Fífi Ìjẹ́kánjúkánjú Sọ Ìhìn Rere Náà
1 A ń fi ìmọrírì wa jíjinlẹ̀ fún àwọn ìlérí Ìjọba Ọlọ́run hàn nípa nínípìn-ín tọkàntọkàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. A ní láti fi ìjẹ́kánjúkánjú kópa nínú iṣẹ́ yìí. Èé ṣe? Nítorí pé àwọn òṣìṣẹ́ kò tó nǹkan, òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí ń sún mọ́lé, ìwàláàyè àwọn tí ó sì wà ní ìpínlẹ̀ wa wà nínú ewu. (Ìsík. 3:19; Mát. 9:37, 38) Irú ẹrù iṣẹ́ wíwúwo bẹ́ẹ̀ ń béèrè fún ìsapá wa dídára jù lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Báwo ni a ṣe lè fi ìjẹ́kánjúkánjú hàn nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá wa? Nípa mímúra àwọn ìgbékalẹ̀ dídára sílẹ̀ ṣáájú, nípa jíjẹ́ aláápọn ní wíwá àwọn ènìyàn kàn níbikíbi tí a bá ti lè rí wọn, nípa pípa àkọsílẹ̀ pípéye nípa gbogbo àwọn tí ó fi ọkàn ìfẹ́ hàn mọ́, kí a sì pa dà lọ ní kánmọ́ láti ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́ yẹn, àti nípa rírántí pé níwọ̀n bí ó ti kan ìwàláàyè, a gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Àwọn ìdámọ̀ràn tí ó tẹ̀ lé e yìí lè ṣèrànwọ́ bí a ti ń múra sílẹ̀ láti fi ìjẹ́kánjúkánjú sọ ìhìn rere náà fúnni ní February. Ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, ni a óò fi lọni.
2 Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kan nípa mímẹ́nuba àwọn ìṣòro mélòó kan tí a ń dojú kọ ládùúgbò ní ṣókí, lẹ́yìn náà, o lè sọ pé:
◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe kàyéfì pé: ‘Irú ọjọ́ ọ̀la wo ni òun ń fẹ́ fún wa?’ Báwo ni ìwọ yóò ṣe dáhùn ìyẹn? [Jẹ́ kí ó fèsì.] O ha mọ̀ pé, ní kedere, Bíbélì ṣàlàyé ìfẹ́ inú Ọlọ́run fún aráyé àti àwọn ìgbésẹ̀ tí òun ń gbé láti mú un ṣẹ bí?” Ṣí i sí ojú ewé 8 nínú ìwé Walaaye. Ka Aísáyà 45:18 ní ìpínrọ̀ 5 àti àlàyé tí a ṣe lórí rẹ̀ ní ìpínrọ̀ 6. Ṣí i sí àwòrán tí ó wà ní ojú ewé 12 àti 13 láti ṣàkàwé ohun tí èyí túmọ̀ sí fún ọjọ́ ọ̀la wa. Ka Aísáyà 11:6-9 ní ìpínrọ̀ 12. Fi ìwé náà lọni fún ọrẹ ₦80, kí o sì ṣètò àkókò rírọgbọ láti pa dà wá láti máa bá ìjíròrò náà nìṣó.
3 O lè pa dà ṣiṣẹ́ lórí ìjíròrò àkọ́kọ́ lórí Aísáyà 45:18, pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ ṣókí yìí:
◼ “Nígbà ìbẹ̀wò mi tí ó kẹ́yìn, a sọ̀rọ̀ nípa ìlérí Ọlọ́run láti ṣètò àwùjọ ilẹ̀ ayé tuntun fún aráyé. [Pe àfiyèsí sí àwòrán tí ó wà ní ojú ewé 12 àti 13 nínú ìwé walaaye lẹ́ẹ̀kan sí i.] Ìwọ yóò ha fẹ́ kí ìdílé rẹ gbádùn irú ipò onídùnnú bẹ́ẹ̀ bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìbéèrè náà ni pé, Báwo ni àwọn ìlérí Ọlọ́run ti ṣeé gbára lé tó? Jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí ohun tí òun fúnra rẹ̀ sọ.” Ka Aísáyà 55:11 ní ìpínrọ̀ 8 ní ojú ewé 9. Béèrè ìbéèrè tí a tẹ̀ fún ìpínrọ̀ 8 ní ojú ewé 9, kí o sì ka ìdáhùn, àti gbólóhùn tí ó gbẹ̀yìn nínú ìpínrọ̀ náà jáde. Mẹ́nu kan ìpèsè ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣètò láti wá ṣàṣefihàn rẹ̀ ní ìgbà míràn.
4 Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ tí ń dàníyàn nípa àwọn ìṣòro tí ń pọ̀ sí i tí ń dojú kọ aráyé, o lè sọ ohun kan bí èyí nígbà ìkésíni àkọ́kọ́:
◼ “Gbogbo àwọn tí mo bá pàdé ní ń ṣàníyàn nípa àwọn ìṣòro tí a ń dojú kọ ní àdúgbò wa. [Mẹ́nu kan díẹ̀.] Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, àwọn òṣèlú ti ṣèlérí láti mú ojútùú wíwà pẹ́ títí wá, àwọn kan sì ti gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ni o rò pé ó fà á tí àwọn ipò fi ń burú sí i? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì pèsè àlàyé kan tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò tí ì ronú lé lórí rí. Ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe ogun kan tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run. Ṣàkíyèsí àbájáde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Ìṣípayá 12:9.” Ka ẹsẹ náà, lẹ́yìn náà, ṣí ìwé walaaye sí ojú ewé 20 àti 21. Lo àwòrán náà láti ṣàlàyé ipa tí Sátánì ń kó nínú àlámọ̀rí ayé. Fi ìwé náà lọni fún ọrẹ ₦80, kí o sì wéwèé láti pa dà wá láti jíròrò bí Ọlọ́run yóò ṣe yanjú àwọn ìṣòro aráyé.
5 Bí o bá ṣèlérí láti pa dà wá láti ṣàlàyé ojútùú tí Ọlọ́run ní sí àwọn ìṣòro tòní, o lè gbìyànjú ọ̀nà ìyọsíni yìí:
◼ “Mo ṣe ìsapá àrà ọ̀tọ̀ láti pa dà wá, kí a lè máa bá ìjíròrò wa nìṣó lórí ojútùú gidi sí àwọn ìṣòro tí ń dojú kọ aráyé. Nígbà ìbẹ̀wò mi tí ó kẹ́yìn, a rí i pé Bíbélì fi Sátánì Èṣù hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé lọ́nà. Níwọ̀n bí òun ti jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tí ó lágbára ju ènìyàn lọ, o ha rò pé ọ̀nà kan wà láti mú agbára ìdarí rẹ̀ kúrò bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jọ̀wọ́ kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ.” Ka Ìṣípayá 20:1-3, kí o sì ṣàlàyé rẹ̀. Nípa lílo àwòrán tí ó wà ní ojú ewé 4 àti 5 nínú ìwé Ìmọ̀, fi bí àwọn nǹkan yóò ti rí láìsí agbára ìdarí Sátánì hàn. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni, kí o sì sakun láti bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lójú ẹsẹ̀.
6 Pẹ̀lú bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ní ọkàn ìfẹ́ nínú àyíká, o lè sọ ohun kan bí èyí láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kan:
◼ “A ti rí i pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ní ń ṣàníyàn nípa sísọ afẹ́fẹ́, omi, àti oúnjẹ wa di eléèérí. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ipò tí àyíká wà ti ń wu ìwàláàyè léwu. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá ilẹ̀ ayé, kí ni o rò pé yóò ṣe nípa èyí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì sọ pé Ọlọ́run yóò mú kí a jíhìn fún ọ̀nà tí a gbà lo pílánẹ́ẹ̀tì yí. [Ka Ìṣípayá 11:18b.] Ronú gbígbé lórí ilẹ̀ ayé tí ó bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ìsọdèérí!” Tọ́ka sí ìlérí Ọlọ́run fún párádísè kan, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú Ìṣípayá 21:3, 4. Fi àwòrán tí ó wà ní ojú ewé 12 àti 13 nínú ìwé walaaye hàn. Fi ìwé náà lọni fún ọrẹ ₦80, kí o sì ṣètò láti pa dà wá.
7 Nígbà tí o bá pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tí ó fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú Párádísè ilẹ̀ ayé, o lè sọ pé:
◼ “Nígbà ìbẹ̀wò mi tí ó kẹ́yìn, a fohùn ṣọ̀kan pé láti yanjú ìṣòro ilẹ̀ ayé tí a sọ di eléèérí, Ọlọ́run yóò ní láti dá sí àlámọ̀rí ènìyàn. Ṣùgbọ́n ìbéèrè náà ni pé, Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti là á já sínú ayé tuntun òdodo àtọwọ́-Ọlọ́run-dá?” Ka Jòhánù 17:3. Ké sí onílé láti lo àǹfààní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ tí a ń ṣe, láti jèrè ìmọ̀ àrà ọ̀tọ̀ yí.
8 Ẹ wo àǹfààní tí ó jẹ́ láti lò wá gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ tí ń kórè lóde òní, kí a sì ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí ń gba ẹ̀mí là! Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú fífi ìjẹ́kánjúkánjú sọ ìhìn rere náà, ‘ní mímọ̀ pé òpò wa kì í ṣe asán.’—1 Kọ́r. 15:58.