Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí
Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ọdún yìí bọ́ sí ọjọ́ Thursday, April 1. Kí àwọn alàgbà fiyè sí àwọn ọ̀ràn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
◼ Ní ṣíṣètò àkókò fún ìpàdé náà, ẹ rí i dájú pé a kì yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri títí di ẹ̀yìn tí oòrùn bá wọ̀.
◼ Kí a fi àkókò tí a óò ṣe ayẹyẹ náà gan-an àti ibi tí a óò ti ṣe é tó gbogbo ènìyàn létí, títí kan olùbánisọ̀rọ̀.
◼ A gbọ́dọ̀ wá irú búrẹ́dì àti wáìnì tí ó bá a mu wẹ́kú, kí wọ́n sì wà ní sẹpẹ́.—Wo Ile-Iṣọ Naa, February 1, 1985, ojú ìwé 17.
◼ Kí a gbé àwo, ago, àti tábìlì àti aṣọ tí ó yẹ wẹ́kú wá sínú gbọ̀ngàn, kí a sì tò wọ́n ṣáájú àkókò.
◼ Kí a mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tí a óò ti pàdé wà ní mímọ́ nigín-nigín ṣáájú àkókò.
◼ Kí a yan àwọn olùbójútó èrò àti àwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri, kí a sì fún wọn nítọ̀ọ́ni ṣáájú nípa ìgbésẹ̀ tí ó yẹ àti ẹrù iṣẹ́ wọn.
◼ A gbọ́dọ̀ ṣètò láti gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tí kò lera, tí kò sì ṣeé ṣe fún láti wà níbẹ̀.
◼ Nígbà tí a bá ṣètò fún ìjọ tó ju ẹyọ kan lọ láti lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìṣètò dáradára gbọ́dọ̀ wà láàárín àwọn ìjọ, kí ìkórajọ tí kò pọndandan má bàa wà ní ibi àbáwọlé tàbí lẹ́nu ọ̀nà, lójú pópó, àti níbi ìgbọ́kọ̀sí.