Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí
Àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí ni àwọn ọ̀ràn tí a ní láti fún ní àfiyèsí ṣáájú ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ní Tuesday, April 2:
◼ A gbọ́dọ̀ fi àkókò gan-an àti ibi tí a óò tí ṣe ayẹyẹ náà tó gbogbo ènìyàn, títí kan olùbánisọ̀rọ̀, létí.
◼ A gbọ́dọ̀ wá irú búrẹ́dì àti wáìnì tí ó bá a mu wẹ́kú, kí wọ́n sì wà ní sẹpẹ́.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, February 1, 1985, ojú ìwé 17.
◼ A gbọ́dọ̀ gbé tábìlì, aṣọ tábìlì, àwo, àti ago wá sí gbọ̀ngàn ṣáájú, kí á sì gbé wọn sí ibi tí ó yẹ.
◼ A ní láti tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tí a óò ti pàdé ṣe, kí ó wà ní mímọ́ nigín-nigín ṣáájú àkókò.
◼ A gbọ́dọ̀ yan àwọn olùbójútó èrò àti àwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri, kí á sì fún wọn nítọ̀ọ́ni ṣáájú nípa ìgbésẹ̀ tí ó yẹ àti ẹrù iṣẹ́ wọn.
◼ A gbọ́dọ̀ ṣètò láti gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tí kò lera, tí kò sì ṣeé ṣe fún láti wà níbẹ̀.
◼ Nígbà tí a bá ṣètò fún ayẹyẹ tí ó ju ẹyọ kan lọ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìṣètò dáradára gbọ́dọ̀ wà láàárín àwọn ìjọ, kí ìkórajọpọ̀ tí kò pọn dandan má baà wà ní ẹnu ìta gbọ̀ngàn, ọ̀nà àbáwọlé, òpópónà, àti ibi ìgbọ́kọ̀sí.