ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • A gbé òkè Jèhófà ga (1-5)

        • Wọ́n á fi idà rọ ohun ìtúlẹ̀ (4)

      • Ọjọ́ Jèhófà máa tẹ àwọn agbéraga lórí ba (6-22)

Àìsáyà 2:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:1

Àìsáyà 2:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 8:3
  • +Sm 72:1, 8; 86:9; Mik 4:1-3; Hag 2:7; Iṣe 10:34, 35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 142, 154

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    12/2016, ojú ìwé 3

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2007, ojú ìwé 24-25

    12/1/1994, ojú ìwé 11

    4/1/1994, ojú ìwé 15-17

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 38-44

    Jí!,

    4/22/1996, ojú ìwé 11

    Akoso, ojú ìwé 24

Àìsáyà 2:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìtọ́ni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 8:23
  • +Ais 54:13
  • +Ais 51:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2016, ojú ìwé 23

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 2 2016 ojú ìwé 13

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    12/2016, ojú ìwé 3

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 44-45

    Akoso, ojú ìwé 24

    “Sawo O!,” ojú ìwé 28

Àìsáyà 2:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tún nǹkan ṣe.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 46:9
  • +Sm 72:7; Ais 60:18; Mt 26:52

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    12/2016, ojú ìwé 3

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2000, ojú ìwé 26-27

    4/15/1997, ojú ìwé 13-15, 22

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 37-38, 45-48

    Jí!,

    4/22/1996, ojú ìwé 4, 8-10

Àìsáyà 2:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 60:19, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 48

Àìsáyà 2:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 31:16, 17
  • +Di 18:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 49-50

Àìsáyà 2:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:15, 16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 50

Àìsáyà 2:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 28:1, 2; 33:1, 7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 50-51

Àìsáyà 2:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 50-51

Àìsáyà 2:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 51

Àìsáyà 2:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “rẹ ìgbéraga àwọn èèyàn wálẹ̀.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 51

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    12/1/1994, ojú ìwé 11

Àìsáyà 2:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 1:4, 7
  • +Ais 66:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 51-53, 54-56

Àìsáyà 2:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “igi óákù.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 51

Àìsáyà 2:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 51

Àìsáyà 2:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 51

Àìsáyà 2:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:22; Isk 27:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 51

Àìsáyà 2:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “rẹ ìgbéraga àwọn èèyàn wálẹ̀.”

Àìsáyà 2:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 27:9

Àìsáyà 2:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 6:15
  • +Ais 2:10; 2Tẹ 1:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 53-54

Àìsáyà 2:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Àwọn ẹranko kéékèèké afọ́mọlọ́mú tó ń jẹ nǹkan run.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:22; 31:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 53-54

Àìsáyà 2:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 53-54

Àìsáyà 2:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí èémí rẹ̀ wà nínú ihò imú rẹ̀.”

Àwọn míì

Àìsá. 2:1Ais 1:1
Àìsá. 2:2Sek 8:3
Àìsá. 2:2Sm 72:1, 8; 86:9; Mik 4:1-3; Hag 2:7; Iṣe 10:34, 35
Àìsá. 2:3Sek 8:23
Àìsá. 2:3Ais 54:13
Àìsá. 2:3Ais 51:4
Àìsá. 2:4Sm 46:9
Àìsá. 2:4Sm 72:7; Ais 60:18; Mt 26:52
Àìsá. 2:5Ais 60:19, 20
Àìsá. 2:6Di 31:16, 17
Àìsá. 2:6Di 18:10
Àìsá. 2:7Di 17:15, 16
Àìsá. 2:82Kr 28:1, 2; 33:1, 7
Àìsá. 2:10Ẹk 20:18
Àìsá. 2:12Sef 1:4, 7
Àìsá. 2:12Ais 66:16
Àìsá. 2:161Ọb 10:22; Isk 27:25
Àìsá. 2:18Ais 27:9
Àìsá. 2:19Ifi 6:15
Àìsá. 2:19Ais 2:10; 2Tẹ 1:9
Àìsá. 2:20Ais 30:22; 31:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 2:1-22

Àìsáyà

2 Ohun tí Àìsáyà ọmọ Émọ́ọ̀sì rí nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù nìyí:+

 2 Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,*

Òkè ilé Jèhófà

Máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn òkè,+

A sì máa gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,

Gbogbo orílẹ̀-èdè á sì máa rọ́ lọ síbẹ̀.+

 3 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa lọ, wọ́n á sì sọ pé:

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sórí òkè Jèhófà,

Sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù.+

Ó máa kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,

A ó sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”+

Torí òfin* máa jáde láti Síónì,

Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì máa jáde láti Jerúsálẹ́mù.+

 4 Ó máa ṣe ìdájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,

Ó sì máa yanjú ọ̀rọ̀* láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn.

Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀,

Wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.+

Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,

Wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+

 5 Ẹ̀yin ilé Jékọ́bù, ẹ wá,

Ẹ jẹ́ ká rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà.+

 6 Torí o ti pa àwọn èèyàn rẹ, ilé Jékọ́bù tì.+

Torí àwọn nǹkan tó wá láti Ìlà Oòrùn ti kún ọwọ́ wọn;

Wọ́n ń pidán+ bí àwọn Filísínì,

Àwọn ọmọ àjèjì sì pọ̀ láàárín wọn.

 7 Fàdákà àti wúrà kún ilẹ̀ wọn,

Ìṣúra wọn kò sì lópin.

Ẹṣin kún ilẹ̀ wọn,

Kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn ò sì níye.+

 8 Àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí kún ilẹ̀ wọn.+

Wọ́n ń forí balẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,

Fún ohun tí wọ́n fi ìka ara wọn ṣe.

 9 Èèyàn wá ń forí balẹ̀, ó di ẹni tó rẹlẹ̀,

O ò sì lè dárí jì wọ́n.

10 Wọ inú àpáta, kí o sì fi ara rẹ pa mọ́ sínú iyẹ̀pẹ̀,

Torí bí Jèhófà ṣe wà níbí ń dẹ́rù bani,

Iyì rẹ̀ sì ga lọ́lá.+

11 Ojú èèyàn tó ń gbéra ga máa wálẹ̀,

A sì máa tẹrí ìgbéraga àwọn èèyàn ba.*

Jèhófà nìkan la máa gbé ga ní ọjọ́ yẹn.

12 Torí ọjọ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni.+

Ó ń bọ̀ wá sórí gbogbo ẹni tó ń gbéra ga àti ẹni gíga,

Sórí gbogbo èèyàn, ì báà jẹ́ ẹni gíga tàbí ẹni tó rẹlẹ̀,+

13 Sórí gbogbo igi kédárì Lẹ́bánónì tó ga, tó sì ta yọ

Àti sórí gbogbo igi ràgàjì* Báṣánì,

14 Sórí gbogbo òkè ńláńlá

Àti sórí gbogbo òkè tó ga,

15 Sórí gbogbo ilé gogoro àti gbogbo odi ààbò,

16 Sórí gbogbo ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+

Àti sórí gbogbo ọkọ̀ ojú omi tó wuni.

17 Ìgbéraga èèyàn máa wálẹ̀,

A sì máa tẹrí ìgbéraga àwọn èèyàn ba.*

Jèhófà nìkan la máa gbé ga ní ọjọ́ yẹn.

18 Àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí máa pòórá pátápátá.+

19 Àwọn èèyàn sì máa wọ ihò inú àpáta

Àti àwọn ihò inú ilẹ̀,+

Torí bí Jèhófà ṣe wà níbí ń dẹ́rù bani,

Iyì rẹ̀ sì ga lọ́lá,+

Nígbà tó dìde láti mi ayé jìgìjìgì, kó sì kó jìnnìjìnnì bá a.

20 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn èèyàn máa mú àwọn ọlọ́run wọn tí kò ní láárí, tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe,

Èyí tí wọ́n ṣe fúnra wọn kí wọ́n lè máa forí balẹ̀ fún un,

Wọ́n á sì jù wọ́n sí àwọn asín* àti àwọn àdán,+

21 Kí wọ́n lè wọ àwọn ihò inú àpáta

Àti inú àwọn pàlàpálá àpáta,

Torí bí Jèhófà ṣe wà níbí ń dẹ́rù bani,

Iyì rẹ̀ sì ga lọ́lá,

Nígbà tó dìde láti mi ayé jìgìjìgì, kó sì kó jìnnìjìnnì bá a.

22 Fún àǹfààní ara yín, ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn lásán mọ́,

Ẹni tí kò yàtọ̀ sí èémí ihò imú rẹ̀.*

Kí nìdí tí ẹ fi máa kà á sí?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́