ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/96 ojú ìwé 8
  • Ìmọ̀ Ọlọrun Tòótọ́ Ń Sinni Lọ sí Ìyè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìmọ̀ Ọlọrun Tòótọ́ Ń Sinni Lọ sí Ìyè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Èyí Túmọ̀ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Jèrè Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ìmọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ń Dáhùn Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Títan Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun Kálẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 3/96 ojú ìwé 8

Ìmọ̀ Ọlọrun Tòótọ́ Ń Sinni Lọ sí Ìyè

1 Jesu sọ nínú àdúrà sí Bàbá rẹ̀ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ iwọ, Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo naa sínú.” (Joh. 17:3) Ẹ wo irú èrè ńlá tí ìyẹ́n jẹ́! Nípa lílo ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, a lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí wọ́n ní láti ṣe láti wà láàyè títí láé. Kí ni a lè sọ láti ru ọkàn-ìfẹ́ wọn sókè, kí ó sì sún wọn láti fẹ́ láti ka ìwé Ìmọ̀?

2 O lè lo ìgbékalẹ̀ tí ó gbé Bibeli jáde gẹ́gẹ́ bí orísun ìtọ́sọ́nà ṣíṣeé mú lò, nípa sísọ pé:

◼ “A ń jíròrò pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wa nípa ibi tí a ti lè rí orísun ìtọ́sọ́nà ṣíṣeé mú lò láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Nígbà kan, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn kọ́kọ́ máa ń yẹ Bibeli wò. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn ti yí padà; ọ̀pọ̀ ń ṣiyè méjì nípa Bibeli, ní wíwulẹ̀ kà á sí ìwé kan tí àwọn ènìyàn kọ. Kí ní èrò rẹ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìdí dáradára kan wà tí a fi lè sọ pé Bibeli gbéṣẹ́ ní ọjọ́ wa. [Ka 2 Timoteu 3:16, 17.] Àwọn ìlànà Bibeli ṣeé fi sílò nísinsìnyí gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣeé fi sílò nígbà tí Ọlọrun mí sí kíkọ Bibeli.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ìwé 16, kí o sì ṣàlàyé ṣókí lórí ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́ tí a rí nínú Ìwàásù Jesu Lórí Òkè. Ka àyọkà tí ó wà ní ìpínrọ̀ 11 tàbí èyí tí ó wà ní ìpínrọ̀ 13. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́, kí o sì ṣètò láti padà wá láti dáhùn ìbéèrè náà, Báwo ni àwa fúnra wa ṣe lè jàǹfààní láti inú ìmọ̀ tí ó wà nínú Bibeli?

3 Níwọ̀n bí àdúrà tí jẹ́ àkòrí ọ̀rọ̀ kan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí, o lè fẹ́ láti jíròrò rẹ̀ nípa bíbéèrè pé:

◼ “Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro líle koko tí a gbọ́dọ̀ dojú kọ nínú ìgbésí ayé òde òní, ìwọ́ ha rò pé àdúrà lè jẹ́ ìrànwọ́ gidi fún wa? [Dánu dúró fún èsì.] Ọ̀pọ̀ ronú pé àwọ́n ti sún mọ́ Ọlọrun nípa gbígbàdúrà sí i àti pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ti fún wọn ní okun inú, ohun tí Bibeli sì ṣèlérí gan-an nìyẹn. [Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ìwé 156, kí o sì ka Filippi 4:6, 7.] Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹnì kan lè ronú pé a kì í dáhùn àdúrà òun nígbà míràn. Àkòrí yìí jíròrò ‘Bí O Ṣe Lè Súnmọ́ Ọlọrun.’ [Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye owó tí a ń fi síta.] Orí yìí tún ṣàlàyé bí a ṣe lè fetí sí Ọlọrun, níwọ̀n bí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ kì í ti í ṣe alápá kan. A lè jíròrò èyí nígbà míràn tí mo bá padà wa.”

4 Ìwọ yóò ha fẹ́ láti gbìyànjú ìyọsíni tààràtà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan bí? Ọ̀kan nìyí tí ó lè yọrí sí rere fún ọ:

◼ “A ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ lọni. Ìwọ́ ha ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rí bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jẹ́ kí ń fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ń lò hàn ọ́.” Fi ìwé Ìmọ̀ hàn án, ṣí i sí ojú ìwé 3 kí onílé lè rí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé náà, kí o sì béèrè pé, “O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa ohun tí Bibeli ní í sọ lórí àwọn kókó wọ̀nyí bí?” Ṣí i sí orí tí onílé fi ọkàn-ìfẹ́ hàn sí jù lọ, kí o sì ka àwọn ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀. Ṣàlàyé pé ìwọ yóò fẹ́ láti fi bí a ṣe ń kárí àwọn ìsọfúnni yìí nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa hàn ní ṣókí. Yálà o bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, fí ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye owó tí a ń fi síta.

5 Lónìí, ọ̀pọ̀ jaburata ènìyàn ń dáhùn padà sí ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọrun tòótọ́ náà. (Isa. 2:2-4) Ó jẹ́ àǹfààní wa láti ran iye ẹni tí ó bá ṣeé ṣe lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jehofa, kí ó sì sìn wọ́n lọ sí ìyè.—1 Tim. 2:4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́