Ìmọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ń Dáhùn Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè
1 Ṣáájú kí o tó ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́, ó ṣeé ṣe kí o ti ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí o kò lè dáhùn nípa ìgbésí ayé. Wo bí o ti láyọ̀ tó láti rí àwọn ìdáhùn tí a gbé karí Bíbélì sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn! Nísinsìnyí o lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rí àwọn ìdáhùn kan náà wọ̀nyẹn. (Fi wé Tímótì Kejì 2:2.) O lè bá wọn ṣàjọpín ìmọ̀ Ọlọ́run tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 17:3) Ṣùgbọ́n, báwo ni o ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti mọrírì ìníyelórí ìmọ̀ yí? Ó dára, ronú nípa àwọn ìbéèrè tí òtítọ́ dáhùn fún ọ. Kí ni àwọn olùwá òtítọ́ ní ìfẹ́ ọkàn láti mọ̀? Ríronú lọ́nà yí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun lọni. Àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń múra sílẹ̀ fún ìjẹ́rìí ní oṣù June.
2 Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí ìjìyà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nínú ayé, ó ṣeé ṣe kí ìdáhùnpadà dídára wà sí ìyọsíni yìí:
◼ “Nígbà tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ tàbí nígbà tí ìwà ọ̀daràn tàbí ìwà ipá bá ń pọ̀ sí i, àwọn ènìyàn sábà máa ń béèrè nípa ìdí tí irú àwọn ohun búburú bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀. Kí ni yóò jẹ́ ìdáhùn rẹ?” Jẹ́ kí ẹni náà fèsì kí o sì fi ìmọrírì hàn fún èsì rẹ̀. Lẹ́yìn náà ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 8 kí o sì pe àfiyèsí sí ohun tí ó wà ní ìpínrọ̀ 2. Ṣàlàyé pé ìwé yìí gbé àwọn àlàyé Bíbélì kalẹ̀ nípa ìdí tí ohun búburú fi ń ṣẹlẹ̀, kí o sì sọ pé: “Inú mi yóò dùn láti fi ìwé yìí sílẹ̀ fún ọ ní ọrẹ ₦55.”
3 Nígbà tí o bá ń pa dà ṣe ìkésíni síbi tí o ti fi ìwé “Ìmọ̀” sóde, o lè sọ pé:
◼ “Mo ní ọkàn ìfẹ́ nínú ìparí èrò tí o dé nípa ìdí tí ìjìyà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nínú ayé. O ha gbà pẹ̀lú ìdáhùn Bíbélì gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú ìwé náà bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ka ìpínrọ̀ 17 ní ojú ìwé 77 nínú ìwé Ìmọ̀, kí o sì sọ pé o fẹ́ ka Róòmù 9:14 láti inú Bíbélì onílé náà. Lẹ́yìn náà sọ pé: “Ìhìn rere náà ni pé Ọlọ́run kì í fi àìṣèdájọ́ òdodo fa ìrora àti ìjìyà fún wa. Ó ti ṣèlérí láti fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú àlàáfíà àti ayọ̀. A pe àkọlé orí àkọ́kọ́ nínú ìwé yìí ní ‘O Lè Ní Ọjọ́-Ọ̀la Aláyọ̀!’ Èmi yóò fẹ́ láti ṣàlàyé bí ìyẹn ṣe lè jóòótọ́ fún ìwọ àti àwọn olólùfẹ́ rẹ.” Ṣí i sí orí 1, kí o sì ṣàṣefihàn ọ̀nà tí a ń gbà kẹ́kọ̀ọ́. Kárí apá púpọ̀ nínú orí náà bí ó bá ti yẹ lábẹ́ àyíká ipò náà.
4 O lè yàn láti lo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ojú ìwé 6 nínú ìwé kékeré náà, “Ìjíròrò Bibeli,” lábẹ́ àkòrí náà “Ọjọ́ Ogbó/Ikú”:
◼ “O ha ti béèrè rí pé, ‘Ṣé ikú ni òpin ohun gbogbo? Tàbí ohun mìíràn ha wà lẹ́yìn ikú bí?’ [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí tí a lè ní nípa ikú. [Ka Oníwàásù 9:5, 10.] Ó tún fi hàn pé ìrètí gidi wà fún àwọn tí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́. [Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ìpínrọ̀ 13 ní ojú ìwé 84; ka àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tí ó wà ní Jòhánù 11:25, kí o sì ṣàlàyé wọn.] Orí yìí látòkè délẹ̀ ni a lò láti dáhùn ìbéèrè náà, Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú? Ẹ̀dà yí lè jẹ́ tìrẹ fún ọrẹ ₦55.”
5 Nígbà tí o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, o lè túbọ̀ sọ ara rẹ dojúlùmọ̀ sí i kí o sì sọ lẹ́yìn náà pé:
◼ “Ní ìṣáájú, a sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹnì kan bá kú. Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé ìyè èyíkéyìí lẹ́yìn ikú yóò jẹ́ nínú ọ̀run tàbí nínú hẹ́ẹ̀lì. Ṣùgbọ́n o ha ti ronú rí nípa ṣíṣeéṣe náà pé kí àwọn òkú wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín gan-an bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, àwọn tí a jí dìde yóò wà lára àwọn ọlọ́kàn tútù tí yóò jogún ayé. [Ka Orin Dáfídì 37:11, 29, lẹ́yìn náà, jíròrò ìpínrọ̀ 20 ní ojú ìwé 88 nínú ìwé Ìmọ̀.] Ìrètí yẹn ti tu àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí wọ́n ti gbé nínú ìbẹ̀rù ikú rí nínú. Ìwé yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ọ̀ràn náà dáradára sí i. Ṣé kí n ṣàṣefihàn bí ó ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́?”
6 Bí o bá ń fẹ́ ìgbékalẹ̀ rírọrùn, o lè gbìyànjú èyí:
◼ “Èmi yóò fẹ́ láti fi àwòrán kan hàn ọ́ nínú ìwé yìí, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Àwòrán yìí kò ha lẹ́wà bí?” Ṣí ìwé náà kí onílé lè rí ojú ìwé 4 àti 5. Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ojú ìwé 5. Parí ọ̀rọ̀ rẹ nípa sísọ pé: “O lè ní ìwé yìí fún kíkà tìrẹ ní ọrẹ ₦55.” Wádìí ìgbà rírọgbọ tí ìwọ lè pa dà wá láti ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́ tí ó fi hàn.
7 A ní ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí ó dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì ní ìgbésí ayé. Múra sílẹ̀ taápọntaápọn, Jèhófà yóò sì bù kún ìsapá rẹ láti bá àwọn tí ń wá òtítọ́ ṣàjọpín ìsọfúnni tí ń fúnni ní ìyè yí.