Àwọn Ìbátan Rẹ Ńkọ́?
1 Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa ní àwọn ìbátan mélòó kan tí kò sí nínú òtítọ́. Ẹ wo bí a ti yán hànhàn tó pé kí irú àwọn tí a nífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ dara pọ̀ mọ́ wa ní ojú ọ̀nà sí ìyè! Àníyàn wa fún ọjọ́ ọ̀la àìnípẹ̀kun wọn lè ga sí i nígbà tí wọ́n bá jẹ́ mẹ́ńbà agbo ilé tiwa gan-an. Bí a bá tilẹ̀ ti gbìyànjú fún ọ̀pọ̀ ọdún láti mú kí wọ́n ní ọkàn ìfẹ́ nínú òtítọ́, a kò gbọ́dọ̀ parí èrò sí pé kò sí ìrètí fún ipò wọn.
2 Nígbà tí Jésù ń wàásù, “ní ti tòótọ́, àwọn arákùnrin rẹ̀ kì í lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (Jòh. 7:5) Ní àkókò kan, àwọn ìbátan rẹ̀ rò pé orí rẹ̀ ti yí. (Máàk. 3:21) Síbẹ̀, Jésù kò juwọ́ sílẹ̀ nítorí wọn. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn arákùnrin rẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́. (Ìṣe 1:14) Iyèkan rẹ̀, Jákọ́bù, di ọwọ̀n kan nínú ìjọ Kristẹni. (Gál. 1:18, 19; 2:9) Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti ní ìdùnnú rírí àwọn ìbátan rẹ tí wọ́n ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́, má ṣe dáwọ́ gbígbìyànjú láti mú ìhìn rere Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ wọn dúró.
3 Jẹ́ Atunilára, Kì Í Ṣe Arọniyó: Nígbà tí Jésù ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, ara tu àwọn tí ń tẹ́tí sí i, jìnnìjìnnì kò mú wọn. (Mát. 11:28, 29) Kò fi àwọn ẹ̀kọ́ tí wọn kò lè lóye rọ wọ́n yó. Láti fi omi òtítọ́ tu àwọn ìbátan rẹ lára, fún wọn mu díẹ̀díẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó pọ̀ jù! Alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ pé: “Àbájáde dídára jù lọ máa ń wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ń ru ẹ̀mí ìṣèwádìí sókè nínú àwọn ìbátan wọn nípa dídíwọ̀n ìjẹ́rìí tí wọ́n ń ṣe fún wọn.” Lọ́nà yí, àwọn alátakò pàápàá lè bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àwọn ìbéèrè, wọ́n sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í kóùngbẹ fún òtítọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.—1 Pét. 2:2; fi wé Kọ́ríńtì Kíní 3:1, 2.
4 Ọ̀pọ̀ Kristẹni tí wọ́n ti ṣègbéyàwó ti jẹ́rìí lọ́nà gbígbéṣẹ́ fún alábàáṣègbéyàwó wọn tí kò gbà gbọ́ nípa ṣíṣí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ sí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n lè ní ọkàn ìfẹ́ sí. Arábìnrin kan tí ó ṣe èyí tún bá àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ní etígbọ̀ọ́ ọkọ rẹ̀, ní ṣíṣe àlàyé tí yóò ṣe ọkùnrin náà láǹfààní. Nígbà míràn yóò bi í pé: “Mo kọ́ ohun báyìí báyìí nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ mi lónìí. Kí ni o rò nípa rẹ̀?” Ọkọ rẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
5 Jẹ́ Abọ̀wọ̀fúnni, Kì Í Ṣe Aláìnísùúrù: Akéde kan sọ pé “àwọn ìbátan pàápàá ní ẹ̀tọ́ sí ojú ìwòye àti èrò tiwọn fúnra wọn.” Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún wọn nígbà tí wọ́n bá sọ èrò wọn tàbí nígbà tí wọ́n bá sọ fún wa pàtó pé kí a má ṣe bá àwọn sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́. (Oníw. 3:7; 1 Pét. 3:15) Nípa jíjẹ́ onísùúrù àti onífẹ̀ẹ́, àti nípa jíjẹ́ olùfetísílẹ̀ rere, a lè wá àwọn àǹfààní yíyẹ wẹ́kú láti dọ́gbọ́n jẹ́rìí. Irú sùúrù bẹ́ẹ̀ lè mérè wá, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú ọ̀ràn Kristẹni kan tí ó jẹ́ ọkọ, tí ó fi sùúrù fara da bíbá tí aya rẹ̀ aláìgbàgbọ́ bá a lò lọ́nà tí kò tọ́ fún 20 ọdún. Gbàrà tí aya rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà, ọkùnrin náà wí pé: “Ẹ wo bí mo ti kún fún ọpẹ́ sí Jèhófà tó pé ó ràn mí lọ́wọ́ láti mú ìpamọ́ra dàgbà, nítorí pé mo lè rí ìyọrísí náà nísinsìnyí: Aya mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ní ipa ọ̀nà ìyè!”
6 Àwọn ìbátan rẹ ńkọ́? Ó lè jẹ́ pé nípa ìwà rere Kristẹni rẹ, àti nípa àdúrà tí o ń gbà nítorí wọn, “o lè jèrè wọn fún Jèhófà.”—1 Pét. 3:1, 2, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW.