ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 10/15 ojú ìwé 4-7
  • Idaamu Idile Àmì Awọn Akoko

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Idaamu Idile Àmì Awọn Akoko
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Owó ati Iṣẹ́
  • Ìdè Igbeyawo ti A Sọ Di Ahẹrẹpẹ
  • Awọn Ọ̀dọ́ Ń Fojúwiná Igbejako
  • Awọn Gbòǹgbò Idaamu Idile
  • Awọn Idile Tí Ń Gbèrú
  • Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Máa Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Wá Ọjọ́ Ọ̀la Wíwà Pẹ́ Títí fún Ìdílé Rẹ
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ṣètò Ìgbéyàwó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 10/15 ojú ìwé 4-7

Idaamu Idile Àmì Awọn Akoko

IDAAMU idile—ọpọ rí i gẹgẹ bi àmì pe awọn ilana atọwọdọwọ nipa igbeyawo ati itọju ọmọ kò bá ìgbà mu mọ́. Awọn miiran rí i gẹgẹ bii abajade iyipada oṣelu, ọrọ-aje, ati ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Sibẹ awọn miiran rí i gẹgẹ bii ibajẹ miiran kan tí ọgbọ́n-iṣẹ-ẹrọ ode-oni dá silẹ. Niti tootọ awọn iṣoro tí idile ń fàyàrán lonii tọka si ohun kan ti o ni ijẹpataki titobi lọpọlọpọ. Kiyesi awọn ọ̀rọ̀ Bibeli ni 2 Timoteu 3:1-4:

“Eyi ni ki o mọ̀, pe ni ikẹhin ọjọ ìgbà ewu yoo dé. Nitori awọn eniyan yoo jẹ́ olufẹ ti araawọn, olufẹ owó, afunnu, agberaga, asọrọbuburu, aṣaigbọran si obi, alailọpẹ, alaimọ, alainifẹẹ, alaile-darijini, abanijẹ, alaile-koraawọn-nijaanu, onroro, alainifẹẹ ohun rere, onikupani, alagidi, ọlọ́kàn giga, olufẹ faaji ju olufẹ Ọlọrun lọ.”

Awọn ọ̀rọ̀ wọnyi kò ha hú gbòǹgbò okunfa awọn iṣoro ode-oni gan-an jade bi? Idaamu idile ti ode-oni ni kedere jẹ́ iyọrisi taarata nipa awọn ipo ti a sọtẹlẹ pe yoo wáyé ni awọn ọjọ ikẹhin ayé yii. Ẹ̀rí ti ń yinileropada sì wà pe sáà akoko idaamu yii bẹrẹ ni ọdun 1914.a Lati ìgbà naa wá, ni agbara idari ẹ̀dá ẹmi ti ó ju eniyan lọ ti a ń pè ni Satani Eṣu ti jẹ́ aṣekupani ni pataki.—Matteu 4:8-10; 1 Johannu 5:19.

Bi a ti há a mọ́ sí sàkáání ayika ori ilẹ̀-ayé lati 1914, Satani ní “ibinu ńlá, nitori ó mọ̀ pe ìgbà kukuru ṣá ni oun ní.” (Ìfihàn 12:7-12) Niwọn bi Satani ti jẹ́ ọ̀tá paraku ti Ọlọrun “orukọ ẹni ti a fi ń pe gbogbo idile ti ń bẹ ni ọ̀run ati ni ayé,” ó ha yanilẹnu pe ilẹ̀-ayé ti di ibi eléwu fun awọn idile bi? (Efesu 3:15) Satani ti pinnu lati yí gbogbo araye kuro lọdọ Ọlọrun. Ni ọ̀nà didara ju wo ni oun lè gbà ṣaṣepari eyi ju nipa fífipá kọlu awọn idile pẹlu iṣoro lọ?

Yoo gbà ju ìgbọ́nféfé àbá-èrò-orí awọn ogbontarigi ti a tànmọ́-ọ̀n lọ lati daabobo awọn idile kuro lọwọ iru igbejakoni bẹẹ ti o ju agbara ẹda eniyan lọ. Bi o tilẹ ri bẹẹ, Bibeli sọ nipa Satani pe: “Awa kò ṣe aláìmọ arekereke rẹ̀.” (2 Korinti 2:11) Ìwọ̀n aabo wà ninu mímọ diẹ lara awọn ọ̀nà pàtó ti ó ń gbà ṣe ìfipákọluni rẹ̀.

Owó ati Iṣẹ́

Ikimọlẹ ìṣúnná-owó jẹ́ ọ̀kan lara ohun eelo ìjà ìfipákọluni Satani ti o lagbara julọ. Iwọnyi ni “ìgbà ewu,” tabi gẹgẹ bi Revised Standard Version ṣe tumọ 2 Timoteu 3:1, “akoko másùnmáwo.” Ni awọn ilẹ ti ó ṣẹṣẹ ń goke agba, awọn iṣoro bii àìgbanisíṣẹ́, owó-iṣẹ́ táṣẹ́rẹ́, ati aito awọn ohun koṣeemanii ń fa ọpọ inira wá fun awọn idile. Bi o ti wu ki o ri, àní ni ilu United States ti ó lọ́rọ̀ ni ifiwera paapaa, awọn ikimọlẹ ìṣúnná-owó kó ipa tiwọn. Iwadii U.S. kan fihàn pe owó jẹ́ ọ̀kan ninu okunfa pataki nipa iforigbari idile. Iwe naa Secrets of Strong Families ṣalaye pe “akoko, afiyesi, [ati] okun” ti a ń lò fun kikaju ohun ti iṣẹ́ ounjẹ-oojọ beere fun tún lè jẹ́ “ọ̀tá ti ó ṣoro lati dámọ̀” ti ń ba ẹ̀jẹ́-àdéhùn igbeyawo jẹ́ diẹdiẹ.

Ipo ayika ti fipá mú iye awọn obinrin pupọ sii ju ti igbakigba ri lọ wọnu wíwá iṣẹ ṣe. Onkọwe Vance Packard rohin pe: “Ní lọwọlọwọ, ó keretan ìdámẹ́rin awọn ọmọ-ọwọ́ ati awọn ọmọ ti wọn ṣẹṣẹ ń dásẹ̀ tẹlẹ ti ọjọ-ori wọn dín si ọdun mẹta ni America ní awọn ìyá ti wọn ń ṣiṣẹ lóde.” Bibojuto aini awọn ọmọ wẹẹrẹ ti o fẹrẹẹ má ṣeé tẹlọrun ati ti iṣẹ kan bakan naa lè jẹ́ isapa fífakasọ, tí ń tánnilókun—pẹlu awọn iyọrisi òdì lori awọn òbí ati awọn ọmọ. Packard fikun un pe nitori aisi awọn ipese itọju ọmọ titotẹrun ni United States, “ọpọ million diẹ awọn ọmọde lonii ni a ń fi ẹ̀tọ́ itọju didara dù ni awọn ọdun ijimiji wọn.”—Our Endangered Children.

Ibi-iṣẹ funraarẹ sábà maa ń jin agbara iṣọkan idile lẹ́sẹ̀. Ọpọ awọn oṣiṣẹ ni a ń fà wọnu awọn alamọri ti kò bofinmu pẹlu awọn oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ wọn. Sibẹ awọn miiran di ẹni ti ọ̀ràn wíwá aṣeyọri asán gbámú ti wọn sì fi igbesi-aye idile wọn rubọ fun ilọsiwaju iṣẹ igbesi-aye. (Fiwe Oniwasu 4:4.) Ọkunrin kan di ẹni ti iṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi aṣoju òǹtàjà mu lómi debi pe iyawo rẹ̀ ṣapejuwe araarẹ gẹgẹ bi “òbí anìkàntọ́mọ ti ó ni baba.”

Ìdè Igbeyawo ti A Sọ Di Ahẹrẹpẹ

Eto idasilẹ igbeyawo funraarẹ tun ti bọ́ sabẹ ìfipákọluni. Iwe The Intimate Environment wi pe: “Ni ìgbà laelae, ohun ti a fojusọna fun ni pe tọkọtaya kan yoo wà gẹgẹ bi ẹni ti o ti fẹ́ra ayafi bi ọ̀kan lara awọn ti wọn fẹ́raawọn naa bá dá ẹṣẹ wiwuwo lodisi igbeyawo naa—panṣaga, ìwà-ìkà, ìpanitì ti ó dé gongo. Nisinsinyi ọpọ julọ eniyan ń rí ète igbeyawo gẹgẹ bii ìtẹ́ra-ẹni-lọ́rùn.” Bẹẹni, igbeyawo ni a kà sí oògùn-atura fun ailayọ, ìsúni, tabi ìdánìkanwà—kìí ṣe gẹgẹ bi ẹ̀jẹ́-àdéhùn wíwà titilọ kánrin pẹlu ẹlomiran kan. Nisinsinyi, afiyesi ti wá wà lori ohun ti o jere lati inu igbeyawo, kìí ṣe ohun ti o fi ṣetilẹhin fún un. (Ṣefiwera iyatọ pẹlu Iṣe 20:35.) “Iyipada pataki yii ninu iniyelori ti o yí igbeyawo ká” ti sọ ìdè igbeyawo di ahẹrẹpẹ gidigidi. Nigba ti ọwọ́ wọn kò bá tẹ itẹlọrun ara-ẹni, awọn tọkọtaya niye ìgbà maa ń nawọ́gán ikọsilẹ gẹgẹ bi ojutuu kóyá-kóyá kan.

Awọn eniyan ni “ikẹhin ọjọ” wọnyi ni a ṣapejuwe lọna alasọtẹlẹ ninu Bibeli gẹgẹ bi “awọn ti wọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn ti wọn sẹ́ agbara rẹ̀.” (2 Timoteu 3:4, 5) Ọpọlọpọ awọn ogbontarigi nimọlara pe ilọsilẹ ninu isin ti kó ipa kan ninu jíjin igbeyawo lẹ́sẹ̀. Ninu iwe rẹ̀ The Case Against Divorce, Dokita Diane Medved kọwe pe: “Gẹgẹ bi ọpọ julọ isin ti wí, Ọlọrun sọ pe igbeyawo nilati wàpẹ́ titi. Nigba ti iwọ kò bá ni idaniloju nipa Ọlọrun tabi ti iwọ kò bá gbà Á gbọ́, nigba naa iwọ yoo ṣe ohun ti o bá fẹ́.” Ni iyọrisi rẹ̀, nigba ti igbeyawo kan bá ni awọn iṣoro, awọn tọkọtaya kìí wá ojutuu ti o yè kooro. “Wọn ń fi kanjukanju fopin si igbeyawo naa.”

Awọn Ọ̀dọ́ Ń Fojúwiná Igbejako

Awọn ọmọ ń yíràá ninu awọn ikimọlẹ ode-oni. Ọpọ rẹ́kẹrẹ̀kẹ awọn ọmọ ni a ń fipa lù bátabàta ti awọn òbí tiwọn funraawọn si ń fi ibalopọ takọtabo tabi èébú ẹnu bà wọn jẹ́. Nipasẹ ikọsilẹ, araadọta-ọkẹ sii ni a kò jẹ ki wọn ni agbara-idari onifẹẹ ti awọn òbí meji, irora ikọsilẹ awọn òbí sì maa ń wà fun gbogbo ọjọ ayé.

Awọn ọ̀dọ́ ni awọn agbara-idari lilagbara dojukọ lọ́tùn-ún-lósì. Nigba ti apẹẹrẹ wiwọpọ julọ ninu ọ̀dọ́ kan ti o jẹ́ ọmọ ilẹ America yoo bá fi pe ọmọ ọdun 14, oun yoo ti rí ipaniyan 18,000 ati ailonka iru awọn iwa-ipa, ibalopọ takọtabo ti kò bofinmu, ìwà-ìkà bíbàlùmọ̀, ati iwa-ọdaran miiran nipa wiwulẹ wo tẹlifiṣọn. Ohùn-orin tún ń lo agbara ńlá lori awọn ọ̀dọ́, lọna ti o dáyàfoni ọpọ julọ ninu wọn sì jẹ́ amúni rèròkerò, eyi ti ń fi kulẹkulẹ ibalopọ takọtabo hàn, tabi ti o tilẹ jẹ́ ti Satani nipa ọ̀rọ̀ rẹ̀. Awọn ile-ẹkọ ń ṣí awọn ọ̀dọ́ payá si awọn àbá-èrò-orí bii ẹfoluṣọn ti o ní itẹsi lati dín agbara igbagbọ ninu Ọlọrun ati Bibeli kù. Ikimọlẹ ojúgbà ń sún ọpọlọpọ lati lọwọ ninu ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo ati ọtí líle tabi ilokulo oogun.

Awọn Gbòǹgbò Idaamu Idile

Nitori naa ìfipákọluni idile gbooro ni fífẹ̀ ó sì lè jẹ́ apanirun. Ki ni ó lè ran idile lọwọ lati yebọ? Olugbaninimọran idile John Bradshaw damọran pe: “Awọn ofin bibojuto ọmọ wa ni a kò tii mú bá ìgbà mu pẹlu ironujinlẹ ni 150 ọdun. . . . Igbagbọ mi ni pe awọn ofin atijọ kò ṣiṣẹ mọ́.” Bi o ti wu ki o ri, awọn ofin àtọwọ́dá eniyan pupọ sii kìí ṣe ojutuu naa. Jehofa Ọlọrun ni Olupilẹṣẹ idile. Ó mọ bi ipa ti igbesi-aye idile ń kó ninu ayọ tiwa funraawa ati ohun ti ó gbà lati mú ki idile layọ ki o sì lagbara ti ṣe pataki tó daradara ju ẹnikẹni miiran lọ. Ó ha yẹ ki o yà wá lẹnu pe Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, pese ojutuu si idaamu idile bi?

Iwe àtayébáyé yẹn ṣalaye bi igbesi-aye idile ṣe di wọ́gọwọ̀gọ. Tọkọtaya ẹda eniyan akọkọ, Adamu ati Efa, ni a fi sinu eto ayika ọgbà ẹlẹ́wà meremere kan ti a sì fun wọn ni ipenija titẹnilọrun ti yiyi ilẹ̀-ayé pada si paradise kari-aye kan. Ọlọrun paṣẹ pe ki Adamu jẹ́ olori idile naa. Efa ni ó nilati fọwọsowọpọ pẹlu ipo-ori rẹ̀ gẹgẹ bi “oluranlọwọ,” tabi “àṣekún” rẹ̀. Ṣugbọn Efa ṣọ̀tẹ̀ si iṣeto yii. Ó fipa gba ipo-ori ọkọ rẹ ó sì ṣaigbọran si ìkàléèwọ̀ kanṣoṣo naa ti Ọlọrun ti gbekari wọn. Nigba naa ni Adamu kọ ipo-ori rẹ̀ silẹ ti ó sì darapọ mọ́ ọn ninu iṣọtẹ yii.—Genesisi 1:26–3:6.

Awọn iyọrisi apanirun ti ìyàbàrá kuro ninu iṣeto Ọlọrun yii di eyi ti o hàn gbangba loju ẹsẹ. Bi wọn kìí tií ṣe ẹni mimọ ati alaimọwọmẹsẹ mọ́, Adamu ati Efa huwapada pẹlu itiju ati ẹ̀bi. Adamu, ti ó ti ṣapejuwe aya rẹ̀ pẹlu awọn èdè-ìsọ̀rọ̀ olórin ewì dídùn mọ̀rọ̀n-ìn-mọrọn-in ní iṣaaju, wá tọka sí i nisinsinyi gẹgẹ bii “obinrin ti iwọ fi pẹlu mi.” Ọ̀rọ̀ ti kò gbeniro yẹn kàn wá di ibẹrẹ irora ọkàn ńláǹlà ninu igbeyawo ni. Awọn igbiyanju Adamu lati jere ipo-ori rẹ̀ pada yoo yọrisi ‘jíjẹgàba lé e lori.’ Efa, ni ipa tirẹ, yoo ní ‘ìfàsí’ fun ọkọ rẹ̀, ó ṣeeṣe ki ó jẹ́ ni ọ̀nà àṣerégèé tabi ti kò wà deedee.—Genesisi 2:23; 3:7-16.

Kò yanilẹnu nigba naa pe, rogbodiyan igbeyawo Adamu ati Efa ní ipa ti ń banininujẹ lori awọn ọmọ wọn. Ọmọkunrin wọn akọkọ, Kaini, di apaniyan ti ọkàn rẹ̀ ti yigbì. (Genesisi 4:8) Lameki, ìran àtẹ̀lé Kaini, fikun ìrẹ̀wálẹ̀ igbesi-aye idile naa nipa didi akobinrinjọ akọkọ ninu akọsilẹ. (Genesisi 4:19) Adamu ati Efa kò tipa bayii ta àtaré kìkì ogún ẹ̀ṣẹ̀ ati iku nikan ṣugbọn apẹẹrẹ idile alaisan ti ó ti jẹ́ ipo iran eniyan lati ìgbà naa wá. Ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi, aifararọ idile ti dé gongo ti o ga ju ti igbakigba ri lọ.

Awọn Idile Tí Ń Gbèrú

Bi o ti wu ki o ri, kìí ṣe gbogbo idile, ní ń wólulẹ̀ labẹ awọn ikimọlẹ ode-oni. Fun apẹẹrẹ, ọkọ kan ń gbé pẹlu aya ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ meji ninu awujọ kekere kan ni United States. Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ninu awọn aladuugbo wọn ní alafo ìran laaarin awọn òbí ati awọn ọmọ wọn, oun ati aya rẹ̀ kò ṣe bẹẹ, bẹẹ ni wọn kò ṣaniyan pe awọn ọmọbinrin wọn lè fi oogun tabi ibalopọ takọtabo danrawo. Ni awọn irọlẹ ọjọ Monday, nigba ti awọn ọ̀dọ́ miiran bá tẹjú ranran mọ́ tẹlifiṣọn, gbogbo idile tiwọn a maa korajọ sidii tabili inu yàrá-ìjẹun fun ijiroro Bibeli. Ó ṣalaye pe, “Alẹ́ ọjọ Monday ni alẹ́ akanṣe wa lati wà papọ ki a sì sọrọ. Awọn ọmọbinrin wa ni ominira fàlàlà lati sọ awọn iṣoro ti wọn ni pẹlu wa ki a sì bá wọn yanju rẹ̀.”

Ni ọwọ keji ẹwẹ, òbí anìkàntọ́mọ kan wà ni New York City ti ó tun ń gbadun ìṣejọ́mújọ́mú idile ara-ọtọ pẹlu awọn ọmọbinrin rẹ̀ meji. Ki ni aṣiri rẹ̀? Ó ṣalaye pe, “a kìí tan tẹlifiṣọn titi di ipari ọsẹ. A ń ní ijiroro ẹsẹ Bibeli kan lojoojumọ. A tún ya irọlẹ kan sọ́tọ̀ fun ijiroro Bibeli idile.”

Awọn idile mejeeji jẹ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọn tẹle imọran fun awọn idile ti a là silẹ ninu Bibeli—ó sì ṣiṣẹ. Sibẹ, wọn kìí ṣe adárayàtọ̀. Ẹgbẹẹgbẹrun lọna ọgọrọọrun awọn idile gẹgẹ bii tiwọn ni wọn wà ti wọn ń rí iyọrisi rere nipa fifi awọn ofin fun igbesi-aye idile ti a rí ninu iwe yẹn silo.b Ki tilẹ ni awọn ilana wọnyẹn? Bawo ni wọn ṣe lè ṣanfaani fun iwọ ati idile rẹ? Ni idahun a késí ọ lati ṣagbeyẹwo awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti ó bẹrẹ ni oju-ewe ti o tẹle e.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fun ẹ̀rí siwaju sii pe awọn ọjọ ikẹhin bẹrẹ ni 1914, wo akori 18 ninu iwe Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, ti a tẹjade lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

b Nipasẹ ikẹkọọ Bibeli inu ile lọ́fẹ̀ẹ́, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń pese itilẹhin ti ara-ẹni ninu fifi awọn ilana Bibeli silo ninu idile. A lè kàn si wọn nipa kikọwe si awọn ti o tẹ iwe-irohin yii jade.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Awọn ipo ìṣúnná-owó ti o buru ń ṣokunfa idaamu pupọ fun awọn idile ni awọn ilẹ ti ń goke àgbà

[Credit Line]

Fọto U.S. Navy

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Nipa fifi awọn ilana Bibeli silo, ọpọlọpọ idile ń dènà awọn ikimọlẹ ode-oni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́