ̀kọ́ tí ń ranni lọ́wọ́ ní òpin orí kọ̀ọ̀kan. Jẹ́ kí akéde kan tí ó dáńgájíá ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi ìwé náà lọni. Rán àwùjọ létí láti gba àwọn ẹ̀dà fún lílò ní òpin ọ̀sẹ̀.
Orin 48 àti àdúrà ìparí.