ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 4/1 ojú ìwé 3-5
  • Ìdílé—Ọ̀ràn Ti Dé Bá A!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdílé—Ọ̀ràn Ti Dé Bá A!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ewu Náà?
  • Agboolé Olóbìí Kan Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I
  • Ṣé Ìjì Tó Ń Jà Yìí Ò Ní Í Gbé Ìgbéyàwó Lọ?
    Jí!—2006
  • Híhá Sínú Ìgbéyàwó Aláìnífẹ̀ẹ́
    Jí!—2001
  • Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I
    Jí!—2002
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 4/1 ojú ìwé 3-5

Ìdílé—Ọ̀ràn Ti Dé Bá A!

“WỌ́N sì fi ayọ̀ gbé ìgbésí ayé wọn títí láé lẹ́yìn náà.” Àwọn ìgbéyàwó tí ọ̀ràn wọ́n rí bí òpin ìtàn àròsọ yẹn ti sọ túbọ̀ ń dínkù sí i lónìí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni ìlérí tí wọ́n ń ṣe nígbà ìgbéyàwó láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn ‘nígbà adùn àti nígbà ìṣòro, níwọ̀n ìgbà tí àwọn méjèèjì bá wà láàyè.’ Ṣíṣeéṣe láti ní ìdílé aláyọ̀ dàbí ohun tí kò ṣeé ṣe rárá.

Láàárín ọdún 1960 sí 1990, ìkọ̀sílẹ̀ ti fi iye tí ó lé ní ìlọ́po méjì lọ sókè ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè oníṣẹ́ ẹ̀rọ ní Ìwọ̀ Oòrùn. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n ti lọ sókè ní ìlọ́po mẹ́rin. Fún àpẹẹrẹ, lọ́dọọdún, nǹkan bí 35,000 ìgbéyàwó ni a ń ṣe ní Sweden, nǹkan bí ìdajì nínú wọn yóò sì forí ṣánpọ́n, tí yóò sì kan àwọn ọmọ tí ó lé ní 45,000. Iye àwọn ẹni méjì tí ń gbé pa pọ̀ láìṣègbéyàwó, tí ń fira wọn sílẹ̀, ju ìyẹn lọ pàápàá, ó sì ń nípa lórí ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọmọ púpọ̀ sí i. Irú ìtẹ̀sí kan náà ń jẹyọ ní àwọn orílẹ̀-èdè jákèjádò ayé, bí a ti lè rí i nínú àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 5.

Òtítọ́ ni pé, ìdílé tí ó tú ká àti ìforíṣánpọ́n ìgbéyàwó kì í ṣe ohun tuntun nínú ìtàn. Ìwé Òfin Hammurabi ti ọ̀rúndún kejìdínlógún ṣááju Sànmánì Tiwa, ní àwọn òfin tí ó fọwọ́ sí ìkọ̀sílẹ̀ ní Babilóníà nínú. Àní Òfin Mósè pàápàá, tí a gbé kalẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ṣááju Sànmánì Tiwa, fàyè gba ìkọ̀sílẹ̀ ní Ísírẹ́lì. (Diutarónómì 24:1) Ṣùgbọ́n, kò tíì sí ìgbà kan nínú ìtàn tí ìdè ìdílé ń tú tó ọ̀rúndún ogún tí a wà yìí. Ní ohun tí ó lé ní ẹ̀wádún kan sẹ́yìn, akọ̀ròyìn kan kọ̀wé pé: “Ní 50 ọdún sí ìgbà tí a wà yìí, a tilẹ̀ lè má ní ìdílé kankan nínú èrò ti àṣà ìbílẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ oríṣiríṣi mìíràn ti lè rọ́pò wọn.” Ó sì jọ bí pé àwọn ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ láti ìgbà náà wá fìdí èrò rẹ̀ múlẹ̀. Ètò ìdílé ti jájòórẹ̀yìn débi pé ìbéèrè náà, “Yóò ha rù ú là bí?” túbọ̀ ń di èyí tí ó ṣe pàtàkì.

Èé ṣe tí ó fi ṣòro gan-an fún ọ̀pọ̀ tọkọtaya láti fà mọ́ ara wọn, kí wọ́n sì pa ìṣọ̀kan ìdílé mọ́? Kí ni àṣírí àwọn tí ó ti fà mọ́ ara wọn fún àkókò gígùn, tí wọ́n ń fayọ̀ ṣayẹyẹ ọdún kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí àádọ́ta ọdún ìgbéyàwó wọn? Lọ́nà tí ó ṣe kòńgẹ́, ní 1983, a ròyìn pé ọkùnrin kan àti obìnrin kan ní orílẹ̀-èdè olómìnira Azerbaijan ti Soviet tẹ́lẹ̀rí, ṣayẹyẹ ọgọ́rùn-ún ọdún ìgbéyàwó wọn—nígbà tí ọkọ jẹ́ ẹni ọdún 126, tí ayá sì jẹ́ ẹni ọdún 116.

Kí Ni Ewu Náà?

Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, panṣágà, gbígbẹ́mìí ẹni gbóná tàbí ṣíṣeniléṣe, fífinisílẹ̀, ìmukúmu, jíjẹ́ akúra, orí yíyí, àìjáwèé ìkọ̀sílẹ̀ nínú ìgbéyàwó àkọ́kọ́, àti ìjoògùnyó jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ìdí fún ìkọ̀sílẹ̀ tí a gbé karí òfin. Ṣùgbọ́n, ìdí tí ó túbọ̀ wọ́pọ̀ ni pé ẹ̀mí ìrònú àtijọ́ tí àwọn ènìyàn ní sí ìgbéyàwó àti ìgbésí ayé ìdílé aláṣà ìbílẹ̀ ti yí padà pátápátá, pàápàá ní àwọn ẹ̀wádún bí mélòó kan sẹ́yìn. Ọ̀wọ̀ fún ètò tí a kà sí mímọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún ti yìnrìn. Àwọn oníwọra tí ń gbé orin jáde, tí ń ṣe sinimá, eré orí tẹlifíṣọ̀n, àti àwọn ìwé ìtàn gbígbajúmọ̀ ti gbé ohun tí wọ́n pè ní òmìnira ìbálòpọ̀, ìwà pálapàla, ìwà àìníjàánu, àti ìgbésí ayé anìkànjọpọ́n lárugẹ. Wọ́n ti gbé àṣà kan tí ó ti sọ èrò orí àti ọkàn-àyà tọmọdé tàgbà dẹlẹ́gbin ga.

Ìwádìí kan tí a ṣe ní ọdún 1996 fi hàn pé ìpín 22 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Amẹ́ríkà sọ pé, nígbà mìíràn, níní ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó lè ṣe ìgbéyàwó láǹfààní. Àkànṣe ẹ̀dà ọ̀kan nínú àwọn ìwé agbéròyìnjáde tí ó tà jù lọ ní ilẹ̀ Sweden, Aftonbladet, rọ àwọn obìnrin láti kọ ọkọ́ wọn sílẹ̀ nítorí “yóò mú ipò rẹ sunwọ̀n si.” Àwọn afìṣemọ̀rònú àti afìṣemọ̀wà inú ilé iṣẹ́ ìròyìn kan tilẹ̀ ti sọ pé ẹfolúṣọ̀n ti “ṣe” ènìyàn láti pààrọ̀ alábàáṣègbéyàwó lẹ́yìn ọdún díẹ̀. Ní èdè mìíràn, wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ pé ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀ jẹ́ ohun tí a ti dá mọ́ wa. Àwọn kan tilẹ̀ ń ṣàlàyé pé ìkọ̀sílẹ̀ àwọn òbí lè ṣe àwọn ọmọ láǹfààní, ó lè múra wọn sílẹ̀ láti kojú ìkọ̀sílẹ̀ tiwọn fúnra wọn lọ́jọ́ ọ̀la!

Ọ̀pọ̀ èwe kò nífẹ̀ẹ́ sí gbígbé ìgbésí ayé ìdílé aláṣà ìbílẹ̀ mọ́, ti bàbá, ìyá, àti àwọn ọmọ. Ojú ìwòye tí ó wọ́pọ̀ kan ni pé, “N kò lè ronú kan gbígbé pẹ̀lú alábàáṣègbéyàwó kan ṣoṣo jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé mi.” Ọmọkùnrin ọlọ́dún 18 kan, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark, sọ pé: “Ìgbéyàwó dà bí Kérésìmesì, ìtàn àròsọ kan lásán ni. N kò nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ rárá.” Noreen Byrne, ti Ìgbìmọ̀ Àwọn Obìnrin Jákèjádò Orílẹ̀-Èdè Ireland, sọ pé: “Èrò náà ni pé, èé ṣe tí o fi ń yọ ara rẹ lẹ́nu láti gbé pẹ̀lú [àwọn ọkùnrin], kí o sì máa fọ ìbọ̀sẹ̀ wọn. Kàn bá wọn jáde, kí o sì gbádùn ara rẹ pẹ̀lú wọn . . . Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ń pinnu pé àwọn kò nílò ọkùnrin láti lè gbáyé.”

Agboolé Olóbìí Kan Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I

Ẹ̀mí ìrònú yìí ti fa ìlọsókè yíyára kánkán nínú iye ìyá anìkàntọ́mọ jákèjádò Yúróòpù. Àwọn kan lára àwọn òbí anìkàntọ́mọ wọ̀nyí jẹ́ ọ̀dọ́langba, tí wọ́n ronú pé gbígboyún kì í ṣàṣìṣe. Àwọn mìíràn jẹ́ àwọn obìnrin tí wọ́n fẹ́ dá tọ́ ọmọ wọn. Èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú wọ́n jẹ́ àwọn ìyá tí wọ́n gbé pẹ̀lú bàbá ọmọ wọn fún ìgbà díẹ̀, láìwéèwé láti ṣègbéyàwó pẹ̀lú rẹ̀. Ní ọdún tí ó kọjá, ìwé ìròyìn Newsweek gbé àkọlé kan jáde lójú ìwé rẹ̀, tí ó béèrè pé, “Ìgbéyàwó Ha Ń Kú Lọ Bí?” Ó sọ pé iye àwọn ọmọ tí a ń bí sẹ́yìn òde ìgbéyàwó ń ròkè lálá ní Yúróòpù, kò sì dàbí ẹni pé àwọn ènìyàn bìkítà nípa rẹ̀. Ó jọ pé Sweden ni ó gbapò kìíní, ìdajì gbogbo ọmọ tí a ń bí níbẹ̀ ni a ń bí sẹ́yìn òde ìgbéyàwó. Ní Denmark àti Norway, ó súnmọ́ ìdajì, ní ilẹ̀ Faransé àti England, nǹkan bí 1 nínú 3.

Ní United States, ìdílé olóbìí méjì ti lọ sílẹ̀ dòò ní àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn. Ìròyìn kan sọ pé: “Ní ọdún 1960, . . . 9 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ọmọ ni ó ń gbé nínú ilé olóbìí kan. Nígbà tí yóò fi di ọdún 1990, iye náà ti fò sókè sí 25 nínú ọgọ́rùn-ún. Lónìí, 27.1 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ọmọ ní Amẹ́ríkà ni a ń bí sínú ilé olóbìí kan, iye náà sì túbọ̀ ń ròkè sí i. . . . Láti ọdún 1970, iye ìdílé olóbìí kan ti ròkè ní iye tí ó ju ìlọ́po méjì. Àwọn olùwádìí kan sọ pé, a ń wu ìdílé aláṣà ìbílẹ̀ léwu lónìí débi pé ó lè wà ní bèbè ìparun ráúráú.”

Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ti sọ èyí tí ó pọ̀ jù nínú àṣẹ tí ó ní lórí ìwà rere ènìyàn nù, ìdílé olóbìí kan túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Iye tí ó dín sí ìdajì agboolé àwọn ará Ítálì ni ó ní ìyá, bàbá, àti àwọn ọmọ, tí àwọn tọkọtaya tí kò bímọ àti agboolé olóbìí kan sì ti rọ́pò ìdílé aláṣà ìbílẹ̀.

Ní ti gidi, ètò afẹ́nifẹ́re ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ń fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti má ṣègbéyàwó. Àwọn ìyá anìkàntọ́mọ, tí ń gba ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ ìjọba, kì yóò rí i gbà mọ́ bí wọ́n bá lọ sílé ọkọ. Àwọn ìyá anìkàntọ́mọ ní Denmark ń gba àfikún owó lọ́wọ́ ìjọba láti fi tọ́jú ọmọ wọn, ní àwọn àwùjọ kan, a máa ń fún àwọn ìyá tí kò tójú bọ́ ní àfikún owó, a sì máa ń bá wọn sanwó ilé wọn. Nítorí náà, ọ̀ràn owó so mọ́ ọn. Alf B. Svensson sọ pé ìkọ̀sílẹ̀ ní Sweden ń ná àwọn tí ń san owó orí ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún 250 sí ẹgbẹ̀rún 375 dọ́là, owó ilé, àti ìrànlọ́wọ́ gbogbogbòò.

Ó jọ bí pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù kò ṣe ohunkóhun láti yí ìtẹ̀sí burúkú yìí padà láàárín ìdílé. Ọ̀pọ̀ pásítọ̀ àti àlùfáà ń bá yánpọnyánrin inú ìdílé àwọn fúnra wọn jìjàkadì, nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n nímọ̀lára pé àwọn kò tóótun láti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Ó jọ bí pé àwọn kan tilẹ̀ ń gbé ìkọ̀sílẹ̀ lárugẹ. Ìwé agbéròyìnjáde Aftonbladet ti April 15, 1996, ròyìn pé pásítọ̀ Steven Allen láti Bradford, England, ṣàkójọ ọ̀rọ̀ fún àkànṣe ààtò ìkọ̀sílẹ̀, tí ó sọ pé a óò máa lò fún ààtò ìsìn ìkọ̀sílẹ̀ ní gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Britain. “Ààtò ìmúláradá ni, tí yóò ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gba ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, kí wọ́n sí mú ara wọn bá ipò náà mu. Yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Ọlọ́run ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn, yóò sì mú ìbànújẹ́ náà kúrò.”

Nítorí náà, ibo ni ètò ìdílé ń forí lé? Ìrètí ha wà pé yóò rù ú là bí? Ìdílé kọ̀ọ̀kan ha lè pa ìṣọ̀kan wọn mọ́ lábẹ́ irú ìwuléwu ńlá bẹ́ẹ̀? Jọ̀wọ́, gbé àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yẹ̀ wò.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 5]

IYE ÌGBÉYÀWÓ NÍ ÌFIWÉRA PẸ̀LÚ IYE ÌKỌ̀SÍLẸ̀ LỌ́DÚN NÍ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ KAN

ORÍLẸ̀-ÈDÈ ỌDÚN ÌGBÉYÀWÓ ÌKỌ̀SÍLẸ̀

Australia 1993 113,255 48,324

Cuba 1992 191,837 63,432

Czech Republic 1993 66,033 30,227

Denmark 1993 31,507 12,991

Estonia 1993 7,745 5,757

Faransé 1991 280,175 108,086

Germany 1993 442,605 156,425

Japan 1993 792,658 188,297

Kánádà 1992 164,573 77,031

Maldives 1991 4,065 2,659

Norway 1993 19,464 10,943

Puerto Rico 1992 34,222 14,227

Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà 1993 1,106,723 663,282

Sweden 1993 34,005 21,673

United Kingdom 1992 356,013 174,717

United States 1993 2,334,000 1,187,000

(A gbé e karí ìwé 1994 Demographic Yearbook, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, New York 1996)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́