ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 4/1 ojú ìwé 6-8
  • Ìdílé—Ohun Kòṣeémánìí fún Ẹ̀dá Ènìyàn!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdílé—Ohun Kòṣeémánìí fún Ẹ̀dá Ènìyàn!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ilé Ni Ibi Ààbò
  • Ríran Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Láti Rù Ú Là
  • Ojú Tí Ó Yẹ Láti Fi Wo Owó
  • Ìníyelórí Ẹ̀kọ́ Bíbélì
  • Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Awọn Ìdílé Kristian Máa Ń Ṣe Nǹkan Papọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
    Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 4/1 ojú ìwé 6-8

Ìdílé—Ohun Kòṣeémánìí fún Ẹ̀dá Ènìyàn!

A MÁA ń sọ pé àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn ń láásìkí kìkì nígbà tí àwọn ìdílé inú rẹ̀ bá láásìkí. Ìtàn fi hàn pé bí ètò ìdílé ṣe ń díbàjẹ́, ni okun ẹgbẹ́ àwùjọ àti ti orílẹ̀-èdè ń yìnrìn. Nígbà tí ìwà rere àwọn ìdílé ní Gíríìkì ìgbàanì bà jẹ́, ọ̀làjú rẹ̀ fọ́ yángá, tí ó mú kí ó rọrùn fún àwọn ara Róòmù láti ṣẹ́gun rẹ̀. Ilẹ̀ Ọba Róòmù jẹ́ alágbára ní gbogbo ìgbà tí àwọn ìdílé tí ń bẹ nínú rẹ̀ fi jẹ́ alágbára. Ṣùgbọ́n bí àwọn ọ̀rúndún ti ń kọjá lọ, ìgbésí ayé ìdílé yìnrìn, okun ilẹ̀ ọba náà sì tán. Charles W. Eliot, ààrẹ Yunifásítì Harvard tẹ́lẹ̀ rí sọ pé: “Ààbò àti ìgbéga ìdílé àti ti ìgbésí ayé ìdílé ni olórí góńgó ọ̀làjú, òun sì ní góńgó akitiyan ẹ̀dá.”

Bẹ́ẹ̀ ni, ìdílé jẹ́ ohun kòṣeémánìí fún ẹ̀dá ènìyàn. Ó ní ipa tààràtà lórí ìdúró déédéé àwùjọ àti ire àwọn ọmọ àti ti ìran ọjọ́ iwájú. Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìyá anìkàntọ́mọ ń bẹ, tí ń ṣiṣẹ́ kára láti tọ́ àwọn ọmọ dáradára dàgbà, wọ́n sì yẹ fún oríyìn fún iṣẹ́ aláápọn tí wọ́n ń ṣe. Ṣùgbọ́n, ìwádìí fi hàn pé àwọn ọmọ máa ń ṣe dáradára jù bí wọ́n bá gbé nínú ìdílé tí ó ní òbí méjèèjì.

Ìwádìí kan tí a ṣe ní Australia nípa 2,100 aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà fi hàn pé “àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n wá láti inú ìdílé tí ó ti dàrú máa ń níṣòro ìlera ní gbogbogbòò, ó ṣeé ṣe dáradára kí wọ́n fi àmì ìṣòro èrò ìmọ̀lára hàn, ó sì ṣeé ṣe dáradára kí wọ́n jẹ́ oníṣekúṣe ju àwọn ọ̀dọ́ tí ó wá láti inú ìdílé tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ lọ.” Ìwádìí kan tí Àjọ Ìṣirò Ètò Ìlera ní United States ṣe ṣí i payá pé àwọn ọmọ tí ó wá láti inú ìdílé tí ó ti forí ṣánpọ́n fi “ìgbà 20 sí 30 nínú ọgọ́rùn-ún ṣeé ṣe kí wọ́n ko àgbákò ìjàǹbá, ìgbà 40 sí 75 nínú ọgọ́rùn-ún ṣeé ṣe kí wọ́n tú kíláàsì kan ká, àti ìgbà 70 nínú ọgọ́rùn-ún ṣeé ṣe kí a lé wọn kúrò ní ilé ẹ̀kọ́.” Ẹnì kan tí ń ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ìlànà sì ròyìn pé “ó ṣeé ṣe dáradára fún àwọn ọmọ tí ó wá láti inú ìdílé olóbìí kan láti lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn ju àwọn tí a tọ́ dàgbà nínú ìdílé aláṣà ìbílẹ̀ lọ.”

Ilé Ni Ibi Ààbò

Ètò ìdílé ń pèsè ilé aláyọ̀, agbéniró, àti alárinrin fún gbogbo mẹ́ńbà ìdílé. Ògbógi kan ní Sweden sọ pé: “Kì í ṣe iṣẹ́, àwọn nǹkan ìní, ìgbòkègbodò àfipawọ́ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ ni orísun pàtàkì ayọ̀ àti ìlera, bí kò ṣe ìdílé.”

Bíbélì fi hàn pé olúkúlùkù ìdílé lórí ilẹ̀ ayé gba orúkọ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá ìdílé, Jèhófà Ọlọ́run, ní ti pé òun ni ó dá ètò ìdílé sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:23, 24; Éfésù 3:14, 15) Ṣùgbọ́n, nínú Ìwé Mímọ́ tí a mí sí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ lílágbára kan tí yóò kọlu ìdílé, tí yóò yọrí sí àìsí ìwà rere mọ́ àti ìfọ́yángá àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí ó wà lẹ́yìn òde ìjọ Kristẹni. Ó sọ pé àìdúróṣinṣin, àìsí “ìfẹ́ni àdánidá,” àti ṣíṣàìgbọràn sí òbí, àní láàárín àwọn “tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run” pàápàá, yóò sàmì sí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Ó rọ àwọn Kristẹni láti yà kúrò lọ́dọ̀ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àtakò sí òtítọ́ Ọlọ́run yóò pín ìdílé níyà.—2 Tímótì 3:1-5; Mátíù 10:32-37.

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi wá sílẹ̀ láìsí ìrànwọ́. Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a pèsè ọ̀pọ̀ àyè fún ìtọ́ni lórí ìbátan ìdílé. Ó sọ fún wa bí a ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú ìdílé àti bí a ṣe lè sọ ilé di ibi ìdùnnú, níbi tí mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan ti ní ẹrú iṣẹ́ láti ṣe fún àwọn mẹ́ńbà yòókù.a—Éfésù 5:33; 6:1-4.

Ọwọ́ ha lè tẹ irú ìbátan aláyọ̀ bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí tí a ti wu ìdílé léwu gidigidi? Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè tẹ̀ ẹ́! O lè ṣàṣeyọrí nínú mímú kí ìdílé rẹ jẹ́ ọgbà eléwéko títutù yọ̀yọ̀, tí ń gbádùn mọ́ni, tí ó sì ń tuni lára nínú ayé tí ó dà bí aṣálẹ̀ líle koránkorán yìí. Ṣùgbọ́n èyí ń béèrè ohun kan lọ́wọ́ olúkúlùkù mẹ́ńbà ìdílé. Àwọn àbá díẹ̀ ni ó tẹ̀ lé e yìí.

Ríran Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Láti Rù Ú Là

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí ó dára jù lọ tí ìdílé lè gbà máa bá a lọ láti wà níṣọ̀kan ni nípa lílo àkókò pọ̀. Kí gbogbo mẹ́ńbà jọ fi tọkàntọkàn lo àkókò gbẹ̀fẹ́ wọn pa pọ̀. Ìyẹn lè béèrè ìrúbọ. Fún àpẹẹrẹ, ẹ̀yin ọ̀dọ́langba lè ní láti fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tí ẹ gbádùn jù lọ, eré ìmárale, tàbí jíjáde lọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ yín rúbọ. Ẹ̀yin bàbá, tí ó jẹ́ ẹ̀yin ni olórí olùgbọ́ bùkátà ìdílé lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ má ṣe lo àkókò gbẹ̀fẹ́ yín kìkì fún ìgbòkègbodò àfipawọ́ tàbí fún àwọn ohun mìíràn tí ẹ lọ́kàn ìfẹ́ sí. Ẹ wéwèé ìgbòkègbodò pẹ̀lú ìdílé yín, bóyá bí ẹ óò ti lo òpin ọ̀sẹ̀ tàbí àkókò ìsinmi pa pọ̀. Dájúdájú, ẹ wéwèé ohun kan tí gbogbo yín yóò máa wọ̀nà fún, tí ẹ óò sì gbádùn.

Ohun tí àwọn ọmọ nílò ju ohun tí a ń pè ní ojúlówó àkókò, ìyẹn ni, ṣíṣètò lílo nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú pẹ̀lú àwọn ọmọ lóòrèkóòrè. Wọ́n nílò àkókò tí ó jọjú. Akọ̀ròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde kan ní Sweden kọ̀wé pé: “Láàárín ọdún 15 tí mo ti lò gẹ́gẹ́ bí oníròyìn, mo ti ṣalábàápàdé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ tí ó ti ya pòkíì . . . Ohun kan tí ó wọ́pọ̀ láàárín wọn ni pé, ó jọ bí pe ojúlówó àkókò nìkan ni àwọn òbí wọ́n lò pẹ̀lú wọn: ‘Àwọn òbí mi kò ráyè.’ ‘Wọn kò tẹ́tí sílẹ̀ rí.’ ‘Gbogbo ìgbà ni bàbá ń rìnrìn àjò.’ . . . Gẹ́gẹ́ bí òbí kan, o lómìnira láti yan iye àkókò tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú ọmọ rẹ. Ọmọ ọlọ́dún 15 kan tí kò lójú àánú ni yóò gbé yíyàn tí o ṣe yẹ̀wò ní ọdún 15 lẹ́yìn náà.”

Ojú Tí Ó Yẹ Láti Fi Wo Owó

Ó yẹ kí gbogbo mẹ́ńbà ìdílé tún ní ojú ìwòye yíyẹ nípa owó. Ó yẹ kí wọ́n múra tán láti pawọ́ pọ̀ kájú ìnáwó ìdílé. Ọ̀pọ̀ obìnrin ní láti wáṣẹ́ kí awọ lè kájú ìlù, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ẹ̀yin aya wà lójúfò sí ewu àti àdánwò tí ẹ lè bá pàdé. Ayé yìí ń rọ̀ yín láti lé “góńgó” yín “bá,” kí ẹ sì “ṣe ohun tí ó wù yín.” Ó lè jẹ́ kí ẹ wà ní dáńfó, kí ó sì mú kí ipa tí Ọlọ́run fún yín láti kó gẹ́gẹ́ bí ìyá àti olùtọ́jú ilé má tẹ yín lọ́rùn.—Títù 2:4, 5.

Bí ẹ̀yin ìyá bá lè máa wà nílé, kí ẹ sì máa jẹ́ atọ́nà àti ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ yín, ó dájú pé yóò fi kún ìdè lílágbára tí yóò ṣèrànwọ́ ní mímú kí ìdílé yín wà pa pọ̀ láìka làásìgbò èyíkéyìí sí. Obìnrin lè ṣe ohun títayọ láti mú kí ilé jẹ́ aláyọ̀, tí ń fọkàn ẹni balẹ̀, tí ó sì gbéṣẹ́. Òṣèlú ọ̀rúndún kọkàndínlógún kan sọ pé: “Yóò gba ọgọ́rùn-ún ọkùnrin láti kọ́ ibùdó kan, ṣùgbọ́n obìnrin kan ṣoṣo lè kọ́ agboolé.”

Bí gbogbo mẹ́ńbà ìdílé bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti máà ná ju iye tí ń wọlé fún wọn lọ, ìdílé yóò bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Ó yẹ kí tọkọtaya gbà láti gbé ìgbésí ayé ṣe-bí-o-ti-mọ, kí wọ́n sì fi ire tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́. Kí àwọn ọmọ kọ́ bí a ti ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, kí wọ́n má máa béèrè ohun tí apá ìdílé kò ká. Ẹ ṣọ́ra fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú! Ìdẹwò ríra àwọn ohun tí agbára kò ká, kíkó sínú gbèsè, ti ri ọkọ̀ ọ̀pọ̀ ìdílé. Ó lè dára fún ìṣọ̀kan ìdílé bí gbogbo mẹ́ńbà ìdílé bá pa owó wọn pọ̀ ṣe ohun kan—rírìnrìn àjò afẹ́, ríra ẹ̀rọ wíwúlò, tí yóò sì gbádùn mọ́ni sílé, tàbí ọrẹ fún ṣíṣètìlẹ́yìn fún ìjọ Kristẹni.

Irú “ọrẹ” mìíràn tí yóò fi kún ẹ̀mí ayọ̀ ìdílé, tí ó yẹ kí gbogbo mẹ́ńbà ìdílé pawọ́ pọ̀ ṣe ni lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ títún nǹkan ṣe àti bíbójútó nǹkan—títọ́jú ilé, ọgbà, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. A lè yan iṣẹ́ fún mẹ́ńbà ìdílé kọ̀ọ̀kan, títí kan àwọn tí ó kéré jù pàápàá. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbìyànjú láti má ṣe fi àkókò yín ṣòfò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ mú ẹ̀mí ṣíṣèrànwọ́ àti fífọwọ́sowọ́pọ̀ dàgbà; èyí yóò yọrí sí ojúlówó ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àti ìfararora, tí ń gbé ìṣọ̀kan ìdílé ró.

Ìníyelórí Ẹ̀kọ́ Bíbélì

Nínú ìdílé Kristẹni tí ìṣọ̀kan wà, a tún máa ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Jíjíròrò àwọn ẹsẹ Bíbélì lójoojúmọ́ àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ń pèsè ìpìlẹ̀ fún ìṣọ̀kan ìdílé. Ó yẹ kí a jíròrò àwọn òtítọ́ àti ìlànà Bíbélì ṣíṣe kókó pa pọ̀ lọ́nà tí yóò ru ọkàn gbogbo mẹ́ńbà ìdílé sókè.

Ó yẹ kí irú àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé bẹ́ẹ̀ kún fún ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n kí ó tún gbádùn mọ́ni, kí ó sì gbéni ró. Ìdílé kan ní àríwá Sweden ń jẹ́ kí àwọn ọmọ kọ àwọn ìbéèrè tí ó jẹ yọ láàárín ọ̀sẹ̀ sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọn yóò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìbéèrè náà máa ń lágbára, wọ́n máa ń múni ronú jinlẹ̀ dáradára, wọ́n sì ń ṣàfihàn bí agbára ìrònú àwọn ọmọ náà àti ìmọrírì tí wọ́n ní fún àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ti tó. Díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè náà nìwọ̀nyí: “Jèhófà ha ń mú kí gbogbo nǹkan dàgbà ní gbogbo ìgbà, àbí ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ó ṣe é?” “Èé ṣe tí Bíbélì fi sọ pé Ọlọ́run dá ènìyàn ‘ní àwòrán rẹ̀’ níwọ̀n bí Ọlọ́run kì í tií ṣe ènìyàn?” “Ṣé òtútù kò pa Ádámù àti Éfà kú nígbà ọ̀gìnnìtìn nínú Párádísè, níwọ̀n bí wọn kò ti wọ bàtà, tí wọn kò sì láṣọ?” “Èé ṣe tí a fi nílò òṣùpá lálẹ́ nígbà tí ó yẹ kí gbogbo nǹkan ṣókùnkùn?” Nísinsìnyí, àwọn ọmọ náà ti dàgbà, wọ́n sì ń sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Nígbà tí ẹ bá ń bójú tó ìṣòro ìdílé, yóò dára bí ẹ̀yin òbí bá làkàkà láti jẹ́ olùfojúsọ́nà fún rere, kí ẹ sì ṣọ̀yàyà. Ẹ jẹ́ ẹni tí ń gba tẹni rò, tí ó sì lè tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, síbẹ̀ kí ẹ jẹ́ aláìgbagbẹ̀rẹ́, nígbà tí ó bá kan ṣíṣègbọràn sí àwọn ìlànà pàtàkì. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ rí i nígbà gbogbo pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún àwọn ìlànà títọ́ rẹ̀ ní ń darí ìpinnu tí ẹ ń ṣe. Àyíká ipò ní ilé ẹ̀kọ́ sábà máa ń fa másùnmáwo àti ìsoríkọ́, àwọn ọmọ sì nílò ìṣírí púpọ̀ nínú ilé láti ṣẹ́pá irú agbára tí ń nípa lórí ẹni bẹ́ẹ̀.

Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe díbọ́n pé ẹ jẹ́ ẹni pípé. Ẹ gba àṣìṣe yín, kí ẹ sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín nígbà tí ó bá pọndandan. Ẹ̀yin ọ̀dọ́, nígbà tí Mọ́mì àti Dádì bá gba àṣìṣe wọn, ẹ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn.—Oníwàásù 7:16.

Bẹ́ẹ̀ ni, ìdílé oníṣọ̀kan ń pèsè agboolé alálàáfíà, aláàbò, àti aláyọ̀. Akéwì ọmọ ilẹ̀ Germany náà, Goethe, sọ nígbà kan pé: “Ẹni tí ilé rẹ̀ bá ń mú inú rẹ̀ dùn, òun ni ó jẹ́ aláyọ̀ jù lọ, ì báà jẹ́ ọba tàbí gbáàtúù.” Fún àwọn òbí àti àwọn ọmọ tí ó mọrírì, kò yẹ kí ó sí ibi tí ó dàbí ilé.

Lóòótọ́, àwọn pákáǹleke inú ayé tí a ń gbé yìí ń wu ìdílé léwu gan-an. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí ìdílé ti wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, yóò rù ú là. Ìdílé rẹ yóò rù ú là, ìwọ pẹ̀lú yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀, bí o bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà òdodo tí Ọlọ́run fún wa fún ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé sí i lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí, wo ìwé olójú ewé 192 náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́