ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • T-21 ojú ìwé 1-6
  • Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
  • Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ìdílé Ṣe Pilẹ̀ṣẹ̀
  • Ọ̀nà Wo La Ó Gbà Ṣàṣeyọrí? 
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ìdílé Rẹ Lè Láyọ̀
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Táá Mú Kí Ìdílé Rẹ Láyọ̀
    Jí!—2021
Àwọn Míì
Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
T-21 ojú ìwé 1-6

Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé

Àwọn ìdílé ha lè láyọ̀ ní ti gidi bí?

Báwo ni ó ṣe lè ṣeé ṣe?

O ha mọ ìdílé kan tó wà níṣọ̀kan tó sì láyọ̀ bíi tàwọn tí a rí nínú ìwé àṣàrò kúkúrú yìí? Ńṣe làwọn ìdílé kàn ń tú pẹ̀ẹ́ níbi gbogbo. Ìkọ̀sílẹ̀, àìsí iṣẹ́ tó fini lọ́kàn balẹ̀, ìṣòro tí àwọn òbí anìkàntọ́mọ ní, ìjákulẹ̀—gbogbo ìwọ̀nyí ní ń pa kún làásìgbò náà. Ògbógi kan lórí ọ̀ràn ìgbésí ayé ìdílé kédàárò pé: “Ní báyìí, gbogbo ènìyàn ló ti mọ̀ nípa àwọn àwítẹ́lẹ̀ pé ìdílé máa tó fọ́nká.”

Èé ṣe tí àwọn ìṣòro lílekoko bẹ́ẹ̀ fi ń rọ́ lu àwọn ìdílé lónìí? Báwo ni a ṣe lè gbádùn ìgbésí ayé ìdílé?

Bí Ìdílé Ṣe Pilẹ̀ṣẹ̀

Láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ó ń béèrè pé kí a mọ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbéyàwó àti ìdílé. Nítorí bí ìwọ̀nyí bá ní Olùpilẹ̀ṣẹ̀ kan—Ẹlẹ́dàá kan—ó yẹ kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé tọ̀ ọ́ lọ fún ìtọ́sọ́nà, níwọ̀n bó ti dájú pé òun yóò mọ ọ̀nà tó dára jù lọ tí a fi lè gbádùn ìgbésí ayé ìdílé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé ètò ìdílé kò ní Olùpilẹ̀ṣẹ̀ kankan. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé: “Àwọn ọ̀mọ̀wé kan fẹ́ máa tọpasẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbéyàwó lọ sórí ètò bí àwọn ẹranko, tí wọ́n rẹlẹ̀ sí ènìyàn, ṣe ń múra wọn ní méjì-méjì.” Síbẹ̀, Jésù Kristi sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ọkùnrin àti obìnrin. Ó fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú àkọsílẹ̀ ìjímìjí tó wà nínú Bíbélì láti fi ti ara rẹ̀ lẹ́yìn, ó sọ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:4-6.

Nítorí náà Jésù Kristi tọ̀nà. Ọlọ́run olóye kan dá àwọn ènìyàn àkọ́kọ́, ó sì ṣètò fún ìgbésí ayé ìdílé. Ọlọ́run fi ìgbéyàwó so àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ pọ̀, ó sì sọ pé kí ọkùnrin “fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:22-24) Nígbà náà, ǹjẹ́ gbígbé tí àwọn ènìyàn ń gbé ìgbésí ayé lọ́nà tí ó rú àwọn ìlànà tí Ẹlẹ́dàá là sílẹ̀ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ha kọ́ ló ń fa àwọn ìṣòro ìdílé òde òní bí?

Ọ̀nà Wo La Ó Gbà Ṣàṣeyọrí? 

Gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ṣe mọ̀, ṣe ni ayé òde òní ń gbé ẹ̀mí ìfẹ́ ti ara ẹni nìkan àti àṣeyọrí ti ara ẹni nìkan lárugẹ. Olùṣekòkáárí owó okòwò kan sọ fún kíláàsì àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n fẹ́ gboyè jáde ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà pé: “Ìwọra kò burú. O lè jẹ́ oníwọra síbẹ̀ kí ara tù ọ́.” Àmọ́, lílépa ọrọ̀ àlùmọ́nì kì í múni ṣàṣeyọrí sí rere. Ní tòótọ́, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó jẹ́ ewu gidigidi fún ìgbésí ayé ìdílé nítorí pé ó ń dínà àjọṣepọ̀ láàárín àwọn ènìyàn, ó sì ń gba àkókò àti owó ènìyàn dà nù. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, gbé bí òwe méjì péré nínú Bíbélì ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti rí ohun tó ṣe pàtàkì fúnni láti láyọ̀ yẹ̀ wò.

“Ó sàn láti bá àwọn ènìyàn tóo fẹ́ràn jẹ ewébẹ̀ ju láti jẹ ẹran tó dára jù lọ níbi tí ìkórìíra wà.”

“Ó sàn láti jẹ búrẹ́dì gígan tòun tàlàáfíà ju láti jẹ àsè nínú ilé tó kún fún ìjàngbọ̀n.”

Òwe 15:17; 17:1, “Today’s English Version.”

Ọ̀rọ̀ ńlá, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣáà ro bí ayé ì bá ti yàtọ̀ tó ká ní gbogbo ìdílé ló ń ṣe àwọn nǹkan pàtàkì wọ̀nyí! Bíbélì tún pèsè ìtọ́sọ́nà oníyebíye lórí bí ó ṣe yẹ kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé máa hùwà sí ara wọn. Gbé ìtọ́ni mélòó kan tó fúnni yẹ̀ wò.

Ẹ̀yin ọkọ: ‘Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín gẹ́gẹ́ bí ara ẹ̀yin fúnra yín.’—Éfésù 5:28-30.

Ó rọrùn, síbẹ̀ ó gbéṣẹ́ gan-an ni! Bíbélì tún pàṣẹ pé kí ọkọ ‘fi ọlá fún aya rẹ̀.’ (1 Pétérù 3:7) Òun ń ṣe èyí nípa fífún un ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀, títí kan ṣíṣìkẹ́ rẹ̀, fífi òye bá a lò, àti fífi í lọ́kàn balẹ̀. A tún máa ka ìmọ̀ràn rẹ̀ sí a sì máa fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 21:12.) O kò ha gbà pé kò sí ìdílé náà tí kò ní jàǹfààní bí ọkọ bá ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí aya rẹ̀ bí òun náà yóò ṣe fẹ́ kí a hùwà sí òun?—Mátíù 7:12.

Ẹ̀yin Aya: ‘Ẹ ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ yín.’ —Éfésù 5:33.

Aya ń fi kún ayọ̀ ìdílé nípa ṣíṣèrànwọ́ fún ọkọ rẹ̀ kí ó lè máa ṣe ojúṣe ńláǹlà tó yẹ kó ṣe. Ohun tí Ọlọ́run pète nìyẹn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe ló pèsè aya láti jẹ́ “olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) O ha lè wòye ìbùkún tó máa wà nínú ìgbésí ayé ìdílé nígbà tí aya bá ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ nípa ṣíṣètìlẹyìn fún àwọn ìpinnu rẹ̀ tó sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti lè lé àwọn góńgó ìdílé bá?

Tọkọtaya: “Ọkọ àti aya ní láti jẹ́ olóòótọ́ sí ẹnì kìíní-kejì.”—Hébérù 13:4, TEV.

Nígbà tí wọ́n bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dájú pé yóò ṣàǹfààní fún ìgbésí ayé ìdílé. Ìwà panṣágà sábà máa ń fọ́ ìdílé. (Òwe 6:27-29, 32) Nítorí náà, lọ́nà ọgbọ́n, Bíbélì rọni pé: “Máa láyọ̀ pẹ̀lú aya rẹ kí o sì rí ìdùnnú nínú ọmọbìnrin tóo fi ṣaya . . . Èé ṣe tí o fi fẹ́ fún obìnrin mìíràn ní ìfẹ́ rẹ?”—Òwe 5:18-20, TEV.

Ẹ̀yin Òbí: “Ẹ tọ́ [àwọn ọmọ yín] ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí [wọn] yóò tọ̀.”—Òwe 22:6.

Nígbà tí àwọn òbí bá fún àwọn ọmọ ní àkókò àti àfiyèsí, ó dájú pé ìdílé yóò sunwọ̀n sí i. Nípa báyìí, Bíbélì rọ àwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn ìlànà títọ́ ‘nígbà tí wọ́n bá jókòó nínú ilé wọn àti nígbà tí wọ́n bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí wọ́n bá dìde.’ (Diutarónómì 11:19) Bíbélì sì tún sọ pé kí àwọn òbí fi hàn pé wọ́n fẹ́ràn àwọn ọmọ wọn nípa bíbá wọn wí.—Éfésù 6:4.

Ẹ̀yin Ọmọ: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa.”—Éfésù 6:1.

Lóòótọ́, nínú ayé aláìlófin yìí, kì í sábà rọrùn láti ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ. Síbẹ̀, o kò ha gbà pé ó bọ́gbọ́n mu láti ṣe ohun tí Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìdílé sọ fún wa bí? Ó mọ ohun tó dára jù lọ tí yóò mú kí ìgbésí ayé ìdílé wa túbọ̀ láyọ̀ sí i. Nítorí náà, gbìyànjú gidigidi láti ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ. Pinnu láti yàgò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdẹwò ayé tí ń múni ṣe ohun tó burú.—Òwe 1:10-19.

Bí olúkúlùkù nínú ìdílé bá ṣe fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò tó ni ìdílé yóò ṣe jàǹfààní tó. Kì í ṣe pé ìdílé yóò gbádùn ìgbésí ayé tó túbọ̀ dára sí i nísinsìnyí nìkan ni, yóò tún fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4) Nítorí náà, ẹ sọ ọ́ di àṣà pé kí ìdílé máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀! Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìdílé kárí ayé ni wọ́n ti rí i pé ìtọ́sọ́nà tí a pèsè nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé ṣàǹfààní gidigidi.

Bí a kò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí a fà yọ wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́