Ṣé Ìjì Tó Ń Jà Yìí Ò Ní Í Gbé Ìgbéyàwó Lọ?
“Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—MÁTÍÙ 19:6.
ÀWỌN ilé yẹn dúró dáadáa lójú, àfi lójijì tí ìpìlẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í mì jìgìjìgì tí wọ́n sì dà wó látòkèdélẹ̀. Ìjì abàmì tó jà káàkiri ibi tó pọ̀ lágbàáyé láìpẹ́ yìí fọwọ́ ba àwọn ilé tí wọ́n kọ́ sáwọn ibi tó ti jà. Ìjì ọ̀hún lágbára gan-an ni, ó fi báwọn ilé ọ̀hún ṣe dúró gbọn-in gbọn-in tó hàn.
Àmọ́ irú ìjì kan wà tó ń jà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Ètò ìgbéyàwó tó ti wà láti ìgbà ìwáṣẹ̀ ló ń rọ́ lù. Òpìtàn Stephanie Coontz, tó máa ń pìtàn nípa ètò ìdílé, sọ pé: “Ọ̀rọ̀ pé ọjọ́ dídùn àtọjọ́ kíkan ni ìgbéyàwó wà fún ti kúrò lọ́kàn àwọn èèyàn, kò sì ṣe pàtàkì mọ́ láwùjọ.”
Ǹjẹ́ o ti rí nǹkan tí ìyẹn ń fà báyìí? Ṣéwọ náà ti rí i pé ìgbéyàwó ò sí nípò ọ̀wọ̀ tó wà látijọ́ mọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló fà á tó fi rí báyìí? Ìrètí wo ló sì wà pé èèyàn á rẹ́ni bá ṣe ìgbéyàwó tí ò ní í forí ṣánpọ́n tàbí pé ìgbéyàwó náà á dùn bí oyin? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ogun wo ló ń ja ìgbéyàwó?
Ogun Tó Ń Ja Ìgbéyàwó
Ogun tó ń ja ìgbéyàwó kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀; ó ti wà látìgbà ìwáṣẹ̀. Ànímọ́ àwọn èèyàn tó jẹ́ òbí wa àkọ́kọ́ àti ìwà wọn ló dá wàhálà tá à ń rí tó ń kojú ìdílé lóde òní sílẹ̀. Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n gba ìmọtara-ẹni-nìkan láàyè, ẹ̀ṣẹ̀ sì tipa bẹ́ẹ̀ “wọ ayé.” (Róòmù 5:12) Ìtàn tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kété lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ yẹn ló di pé “gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà” èèyàn di “kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:5.
Nǹkan ò tíì fi bẹ́ẹ̀ yí padà látìgbà náà wá. Lára àwọn ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà tó ń ṣàkóbá fún ìgbéyàwó ni bó ṣe jẹ́ pé bí kálukú ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn ní gbogbo ọ̀nà ló gbájú mọ́. Ó dà bíi pé aráyé ò ṣe ìgbéyàwó mọ́ láyé òde òní, wọn ò sì kà á sí ohun tó bóde mu mọ́ torí pé ọ̀nà ìwà híhù tuntun ló gbayì lójú wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni bí wọ́n ṣe dẹwọ́ òfin tó wà lórí títú ìgbéyàwó ká ti mú ìtìjú tó máa ń rọ̀ mọ́ ìkọ̀sílẹ̀ kúrò.
Àwọn kan tí wọn ò ní sùúrù, tí wọ́n máa ń fẹ́ kí nǹkan yanjú kíákíá, tí wọ́n sì ń wá ìgbádùn ojú ẹsẹ̀, kì í fi bẹ́ẹ̀ ronú lórí ohun tó máa tẹ̀yìn ìkọ̀sílẹ̀ wá, ìyẹn bí wọ́n bá tiẹ̀ ronú nípa ẹ̀ rárá. Nígbà tó sì ti di pé wọ́n á lómìnira tí ò sì sẹ́ni táá máa yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò tí wọ́n bá kọra wọn sílẹ̀, wọ́n gbà pé táwọn bá kọ ọkọ tàbí aya àwọn, ìgbádùn ti tó àwọn lọ́wọ́ nìyẹn.
Nígbà tí ìṣòro tó dà bí ẹ̀gún bá dé bá ìgbéyàwó àwọn míì, àwọn dókítà àtàwọn agbaninímọ̀ràn lórí ìgbéyàwó ni wọ́n máa ń sá tọ̀ lọ tàbí kí wọ́n máa ka àwọn ìwé táwọn wọ̀nyẹn kọ. Ó bani nínú jẹ́ pé ìmọ̀ràn nípa ìkọ̀sílẹ̀ ló dùn lẹ́nu àwọn tí wọ́n ń pè ní akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa ìgbéyàwó ju ìmọ̀ràn lórí bí ìgbéyàwó ò ṣe ní forí ṣánpọ́n lọ. Ìwé The Case for Marriage sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé nínú ìtàn ẹ̀dà èèyàn tí ìgbéyàwó, tó máa ń wuni í ṣe, máa di ohun tí ogun alénimádẹ̀yìn ń dojú kọ, ó sì ń yani lẹ́nu pé ogun náà máa ń borí rẹ̀. Nígbà míì sì rèé, tààràtà logun náà máa ń dojú kọ ìgbéyàwó, tó sì máa ń jẹ́ pé èrò àwọn tí wọ́n ń pè ní akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ táwọn èèyàn ń tẹ̀ lé ló fà á. Ìgbàgbọ́ irú àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni pé kéèyàn fi tinútinú wà nínú ìgbéyàwó kan títí ayé ẹ̀ kì í ṣara ẹ̀, bí ìgbà téèyàn bá kàn de ara ẹ̀ mọ́lẹ̀ ni.”
Ìrònú Àwọn Èèyàn Ti Yí Padà
Ìrònú àwọn èèyàn nípa ohun tó ń jẹ́ ìgbéyàwó àti ohun tó wà fún pàápàá ti yí padà. Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ gbà mọ́ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn dúró gbágbáágbá ti ọkọ tàbí ìyàwó ẹ̀, ohun tí wọ́n ń kà sí pàtàkì ni àǹfààní tí kálukú á rí nínú ìgbéyàwó, ì báà tiẹ̀ pa ẹni tí wọ́n bá ṣègbéyàwó lára. Ìwé ìròyìn Journal of Marriage and Family sọ pé: “Àárín ọdún 1960 sí 1970 ló di pé àwọn èèyàn ki irú ìmọtara ẹni nìkan yìí bọnú ìgbéyàwó, àárín ọdún 1970 sí 1980 ló sì wá peléke sí i.” Àwọn ìdí táwọn èèyàn fi ń ṣègbéyàwó ò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́. Ohun tó ń sún àwọn èèyàn ṣègbéyàwó, ìyẹn ìfẹ́, àjọṣe tímọ́tímọ́, ìfòtítọ́-bára-lò, ọmọ bíbí àti ìgbádùn tọ̀túntòsì, ò fi bẹ́ẹ̀ jẹ wọ́n lógún mọ́.
Ọ̀pọ̀ nǹkan míì wà tó ń mú kí ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìgbéyàwó yí padà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ọ̀kan ni pé, tẹ́lẹ̀ ọkùnrin ló máa ń lọ wá nǹkan tí gbogbo ilé á jẹ wá nígbà tí obìnrin á sì máa tọ́jú ilé. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Nígbà táwọn obìnrin náà ti ń wáṣẹ́ lọ síta báyìí, ó ti di pé kí ìdílé tí tọkọtaya ti ń ṣiṣẹ́ máa pọ̀ sí i. Èkejì ni pé àwọn èèyàn ti fara mọ́ ọn báyìí pé èèyàn lè bímọ láìsí nílé ọkọ, ó sì ti mú káwọn òbí tó ń nìkan tọ́mọ pọ̀ sí i. Ẹ̀kẹta, àwọn èèyàn tó ń fi àjọgbé láìṣe ìgbéyàwó rọ́pò ṣíṣègbéyàwó ń pọ̀ sí i. (Wo àpótí náà, “Kì í Fìdí Múlẹ̀ Tó Ìgbéyàwó.”) Ẹ̀kẹrin ni pé ìgbéyàwó láàárín ọkùnrin pẹ̀lú ọkùnrin àti obìnrin pẹ̀lú obìnrin ti wọ́pọ̀ báyìí, àwọn tó sì ń jà pé kí wọ́n fàyè gbà á lábẹ́ òfin náà ń pọ̀ sí i. Ǹjẹ́ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí ò ti máa nípa lórí ojú tó o fi ń wo ìgbéyàwó?
Ìkọ̀sílẹ̀ Di Mẹ́ta Kọ́bọ̀
Ẹ jẹ́ ká wo àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan, ká wá rí bí ìkọ̀sílẹ̀ tó di nǹkan iyì ṣe ń jin ìgbéyàwó lẹ́sẹ̀. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan ṣe sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, “iye àwọn tọkọtaya tó kọra wọn sílẹ̀ ti fi ìlọ́po mẹ́rin lọ sókè sí i láàárín ọdún 1970 sí ọdún 1996.” Á tó ẹnì kan nínú márùn-ún lára àwọn tí kì í ṣọmọdé tí ìgbéyàwó wọn ti forí ṣánpọ́n. Àwọn wo ló ṣeé ṣe jù lọ pé kí ìgbéyàwó wọn forí ṣánpọ́n? Ìwádìí tí wọ́n fi ìṣirò ṣe fi hàn pé ìdá mẹ́ta nínú márùn-ún àwọn tí wọ́n kọra wọn sílẹ̀ ni wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín ọdún mẹ́wàá tí wọ́n fẹ́ra wọn sílé.
A tún rí àwọn orílẹ̀-èdè míì tí iye àwọn tó ń kọra wọn sílẹ̀ ti ròkè sí i. Lọ́dún 2004, ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàléláàádọ́jọ, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó dín mẹ́wàá [153,490] làwọn tó kọra wọn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Wales àti England nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ìwádìí fi hàn pé àfi káwọn ará Ọsirélíà máa retí pé ìgbéyàwó méjì nínú márùn-ún níbẹ̀ máa tú ká. Láàárín ọdún 2002 sí 2003 nìkan ṣoṣo, àwọn tó ń kọra wọn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Kòríà fi ọ̀kẹ́ kan àti ẹgbẹ̀sán [21,800] pọ̀ sí i, ìyẹn sì mú kí iye tọkọtaya tó kọra sílẹ̀ lọ́dún yẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàdínláàádọ́sàn-án ó lé ọgọ́rùn-ún [167,100]. Lórílẹ̀-èdè Japan níbi tí ìkọ̀sílẹ̀ ti ń fòpin sí ìgbéyàwó kan nínú mẹ́rin, iye ìkọ̀sílẹ̀ tó wà níbẹ̀ náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ti Yúróòpù. “Nígbà kan rí, àwọn ìgbéyàwó tó ti burú pátápátá nìkan ló máa ń yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí ilé ìwé gíga ti ẹgbẹ́ alágbèélébùú pupa ilẹ̀ Japan, ìyẹn Japan Red Cross University, ṣe sọ. “Àmọ́ báyìí, ó ti di pé tó bá wu èèyàn, ó lè jáwèé fẹ́ni tó fẹ́.”
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ẹ̀sìn àti àjọ tí wọ́n ti wà tipẹ́ máa ń ṣèrànwọ́ láti mú kí ìdílé fẹsẹ̀ múlẹ̀. Àmọ́ báyìí, apá wọn ò ká a mọ́ láti mú káwọn èèyàn dáwọ́ bí ìkọ̀sílẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i dúró. Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀ràn ti Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì níbi tí wọ́n ti ka ìgbéyàwó sí mímọ́. Lọ́dún 1983, àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì náà dẹwọ́ òfin wọn lórí ìdè ìgbéyàwó débí tó fi rọrùn fáwọn ọmọ ìjọ láti máa fòpin sí ìgbéyàwó wọn. Látàrí èyí, látìgbà náà wá, ṣe ni ìgbéyàwó ń tú ká lọ ràì.
Ó dájú pé ìdè tó de ìgbéyàwó pọ̀ ò lágbára tó bẹ́ẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n gbogbo ohun tó ń fà á kọ́ lèèyàn lè tètè rí. Kódà, ohun pàtàkì míì tún wà tó ń fà á tí gbogbo nǹkan fi ń dorí kodò láwùjọ, tó sì tún fà á tí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó fi ń tú ká, ọ̀pọ̀ jù lọ láàárín ọmọ aráyé ni ò sì mọ̀ ọ́n.
Ohun Kan Tó Fara Sin Tó Ń Fa Ìjì Náà
Bíbélì sọ fún wa pé Sátánì Èṣù tó fìmọtara-ẹni-nìkan bora bí aṣọ, ń ta jàǹbá tí kò ṣeé fojú rí fún ayé yìí, ṣe ni jàǹbá ọ̀hún sì ń pọ̀ sí i. Kí ló fà á? Ohun tó fà á ni pé wọ́n ti lé e kúrò lọ́run, inú burúkú sì ń bí i. Àní sẹ́, ó ti pinnu pé gbogbo agbára òun lòun á fi kó “ègbé” àti ìdààmú bá aráyé, ọ̀kan lára ohun tó ń na ọwọ́jà ìbínú burúkú ẹ̀ sì ni ètò ìdílé tí Ọlọ́run dá sílẹ̀.—Ìṣípayá 12:9, 12.
Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa rí lẹ́yìn tí wọ́n bá lé Èṣù kúrò lọ́run, ó sọ pé: “Nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (Mátíù 24:12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan tó fara jọ ìyẹn náà nígbà tó kọ̀wé pé: “Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá [tàbí, láàárín ẹbí], aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:2-4) Àwọn ìwà ìríra bẹ́ẹ̀ ti wà tipẹ́ kò kàn pọ̀ tó báyìí ni, ẹnu àkókò tiwa yìí ló wá gogò sí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ṣe ń rí i báyìí.
Látàrí ìjì tó ń rọ́ lu ètò ìgbéyàwó báyìí, kí la lè ṣe láti dáàbò bo ara wa ká bàa lè mú kí ìgbéyàwó wa jẹ́ èyí tó máa láyọ̀ tó sì máa wà pẹ́ títí? Àpilẹ̀kọ tó máa tẹ̀ lé èyí á yànàná ìbéèrè yìí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
“Láyé tó jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ làwọn èèyàn máa ń ju ohun tí wọn ò bá ti nílò mọ́ nù yìí, ọwọ́ kan náà làwọn èèyàn fi ń mú ọ̀rọ̀ àjọṣe tó wà láàárín tọkọtaya.”—SANDRA DAVIS, ÒGBÓǸKANGÍ AMÒFIN NÍPA Ọ̀RÀN ÌDÍLÉ
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
“Kì í Fìdí Múlẹ̀ Tó Ìgbéyàwó”
Ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin ló ń gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó. Àmọ́, láti ibùdó tí wọ́n ti ń ṣèkáwọ́ àrùn tí wọ́n sì ti ń dènà rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn U.S. Centers for Disease Control and Prevention, wọ́n sọ pé, irú àwọn àjọgbé bẹ́ẹ̀ “kì í fìdí múlẹ̀ tó ìgbéyàwó.” Ṣe làwọn kan lára àwọn tó ń gbé pọ̀ yìí ń bára wọn gbé láti lè wo bí wọ́n ṣe bára wọn mu tó ṣáájú kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. Tí wọ́n bá jọ gbé pọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, ṣó máa mú kí ìgbéyàwó wọn máà níṣòro bí wọ́n bá wá fẹ́ra wọn sílé? Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Journal of Marriage and Family, tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó ṣe sọ, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwé ìròyìn ọ̀hún sọ pé: “Gbígbé pọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó wà lára àwọn ohun tó ń fà á tí ìgbéyàwó kì í fi í dùn bó ṣe yẹ. . . , tí ìṣòro fi máa ń pọ̀ nínú ìdílé, tí . . . ìgbéyàwó sì fi máa ń tètè tú ká.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ipa Tí Ẹ̀mí Gígùn Ń Ní Lórí Ìgbéyàwó
Ẹ̀mí àwọn èèyàn máa ń gùn gan-an lóde òní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó wuni lèyí, síbẹ̀ ohun ìdùnnú yìí ti fi kún ìṣòro tó wà nínú ìgbéyàwó. Lóde òní, ìkọ̀sílẹ̀ ló ń fòpin sí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó tó jẹ́ pé ikú ló máa ń fòpin sí i tẹ́lẹ̀. Ṣàkíyèsí ìṣòro kàyéfì kan tó máa ń dààmú àwọn obìnrin tí wọ́n ti pẹ́ lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ láàárín àwọn ará orílẹ̀-èdè Japan. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Washington Post ṣe sọ, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ pè é ní “ìṣòro tí ọkọ tó fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ máa ń kó báni.” Nígbà tí obìnrin kan tó ti ṣègbéyàwó láti nǹkan bí ogójì ọdún sẹ́yìn ń rántí ìgbà tí ọkọ rẹ̀ fẹ̀yìn tì, ó sọ pé gbogbo èrò òun ni pé: “Mo ní láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí ni. Ohun tí mò ń fojú rí torí pé mo ní láti máa ṣe gbogbo nǹkan fún un ni ṣáá tó bá ti ibi iṣẹ́ dé nìkan ti tó. Àmọ́ kí n tún wá máa wò ó nílé báyìí ti kọjá ohun tí mo lè fara dà.”