ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 6/15 ojú ìwé 20-25
  • Máa Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Ìdílé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Ìdílé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbésí Ayé Ìdílé Wà Nínú Ewu
  • Kí Ní Fa Yánpọnyánrin Ìdílé?
  • Àwọn Ìlànà Mẹ́rin Ṣíṣe Kókó
  • Máa Bá A Lọ Láti Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run
  • Wá Ọjọ́ Ọ̀la Wíwà Pẹ́ Títí fún Ìdílé Rẹ
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
    Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
  • Ìdílé—Ohun Kòṣeémánìí fún Ẹ̀dá Ènìyàn!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 6/15 ojú ìwé 20-25

Máa Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Ìdílé

“Ẹ gbé e fún Jèhófà, ẹ̀yin ìdílé àwọn ènìyàn, ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà.”—ORIN DÁFÍDÌ 96:7, NW.

1. Irú ìbẹ̀rẹ̀ wo ni Jèhófà fún ìgbésí ayé ìdílé?

ÌGBÉSÍ ayé ìdílé alálàáfíà àti aláyọ̀ ni Jèhófà dá sílẹ̀ nígbà tí ó so ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pọ̀ nínú ìgbéyàwó. Ní tòótọ́, Ádámù láyọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fìdùnnú sọ nínú ewì tí a kọ́kọ́ kọ náà pé: “Èyíyìí ni egungun nínú egungun mi, àti ẹran ara nínú ẹran ara mi: Obìnrin ni a óò máa pè é, nítorí tí a mú un jáde láti ara ọkùnrin wá.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:23.

2. Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ìgbéyàwó, ní àfikún sí mímú ayọ̀ wá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn?

2 Nígbà tí Ọlọ́run dá ìgbéyàwó àti ètò ìdílé sílẹ̀, ohun tí ó ní lọ́kàn ju wíwulẹ̀ mú ayọ̀ wá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn lọ. Ó fẹ́ kí wọ́n ṣe ìfẹ́ òun. Ọlọ́run sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ náà pé: “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa rẹ̀, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀; kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun, àti lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, àti lórí ohun alààyè gbogbo tí ń rákò lórí ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ní tòótọ́, iṣẹ́ àyànfúnni tí ó ní èrè nínú ni ó jẹ́. Ẹ wo bí Ádámù, Éfà, àti àwọn ọmọ wọn ọjọ́ ọ̀la ì bá ti láyọ̀ tó, bí tọkọtaya àkọ́kọ́ bá ti ṣe ìfẹ́ Jèhófà tìgbọràn tìgbọràn!

3. Kí ni a ń béèrè bí àwọn ìdílé yóò bá gbé pẹ̀lú ìfọkànsin Ọlọ́run?

3 Àní lónìí pàápàá, àwọn ìdílé máa ń láyọ̀ jù lọ nígbà tí wọ́n bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ẹ sì wo irú ọjọ́ ọ̀la tí ó pinminrin tí irú àwọn ìdílé onígbọràn bẹ́ẹ̀ ní! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìfọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyíinì tí ń bọ̀.” (Tímótì Kíní 4:8) Àwọn ìdílé tí ń gbé ojúlówó ìgbésí ayé olùfọkànsin Ọlọ́run ń tẹ̀ lé ìlànà Ọ̀rọ̀ Jèhófà, wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Wọ́n ń lépa àlàáfíà Ọlọ́run, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ rí ayọ̀ nínú “ìyè ti ìsinsìnyí.”

Ìgbésí Ayé Ìdílé Wà Nínú Ewu

4, 5. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé ìgbésí ayé ìdílé wà nínú ewu kárí ayé lónìí?

4 Ní ti gidi, kì í ṣe gbogbo ìdílé ni ó ní àlàáfíà àti ayọ̀. Ní títọ́ka sí ìwádìí tí àjọ kan tí ń rí sí ìkànìyàn, tí a pè ní Àjọ Elétò Ìkànìyàn ṣe, ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lọ́rọ̀ àti àwọn tí ó tòṣì, ètò ìgbésí ayé ìdílé ń yí pa dà gan-an.” A ròyìn pé òǹṣèwé kan lórí ìwádìí yìí sọ pé: “Àlọ́ gbáà ni èrò náà jẹ́ pé ìdílé jẹ́ ẹ̀ka tí ó dúró déédéé, tí a mú ṣọ̀kan, nínú èyí tí bàbá ti jẹ́ agbọ́bùkátà, tí ìyá sì jẹ́ olùpèsè ìtọ́jú ní ti ìmọ̀lára. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ìtẹ̀sí bíi jíjẹ́ ìyá láìṣègbéyàwó, iye ìkọ̀sílẹ̀ tí ń pọ̀ sí i, [àti] àwọn agboolé kéékèèké . . . ń ṣẹ́ yọ káàkiri àgbáyé.” Nítorí irú àwọn ìtẹ̀sí bẹ́ẹ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìdílé ń mì, wọn kò ní àlàáfíà àti ayọ̀, ọ̀pọ̀ sì ń tú ká. Ní Sípéènì, iye ìkọ̀sílẹ̀ ti ròkè dé ìgbéyàwó 1 nínú 8, ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀wádún tí ó kẹ́yìn ọ̀rúndún ogún yìí—ìlọsókè pípabanbarì láti orí ìgbéyàwó 1 nínú 100 ní kìkì ọdún 25 tí ó ṣáájú. Ìròyìn fi tó wa létí pé ilẹ̀ England jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ní àròpọ̀ iyè ìkọ̀sílẹ̀ tí ó ga jù lọ ní Europe—ìgbéyàwó 4 nínú 10 ń forí ṣánpọ́n. Orílẹ̀-èdè yẹn kan náà ti rí ìbísí ńlá nínú iye ìdílé olóbìí kan.

5 Ó dà bíi pé ekukáká ni àwọn kan fi lè ní sùúrù kí wọ́n tó jáwèé ìkọ̀sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ń rọ́ lọ sí “Ojúbọ Ìpínyà” lẹ́bàá Tokyo, Japan. Tẹ́ńpìlì ẹ̀sìn Ṣintó yìí ń gba ìwé ìkọ̀sílẹ̀ àti pípín ipò ìbátan mìíràn tí a kò nífẹ̀ẹ́ sí mọ́ níyà. Olùjọ́sìn kọ̀ọ̀kan yóò kọ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sórí pákó pẹlẹbẹ kan, wọ́n yóò fi kọ́ sí inú ojúbọ náà, wọn yóò sì gbàdúrà fún ìdáhùn. Ìwé agbéròyìnjáde kan ní Tokyo sọ pé nígbà tí a dá ojúbọ náà sílẹ̀ ní nǹkan bí ọ̀rúndún kan sẹ́yìn, “aya àwọn ọlọ́rọ̀ àdúgbò kọ̀wé àdúrà pé kí ọkọ àwọn fi àwọn àlè wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì wá fara mọ́ àwọn.” Ṣùgbọ́n, lónìí, ọ̀pọ̀ ẹ̀bẹ̀ jẹ́ fún ìkọ̀sílẹ̀, kì í ṣe ìpadàrẹ́. Láìsí àní-àní, ìgbésí ayé ìdílé wà nínú ewu jákèjádò ayé. Èyí ha yẹ kí ó ya àwa Kristẹni lẹ́nu bí? Rárá o, nítorí Bíbélì fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye láti rí yánpọnyánrin òde ìwòyí nínú ìdílé.

Kí Ní Fa Yánpọnyánrin Ìdílé?

6. Ìbátan wo ni Jòhánù Kíní 5:19 ní pẹ̀lú yánpọnyánrin ìdílé lónìí?

6 Ọ̀kan lára ìdí tí ó fa yánpọnyánrin ìdílé ni èyí: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Jòhánù Kíní 5:19) Kí ni a lè retí láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà, Sátánì Èṣù? Òpùrọ́ burúkú, oníwà pálapàla ni. (Jòhánù 8:44) Abájọ tí ayé rẹ̀ fi ń yọ̀ ṣìnkìn nínú ẹ̀tàn àti ìwà pálapàla, tí ń ba ìgbésí ayé ìdílé jẹ́ gan-an! Lẹ́yìn òde ètò àjọ Ọlọ́run, agbára ìdarí Sátánì ń halẹ̀ láti pa ètò ìgbéyàwó tí Jèhófà dá sílẹ̀ run, kí ó sì mú ìgbésí ayé ìdílé alálàáfíà wá sópin.

7. Báwo ni ìwà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fi hàn ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí ṣe lè nípa lórí ìdílé?

7 Ìdí mìíràn fún àwọn ìṣòro ìdílé tí ń bá aráyé fínra nísinsìnyí ni a fi hàn nínú Tímótì Kejì 3:1-5. Àsọtẹ́lẹ̀ Pọ́ọ̀lù tí a ṣàkọsílẹ̀ níbẹ̀ fi hàn pé a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Àwọn ìdílé kò lè jẹ́ alálàáfíà àti aláyọ̀ bí àwọn mẹ́ńbà wọn bá jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní àwòrán ìrísí ìfọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” Ìdílé kan kò lè jẹ́ aláyọ̀ délẹ̀délẹ̀ bí mẹ́ńbà kan nínú rẹ̀ kò bá ní ìfẹ́ni àdánidá tàbí tí kì í ṣe adúróṣinṣin. Báwo ni ìgbésí ayé ìdílé kan yóò ṣe tòrò tó, bí ẹnì kan nínú agbo ilé náà bá jẹ́ òǹrorò, tí kò sì ṣeé bá ṣe àdéhùn kankan? Èyí tí ó burú jù lọ ni pé, báwo ni àlàáfíà àti ayọ̀ ṣe lè wà nígbà tí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá jẹ́ olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run? Ìwà àwọn ènìyàn inú ayé yìí tí Sátánì ń ṣàkóso nìwọ̀nyí. Abájọ tí ayọ̀ ìdílé fi di àléèbá ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí!

8, 9. Ipa wo ni ìwà àwọn ọmọ lè ní lórí ayọ̀ ìdílé?

8 Ìdí mìíràn tí ọ̀pọ̀ ìdílé kò fi ní àlàáfíà àti ayọ̀ ni ìwà burúkú àwọn ọmọ. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí ipò nǹkan yóò ṣe rí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ ọmọ yóò jẹ́ aṣàìgbọràn sí àwọn òbí. Bí o bá jẹ́ èwe, ìwà rẹ ha ń ṣèrànwọ́ láti mú kí ìdílé rẹ jẹ́ alálàáfíà àti aláyọ̀ bí?

9 Àwọn ọmọ kan kì í ṣe àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ìwà. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́mọkùnrin kékeré kan kọ lẹ́tà burúkú yìí sí bàbá rẹ̀ pé: “Bí o kò bá mú mi lọ sí Alẹkisáńdíríà n kò ní kọ lẹ́tà sí ọ mọ́, n kò ní bá ọ sọ̀rọ̀, n kò sì ní kí ọ pé ó dìgbòóṣe, bí o bá sì dá lọ sí Alẹkisáńdíríà, n kò ní dì ọ́ lọ́wọ́ mú, n kò sì ní kí ọ mọ́ láé. Ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nìyí bí o kò bá mú mi lọ . . . Ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ fi [háápù] kan ránṣẹ́ sí mi, mo bẹ̀ ọ́ ni o. Bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, n kò ní jẹ, n kò sì ní mu. Ó kù sí ọ lọ́wọ́!” Ìyẹn kò ha dún bí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lónìí bí? Tóò, ọmọdékùnrin kan ní Íjíbítì ìgbàanì ni ó kọ lẹ́tà yẹn sí bàbá rẹ̀ ní ohun tí ó lé ní 2,000 ọdún sẹ́yìn.

10. Báwo ni àwọn èwe ṣe lè ran ìdílé wọn lọ́wọ́ láti lépa àlàáfíà Ọlọ́run?

10 Ìwà ọmọdékùnrin ọ̀mọ Íjíbítì yẹn kò gbé àlàáfíà ìdílé lárugẹ. Dájúdájú, àwọn ohun tí ó burú ju ìyẹn lọ ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Síbẹ̀, ẹ̀yin èwe lè ran ìdílé yín lọ́wọ́ láti lépa àlàáfíà Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Nípa ṣíṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì yí: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo, nítorí èyí wuni gidigidi nínú Olúwa.”—Kólósè 3:20.

11. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà?

11 Ẹ̀yin òbí ńkọ́? Ẹ fi ìfẹ́ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti di olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Òwe 22:6 sọ pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.” Pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àtàtà tí a gbé karí Ìwé Mímọ́ àti àpẹẹrẹ rere tí àwọn òbí fi lélẹ̀, ọ̀pọ̀ ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin kì í yà kúrò lójú ọ̀nà títọ́ nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Àmọ́ ṣáá o, púpọ̀ sinmi lórí bí ìdálẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti jẹ́ ojúlówó tó àti bí ó ti jinlẹ̀ tó àti ọkàn àyà èwe náà.

12. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ilé Kristẹni kan tòrò?

12 Bí gbogbo mẹ́ńbà ìdílé wa bá ń gbìyànjú láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ó yẹ kí a máa gbádùn àlàáfíà Ọlọ́run. Ilé Kristẹni kan yẹ kí ó kún fún ‘àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà.’ Lúùkù 10:1-6 fi hàn pé Jésù ní irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́kàn nígbà tí ó rán 70 ọmọ ẹ̀yìn jáde gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́, tí ó sì sọ fún wọn pé: “Ní ibi yòó wù tí ẹ bá ti wọ inú ilé kan ẹ kọ́kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí o.’ Bí ọ̀rẹ́ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e.” Bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe ń lọ lálàáfíà láti ilé dé ilé pẹ̀lú “ìhìn rere àlàáfíà,” wọ́n ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà. (Ìṣe 10:34-36; Éfésù 2:13-18) Dájúdájú, ó yẹ kí agbo ilé Kristẹni kan, tí àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀, tòrò.

13, 14. (a) Kí ni Náómì ń fẹ́ fún Rúùtù àti Ópà? (b) Irú ibi ìsinmi wo ni ó yẹ kí agbo ilé Kristẹni kan jẹ́?

13 Agbo ilé yẹ kí ó jẹ́ ibi tí ó tòrò mini bí omi tí a fòwúrọ̀ pọn. Náómì, arúgbó opó náà, nírètí pé Ọlọ́run yóò fún Rúùtù àti Ópà, àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin, opó aya ọmọ rẹ̀, ní ìsinmi àti ìtùnú tí yóò wá láti inú níní ọkọ rere àti ilé rere. Náómì wí pé: “Kí OLÚWA kí ó fi fún yín kí ẹ̀yin lè rí ìsinmi, olúkúlùkù yín ní ilé ọkọ rẹ̀.” (Rúùtù 1:9) Nípa èrò ọkàn Náómì, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan kọ̀wé pé nínú irú ilé bẹ́ẹ̀, Rúùtù àti Ópà “yóò rí ìdáǹdè kúrò nínú àìbalẹ̀ ọkàn àti àníyàn. Wọn yóò rí ìsinmi. Yóò jẹ́ ibì kan tí wọ́n lè gbé títí, tí ìmọ̀lára wọn oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ jù lọ àti ìfẹ́ ọkàn wọn tí wọ́n bọlá fún jù lọ yóò ti rí ìtẹ́lọ́rùn àti ìsinmi. Ìtẹnumọ́ pàtàkì tí ọ̀rọ̀ Hébérù náà . . . ní ni a fi hàn lọ́nà rere nípa bí àwọn gbólóhùn inú [Aísáyà 32:17, 18], tí ó tan mọ́ ọn, ṣe rí.”

14 Jọ̀wọ́ kíyè sí ìtọ́kasí yìí ní Aísáyà 32:17, 18. A kà níbẹ̀ pé: “Iṣẹ́ òdodo yóò sì jẹ́ àlàáfíà, àti èso òdodo yóò jẹ́ ìdákẹ́jẹ́ẹ́ òun ààbò títí láé. Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ibùgbé àlàáfíà, àti ní ibùgbé ìdánilójú, àti ní ibi ìsinmi ìparọ́rọ́.” Ilé Kristẹni yẹ kí ó jẹ́ ibi ìsinmi ti òdodo, ìparọ́rọ́, ààbò, àti àlàáfíà Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n bí àdánwò, èdèkòyedè, tàbí àwọn ìṣòro mìíràn bá dìde ńkọ́? Nígbà náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a mọ àṣírí ayọ̀ ìdílé.

Àwọn Ìlànà Mẹ́rin Ṣíṣe Kókó

15. Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé àṣírí ayọ̀ ìdílé?

15 Olúkúlùkù ìdílé lórí ilẹ̀ ayé jẹ Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá, ní gbèsè fún orúkọ rẹ̀. (Éfésù 3:14, 15) Nítorí náà, ó yẹ kí àwọn tí ń fẹ́ ayọ̀ ìdílé wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀, kí wọ́n sì yìn ín, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù ti ṣe pé: “Ẹ gbé e fún Jèhófà, ẹ̀yin ìdílé àwọn ènìyàn, ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà.” (Orin Dáfídì 96:7, NW) Àṣírí ayọ̀ ìdílé ń bẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, àti nínú lílo àwọn ìlànà rẹ̀. Ìdílé tí ó bá lo àwọn ìlànà wọ̀nyí yóò jẹ́ aláyọ̀, yóò sì gbádùn àlàáfíà Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yẹ mẹ́rin nínú àwọn ìlànà pàtàkì wọ̀nyí wò.

16. Ipa wo ni ó yẹ kí ìkóra-ẹni-níjàánu kó nínú ìgbésí ayé ìdílé?

16 Ọ̀kan nínú àwọn ìlànà wọ̀nyí wé mọ́ èyí: Ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe kókó fún àlàáfíà Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé ìdílé. Ọba Sólómọ́nì wí pé: “Ẹni tí kò lè ṣe àkóso ara rẹ̀, ó dà bí ìlú tí a wó lulẹ̀, tí kò sì ní odi.” (Òwe 25:28) Ṣíṣàkóso ẹ̀mí wa—lílo ìkóra-ẹni-níjàánu—ṣe kókó bí a bá fẹ́ láti ní ìdílé alálàáfíà àti aláyọ̀. Bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, a ní láti lo ìkóra-ẹni-níjàánu, tí ó jẹ́ èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Róòmù 7:21, 22; Gálátíà 5:22, 23) Ẹ̀mí náà yóò pèsè ìkóra-ẹni-níjàánu nínú wa bí a bá gbàdúrà fún ànímọ́ yìí, tí a fi ìmọ̀ràn Bíbélì nípa rẹ̀ sílò, tí a sì kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn mìíràn tí wọ́n ń fi í hàn. Ipa ọ̀nà yí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti “sá fún àgbèrè.” (Kọ́ríńtì Kíní 6:18) Ìkóra-ẹni-níjàánu yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti kọ ìwà ipá sílẹ̀, láti yẹra fún ìmukúmu tàbí láti borí rẹ̀, kí a sì fara balẹ̀ kojú àwọn ipò líle koko.

17, 18. (a) Báwo ni Kọ́ríńtì Kíní 11:3 ṣe kan ìgbésí ayé ìdílé Kristẹni? (b) Báwo ni mímọ ipò orí ṣe ń gbé àlàáfíà Ọlọ́run lárugẹ nínú ìdílé?

17 A lè sọ ìlànà ṣíṣe kókó mìíràn lọ́nà yí: Mímọ ipò orí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lépa àlàáfíà Ọlọ́run nínú ìdílé wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀ orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀ orí Kristi ni Ọlọ́run.” (Kọ́ríńtì Kíní 11:3) Èyí túmọ̀ sí pé ọkọ ń mú ipò iwájú nínú ìdílé, aya rẹ̀ ń fi ìdúróṣinṣin ṣètìlẹ́yìn, àwọn ọmọ sì ń ṣègbọràn. (Éfésù 5:22-25, 28-33; 6:1-4) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ yóò gbé àlàáfíà Ọlọ́run lárugẹ nínú ìgbésí ayé ìdílé.

18 Kristẹni ọkọ gbọ́dọ̀ rántí pé ipò orí tí a gbé karí ìlànà Ìwé Mímọ́ kì í ṣe ipò apàṣẹwàá. Ó gbọ́dọ̀ fara wé Jésù, Orí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ “orí lórí ohun gbogbo,” Jésù “wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́.” (Éfésù 1:22; Mátíù 20:28) Ní ọ̀nà kan náà, Kristẹni ọkọ kan ń lo ipò orí lọ́nà tí ó fi ìfẹ́ hàn, tí ń mú kí ó ṣeé ṣe fún un láti bójú tó ire ìdílé rẹ̀ dáradára. Dájúdájú, Kristẹni aya kan ń fẹ́ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí “olùrànlọ́wọ́,” àti “àṣekún” rẹ̀, ó ń pèsè àwọn ànímọ́ tí ọkọ rẹ̀ ṣaláìní, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fún un ní ìtìlẹ́yìn tí ó nílò. (Jẹ́nẹ́sísì 2:20; Òwe 31:10-31) Lílo ipò orí lọ́nà yíyẹ ń ran ọkọ àti aya lọ́wọ́ láti bọ̀wọ̀ fún ara wọn lẹ́nì kíní kejì, ó sì ń sún àwọn ọmọ láti ṣègbọràn. Bẹ́ẹ̀ ni, mímọ ipò orí ń gbé àlàáfíà Ọlọ́run lárugẹ nínú ìgbésí ayé ìdílé.

19. Èé ṣe tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídánmọ́rán fi ṣe kókó fún àlàáfíà àti ayọ̀ ìdílé?

19 A lè sọ ìlànà pàtàkì kẹta lọ́nà yí: Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídánmọ́rán ṣe kókó fún àlàáfíà àti ayọ̀ ìdílé. Jákọ́bù 1:19 sọ fún wa pé: “Olúkúlùkù ènìyàn gbọ́dọ̀ yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé tẹ́tí sílẹ̀ sí ara wọn, kí wọ́n sì bá ara wọn sọ̀rọ̀, nítorí pé sọ-sí-mi-n-sọ-sí-ọ ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ìdílé jẹ́. Ṣùgbọ́n, bí ohun tí a sọ bá tilẹ̀ tọ̀nà, ó ṣeé ṣe kí ó ba nǹkan jẹ́ ju kí ó tún un ṣe lọ, bí a bá fi ẹ̀mí òǹrorò, ìgbéraga, tàbí ẹ̀mí àìgbatẹnirò sọ ọ́. Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wá jẹ́ èyí tí ó dùn létí, “tí a fi iyọ̀ dùn.” (Kólósè 4:6) Àwọn ìdílé tí ń tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́, tí wọ́n sì ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ dáradára ń lépa àlàáfíà Ọlọ́run.

20. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi sọ pé ìfẹ́ ṣe kókó fún àlàáfíà ìdílé?

20 Ìlànà kẹrin nìyí: Ìfẹ́ ṣe kókó fún àlàáfíà àti ayọ̀ ìdílé. Ìfẹ́ eléré ìfẹ́ lè kó ipa pàtàkì nínú ìgbéyàwó, àwọn mẹ́ńbà ìdílé sì lè mú ìfẹ́ni jíjinlẹ̀ dàgbà fún ara wọn. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·gaʹpe, dúró fún ni ó ṣe pàtàkì jù lọ. Ìfẹ́ yìí ni a ń fi hàn sí Jèhófà, sí Jésù, àti sí aládùúgbò wa. (Mátíù 22:37-39) Ìfẹ́ yìí ni Ọlọ́run fi hàn sí ìran ènìyàn nípa fífi “Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má baà pa run ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ohun àgbàyanu tó pé a lè fi irú ìfẹ́ kan náà yìí hàn sí àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa! Ìfẹ́ tí a gbé ga yìí jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Ó ń so tọkọtaya pọ̀, ó sì ń sún wọn láti ṣe ohun tí ó dára jù lọ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. Nígbà tí àwọn ipò líle koko bá dìde, ìfẹ́ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti para pọ̀ yanjú àwọn ìṣòro. A lè ní ìdánilójú èyí nítorí pé “ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan . . . A máa gba ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (Kọ́ríńtì Kíní 13:4-8) Ní tòótọ́, aláyọ̀ ni àwọn ìdílé tí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà so ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ẹnì kíní kejì pọ̀!

Máa Bá A Lọ Láti Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run

21. Kí ní ṣeé ṣe kí ó fi kún àlàáfíà àti ayọ̀ ìdílé rẹ?

21 Àwọn ìlànà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kàn tán yìí, àti àwọn mìíràn tí ó wà nínú Bíbélì, ni a ti tò lẹ́sẹẹsẹ fún wa nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí Jèhófà ti fi inú rere pèsè nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú.” (Mátíù 24:45) Fún àpẹẹrẹ, a rí irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ nínú ìwé olójú ewé 192 náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, tí a mú jáde ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ti “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run,” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí a ṣe kárí ayé láàárín 1996 sí 1997. Dídákẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan pẹ̀lú irú ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ lè mú ọ̀pọ̀ àǹfààní wá. (Aísáyà 48:17, 18) Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe kí lílo ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ fi kún àlàáfíà àti ayọ̀ ìdílé rẹ.

22. Kí ló yẹ kí ìgbésí ayé ìdílé wa dá lé lórí?

22 Jèhófà ní àwọn nǹkan àgbàyanu ní ìpamọ́ fún àwọn ìdílé tí wọ́n ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó sì yẹ fún ìyìn wa àti iṣẹ́ ìsìn wa. (Ìṣípayá 21:1-4) Nítorí náà, ǹjẹ́ kí ìdílé rẹ jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ̀ dá lórí ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ náà. Ǹjẹ́ kí Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, fi ayọ̀ jíǹkí rẹ, bí o ti ń lépa àlàáfíà Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé ìdílé rẹ!

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Kí ni a ń béèrè bí àwọn ìdílé yóò bá gbé pẹ̀lú ìfọkànsin Ọlọ́run?

◻ Èé ṣe tí yánpọnyánrin fi wà nínú ìdílé lónìí?

◻ Kí ni àṣírí ayọ̀ ìdílé?

◻ Kí ni díẹ̀ lára ìlànà tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbé àlàáfíà àti ayọ̀ lárugẹ nínú ìgbésí ayé ìdílé?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídánmọ́rán ń ràn wá lọ́wọ́ láti lépa àlàáfíà Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé ìdílé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́