ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/97 ojú ìwé 1
  • “Gbé Agbo Ilé Rẹ Ró”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Gbé Agbo Ilé Rẹ Ró”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ṣíṣàjọpín Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Máa Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ríran Àwọn Ìdílé Lọ́wọ́ Láti Ní Ọjọ́ Ọ̀la Wíwà Pẹ́ Títí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 3/97 ojú ìwé 1

“Gbé Agbo Ilé Rẹ Ró”

1 Ní kedere, nínú gbogbo ẹgbẹ́ àwùjọ kárí ayé, ìgbésí ayé ìdílé ń fọ́ sí wẹ́wẹ́. Ayé Sátánì ń yíràá nínú ẹ̀tàn àti ìwà pálapàla. (1 Jòh. 5:19) Èyí tẹnu mọ́ bí ó ti jẹ́ kánjúkánjú tó fún wa láti ‘gbé agbo ilé wa ró,’ kí a sì kọ́ àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n ṣe lè ṣe bákan náà fún tiwọn.—Òwe 24:3, 27, NW.

2 Àwọn Ìlànà Bíbélì Jẹ́ Ààbò: Àṣírí ayọ̀ ìdílé tòótọ́ ń bẹ nínú fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Òtítọ́ lílágbára wọ̀nyí ń ṣàǹfààní fún gbogbo mẹ́ńbà nínú agbo ilé ní gbogbo apá ìgbésí ayé. Ìdílé tí ó bá ń fi wọ́n sílò yóò láyọ̀, yóò sì gbádùn àlàáfíà Ọlọ́run.—Fi wé Aísáyà 32:17, 18.

3 Àwọn ìlànà tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé agbo ilé wa ró ni a tò lẹ́sẹẹsẹ lọ́nà tí ó mọ níwọ̀n nínú ìwé tuntun náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Orí kọ̀ọ̀kan parí pẹ̀lú àpótí ẹ̀kọ́ tí ń ranni lọ́wọ́ tí ó ń tẹnu mọ́ àwọn ìlànà tí àwọn mẹ́ńbà ìdílé gbọ́dọ̀ rántí. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn àpótí wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbéèrè náà, “Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì wọ̀nyí ṣe lè ṣèrànwọ́ fún . . . ?” Èyí ń pe àfiyèsí sí àwọn èrò Ọlọ́run, kí a lè mọ ìrònú rẹ̀ lórí kókó ẹ̀kọ́ tí a ń jíròrò.—Aísá. 48:17.

4 Di ojúlùmọ̀ ìwé náà. Kọ́ láti ṣàwárí àwọn ìlànà tí ó lè ṣèrànwọ́ nígbà tí onírúurú ìṣòro bá dìde. Ìwé náà jíròrò irú àwọn ọ̀ràn bí ìwọ̀nyí: ohun tí ó yẹ kí ẹnì kan wò nígbà tí ó bá ń ṣàgbéyẹ̀wò ẹnì kan tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ alábàáṣègbéyàwó lọ́la (orí 2), àwọn kọ́kọ́rọ́ pàtàkì tí ó wà fún ayọ̀ ìgbéyàwó wíwà pẹ́ títí (orí 3), bí àwọn òbí ṣe lè tọ́ àwọn ọ̀dọ́langba wọn láti dàgbà di ẹni tí ó wúlò, olùbẹ̀rù Ọlọ́run (orí 6), bí a ṣe lè dáàbò bo ìdílé kúrò lọ́wọ́ agbára apanirun (orí 8), àwọn ìlànà tí ó lè ran àwọn ìdílé olóbìí kan lọ́wọ́ láti kẹ́sẹ járí (orí 9), ìrànwọ́ tẹ̀mí fún àwọn ìdílé tí ìmukúmu àti ìwà ipá ń dà láàmú (orí 12), ohun tí a lè ṣe nígbà tí ìdè ìgbéyàwó bá fẹ́ já (orí 13), ohun tí a lè ṣe láti bọlá fún àwọn òbí àgbàlagbà (orí 15), àti bí a ṣe lè wá ọjọ́ ọ̀la wíwà pẹ́ títí fún ìdílé ẹni (orí 16).

5 Lo Ìwé Tuntun Náà Lẹ́kùn-ún Rẹ́rẹ́: Bí ìwọ kò bá tí ì ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, èé ṣe tí o kò fi kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ayọ̀ Ìdílé pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan? Pẹ̀lúpẹ̀lù, nígbàkigbà tí àwọn ìṣòro tàbí ìpèníjà tuntun bá dojú kọ ìdílé rẹ, ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àkòrí tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìwọ̀nyí nínú ìwé náà, kí o sì ronú tàdúràtàdúrà nípa bí o ṣe lè fi ìmọ̀ràn náà sílò. Ní àfikún sí i, ní March, jẹ́ ọ̀làwọ́ ní ṣíṣètò àkókò fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá kí o baà lè sakun láti fi ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé sóde fún ọ̀pọ̀ ènìyàn bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.

6 Àwọn ìdílé tí ń fi ìfọkànsìn Ọlọ́run ṣèwà hù yóò lókun nípa tẹ̀mí, wọn yóò ṣọ̀kan, wọn yóò sì múra sílẹ̀ dáradára láti kápá àwọn ìkọlù Sátánì. (1 Tím. 4:7, 8; 1 Pét. 5:8, 9) Ẹ wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó pé a ní ìtọ́ni àtọ̀runwá láti ọ̀dọ̀ Olùdásílẹ̀ ìdílé!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́