ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 6/15 ojú ìwé 26-29
  • Ṣíṣèbẹ̀wò sí Pápá Míṣọ́nnárì Ilẹ̀ Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣèbẹ̀wò sí Pápá Míṣọ́nnárì Ilẹ̀ Wa
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ṣíṣẹ́pá Ìṣòro Àìgbédè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Yíyàtọ̀ Síra
  • Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Yíyàtọ̀ Síra
  • Ìfojúsọ́nà Amọ́kànyọ̀
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 6/15 ojú ìwé 26-29

Ṣíṣèbẹ̀wò sí Pápá Míṣọ́nnárì Ilẹ̀ Wa

ÀWÙJỌ ìjọ Kristẹni tí mo ń bẹ̀ wò ń mú kí n rìnrìn àjò láti ilẹ̀ Potogí lọ sí China—tàbí kí a sọ pé bí ó ti jọ nìyẹn. Síbẹ̀, èmi àti aya mi, Olive, kò fi Britain sílẹ̀ rí.

A ń ṣèbẹ̀wò sí ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń sọ èdè àjòjì, tí ń pọ̀ sí i, tí wọ́n wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà. A ń ṣàjọpín nínú pápá onírúurú èdè tí ń gbèrú, tí ń láásìkí nípa tẹ̀mí, láti erékùṣù Jersey tí ó tó nǹkan bí 20 kìlómítà sí etíkun Normandy ti ilẹ̀ Faransé, níbi tí a ti ní àwùjọ tí ń sọ èdè Potogí, a ń dé ìlú Sunderland ní àríwá England, níbi tí a ti ń bẹ àwọn olùfìfẹ́hàn tí ń sọ èdè Chinese wò. Báwo ni irú iṣẹ́ àyànfúnni àrà ọ̀tọ̀ yí ṣe wá jẹ́ tiwa? Kí ní sì ń ṣẹlẹ̀ ní pápá míṣọ́nnárì ilẹ̀ wa? Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.

Èmi àti Olive ti ṣiṣẹ́ arìnrìn-àjò fún nǹkan bí 20 ọdún, ní bíbẹ ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìrìn àjò wá tí gbé wa láti àríwá dé gúúsù, láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn, jákèjádò Britain, àti lẹ́nu àìpẹ́ yìí dé ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ará wa ní erékùṣù Málítà tí ó wà ní Meditaréníà, níbi tí a ti gbádùn aájò àlejò Kristẹni lọ́nà títayọ lọ́lá. (Fi wé Ìṣe 28:1, 2.) Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta ní Málítà, a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì nípa ibi tí iṣẹ́ àyànfúnni wa yóò gbé wa lọ tẹ̀ lé e. A finú wòye pé, ó ṣeé ṣe kí a ṣèbẹ̀wò sí àgbègbè ìgbèríko kan ní England, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í múra ọkàn wa sílẹ̀ fún ṣíṣeéṣe yìí. Ẹ wo irú ìyàlẹ́nu tí ó jẹ́ nígbà tí a gba iṣẹ́ àyànfúnni wa láti ṣiṣẹ́ sin àyíká tuntun yìí, tí ó ní àwọn àwùjọ àti ìjọ tí ń sọ èdè 23 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú!

A ṣe kàyéfì nípa bí a óò ṣe kojú rẹ̀. Yàtọ̀ sí ìrírí tí a ní ní Málítà, a kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìfararora pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ipò àtilẹ̀wá àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó yàtọ̀ sí tiwa. Yóò ha ṣeé ṣe fún wa ní ti gidi láti fún àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì ní ìṣírí bí? Báwo ni a óò ṣe bá wọn sọ̀rọ̀ láìgbọ́ èdè míràn? Oúnjẹ àti onírúurú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ńkọ́? A óò ha lè mú ara wa bá ipò náà mu gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yẹ bí? Àwọn ìbéèrè bí irú ìwọ̀nyí ń wá sí wa lọ́pọlọ, bí a ti ń gbé dídáhùn ìkésíni láti wá sí Makedóníà yí yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà.—Ìṣe 16:9, 10; Kọ́ríńtì Kíní 9:19-22.

Ṣíṣẹ́pá Ìṣòro Àìgbédè

Olive ṣàlàyé pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, mo nímọ̀lára pé n kò tóótun tó, nítorí n kò gbédè. N kò rí bí mo ṣe lè ran àwọn arábìnrin lọ́wọ́. Mo wá rántí bí tọkọtaya tí ó kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wa ṣe fún wa níṣìírí láti má ṣe yẹ iṣẹ́ àyànfúnni kankan sílẹ̀ láé. Wọ́n kọ́ wa pé Jèhófà kì í sọ pé kí a ṣe ohun tí a kò lè ṣe láé.” Nítorí náà, àwa méjèèjì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àyànfúnni náà tinútinú.

Ní ríronú jinlẹ̀, a rí i pé àìgbédè míràn wa ti ràn wá lọ́wọ́ láti bá gbogbo ènìyàn lò ní ọgbọọgba. Fún àpẹẹrẹ, pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tí a ń lo èdè míràn láti darí, ti jẹ́ kí a lóye ìmọ̀lára àwọn ará wa nígbà tí wọ́n bá jókòó nínú àwọn ìpàdé tí a ń darí ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, tí wọn kò sì lóye ọ̀pọ̀ ohun tí a ń sọ. A ní láti múra sílẹ̀ dáradára fún àwọn ìpàdé kí a baà lè lóye ohun tí a ń gbé kalẹ̀. Olive sábà máa ń dáhùn ìbéèrè kan ní ìpàdé. Ó máa ń múra ìdáhùn náà sílẹ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, yóò sì ní kí arábìnrin kan bá òun ṣe ìtumọ̀ rẹ̀, yóò sì kọ ìtumọ̀ náà sílẹ̀ lọ́nà tí yóò ṣeé kà fún un. Ó jẹ́wọ́ pé, òun máa ń lọ́ tìkọ̀ láti na ọwọ́ òun sókè láti dáhùn. Nígbà míràn, ìsapá rẹ̀ máa ń fa ẹ̀rín. Ṣùgbọ́n èyí kò mú kí ó rẹ̀ wẹ̀sì. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé àwọn ará mọrírì ìgbìyànjú mi. Ní tòótọ́, dídáhùn mi ń fún àwọn tí ó mọ èdè náà dáadáa níṣìírí láti ṣàjọpín nínú ìpàdé.”

Sísọ àsọyé ṣòro fún èmi pẹ̀lú, nítorí mo ní láti fàyè sílẹ̀ fún ògbufọ̀ láti ṣètumọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn gbólóhùn kọ̀ọ̀kan. Ó rọrùn púpọ̀ fún mi láti pàdánù èrò ti mo ti ń bá bọ̀. Mo rí i pé, mo ní láti pọkàn pọ̀ gidigidi gan-an, kí n sì gé àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ mi kúrú. Ṣùgbọ́n mo máa ń gbádùn rẹ̀.

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Yíyàtọ̀ Síra

Àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè àjòjì ní àgbègbè ìgboro ìlú Britain wà káàkiri, bóyá méjì ní ojú pópó kan, tí o sì ní láti rìn lọ sí ọ̀nà jíjìn kí o tó rí àwọn mìíràn. Síbẹ̀, nígbà tí o bá lo èdè wọn láti fi kí wọn, tí o sì rí ìdáhùn pa dà wọn, ìwọ yóò nímọ̀lára pé ìsapá náà kì í ṣe lásán. Bí arákùnrin tí mo ń bá ṣiṣẹ́ bá lo èdè onílé láti fi gbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀, ìdáhùn pa dà náà máa ń kọyọyọ.

Ní tòótọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àwọn pápá tí a ti ń sọ èdè àjòjì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó lárinrin jù lọ tí a tí ì nírìírí láàárín 40 ọdún iṣẹ́ ìsìn Ìjọba wa. Ó ṣeé ṣe kí ìbísí jaburata wà. Kò sí iyèméjì pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní kíákíá sí i àti pẹ̀lú ìmọrírì jíjinlẹ̀ sí i, nígbà tí a bá lo èdè ìbílẹ̀ wọn láti fi kọ́ wọn. (Ìṣe 2:8, 14, 41) Ó máa ń ru ìmọ̀lára wa sókè gidi gan-an láti rí àwọn arákùnrin àti arábìnrin pẹ̀lú omijé ayọ̀ lójú lẹ́yìn ìpàdé, tí ó lè jẹ́ pé fún ìgbà àkọ́kọ́, ó ṣeé ṣe fún wọn láti gbọ́, kí wọ́n sì lóye gbogbo ìtòlẹ́ṣẹẹsẹ náà.

Nígbà tí a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, a máa ń gbìyànjú láti ṣe ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan, ó kéré tán, ní èdè onílé náà, bí a tilẹ̀ máa ń kó sínú ìṣòro nígbà míràn. Fún àpẹẹrẹ, ìkíni tí ó wọ́pọ̀ tí a fi ń kí onílé tí ó jẹ́ Gujarati ni Kemcho, tí ó wulẹ̀ túmọ̀ sí, “Ẹ ǹ lẹ́ o.” Ó ṣe kedere pé ohun tí mo ṣì sọ ní ìgbà kan dún bíi pé mo ń polówó oríṣi kọfí kan. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ilé kan, ọkọ àti aya kan rẹ́rìn-ín músẹ́ nígbà tí mo kí wọn ní èdè Gujarati. Lọ́gán, wọ́n ké sí wa wọlé, wọ́n sì fi kọfí lọ̀ wá—kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tí mo ṣì sọ o. Ó ṣẹlẹ̀ pé wọ́n tan mọ́ díẹ̀ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà nínú àwùjọ tí a ń bẹ̀ wò, wọ́n sì fi ojúlówó ìfẹ́ hàn nínú òtítọ́.

Arábìnrin kan tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì máa ń fi àwọn ìwé ìròyìn sílẹ̀ fún obìnrin kan tí ń sọ èdè Chinese ní gbogbo ìgbà, fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ó ti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀fẹ́ lọ obìnrin náà ní àwọn ìgbà mélòó kan, ṣùgbọ́n tí obìnrin náà kọ̀ ọ́. Ní ọjọ́ kan, arábìnrin kan tí ń kọ́ èdè Chinese bá a ṣiṣẹ́, ó sì fi ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, ní èdè yẹn lọ̀ ọ́, onílé tí ń fìfẹ́ hàn náà tẹ́wọ́ gbà á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.a Nísinsìnyí tí ó ní ìwé náà ní èdè rẹ̀, ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ tí a sọ ní èdè obìnrin náà ni ó mú ìyàtọ̀ yí wá.

Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Yíyàtọ̀ Síra

A kò mọ̀ pé, ní àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, àwọn ọkùnrin kì í fẹ́ kí àwọn obìnrin wọ́n dá jáde ní alẹ́. Èyí mú kí ó ṣòro gan-an fún ọ̀pọ̀ arábìnrin láti wá sí àwọn ìpàdé tí a ń ṣe ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Àwùjọ Éṣíà kan gbà gbọ́ pé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n yàn láti máà fọ́kọ, tí wọ́n sì ń bá a nìṣó láti gbé nílé, ń dójú ti ìdílé wọn. Bàbá arábìnrin ọ̀dọ́ kan fẹ́ gbé májèlé jẹ nítorí tí arábìnrin náà kọ̀ láti fẹ́ ọkùnrin tí ìdílé rẹ̀ yàn fún un. Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí irú àwọn arábìnrin bẹ́ẹ̀ ní láti fojú gbiná rẹ̀ kàmàmà! Síbẹ̀, bí o bá rí ipa tí òtítọ́ ti ní lórí ìgbésí ayé ìdílé náà, àti bí ìdúróṣinṣin irú àwọn arábìnrin bẹ́ẹ̀ sí Jèhófà ṣe wú àwọn òbí wọn lórí, ó jẹ́ ohun àgbàyanu ní tòótọ́.

Ní ṣíṣàjọpín nínú iṣẹ́ àyànfúnni yìí, a ti ní láti ṣe àwọn ìyípadà díẹ̀. Kí a tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ arìnrìn-àjò, kìkìdá oúnjẹ àwọn ará England ni mo máa ń jẹ, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, bí a bá ṣe fi èèlò pá a lórí tó ni mo túbọ̀ ń gbádùn rẹ̀. Ó dùn wá pé, a jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ọdún kọjá lọ kí a tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn irú àwọn oúnjẹ àjẹpọ́nnulá bẹ́ẹ̀—láti orí ẹja tútù sí àwọn oúnjẹ tí a fi kọrí pá lórí.

Ìfojúsọ́nà Amọ́kànyọ̀

Ó ṣe kedere pé àkókò nìyí fún pápá tí a ti ń sọ àwọn èdè àjòjì láti gbèrú ní ọ̀pọ̀ àgbègbè. Àwọn ìtẹ̀jáde púpọ̀ sí i wà lárọ̀ọ́wọ́tó nísinsìnyí ní onírúurú èdè. O lè rí ìbùkún Jèhófà bí a ti ń ṣètò àwọn ìjọ tuntun. Àwọn ará tí wọ́n gbọ́ àwọn èdè míràn ń wá láti àwọn ìjọ jíjìnnà láti ṣèrànwọ́.

Àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá kan ni ìdáhùn pa dà sí wíwàásù ìhìn rere Ìjọba ní èdè Faransé. Ọ̀pọ̀ àwọn olùwá-ibi-ìsádi láti Zaire àti àwọn orílẹ̀-èdè míràn ní Áfíríkà, tí wọ́n ń sọ èdè Faransé, ti ṣí wá sí Britain ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Nígbà tí a dá ìjọ èdè Faransé àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní London, àwọn akéde Ìjọba 65 ni ó dara pọ̀ mọ́ ọn. Ní ọdún kan lẹ́yìn náà, iye náà ti fò sókè sí 117, 48 lára àwọn wọ̀nyí sì ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Kò pẹ́ kò jìnnà, a dá ìjọ kejì sílẹ̀ láti bójú tó ìfẹ́ ọkàn tí ń pọ̀ sí i. Nísinsìnyí, a lè fún àwọn olùfìfẹ́hàn ní àfiyèsí púpọ̀ sí i, ti 345 lára wọ́n wá sí ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ní 1995. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead tẹ́lẹ̀ rí, tí wọ́n ti ṣiṣẹ́sìn ní Benin, Côte d’Ivoire, Morocco, àti Zaire, ń lo ìrírí wọn nísinsìnyí láti bójú to pápá tí ń gbèrú yìí, ìdáhùnpadà náà sì kọyọyọ.

Nígbà ìbẹ̀wò kan sí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé, mo tẹ̀lé ọ̀dọ́mọbìnrin ará Áfíríkà kan lọ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan. Nígbà tí ó tó àkókò fún wa láti lọ, ọ̀dọ́mọbìnrin náà rọ̀ wá pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ì lọ. Ẹ dúró díẹ̀ sí i.” Ó ṣáà fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. Ó mú kí n rántí Lídíà ọ̀rúndún kìíní.—Ìṣe 16:14, 15.

Iṣẹ́ wa àkọ́kọ́ ni láti ran àwọn àwùjọ kékeré tí ń sọ èdè àjòjì lọ́wọ́ láti di ìjọ. Níbi tí àwọn ará ti ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, a óò bẹ̀rẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run tí a ké kúrú fún wọn ní ẹ̀ẹ̀kan lóṣù. Èyí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe gbogbo ìpàdé ìjọ márààrún lọ́sẹ̀. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, a ní àwọn ìjọ tuntun tí ń sọ èdè Chinese (Cantonese), Faransé, Gujarati, Japanese, Potogí, Punjabi, Tamil, àti Welsh.

A tún ti gbádùn lílọ sí àwọn ìpàdé àwọn ará tí wọ́n jẹ́ adití. Wíwo àwọn ará bí wọ́n ti ń fi ọwọ́ wọn kọrin jẹ́ ohun tí ń ru ìmọ̀lára ẹni sókè. Ní mímọ̀ pé ọwọ́ ni wọ́n fi ń sọ̀rọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, mo mọrírì ìsapá gíga lọ́lá wọn láti ṣàjọpín nínú ìwàásù Ìjọba. Àwọn olùtúmọ̀ tilẹ̀ wà fún àwọn tí wọ́n dití tí wọ́n sì fọ́jú. Ó jọ bí ẹni pé Jèhófà rí sí i pé a kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀.

Bí a óò bá béèrè ohun kan ní pàtó, yóò jẹ ohun kan náà tí Jésù béèrè pé: “Ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mátíù 9:38) Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ń tẹ́wọ́ gba ìpèníjà kíkọ́ èdè àwọn àwùjọ ẹ̀yà ìran tí ó wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ wọn. Bí a kò tilẹ̀ fún wa ní ẹ̀bùn sísọ onírúurú èdè lọ́nà ìyanu, dájúdájú Jèhófà ń ṣí iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà sílẹ̀ ní pápá míṣọ́nnárì ilẹ̀ yí—pápá tí ó ti funfun fún kíkórè. (Jòhánù 4:35, 36)—Gẹ́gẹ́ bí Colin Seymour ṣe sọ ọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́